ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 7/15 ojú ìwé 27-31
  • Ẹ Jẹ́ Ká Máa Lo Ìfaradà Bá a Ṣe Ń retí Ọjọ́ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Ká Máa Lo Ìfaradà Bá a Ṣe Ń retí Ọjọ́ Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìsàn Ò Mú Kí Wọ́n Jáwọ́
  • Béèyàn Ṣe Lè Fara Da Ikú Èèyàn Ẹni
  • Bá A Ṣe Lè Fara Da Onírúurú Ìṣòro
  • O Lè Fara Dà Á!
  • Ìfaradà—Ṣekókó fún Àwọn Kristian
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Ẹ Jẹ́ Kí Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Rẹ̀ Pé Pérépéré”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Má Ṣe Fi Ètò Jèhófà Sílẹ̀
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • ‘Ẹ Ronú Jinlẹ̀ Nípa Ẹni Tó Lo Ìfaradà’
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 7/15 ojú ìwé 27-31

Ẹ Jẹ́ Ká Máa Lo Ìfaradà Bá a Ṣe Ń retí Ọjọ́ Jèhófà

‘Ẹ pèsè ìfaradà kún ìgbàgbọ́ yín.’—2 PÉTÉRÙ 1:5, 6.

1, 2. Kí ni ìfaradà, kí sì nìdí táwa Kristẹni fi ní láti ní in?

ỌJỌ́ ńlá Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an. (Jóẹ́lì 1:15; Sefanáyà 1:14) Níwọ̀n bí àwa Kristẹni ti pinnu pé a ò ní ṣíwọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, à ń fi tọkàntara retí àkókò tó máa di mímọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àmọ́ ní báyìí ná, ayé ń kórìíra wa, wọ́n ń kẹ́gàn wa, wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, wọn tiẹ̀ ń pa àwọn kan lára wa pàápàá nítorí ìgbàgbọ́ wa. (Mátíù 5:10-12; 10:22; Ìṣípayá 2:10) Nítorí náà, a ní láti ní ìfaradà. Kí ni ìfaradà? Ìfaradà ni kéèyàn lè ní ìforítì nígbà ìṣòro. Àpọ́sítélì Pétérù rọ̀ wá pé: ‘Ẹ pèsè ìfaradà kún ìgbàgbọ́ yín.’ (2 Pétérù 1:5, 6) A ní láti ní ìfaradà, torí Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mátíù 24:13.

2 Àwọn ìṣòro míì tó tún ń bá wa fínra ni àìsàn, ikú èèyàn ẹni àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Ohun tí Sátánì sì ń wá ni pé kírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ mú ká sọ ìgbàgbọ́ wa nù. (Lúùkù 22:31, 32) Àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè fara da onírúurú ìṣòro. (1 Pétérù 5:6-11) Ẹ jẹ́ ká wo ìrírí mélòó kan tó fi hàn pé a lè máa fara da ìṣòro kí ìgbàgbọ́ wa sì má yingin bá a ṣe ń retí ọjọ́ Jèhófà.

Àìsàn Ò Mú Kí Wọ́n Jáwọ́

3, 4. Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé èèyàn lè máa fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣàìsàn.

3 Ní báyìí, Jèhófà kì í fi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn fún wa, àmọ́ ó máa ń fún wa lókun tá a fi lè fara da àìsàn. (Sáàmù 41:1-3) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sharon sọ pé: “Ńṣe ni mo gbọ́njú bá ara mi tí mò ń jókòó sínú kẹ̀kẹ́ arọ nígbà gbogbo. Látìgbà tí wọ́n ti bí mi ni mo ti ní àrùn tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ lè darí ìsọ̀rọ̀ àti iṣan ara bó ṣe yẹ [ìyẹn àrùn cerebral palsy]. Èyí ò jẹ́ kí n gbádùn ìgbà ọmọdé mi.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sharon kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ìlérí rẹ̀ pé aráyé á ní ìlera pípé lọ́jọ́ iwájú? Ó dẹni tó nírètí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń nira fún un gan-an láti rìn àti láti sọ̀rọ̀, inú rẹ̀ máa ń dùn láti wàásù. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, ó sọ pé: “Àìlera mi lè máa burú sí i o, àmọ́ àjọṣe àárín èmi àti Ọlọ́run àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí mo ní nínú Ọlọ́run ń gbé mi ró. Mo mà dúpẹ́ o, pé mo wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà àti pé Jèhófà ń tì mí lẹ́yìn!”

4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé kí wọ́n “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Lára nǹkan tó lè fa ìsoríkọ́ tàbí àárẹ̀ ọkàn ni ìjákulẹ̀ téèyàn máa ń ní nígbà tí nǹkan ò bá rí béèyàn ṣe rò. Ní 1993, Sharon kọ̀wé pé: “Àìlera mi mú kí n ka ara mi sẹ́ni tí ò wúlò rárá, . . . ìyẹn wá kó àárẹ̀ ọkàn tó kọjá sísọ bá mi fún ọdún mẹ́ta gbáko. . . . Àwọn alàgbà ń tù mí nínú, wọ́n sì ń gbà mí nímọ̀ràn . . . Jèhófà tún ń lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láti jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe tí ìrònú bá sorí ẹni kodò. Dájúdájú, Jèhófà bìkítà nípa àwa èèyàn rẹ̀ ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa.” (1 Pétérù 5:6, 7) Títí di báyìí, arábìnrin Sharon ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run bó ṣe ń retí ọjọ́ ńlá Jèhófà.

5. Kí ló fi hàn pé àwọn Kristẹni lè fara da másùnmáwo tó bùáyà?

5 Másùnmáwo tó bùáyà bá àwọn Kristẹni kan nítorí àwọn ohun tójú wọn ti rí sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, Harley rí bí ìjà tó le kú ṣe wáyé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, èyí sì mú kó máa lá àlákálàá nípa ogun. Ó máa ń lọgun látojú oorun pé: “Yéè, wọ́n dé o!” Tó bá wá jí, ńṣe lòógùn á bò ó. Àmọ́ ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe máa gbé ìgbé ayé tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, nígbà tó sì yá, àlá yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í rọjú kì í sì í wáyé lemọ́lemọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.

6. Báwo ni Kristẹni kan ṣe fara da ìṣòro kéèyàn máa hùwà lódìlódì?

6 Arákùnrin kan ní àrùn tó máa ń múni hùwà lódìlódì, èyí tó máa ń mú kó ṣòro fún un láti wàásù láti ilé dé ilé. Àmọ́ kò jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù torí ó mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ló máa yọrí sí fóun àtàwọn tó bá kọbi ara sí ohun tí wọ́n gbọ́. (1 Tímótì 4:16) Nígbà míì, àrùn yìí kì í jẹ́ kó lè dé ilé tó kàn. Àmọ́ ó ní: “Tó bá yá, ara mi á wálẹ̀, màá wá lọ sílé tó kàn màá sì tún gbìyànjú. Nítorí pé mi ò jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run kò bà jẹ́.” Yàtọ̀ sí òde ẹ̀rí, ó tún ṣòro fún arákùnrin yìí láti máa lọ sípàdé, àmọ́ ó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa bá àwọn ará pé jọ. Nítorí náà, ó máa ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti lọ sípàdé.—Hébérù 10:24, 25.

7. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù máa ń ba àwọn kan láti sọ̀rọ̀ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn tàbí láti wá sípàdé, kí ni wọ́n ń ṣe tó fi hàn pé wọ́n ní ìfaradà?

7 Ìbẹ̀rù ni ìṣòro àwọn Kristẹni míì. Irú ìbẹ̀rù tá à ń sọ yìí ni kí àyà èèyàn máa já jù tó bá rí àwọn nǹkan kan, tó bá wà láwọn ibì kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀rù lè máa ba àwọn Kristẹni kan láti sọ̀rọ̀ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn tàbí láti lọ sípàdé pàápàá. Ẹ̀yin ẹ wo bó ṣe máa ṣòro fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tó láti dáhùn nípàdé tàbí láti ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run! Síbẹ̀, wọn ò ṣíwọ́, ńṣe ni wọ́n ń fara dà á. A mọyì wíwá tí wọ́n ń wá sípàdé, a sì mọrírì ìlóhùnsí wọn gan-an ni.

8. Kí ló lè ṣèrànlọ́wọ́ jù lọ fẹ́ni tó wà nínú másùnmáwo?

8 Táwọn tí másùnmáwo bá bá lè máa sinmi kí wọ́n sì máa sùn dáadáa, ìyẹn lè jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wọn láti fara da ìṣòro wọn. Ó sì lè dáa pé kí wọ́n lọ rí dókítà. Àmọ́ ohun tó máa ṣèrànwọ́ jù ni pé kéèyàn gbára lé Ọlọ́run kó sì máa gbàdúrà. Sáàmù 55:22 sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” Nítorí náà, rí i dájú pé o “fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”—Òwe 3:5, 6.

Béèyàn Ṣe Lè Fara Da Ikú Èèyàn Ẹni

9-11. (a) Kí ni ò ní jẹ́ ká banú jẹ́ jù nígbà téèyàn ẹni bá kú? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Ánà ṣe lè ranni lọ́wọ́ tá ò fi ní banú jẹ́ jù nítorí ikú èèyàn ẹni?

9 Nígbà téèyàn ẹni bá kú, àdánù ńlá tó lè kóni sí ìbànújẹ́ tó bùáyà ni. Ábúráhámù sunkún nígbà tí Sárà aya rẹ̀ ọ̀wọ́n kú. (Jẹ́nẹ́sísì 23:2) Àní Jésù ọkùnrin pípé “da omijé” lójú nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú. (Jòhánù 11:35) Nítorí náà, kì í ṣe ohun tó burú pé kéèyàn banú jẹ́ nítorí ikú èèyàn ẹni. Àmọ́, àwọn Kristẹni mọ̀ pé àjíǹde òkú ń bọ̀. (Ìṣe 24:15) Nítorí náà, wọn kì í “kárísọ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí ti ń ṣe.”—1 Tẹsalóníkà 4:13.

10 Kí lèèyàn lè ṣe tí ò fi ní banú jẹ́ jù nígbà téèyàn rẹ̀ bá kú? Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. Tẹ́nì kan tá a fẹ́ràn bá rìnrìn àjò, a kì í banú jẹ́ púpọ̀ jù torí a mọ̀ pé a tún máa rí i tó bá dé. Tá a bá firú ojú bẹ́ẹ̀ wo ikú Kristẹni olóòótọ́ kan, ìbànújẹ́ wa máa dín kù, torí a mọ̀ pé ó máa jíǹde.—Oníwàásù 7:1.

11 Tá a bá gbára lé “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” pátápátá, a ò ní banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ nígbà téèyàn wa bá kú. (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Ohun míì tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká ronú nípa ohun tí Ánà tó jẹ́ opó ṣe ní ọ̀rúndún kìíní. Ọdún méje péré lẹ́yìn tí Ánà ṣègbéyàwó lọkọ rẹ̀ kú. Àmọ́ nígbà tó wà lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84], ó ṣì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì. (Lúùkù 2:36-38) Ó dájú pé bó ṣe fi ara rẹ̀ fún ìjọsìn Ọlọ́run pátápátá yẹn ràn án lọ́wọ́ tó fi lè fara da ìdánìkanwà tí ò sì banú jẹ́ jù. Bá a bá ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa tá a sì ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ lè fara da àwọn nǹkan tí ikú èèyàn ẹni máa ń fà.

Bá A Ṣe Lè Fara Da Onírúurú Ìṣòro

12. Irú ìṣòro wo làwọn Kristẹni kan ti fara dà nínú ìdílé wọn?

12 Àwọn Kristẹni kan ń fara da ìṣòro nínú ìdílé wọn. Bí àpẹẹrẹ, tí ọkọ tàbí aya bá ṣe panṣágà, ẹ wo bí ìpalára tíyẹn máa ṣe fún ìdílé náà á ṣe pọ̀ tó! Nítorí ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn tó bá ẹni tí ọkọ rẹ̀ ṣe panṣágà tàbí ẹni tí aya rẹ̀ ṣe panṣágà, ó lè má lè sùn tàbí kó kàn máa sunkún ṣáá. Ó lè ṣòro fún un gan-an láti máa ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ débi pé ó lè máa ṣàṣìṣe tàbí kó tiẹ̀ fara pa bó ṣe ń ṣe é. Ó lè má lè jẹun, ó lè máa rù, tàbí kó máa ronú. Ó lè ṣòro fún un láti lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. Ìwà panṣágà náà sì lè nípa tó burú gan-an lórí àwọn ọmọ wọn!

13, 14. (a) Ìtùnú wo ni àdúrà tí Sólómọ́nì gbà níbi ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì fún ọ? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́?

13 Nígbà tá a bá nírú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́. (Sáàmù 94:19) Àdúrà tí Sólómọ́nì Ọba gbà nígbà tí wọ́n ń ya tẹ́ńpìlì Jèhófà sí mímọ́ fi hàn pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àwọn èèyàn rẹ̀. Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Àdúrà yòówù, ìbéèrè fún ojú rere yòówù tí ó bá wáyé láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tàbí láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, nítorí pé olúkúlùkù wọ́n mọ ìyọnu àjàkálẹ̀ ọkàn-àyà tirẹ̀, tí wọ́n sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ wọn ní tòótọ́ síhà ilé yìí, nígbà náà, kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run, ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé, kí o sì dárí jì, kí o sì gbé ìgbésẹ̀, kí o sì fi fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, nítorí pé o mọ ọkàn-àyà rẹ̀ (nítorí ìwọ fúnra rẹ nìkan ṣoṣo ni o mọ ọkàn-àyà gbogbo ọmọ aráyé ní àmọ̀dunjú); kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà láàyè ní orí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wa.”—1 Àwọn Ọba 8:38-40.

14 Tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà gbogbo pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, èyí á ràn wá lọ́wọ́ gan-an. (Mátíù 7:7-11) Ìdí ni pé ìdùnnú àti àlàáfíà jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí yìí. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹ wo bí ara ṣe máa ń tù wá tó nígbà tí Bàbá wa ọ̀run bá gbọ́ àdúrà wa! Ńṣe ló máa ń jẹ́ kí ìdùnnú rọ́pò ìbànújẹ́, kí àlàáfíà ọkàn sì rọ́pò ìdààmú ọkàn!

15. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló lè jẹ́ kí àníyàn wa dín kù?

15 Èèyàn ò lè ṣe kó má ṣàníyàn rárá nígbà tó bá wà nínú ipò tí kò fara rọ. Àmọ́ àníyàn náà lè dín kù tá a bá fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sọ́kàn, pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀. . . . Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:25, 33, 34) Àpọ́sítélì Pétérù rọ̀ wá pé ká ‘kó gbogbo àníyàn wa lé Ọlọ́run, nítorí ó bìkítà fún wa.’ (1 Pétérù 5:6, 7) Ó dáa tá a bá sapá láti yanjú ìṣòro tá a ní. Àmọ́ lẹ́yìn tá a bá ti sa gbogbo ipá wa, ńṣe ni ká máa gbàdúrà sí Jèhófà dípò ká máa ṣàníyàn, torí àdúrà ló máa ràn wá lọ́wọ́. Onísáàmù náà kọrin pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.”—Sáàmù 37:5.

16, 17. (a) Kí nìdí tá ò fi lè ṣe ká má ṣàníyàn rárá? (b) Kí la máa ní tá a bá ṣe ohun tí Fílípì 4:6, 7 sọ?

16 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Kò sí kí aláìpé ọmọ Ádámù má ṣàníyàn rárá. (Róòmù 5:12) Àwọn ọmọ Hétì tí Ísọ̀ fi ṣaya “jẹ́ orísun ìkorò ẹ̀mí” tàbí ìbànújẹ́ fún àwọn òbí rẹ̀ tó jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run, ìyẹn Ísákì àti Rèbékà. (Jẹ́nẹ́sísì 26:34, 35) Bákan náà, kò sí àní-àní pé àìsàn kó àníyàn bá àwọn Kristẹni bíi Tímótì àti Tírófímù. (1 Tímótì 5:23; 2 Tímótì 4:20) Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú ṣàníyàn nípa àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (2 Kọ́ríńtì 11:28) Àmọ́ gbogbo ìgbà ni “Olùgbọ́ àdúrà” máa ń wà nítòsí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 65:2.

17 Bá a ṣe ń retí ọjọ́ Jèhófà, “Ọlọ́run àlàáfíà” ń ràn wá lọ́wọ́ ó sì ń tù wá nínú. (Fílípì 4:9) Jèhófà jẹ́ “aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́,” ó jẹ́ “ẹni rere,” ó “ṣe tán láti dárí jini,” ó sì máa ń “rántí pé ekuru ni wá.” (Ẹ́kísódù 34:6; Sáàmù 86:5; 103:13, 14) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ‘máa sọ àwọn ohun tí à ń tọrọ di mímọ̀ fún un,’ nítorí pé ìyẹn máa jẹ́ ká ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” ìyẹn àlàáfíà ọkàn tó kọjá òye ẹ̀dá.

18. Báwo lèèyàn ṣe lè “rí” Ọlọ́run lọ́nà tí Jóòbù 42:5 gbà sọ ọ́?

18 Nígbà tá a bá rí ìdáhùn sí àdúrà wa, a máa ń mọ̀ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa. Lẹ́yìn tí Jóòbù ti fara da àdánwò, ó sọ pé: “Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ [Jèhófà], ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ojú mi ti rí ọ.” (Jóòbù 42:5) Tá a bá lóye ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣe nǹkan, tá a moore rẹ̀, tá a sì nígbàgbọ́, a óò máa ronú lórí àwọn ọ̀nà tó gbà ń bá wa lò, a ó lè “rí” Ọlọ́run, ìyẹn ni pé a ó mọ̀ ọ́n ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀, a óò túbọ̀ ní àlàáfíà ọkàn.

19. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá ‘kó gbogbo àníyàn wa lé Jèhófà’?

19 Tá a bá ‘kó gbogbo àníyàn wa lé Jèhófà’ a óò lè ní àlàáfíà inú lọ́hùn-ún, èyí táá máa ṣọ́ ọkàn àti agbára ìrònú wa bá a ṣe ń fara da ìṣòro. Ọkàn wa á balẹ̀, a ò ní máa bẹ̀rù, a ò sì ní máa jáyà. Ìyẹn nìkan kọ́, ìdààmú àti àníyàn ò ní máa gbé wa lọ́kàn sókè.

20, 21. (a) Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sítéfánù ṣe fi hàn pé ọkàn èèyàn lè balẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí i? (b) Sọ àpẹẹrẹ ẹnì kan lóde òní tí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ nígbà àdánwò.

20 Ọkàn Sítéfánù ọmọ ẹ̀yìn Jésù balẹ̀ nígbà tí ìdánwò ìgbàgbọ́ tó le gan-an dojú kọ ọ́. Kó tó jẹ́rìí tó jẹ́ kẹ́yìn, àwọn tí wọ́n wà nínú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn “rí i pé ojú rẹ̀ rí bí ojú áńgẹ́lì.” (Ìṣe 6:15) Bẹ́ẹ̀ ni o, àlàáfíà Ọlọ́run tó mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ hàn lójú rẹ̀ tí ojú rẹ̀ fi dà bíi ti áńgẹ́lì, ìyẹn ońṣẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tí Sítéfánù túdìí àṣírí àwọn onídàájọ́ náà pé àwọn ni wọ́n pa Jésù, “ọkàn-àyà wọn gbọgbẹ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí payín keke sí i.” Bí Sítéfánù ṣe “kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọ̀run, ó sì tajú kán rí ògo Ọlọ́run àti Jésù tí ó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” Ìran tí Sítéfánù rí yẹn fún un lókun tó fi lè jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú. (Ìṣe 7:52-60) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa kì í rí ìran, Ọlọ́run lè mú kí ọkàn wa balẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa.

21 Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn Kristẹni kan tí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Násì pa nígbà Ogun Àgbáyé Kejì sọ kó tó di pé wọ́n pa wọ́n. Ọ̀kan lára wọn sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nílé ẹjọ́, ó ní: “Wọ́n ti dájọ́ ikú fún mi. Lẹ́yìn tí mo gbọ́ bí wọ́n ṣe dájọ́ náà, mo sọ ọ̀rọ̀ Olúwa wa tó sọ pé, ‘Jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú,’ àti díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ míì, mo wá mọ́kàn. Àmọ́ ẹ má ronú o. Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Ìbàlẹ̀ ọkàn tí mò ń wí yìí kọyọyọ, ẹ ò lè mọ bó ṣe pọ̀ tó!” Ọ̀dọ́kùnrin míì táwọn onínúnibíni fẹ́ bẹ́ lórí kọ̀wé sáwọn òbí rẹ̀ pé: ‘Ó ti kọjá ọ̀gànjọ́ òru nísinsìnyí. Mo ṣì ní àkókò síbẹ̀ láti yí èrò mi padà. Áà! èmi yóò ha láyọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i nínú ayé yìí lẹ́yìn tí mo bá ti sẹ́ Olúwa wa? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ kọ́! Ṣùgbọ́n nísinsìnyí kẹ́ ẹ ní ìdánilójú pé mo fi ayé yìí sílẹ̀ ní ayọ̀ àti àlàáfíà.’ Kò sí àní-àní pé Jèhófà ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí i lókun.

O Lè Fara Dà Á!

22, 23. Ìdánilójú wo lo ní bó o ṣe ń fẹ̀mí ìfaradà retí ọjọ́ Jèhófà?

22 Ìwọ lè má ní irú àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí. Síbẹ̀, òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tí Jóòbù olùbẹ̀rù Ọlọ́run sọ, pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Bóyá òbí ni ẹ́ tó ò ń sa gbogbo ipá rẹ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ ní ọ̀nà Ọlọ́run. Kò sí àní-àní pé wọ́n á rí ìdẹwò níléèwé, àmọ́ wo bí inú rẹ á ṣe dùn tó tí wọ́n bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà tí wọn ò sì tẹ ìlànà òdodo rẹ̀ lójú! Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni ìṣòro àti ìdẹwò máa ń dojú kọ ẹ́ níbi iṣẹ́. Síbẹ̀, o lè fara da ìyẹn àtàwọn ìṣòro míì nítorí pé ‘Jèhófà ń bá ọ gbé ẹrù lójoojúmọ́.’—Sáàmù 68:19.

23 O lè máa wò ó pé o ò já mọ́ nǹkan kan, àmọ́ fi sọ́kàn pé Jèhófà ò ní gbàgbé iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́ tó o fi hàn fún orúkọ mímọ́ rẹ̀. (Hébérù 6:10) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, wàá lè fara da ìdánwò ìgbàgbọ́. Nítorí náà, máa fi sínú àdúrà rẹ pé ìfẹ́ Ọlọ́run lo fẹ́ máa ṣe, kó o sì máa fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sọ́kàn tó o bá ń gbèrò àwọn ohun tó o fẹ́ ṣe. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Ọlọ́run á máa ràn ọ́ lọ́wọ́ á sì máa tì ọ́ lẹ́yìn láti lè máa lo ìfaradà bó o ṣe ń retí ọjọ́ Jèhófà.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí táwa Kristẹni fi ní láti ní ìfaradà?

• Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àìsàn àti ikú èèyàn wa?

• Báwo ni àdúrà ṣe ń jẹ́ ká lè fara da onírúurú ìṣòro?

• Kí ló lè mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa lo ìfaradà bá a ṣe ń retí ọjọ́ Jèhófà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Gbígbára lé Jèhófà máa ń jẹ́ kéèyàn lè fara da ikú èèyàn ẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Gbígbàdúrà àtọkànwá máa ń jẹ́ ká lè fara da ìdánwò ìgbàgbọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́