Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kejì
NÍ OṢÙ December ọdún 609 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọba Bábílónì ti bẹ̀rẹ̀ sí í sàga ti ìlú Jerúsálẹ́mù. Títí di àkókò yẹn, iṣẹ́ tí Ìsíkíẹ́lì ń jẹ́ fáwọn ìgbèkùn tó wà ní Bábílónì dá lórí ìṣubú àti ìparun ìlú wọn tí wọ́n fẹ́ràn gan-an, ìyẹn Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ báyìí, àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ti yí padà, ó wá dá lorí ìparun àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ abọ̀rìṣà, tínú wọn ń dùn nígbà tí àjálù bá àwọn èèyàn Ọlọ́run. Nígbà tí Jerúsálẹ́mù ṣubú ní ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, iṣẹ́ tí Ìsíkíẹ́lì ń jẹ́ tún yí padà, ó wá dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tuntun kan, pé ìjọsìn tòótọ́ á fẹsẹ̀ múlẹ̀ padà lọ́nà ológo.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká àti ìdáǹdè àwọn èèyàn Ọlọ́run ló wà nínú Ìsíkíẹ́lì 25:1 sí Ìsíkíẹ́lì 48:35.a Ńṣe ni wọ́n to àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú àwọn orí wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra àti ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Àmọ́ wọn kò to àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ẹsẹ mẹ́rin tó wà ní Ìsíkíẹ́lì 29:17-20 gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Níwọ̀n bí ìwé Ìsíkíẹ́lì ti jẹ́ ará àwọn Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ “yè, ó sì ń sa agbára.”—Hébérù 4:12.
‘ILẸ̀ YẸN YÓÒ DÀ BÍ ỌGBÀ ÉDẸ́NÌ’
Jèhófà ti mọ báwọn orílẹ̀-èdè tó yí Jerúsálẹ́mù ká ṣe máa ṣe nígbà tí wọ́n bá rí i tí ìlú Jerúsálẹ́mù ṣubú. Ó wá ní kí Ìsíkíẹ́lì sàsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Ámónì, Móábù, Édómù, Filísíà, Tírè àti Sídónì. Àwọn ọ̀tá yóò kó gbogbo ẹrù ilẹ̀ Íjíbítì lọ. Ìsíkíẹ́lì fi “Fáráò ọba Íjíbítì àti ogunlọ́gọ̀ rẹ̀” wé kédárì tí “idà ọba Bábílónì” yóò gé lulẹ̀.—Ìsíkíẹ́lì 31:2, 3, 12; 32:11, 12.
Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn táwọn ọ̀tá pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ẹnì kan sá àsálà, ó sì wá sọ́dọ̀ Ìsíkíẹ́lì, ó sọ fún un pé: “A ti ṣá ìlú ńlá náà balẹ̀!” Nítorí náà, wòlíì yìí ‘kò jẹ́ aláìlèsọ̀rọ̀ mọ́’ sáwọn tó wà nígbèkùn. (Ìsíkíẹ́lì 33:21, 22) Yóò sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ìlú náà yóò ṣe padà bọ̀ sípò. Jèhófà “yóò gbé olùṣọ́ àgùntàn kan dìde sórí wọn,” ìyẹn “ìránṣẹ́ [rẹ̀] Dáfídì.” (Ìsíkíẹ́lì 34:23) Édómù yóò dahoro, àmọ́ ilẹ̀ ọ̀hún yẹn, ìyẹn Júdà, yóò “dà bí ọgbà Édẹ́nì.” (Ìsíkíẹ́lì 36:35) Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò dáàbò bo àwọn èèyàn òun tí yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn nígbà tí “Gọ́ọ̀gù” bá gbógun tì wọ́n.—Ìsíkíẹ́lì 38:2.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
29:8-12—Ìgbà wo làwọn ọ̀tá sọ ilẹ̀ Íjíbítì dahoro fún ogójì ọdún? Lẹ́yìn ìparun ìlú Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn tó ṣẹ́ kù nílẹ̀ Júdà sá lọ sílẹ̀ Íjíbítì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wòlíì Jeremáyà ti kìlọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. (Jeremáyà 24:1, 8-10; 42:7-22) Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì, nítorí pé Nebukadinésárì gbógun wá sí ilẹ̀ Íjíbítì ó sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn táwọn ọ̀tá ṣẹ́gun ilẹ̀ Íjíbítì yìí ni ìsọdahoro ogójì ọdún náà bẹ̀rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òpìtàn ò sọ ohunkóhun nípa ìsọdahoro yìí, ó yẹ ká gbà gbọ́ pé ó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ nítorí pé Ọlọ́run tó ń mú ìlérí ṣẹ ni Jèhófà.—Aísáyà 55:11.
29:18—Báwo ‘la ṣe mú gbogbo orí pá tí gbogbo èjìká sì di èyí tí a mú bó?’ Ìsàgatì àwọn ọmọ ogun Nebukadinésárì sí ìlú Tírè ti orí ilẹ̀ le gan-an, ó sì mu wọ́n lómi débi pé orí wọn pá nítorí akoto wọn tó ń ha wọ́n lórí, èjìká wọn sì bó níbi tí wọ́n ti ń fi èjìká ru àwọn ohun èlò tí wọ́n fẹ́ fi kọ́ àwọn ilé gogoro àtàwọn ògiri.—Ìsíkíẹ́lì 26:7-12.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
29:19, 20. Níwọ̀n báwọn ará Tírè ti kó ọ̀pọ̀ lára ọrọ̀ ilẹ̀ wọn sá lọ sí Tírè orí omi, Ọba Nebukadinésárì kò fi bẹ́ẹ̀ rí ìkógun gbà lọ́wọ́ ìlú Tírè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbéraga ni ọba Nebukadinésárì, ó tún jẹ́ anìkànjọpọ́n àti abọ̀rìṣà, síbẹ̀ Jèhófà san èrè fún un nítorí iṣẹ́ tó ṣe nípa fífún un ní ilẹ̀ Íjíbítì gẹ́gẹ́ bí “owó ọ̀yà fún ẹgbẹ́ ológun rẹ̀.” Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà fara wé Ọlọ́run tòótọ́, ká máa san owó orí fáwọn ìjọba nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fún wa? Ìwà táwọn aláṣẹ ń hù tàbí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ná owó orí náà kò sọ pé ká má ṣe ojúṣe wa.—Róòmù 13:4-7.
33:7-9. Ẹgbẹ́ olùṣọ́ ti òde òní, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, kò gbọ́dọ̀ kọ̀ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n sì máa kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀.—Mátíù 24:21.
33:10-20. Ká tó lè rí ìgbàlà, a ní láti yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú ká sì máa ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ká ṣe. Ká sòótọ́, ‘ọ̀nà Jèhófà gún.’
36:20, 21. Nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò hùwà níbàámu pẹ̀lú ohun táwọn èèyàn mọ̀ wọ́n sí, ìyẹn “àwọn ènìyàn Jèhófà,” wọ́n kó ẹ̀gbin bá orúkọ Jèhófà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. A ò gbọ́dọ̀ dẹni tó ń fẹnu lásán jẹ́ orúkọ Jèhófà.
36:25, 37, 38. “Àwọn ẹni mímọ́” ló kúnnú Párádísè tẹ̀mí tí à ń gbádùn lónìí. Nítorí náà, ó yẹ ká sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ kó máa wà ní mímọ́.
38:1-23. Ẹ ò rí i pé mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà yóò gba àwọn èèyàn rẹ̀ là nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbógun tì wọ́n fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Gọ́ọ̀gù lorúkọ tí “olùṣàkóso ayé yìí,” ìyẹn Sátánì Èṣù, ń jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n lé e kúrò lọ́run. Àgbègbè ilẹ̀ ayé yìí, níbi tí Ọlọ́run sé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ mọ́, ni ilẹ̀ Mágọ́gù ń tọ́ka sí.—Jòhánù 12:31; Ìṣípayá 12:7-12.
“FI ỌKÀN-ÀYÀ RẸ SÍ GBOGBO OHUN TÍ ÈMI YÓÒ FI HÀN Ọ́”
Ọdún mẹ́rìnlá ti kọjá lẹ́yìn táwọn ọ̀tá bi ìlú Jerúsálẹ́mù ṣubú. (Ìsíkíẹ́lì 40:1) Ó ṣì ku ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta táwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà máa lò nígbèkùn. (Jeremáyà 29:10) Ìsíkíẹ́lì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni àádọ́ta ọdún báyìí. Nínú ìran kan, ó bá ara rẹ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Wọ́n sọ fún un pé: “Ọmọ ènìyàn, fi ojú rẹ wò, kí o sì fi etí rẹ gbọ́, kí o sì fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ohun tí èmi yóò fi hàn ọ́.” (Ìsíkíẹ́lì 40:2-4) Ẹ ò rí i pé inú Ìsíkíẹ́lì ti ní láti dùn gan-an nígbà tó rí ìran tẹ́ńpìlì tuntun kan!
Àwọn ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú tẹ́ńpìlì ológo náà nìwọ̀nyí: Àwọn ibi àbáwọlé mẹ́fà, ọgbọ̀n yàrá ìjẹun, ibi Mímọ́, ibi Mímọ́ Jù Lọ, pẹpẹ onígi àti pẹpẹ kan tó wà fún àwọn ọrẹ ẹbọ sísun. Odò kékeré kan tó wá di ibú omi “ń jáde” wá látinú tẹ́ńpìlì náà. (Ìsíkíẹ́lì 47:1) Ìsíkíẹ́lì tún rí ìran tó dá lórí pípín ilẹ̀ fáwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ibi tí wọ́n pín fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti ìhà ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn. Ibì kan tó wà fún iṣẹ́ àbójútó sì wà láàárín ilẹ̀ tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Júdà àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Ibẹ̀ náà ni “Ibùjọsìn Jèhófà” àti “Ìlú ńlá náà” tó ń jẹ́ Jèhófà-Ṣamà wà.—Ìsíkíẹ́lì 48:9, 10, 15, 35.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
40:3–47:12—Kí ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà dúró fún? Tẹ́ńpìlì gìrìwò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà kì í ṣe tẹ́ńpìlì gidi tí wọ́n fọwọ́ kọ́. Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí Ọlọ́run ló dúró fún, ìyẹn ètò tó ṣe fún ìjọsìn mímọ́ lọ́jọ́ òní, tó dà bí ètò inú tẹ́ńpìlì. (Ìsíkíẹ́lì 40:2; Míkà 4:1; Hébérù 8:2; 9:23, 24) “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ni ìran nípa tẹ́ńpìlì yìí nímùúṣẹ, nígbà tí Jèhófà yọ́ ẹgbẹ́ àlùfáà mọ́. (2 Tímótì 3:1; Ìsíkíẹ́lì 44:10-16; Málákì 3:1-3). Àmọ́ o, inú Párádísè ni yóò ti nímùúṣẹ tán pátápátá. Tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran yìí fi àwọn Júù tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀ pé ìjọsìn tòótọ́ yóò fìdí múlẹ̀ padà, pé ìdílé kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ Júù yóò rí ogún gbà ní ilẹ̀ náà.
40:3–43:17—Kí ni wíwọ̀n tí wọ́n wọn tẹ́ńpìlì náà túmọ̀ sí? Wíwọ̀n tí wọ́n wọn tẹ́ńpìlì yìí jẹ́ àmì pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nípa ìjọsìn mímọ́ yóò nímùúṣẹ dájúdájú.
43:2-4, 7, 9—Kí làwọn “òkú àwọn ọba wọn” tí wọ́n ní láti mú kúrò nínú tẹ́ńpìlì? Láìsí àní-àní, òrìṣà làwọn òkú náà ń tọ́ka sí. Àwọn alákòóso ìlú Jerúsálẹ́mù àtàwọn èèyàn ibẹ̀ ti fi àwọn ère òrìṣà sọ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run dìdàkudà, wọ́n sì tipa báyìí sọ àwọn òrìṣà náà di ọba wọn.
43:13-20—Kí ni pẹpẹ tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà dúró fún? Pẹpẹ yìí dúró fún ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó mú kó ṣètò fún ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Ẹbọ ìràpadà yìí ló jẹ́ káwọn ẹni àmì òróró lè dẹni tí Ọlọ́run kà sí olódodo, òun ló sì jẹ́ káwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” lè jẹ́ ẹni mímọ́ lójú Ọlọ́run. (Ìṣípayá 7:9-14; Róòmù 5:1, 2) Bóyá èyí ló fà á tí “òkun dídà” inú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì, ìyẹn agbada omi gìrìwò táwọn àlùfáà fi máa ń wẹ̀, kò fi sí nínú tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran yìí.—1 Àwọn Ọba 7:23-26.
44:10-16—Ta ni ẹgbẹ́ àlùfáà ṣàpẹẹrẹ? Ẹgbẹ́ àlùfáà ṣàpẹẹrẹ àwùjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lóde òní. Ọdún 1918 ni yíyọ́ wọn mọ́ ṣẹlẹ̀, nígbà tí Jèhófà jókòó “gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń yọ́ mọ́, tí ó sì ń fọ̀ mọ́” nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀. (Málákì 3:1-5) Èyí jẹ́ káwọn tí wọ́n di mímọ́ tàbí tí wọ́n ronú pìwà dà lè máa bá iṣẹ́ ìsìn àrà ọ̀tọ̀ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ nìṣó. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n ní láti máa sapá láti rí i pé àwọn pa ara àwọn mọ́ “láìní èérí kúrò nínú ayé,” kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” táwọn ẹ̀yà tí kì í ṣe ẹ̀yà àlùfáà dúró fún.—Jákọ́bù 1:27; Ìṣípayá 7:9, 10.
45:1; 47:13–48:29—Kí ni “ilẹ̀ náà” àti pípín tí wọ́n pín in ṣàpẹẹrẹ rẹ̀? Àgbègbè táwọn èèyàn Ọlọ́run ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn ni ilẹ̀ yìí ṣàpẹẹrẹ. Ibi yòówù kí olùjọ́sìn Jèhófà kan wà, ilẹ̀ tí Ọlọ́run mú padà bọ̀ sípò lẹni náà wà níwọ̀n ìgbà tó bá ti ń ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Inú ayé tuntun ni àsọtẹ́lẹ̀ ilẹ̀ pípín yìí yóò ti nímùúṣẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ olóòótọ́ yóò jogún ilẹ̀ kan.—Aísáyà 65:17, 21.
45:7, 16—Kí ni ọrẹ táwọn èèyàn mú wá fún ẹgbẹ́ àlùfáà àti ìjòyè dúró fún? Nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, èyí dìídì tọ́ka sí ìtìlẹ́yìn tẹ̀mí, ìyẹn ni ṣíṣèrànwọ́ àti níní ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀.
47:1-5—Kí ni omi odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣàpẹẹrẹ? Àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà ṣe kí ìran èèyàn lè wà láàyè ni omi yìí ṣàpẹẹrẹ, títí kan ẹbọ ìràpadà tí Kristi Jésù fi ara rẹ̀ rú àti ìmọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì. (Jeremáyà 2:13; Jòhánù 4:7-26; Éfésù 5:25-27) Odò yẹn ń jìn sí i díẹ̀díẹ̀ kó bàa lè gba àwọn ẹni tuntun tó ń tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́. (Aísáyà 60:22) Ìgbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ni omi odò tó lè fúnni ní ìyè yìí yóò túbọ̀ lágbára sí i. Omi yìí tún ní í ṣe pẹ̀lú òye tí yóò túbọ̀ máa wá látinú “àwọn àkájọ ìwé” tí a óò ṣí sílẹ̀ nígbà yẹn.—Ìṣípayá 20:12; 22:1, 2.
47:12—Kí làwọn igi tó ń méso jáde dúró fún? Àwọn igi wọ̀nyí dúró fún àwọn ìpèsè tẹ̀mí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí aráyé lè padà di pípé.
48:15-19, 30-35—Kí ni ìlú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran dúró fún? Ilẹ̀ “àìmọ́” ni ìlú yìí wà, tó fi hàn pé ó ní láti ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé. Ó jọ pé ìlú yìí dúró fún ètò bíbójútó ilẹ̀ ayé, èyí tó máa ṣàǹfààní fáwọn tó máa para pọ̀ di “ayé tuntun” ti òdodo. (2 Pétérù 3:13) Níní tó ní àwọn ẹnubodè ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ fi hàn pé ó rọrùn láti wọnú rẹ̀. Ó yẹ káwọn tó jẹ́ alábòójútó láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
40:14, 16, 22, 26. Àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri tó wà láwọn ibi àbáwọlé tẹ́ńpìlì náà fi hàn pé kìkì àwọn tí ìwà wọn bá dára nìkan ló lè wọbẹ̀. (Sáàmù 92:12) Èyí kọ́ wa pé tá a bá ń hùwà tó dára nìkan ni Jèhófà á fi tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.
44:23. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká mọrírì iṣẹ́ takuntakun tí ẹgbẹ́ àlùfáà ti òde òní ń ṣe! “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ló ń rí sí pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí lásìkò tó yẹ, èyí tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí kò mọ́ àtohun tó mọ́ lójú Jèhófà.—Mátíù 24:45.
47:9, 11. Ìmọ̀, tó jẹ́ apá pàtàkì nínú omi ìṣàpẹẹrẹ náà, ti ń ṣe ìwòsàn tí kò lẹ́gbẹ́ lákòókò tiwa yìí. Níbikíbi táwọn èèyàn bá ti ń mú un ló ti ń sọ wọ́n dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run. (Jòhánù 17:3) Àmọ́ o, ní tàwọn tí wọn kò bá tẹ́wọ́ gba omi tí ń fúnni ní ìyè yìí, a ó “fi wọ́n fún iyọ̀,” ìyẹn ni pé a ó pa wọ́n run yán-ányán-án. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa ‘sa gbogbo ipá wa láti máa fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́’!—2 Tímótì 2:15.
‘Dájúdájú, Èmi Yóò Sọ Orúkọ Ńlá Mi Di Mímọ́’
Lẹ́yìn tí wọ́n ti mú ọba tó jẹ kẹ́yìn ní ìran Dáfídì kúrò, Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ kí àkókò gígùn gan-an kọjá kí Ẹni “tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin” sí ìjọba yẹn tó dé. Àmọ́ Ọlọ́run kò gbàgbé májẹ̀mú tó bá Dáfídì dá. (Ìsíkíẹ́lì 21:27; 2 Sámúẹ́lì 7:11-16) Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì sọ nípa “ìránṣẹ́ mi Dáfídì” ẹni tí yóò di “olùṣọ́ àgùntàn” àti “ọba.” (Ìsíkíẹ́lì 34:23, 24; 37:22, 24, 25) Jésù Kristi tí Ọlọ́run gbé àkóso Ìjọba náà lé lọ́wọ́ ni ẹni yìí. (Ìṣípayá 11:15) Ìjọba Mèsáyà ni Jèhófà yóò lò láti “sọ orúkọ ńlá [rẹ̀] di mímọ́.”—Ìsíkíẹ́lì 36:23.
Láìpẹ́ rárá sígbà tá a wà yìí, gbogbo àwọn tó ń sọ orúkọ mímọ́ Ọlọ́run di aláìmọ́ ni yóò pa run. Àmọ́ àwọn tó ń sọ orúkọ yẹn di mímọ́ nínú ìgbésí ayé wọn nípa jíjọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fọwọ́ sí yóò gba ẹ̀bùn ìyè ayérayé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká lo àǹfààní omi ìyè náà ní kíkún, èyí tó ń ṣàn lọ́pọ̀ yanturu lákòókò tiwa yìí, ká sì fi ìjọsìn tòótọ́ sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí Ìsíkíẹ́lì 1:1 sí Ìsíkíẹ́lì 24:27, wo “Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní,” nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2007.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Tẹ́ńpìlì ológo tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí ni odò omi ìyè tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣàpẹẹrẹ?
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.