ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 8/1 ojú ìwé 12-15
  • Kò Sóhun Tó Dà Bí Àǹfààní Tí Mo Ní Láti Máa Sin Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kò Sóhun Tó Dà Bí Àǹfààní Tí Mo Ní Láti Máa Sin Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Mo Ṣe Rí Ẹnì Kejì
  • Mo Padà Sẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún
  • Àwọn Ìbùkún Tí Mi Ò Jẹ́ Gbàgbé
  • Èmi Àtàwọn Ọmọ Mi Ń Ṣiṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà
  • Mo Ṣì Ń Ṣiṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà!
  • Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Ń Fìbùkún Jíǹkí Ẹni Wọ́n Sì Ń Rí I Gbà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà—Ǹjẹ́ O Lè Ṣe É?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 8/1 ojú ìwé 12-15

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Kò Sóhun Tó Dà Bí Àǹfààní Tí Mo Ní Láti Máa Sin Jèhófà

Gẹ́gẹ́ Bí Zerah Stigers Ṣe Sọ Ọ́

Ó pẹ́ témi àtọkọ mi ti ń bá a bọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, àmọ́ ó kú lọ́dún 1938. Ó wá kù mí ku àwọn ọmọ wa ọkùnrin méjì, ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọwọ́, èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ṣì ń wù mí gan-an, ọ̀nà wo ni mo fẹ́ gbé e gbà? Jẹ́ kí n mẹ́nu ba díẹ̀ nípa àárọ̀ ọjọ́ ayé mi, kí n tó wá ṣàlàyé bí iṣu ṣe kú àti bí ọ̀bẹ ṣe bù ú.

KÒ PẸ́ púpọ̀ tí wọ́n bí mi ní July 27, ọdún 1907, ní ìpínlẹ̀ Alabama, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí èmi, àwọn òbí mi, àtàwọn àbúrò mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, fi kó lọ sí ìpínlẹ̀ Georgia. Kò sì pẹ́ tá a kó débẹ̀ tá a fi lọ ń gbé ní ìpínlẹ̀ Tennessee, ẹ̀yìn ìyẹn la wá kó lọ sí ìtòsí ìlú Tampa ní ìpínlẹ̀ Florida. Ìpínlẹ̀ Florida yìí la wà títí di ọdún 1916 tí mo wo sinimá “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] tó ń gbé àwòrán àti ohùn jáde. Kò tíì fi bẹ́ẹ̀ sí ilé iṣẹ́ sinimá nígbà yẹn, nítorí náà àwọn èèyàn gbádùn sinimá náà gan-an!

Àwọn òbí mi fẹ́ràn àtimáa ka Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tó ń sọ nípa Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi fẹ́ràn àtimáa ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ń pè ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà yẹn. Síbẹ̀, màmá wa máa ń kó wa lọ sípàdé. Nígbà tá a tiẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kó dé abúlé Nile, ní ìpínlẹ̀ Michigan, ìgbà gbogbo la máa ń rìnrìn-àjò tó lé ní kìlómítà mẹ́rìndínlógún nínú ọkọ ojú irin láti lọ ṣèpàdé níbì kan tí wọ́n ń pè ní South Bend ní ìpínlẹ̀ Indiana.

Lẹ́yìn tí mo ti ya ara mí sí mímọ́ fún Jèhófà, mo ṣèrìbọmi ní July 22, 1924. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí màmá mi fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbára dì láti di àpínwèé-ìsìn-kiri, ìyẹn orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nígbà yẹn. Àpẹẹrẹ rere Màmá àti tàwọn apínwèé-ìsìn-kiri mìíràn ló mú kó wu èmi náà láti wọṣẹ́ alákòókò kíkún.

Bí Mo Ṣe Rí Ẹnì Kejì

Lọ́dún 1925, mo lọ sí àpéjọ kan nílùú Indianapolis, ní ìpínlẹ̀ Indiana, níbẹ̀ ni mo ti bá Arákùnrin James Stigers tó wá láti ìlú Chicago pàdé. Ohun tó sì fà mí mọ́ra nípa rẹ̀ ni pé, ìránṣẹ́ Jèhófà tó lákíkanjú ni. Nǹkan bí ọgọ́jọ kìlómítà nibi tí mò ń gbé sí ìlú Chicago, nítorí náà kò rọrùn fún wa láti máa bẹ ara wa wò. Nígbà yẹn sì rèé, ìjọ kan ṣoṣo ló wà nílùú ńlá yẹn, nínú yàrá kan tá a háyà lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì la sì ti máa ń ṣèpàdé. Arákùnrin Stigers sábà máa ń kọ lẹ́tà sí mi láti fi gbé mi ró kí n lè máa ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. A ṣègbéyàwó lóṣù December ọdún 1926, ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà la bí àkọ́bí wa, tá a pè ní Eddie.

Kò pẹ́ sígbà yẹn tá a jọ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ìpínlẹ̀ mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la sì ti ṣiṣẹ́ náà, ìyẹn ìpínlẹ̀ Michigan, Louisiana, Mississippi, South Dakota, Iowa, Nebraska, California àti Illinois. A gbádùn ara wa gan-an láwọn àkókò yẹn. Àmọ́, ìgbádùn náà ò pẹ́ lọ títí torí pé àmódi kọ lu ọkọ mi nígbà tó yá.

Àìsàn yìí mú kí àtijẹ àtimu ṣòro fún wa. Nítorí náà, lọ́dún 1936, a padà síbi tá à ń gbé tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Chicago, láti lọ máa gbé pẹ̀lú màmá ọkọ mi tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Oyún ọmọ wa kejì ló wà nínú mi nígbà tí àìsàn náà le débi gẹ́ẹ́, torí náà mo ní láti máa ṣiṣẹ́ nílé oúnjẹ kan báyìí tí wọ́n ti ń san dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan fún mi lóòjọ́. Èèyàn rere ni màmá ọkọ mi, kì í jẹ́ kóúnjẹ wọ́n wa, kì í sì gbá kọ́bọ̀ lọ́wọ́ mi. Kò fi ohunkóhun jẹ wá níyà rí.

Ọdún bíi méjì lọkọ mi fi ṣàìsàn. Ibi kan tó wú nínú ọpọlọ ẹ̀ ló fa àìsàn yìí. Àìsàn náà ló sì pa á ní July ọdún 1938. Lákòókò tó fi ṣàìsàn yẹn, kò lè wa mọ́tò kò sì lè jáde òde ẹ̀rí, àmọ́ bí àyè bá ti yọ, kò lè ṣe kó máà jẹ́rìí fáwọn ẹlòmíì. Nítorí àtilè máa ran màmá ọkọ mi lọ́wọ́ láti gbọ́ bùkátà èmi àtàwọn ọmọ, mo dáwọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún dúró. Onírúurú ibi ni mo ríṣẹ́ sí, àmọ́ kì í pẹ́ tí iṣẹ́ náà fi ń bọ́ lọ́wọ́ mi.

Ní ọgbọ̀njọ́ oṣù July, ọdún 1938, ìyẹn ọjọ́ kẹjọ géérégé lẹ́yìn ikú ọkọ mi ni mo bí ọmọ wa ọkùnrin tó ń jẹ́ Bobby. Àmọ́, màmá ọkọ mi ò jẹ́ kí ń lọ sílé ìwòsàn ọ̀fẹ́ nítorí wọn kì í ní àwọn dókítà tó mọṣẹ́. Dípò ìyẹn, ńṣe ló ṣètò pé kí n lọ sílé ìwòsàn tó sàn jùyẹn lọ táwọn dókítà tó mọṣẹ́ á ti tọ́jú mi. Ohun náà ló sì tún san gbogbo owó ọsibítù. Ó dájú pé ìfẹ́ Kristẹni ló sún un ṣe gbogbo èyí, mo sì mọrírì rẹ̀ gidigidi.

Mo Padà Sẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Ọ̀dọ́ màmá ọkọ mi la ṣì ń gbé tí Bobby fi lé lọ́mọ ọdún méjì, Eddie sì ti pé ọmọ ọdún méjìlá nígbà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní láti mú ara mi bá ipò tuntun tí mo wà mu, iná ìfẹ́ tí mo ní fún sísin Jèhófà àti ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣì ń jó lala. Ní àpéjọ tó wáyé lọ́dún 1940 nílùú Detroit, ní ìpínlẹ̀ Michigan, mo bá tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà kan pàdé tí wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n máa bọ̀ wá ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ South Carolina. Nítorí náà, mo fi àádọ́jọ dọ́là ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan mo sì mú ọ̀nà pọ̀n. Lọ́dún 1941 tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èmi àtàwọn ọmọ mi méjèèjì forí lé ìhà gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ibẹ̀ ni mo sì ti padà wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún.

Nígbà tá a dé ìpínlẹ̀ South Carolina, ìlú Camden la kọ́kọ́ gbé, lẹ́yìn náà la gbé nílùú Little River, ká tó wá lọ gbé nílùú Conway. Nílùú Conway, mo ra ilé alágbèérìn kékeré kan. Mo sì gbàṣẹ lọ́wọ́ ẹnì kan tó ni ilé iṣẹ́ epo tí wọ́n ti ń ta gáàsì pé kó jẹ́ kí n gbé ilé alágbèérìn náà sítòsí ilé epo rẹ̀. Mo tún bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí n fa gáàsì àti iná láti ilé epo náà, kó sì tún jẹ́ kí n máa lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, gáàsì wọ́n bí ojú, mi ò sì rí i lò láti dáná mọ́. Nítorí náà, mo ra kẹ̀kẹ́ àlòkù kan. Nígbà tó sì di ọdún 1943 tó dà bíi pé kò ní ṣeé ṣe fún mi láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nìṣó torí pé kò sówó lọ́wọ́ mi mọ́, ètò Ọlọ́run ni kí ń wá máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe; èyí mú kí n máa rí owó táṣẹ́rẹ́ gbà láti fi wá oúnjẹ jẹ. Láti àwọn ọdún wọ̀nyẹn wá, Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀!

Kó sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tó ń gbé nílùú Conway nígbà yẹn, ó sì ṣòro fémi àtàwọn ọmọ láti máa dá lọ sòde ẹ̀rí. Nítorí náà, mo kọ̀wé pé kí wọ́n fún mi ní aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tá a ó jọ máa ṣiṣẹ́. Nígbà tó sì di ọdún 1944, wọ́n rán Edith Walker wá, a sì mọwọ́ ara wa gan-an! A jọ ṣiṣẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù bíi mélòó kan fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Àmọ́, ó dùn mí pé ó ní láti padà sí ìpínlẹ̀ Ohio nítorí àìlera.

Àwọn Ìbùkún Tí Mi Ò Jẹ́ Gbàgbé

Ìrírí Albertha wà lára ọ̀pọ̀ ìrírí mánigbàgbé tó ń mú kí n láyọ̀ láwọn ọdún yẹn. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni Albertha. Ìlú Conway ló ń gbé, ó sì ń tọ́jú ìyá rẹ̀ àgbà tó yarọ àtàwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin méjì. Ó fẹ́ràn ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì tí mo fi kọ́ ọ, ó sì ń fẹ́ láti sọ fáwọn ẹlòmíì nípa ohun tó kọ́. Òun náà ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́yìn tó jáde ilé ìwé gíga lọ́dún 1950. Ó ti lé lọ́dún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta báyìí tó ti bẹ̀rẹ̀, kò sì tíì ṣíwọ́!

Lọ́dún 1951, ètò Ọlọ́run ní kí èmi àti Edith lọ sí ìlú Rock Hill ní ìpínlẹ̀ South Carolina, ká sì lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀nba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbébẹ̀. Látibẹ̀, a mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí ìlú Elberton ní ìpínlẹ̀ Georgia, a sì lo ọdún mẹ́ta níbẹ̀. Lẹ́yìn yẹn la wá padà sí ìpínlẹ̀ South Carolina, ibẹ̀ ni mo sì wà láàárín ọdún 1954 sí ọdún 1962. Ní àrọko kan báyìí nílùú Walhalla, mo pàdé Nettie, obìnrin àgbàlagbà kan tí kò gbọ́rọ̀ dáadáa; òun nìkan ló sì ń dá gbé. Ká bàa lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa kọ́kọ́ ka ìpínrọ̀ kan nínú ìwé tó wà lọ́wọ́ ẹ̀, màá wá nawọ́ sí ìbéèrè tó wà fún ìpínrọ̀ náà nísàlẹ̀ ojú ìwé, òun náà á sì nawọ́ sí ìdáhùn nínú ìpínrọ̀.

Bí ohun kan ò bá yé e, á kọ ìbéèrè ẹ̀ sínú ìwé pélébé kan, èmi náà á sì kọ ìdáhùn sísàlẹ̀ ìbéèrè ẹ̀. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, Nettie túbọ̀ mọrírì ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé ìjọ, a sì jọ máa ń wàásù láti ilé dé ilé. Ó tún máa ń dá ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n n kì í jìnnà sí i, bíi kí n wà ní òdì kejì títì, bó bá lọ ṣẹlẹ̀ pé ó nílò ìrànlọ́wọ́.

Lọ́jọ́ kan báyìí, nígbà tí mo ṣì wà ní Walhalla, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí mo ti ń lò tipẹ́ ṣàdédé takú. Àǹfààní míì yọjú fún mi láti ra òmíràn ní ọgọ́rùn-ún dọ́là, àmọ́ mi ò lówó lọ́wọ́. Mo lọ bá Ẹlẹ́rìí mìíràn kan tó jẹ́ ọ̀gá ilé iṣẹ́, ó sì gbà láti yá mi ní ọgọ́rùn-ún dọ́là. Láìpẹ́ sígbà yẹn, mo ṣàdédé rí lẹ́tà kan gbà látọ̀dọ̀ àbúrò mi obìnrin. Mo rí i kà nínú lẹ́tà náà pé àwọn àbúrò mi ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé bàbá wa fowó díẹ̀ pa mọ́ sí báńkì, kó tó kú. Gbogbo wọn jíròrò ohun tí wọ́n á fẹ́ láti fi owó náà ṣe, wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan pé káwọn fi ránṣẹ́ sí mi. Ọgọ́rùn-ún dọ́là géérégé lowó ọ̀hún!

Èmi Àtàwọn Ọmọ Mi Ń Ṣiṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà

Látìgbà tí Eddie àti Bobby ti wà ní kékeré ni mo ti máa ń kó wọn lọ sóde ẹ̀rí. Nígbà yẹn sì rèé, àwọn èèyàn ò tíì máa gbé oògùn olóró, ìṣekúṣe ò sì tíì fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Nítorí náà, gbígbé ìgbésí ayé tó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti gbígbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ni ò jẹ́ kí n kó sí ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń kojú àwọn òbí lónìí bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n bàa lè sin Jèhófà.

Ilé ìwé tó wà ní ìlú Camden ni Eddie lọ, nígbà tó sì parí ọdún kejì nílé ìwé gíga, ó sọ fún mi pé òun á fẹ́ ká jọ máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. A jọ gbádùn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fáwọn ọdún mélòó kan. Lẹ́yìn yẹn ló sọ pé òun á fẹ́ láti lọ ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, nílùú New York. Ó sì láǹfààní láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láàárín ọdún 1947 sí ọdún 1957. Lọ́dún 1958, ó fẹ́ Albertha, tí mo bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà kan, àwọn méjèèjì sì jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Inú mi dùn gan-an nígbà táwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jọ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà lọ́dún 2004!

Mo rántí pé lọ́jọ́ kan báyìí, ìgbà tí mò ń wí yìí ti pẹ́ o, mo gbọ́ tí Bobby ń sọ fún Jèhófà nínú àdúrà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè rí epo tó tó rà sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi kí n bàa lè máa rí i gbé lọ sọ́dọ̀ àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bobby ti fi hàn ní gbogbo ọjọ́ ayé ẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì fi ọdún bíi mélòó kan ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àjálù bá òun náà. Lọ́dún 1970, nígbà tó ku oṣù méjì kó pé ọdún méjì tó ti ṣègbéyàwó ni ìyàwó ẹ̀ kú nígbà tó ń rọbí ọmọ tí ì bá fi bí ìbejì. Ìtòsí ara wa lèmi àti Bobby ń gbé látìgbà yẹn, a kì í sì í jìnnà síra wa.

Mo Ṣì Ń Ṣiṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà!

Lọ́dún 1962 ni iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà gbé mi dé ìjọ tí mo wà nísinsìnyí, ìyẹn ìjọ Lumberton, ní ìpínlẹ̀ North Carolina. Ọdún karùndínláàádọ́ta tí mo sì ti wà níbẹ̀ rèé. Mo ṣì ń wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi títí tí mo fi lé lọ́mọ ọgọ́rin ọdún. Ọ̀kan lára àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tó ń gbé nítòsí ilé wa ló ń gbé mi lọ sáwọn ìpàdé ìjọ báyìí. Òun náà ló sì tún máa ń mú mi lọ sódè ẹ̀rí.

Mo ní ọ̀pá tí mo fi ń rìn, mo sì ní kẹ̀kẹ́ aláfọwọ́yí, ṣùgbọ́n mi ò kì ń lò wọ́n, torí pé mo ṣì lè rìn láìlo èyíkéyìí nínú wọn. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi ní ìlera tó dáa, ẹnu àìpẹ́ yìí ni ojú ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yọ mí lẹ́nu. N kì í pa ìpàdé jẹ, àfi bí ara mi ò bá yá, mo sì ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà aláìlera.

Ní báyìí tó ti lé láàádọ́rin ọdún tí mo ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà bọ̀, mo sì lè sọ tọkàntọkàn pé Jèhófà ni aláàbò mi látìgbà yìí wá.a Mo mọ̀ pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ ní làákàyè o, bẹ́ẹ̀ ni n kì í ṣe ọ̀jáfáfá, àmọ́ Jèhófà mọ ohun tí mo lè ṣe àti ohun tí mi ò lè ṣe. Ọ̀pẹ́ ni pé ó mọ̀ pé mò ń gbìyànjú, ó sì ti lò mí.

Mo mọ̀ pé sísin Jèhófà dé gbogbo ibi tí agbára wa bá gbé e dé ṣe pàtàkì nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ni ohun gbogbo ti wá. Bí mo bá ṣì wà lókè eèpẹ̀, mi ò rò pé iṣẹ́ míì wà tí máa yàn láti ṣe ju iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ. Àǹfààní àgbàyanu ni iṣẹ́ náà jẹ́ fún mi! Ohun tí mò ń gbà ládùúrà ni pé kí Jèhófà lè lò mí títí ayérayé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Arábìnrin Stigers parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní ogúnjọ́ oṣù April, odún 2007. Oṣù mẹ́ta péré ló kù kó pé ọmọ ọgọ́rùn-ún ọdún. Ìṣírí lọ̀pọ̀ ọdún tó fi ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà láìyẹsẹ̀ jẹ́ fún wa, inú wa sì dùn pé ọwọ́ rẹ̀ tẹ ìyè ti ọ̀run nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ọkọ̀ yìí lèmi àti ọkọ mi lò nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Èmi àtàwọn ọmọ mi rèé lọ́dún 1941

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Fọ́tò tí èmi, Eddie àti Bobby yà láìpẹ́ yìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́