Ǹjẹ́ Iṣẹ́ Ọnà Lè Wà Láìsí Ẹni Tó Ṣe é?
Ó TI fẹ́rẹ̀ẹ́ lé ní àádọ́jọ [150] ọdún báyìí tí Charles Darwin ti gbìyànjú láti fi ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣàlàyé bí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ẹ̀dá alààyè ṣe dèyí tó wà. Ó ní kò sẹ́ni tó dá wọn, pé wọ́n ṣèèṣì wà ni. Àmọ́ àwọn kan ti ń ta ko ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n rẹ̀ yìí àti onírúurú ọ̀nà tó pín sí. Àwọn tó ń ta kò ó ni àwọn kan tó gbà gbọ́ pé bí ìrísí àti ìgbékalẹ̀ ara ẹ̀dá alààyè ṣe jẹ́ àgbàyanu fi hàn pé ẹnì kan ló dìídì dá wọn. Kódà ọ̀pọ̀ àwọn ògbóǹkangí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni ò fara mọ́ ohun tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ pé ńṣe ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun alààyè ṣàdédé wà láìsí ẹni tó dá wọn.
Díẹ̀ lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì yẹn sọ pé ọ̀nà míì tó yàtọ̀ sí ẹfolúṣọ̀n ni onírúurú ẹ̀dá alààyè gbà wà. Wọ́n pe ọ̀nà náà ní iṣẹ́ ọnà àfòyeṣe. Wọ́n ní ẹ̀kọ́ nípa àwọn ohun alààyè àti ẹ̀kọ́ ìṣirò fi hàn pé àwọn ohun alààyè àtàwọn nǹkan míì tá à ń rí láyìíká wa jẹ́ iṣẹ́ ọnà àfòyeṣe àti pé àwọn onílàákàyè ẹ̀dá pàápàá gbà bẹ́ẹ̀. Wọ́n wá rọ àwọn iléèwé pé kí wọ́n fi ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ ọnà àfòyeṣe kún ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni níléèwé. Àríyànjiyàn ńlá wà nílẹ̀ báyìí nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, pàápàá nílẹ̀ Amẹ́ríkà, a sì tún gbúròó pé ó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Netherlands, Pakistan, Serbia àti Turkey.
Wọ́n Gbójú Fo Ohun Tó Ṣe Pàtàkì
Àmọ́ ṣá o, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì yìí ò mẹ́nu kan nǹkan kan nínú àlàyé tí wọ́n ṣe pé àwọn ohun tá à ń rí ní àyíká wa jẹ́ iṣẹ́ ọnà àfòyeṣe. Wọ́n ṣọ́ ọ̀rọ̀ lò débi pé wọn ò sọ̀rọ̀ kan ẹni tó ṣe iṣẹ́ ọnà yìí. Ǹjẹ́ o gbà gbọ́ pé iṣẹ́ ọnà kan lè ṣàdédé wà láìsí ẹni tó ṣe é? Ìwé ìròyìn The New York Times Magazine sọ pé àwọn tó ń tan ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ ọnà àfòyeṣe yìí kálẹ̀ “kò sọ nǹkan pàtó nípa ẹni tàbí ohun tó ṣe iṣẹ́ àrà tí wọ́n sọ pé ó wà nínú ìṣẹ̀dá.” Òǹkọ̀wé Claudia Wallis sọ pé àwọn tó ń polongo ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọnà àfòyeṣe máa ń “gbìyànjú láti má sọ̀rọ̀ kan Ọlọ́run rárá nínú àlàyé wọn.” Ìwé ìròyìn Newsweek sì sọ pé: “Ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọnà àfòyeṣe ò sọ nǹkan kan nípa bóyá ẹni tó ṣe iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá wà tàbí kò sí, kò sì sọ bí onítọ̀hún ṣe jẹ́.”
Àmọ́ asán ni gbogbo àlàyé wọn máa já sí tí wọ́n bá gbójú fo ẹni tó ṣe iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá. Àbí, ṣé àlàyé nípa iṣẹ́ àrà tá a rí nínú ìṣẹ̀dá tó wà láyé àti lójú ọ̀run àti nípa ìwàláàyè ohun abẹ̀mí máa kún rẹ́rẹ́ bí ẹni tó ń ṣàlàyé bá gbójú fo ẹni tó ṣe iṣẹ́ àrà náà tàbí bí ò bá fẹ́ sọ̀rọ̀ kàn án rárá?
Ara àwọn ìbéèrè pàtàkì táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń jiyàn lé lórí tó bá dọ̀rọ̀ bóyá kí wọ́n sọ ẹni tó ṣe iṣẹ́ àrà tó wà nínú ìṣẹ̀dá tàbí kí wọ́n má sọ ọ́ ni: Táwọn bá gbà pé olóye kan tó ju èèyàn lọ ló ṣẹ̀dá àwọn nǹkan, ṣé ìyẹn ò ní ṣèdíwọ́ fún ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti béèyàn ṣe ń lo làákàyè? Ṣé téèyàn ò bá rí àlàyé kankan ṣe mọ́ ni kó kàn gbà pé ẹni olóye kan ló ṣe iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá? Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kí iṣẹ́ ọnà tá à ń rí lára ìṣẹ̀dá múni gbà pé ẹnì kan ló ṣe àwọn iṣẹ́ àrà náà? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn míì tó jẹ mọ́ ọn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Charles Darwin gbà gbọ́ pé ńṣe ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀dá alààyè tá à ń rí ṣèèṣì wà
[Credit Line]
Àwòrán Darwin: Fọ́tò látọwọ́ Ìyáàfin J. M. Cameron àti U.S. National Archives