Bó o Bá Gbà Pé Ìṣẹ̀dá Jẹ́ Iṣẹ́ Àrà Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ẹni Tó Ṣe É
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló ti gbọ́ nípa Michelangelo, ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan tó jẹ́ ayàwòrán àti oníṣẹ́ ọnà. Tí ìwọ náà bá rí èyíkéyìí nínú àgbà iṣẹ́ ọnà tó ṣe, ó ṣeé ṣe kó o gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ òpìtàn iṣẹ́ ọnà tó pè é ní “oníṣẹ́ ọ̀nà tí kò lẹ́gbẹ́.” Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ fi hàn pé àgbà oníṣẹ́ ọnà ni. Àbí ta ló máa sọ pé iṣẹ́ ọnà rẹ̀ wú òun lórí tí ò ní gbà pé ọ̀gá ló jẹ́ nídìí iṣẹ́ ọnà?
Wàyí o, fojú ìyẹn wo ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ onírúurú ohun alààyè tó wà láyé yìí. Ìwé ìròyìn The New York Times ṣàyọlò ọ̀rọ̀ ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀dá abẹ̀mí, ọ̀rọ̀ yẹn sì bá a mu gan-an ni. Ó ní: “Ó hàn lára gbogbo ohun abẹ̀mí pé ẹnì kan ló dá wọn.” Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí tún sọ pé: “Gbogbo ibi tá a bá wò la ti ń rí iṣẹ́ ọnà àràbarà tó jọ wá lójú gan-an nínú ìṣẹ̀dá.” Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbà pé iṣẹ́ ọnà àràbarà kan wú òun lórí kó má sì gbà pé ẹnì kan ló ṣe é?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó fara balẹ̀ ṣàkíyèsí àwọn ohun tó wà yí i ká sọ pé àwọn èèyàn kan ń “bọ nǹkan tí Ọlọ́run dá, wọ́n ń tẹríba fún wọn, dípò èyí tí [wọn] ìbá fi máa sin ẹni tí ó dá wọn.” (Róòmù 1:25, Ìròhìn Ayọ̀) Ẹ̀kọ́ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n tó gbayé kan ló mú káwọn kan má gbà pé iṣẹ́ ọnà tó wà lára ìṣẹ̀dá fi hàn dájúdájú pé ẹnì kan ní láti wà tó ṣe wọ́n. Àmọ́, ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n yìí tiẹ̀ bá ojúlówó ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu? Ìwé ìròyìn The New York Times sọ ohun tí bíṣọ́ọ̀bù àgbà ìjọ Kátólíìkì tó wà nílùú Vienna, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Christoph Schönborn, sọ nípa ọ̀rọ̀ náà, ó ní: “Ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tó bá ti ta ko ẹ̀rí jáǹrẹrẹ tá à ń rí, èyí tó fi hàn pé iṣẹ́ àrà tó wà nínú ìṣẹ̀dá jẹ́ ohun àfòyeṣe, tàbí tó ṣàì ka àwọn ẹ̀rí náà sí, kì í ṣe ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì rárá, àbá tí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ lásán ni.”
Ṣé Táráyé Bá Gbà Pé Ẹlẹ́dàá Wà Òpin Dé Bá Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Nìyẹn?
Àwọn kan wà ṣá o, tí wọ́n ń bẹ̀rù pé táráyé bá lọ gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, ìyẹn “yóò paná ìfẹ́ tí aráyé ní láti máa ṣèwádìí.” Irú ohun tí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn New Scientist sọ nìyẹn. Ó ní: “Kò sẹ́ni tí yóò tún máa ṣe kàyéfì mọ́ nípa ìdí táwọn nǹkan kan fi wà bí wọ́n ṣe wà, nítorí èèyàn á ti gbà pé ‘ó wu ẹni tó ṣẹ̀dá wọn ló ṣe dá wọn bẹ́ẹ̀.’ Bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó máa ń jẹ́ kéèyàn lè ṣèwádìí débi tó wù ú yóò sì ṣe dópin nìyẹn.” Ṣùgbọ́n, ṣé ìbẹ̀rù yẹn lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀? Rárá o. Kódà ìgbà téèyàn bá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà gan-an nìwádìí á túbọ̀ pọ̀ sí i. Kí nìdí tó fi máa rí bẹ́ẹ̀?
Tá a bá gbà pé ńṣe ni gbogbo nǹkan láyé àtọ̀run, títí kan àwọn ohun abẹ̀mí, kàn ṣèèṣì wáyé, pé kò sẹ́ni tó dá wọn, ìyẹn ò ní jẹ́ ká lè ṣèwádìí tó nítumọ̀ nípa wọn, torí kò lè sí àlàyé tó nítumọ̀ rárá fóhun tó kàn ṣèèṣì ṣẹlẹ̀. Àmọ́ tá a bá gbà pé Ẹlẹ́dàá olóye kan ló ṣẹ̀dá gbogbo ohun tá à ń rí, ìyẹn lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí nípa ọgbọ́n àti òye tó lò láti ṣe àwọn nǹkan tó wà nínú ayé àti lójú ọ̀run. Wo àpẹẹrẹ kan ná, bí àwọn òpìtàn iṣẹ́ ọnà bá mọ oníṣẹ́ ọnà tó ṣe iṣẹ́ ọnà kan, ìyẹn kì í dí wọn lọ́wọ́ láti ṣèwádìí síwájú sí í nípa ọgbọ́n tó fi ṣe é àti ohun tó lò. Nítorí náà, kò yẹ kí gbígbà téèyàn gbà pé Ẹlẹ́dàá wà paná ìfẹ́ téèyàn ní láti ṣèwádìí nípa àwọn ohun tó dá.
Bíbélì ò ṣèdíwọ́ fún ìwádìí ṣíṣe o, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló gbà wá níyànjú pé ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì àtàwọn ìbéèrè tá jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run. Láyé ọjọ́un, nígbà tí Dáfídì Ọba ronú jinlẹ̀ nípa bí ara òun látòkèdélẹ̀ ṣe jẹ́ iṣẹ́ àrà ńlá, ó ní: “Lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.” (Sáàmù 139:14) Bíbélì tiẹ̀ fi yé wa pé Ẹlẹ́dàá bi Jóòbù, baba ńlá ìgbàanì léèrè pé: “Ìwọ ha ti fi làákàyè ronú nípa àwọn àyè fífẹ̀ ilẹ̀ ayé?” (Jóòbù 38:18) Ìbéèrè yìí ò paná ìfẹ́ téèyàn ní láti ṣèwádìí, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ àgbà oníṣẹ́ àrà ń fi ìbéèrè yẹn rọ Jóòbù pé kó ṣèwádìí nípa iṣẹ́ ọwọ́ òun. Tún wo ọ̀rọ̀ tí wòlíì Aísáyà kọ, èyí tó sọ pé ká túbọ̀ mọ̀ nípa Ẹni tó dá gbogbo nǹkan tó wà yí wa ká. Ó ní: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí?” Ńṣe ni ìwé Aísáyà 40:26 yìí ń jẹ́ kó yé wa pé ẹni tó ní agbára gíga lọ́nà tó bùáyà ló dá ayé àtọ̀run. Èyí sì bá àwárí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe mu, pé ipasẹ̀ oríṣi agbára kan làwọn nǹkan fi máa ń wáyé.
Lóòótọ́, kì í rọrùn rárá nígbà míì láti rí ìdáhùn sí àwọn nǹkan tá a máa ń fẹ́ mọ̀ nípa ìṣẹ̀dá. Ara ohun tó sì fà á ni pé ó níbi tí òye àwa èèyàn mọ àti pé kì í ṣe gbogbo nǹkan la mọ̀ nípa ilẹ̀ ayé tá à ń gbé yìí. Jóòbù pẹ̀lú mọ ìyẹn dájú. Ó yin Ẹlẹ́dàá tó mú kí ayé wa yìí wà lófuurufú láìsí ohun téèyàn rí pé ó so ó rọ̀ síbẹ̀, tó sì tún ń mú kí òjò rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lójú sánmà láìjábọ́. (Jóòbù 26:7-9) Síbẹ̀, Jóòbù gbà pé ‘bèbè àwọn ọ̀nà Ẹlẹ́dàá’ ni irú àwọn iṣẹ́ àrà bẹ́ẹ̀ ṣì jẹ́. (Jóòbù 26:14) Láìsí àní-àní, Jóòbù ń fẹ́ láti mọ̀ sí i nípa ayé yìí àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. Dáfídì pàápàá gbà pé ó níbi tí òye òun mọ, ó ní: “Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àgbàyanu gidigidi fún mi. Ó ga sókè tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ọwọ́ mi kò fi lè tẹ̀ ẹ́.”—Sáàmù 139:6.
Téèyàn bá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, ìyẹn ò lè ṣèdíwọ́ fún ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì rárá. Ìwádìí téèyàn lè ṣe nípa àwọn nǹkan tó ṣeé fojú rí àtàwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ọlọ́run kò lópin, títí gbére ni pàápàá. Ọba ìgbàanì kan tó ní ìmọ̀ gan-an tí òkìkí rẹ̀ sì kàn kọ̀wé tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Ó fi èrò wíwà títí ayé sí ọmọ èèyàn lọ́kàn, síbẹ̀ aráyé ó lè mọ iṣẹ́ Ọlọ́run tán látìbẹ̀rẹ̀ dópin.”—Oníwàásù 3:11, Bíbélì Holy Bible—New Life Version.
Ṣé “Ohun Àfi-dígẹrẹwú” Ni Ọlọ́run?
Àwọn kan sọ pé táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ọnà àfòyeṣe ò bá ti rí àlàyé tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu ni wọ́n máa ń dọ́gbọ́n fi ọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run “gba ara wọn sílẹ̀.” Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun táwọn yìí ń sọ ni pé tí wọ́n bá sọ pé Ọlọ́run ló ṣe iṣẹ́ àrà kan kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run gidi kan wà. Wọ́n ní ńṣe ni wọ́n kàn ń dọ́gbọ́n lo ọ̀rọ̀ náà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “ohun àfi-dígẹrẹwú” tàbí láti fi gba ara wọn sílẹ̀ “níbi tí wọ́n bá ti há pátápátá,” tí wọn ò mọ bí wọ́n ṣe lè fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá mọ́. Ibo wá ni wọ́n ti ń há pátápátá nínú àlàyé wọn? Ṣé àlàyé àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí ò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan ni kò yé wọn ni? Ó tì o. Àlàyé àwọn nǹkan tó ṣe kókó ni, èyí táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n tí ọ̀gbẹ́ni Darwin dá sílẹ̀ pàápàá ò rójútùú rẹ̀. Wọ́n jẹ́ apá tó ṣe kókó nínú ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀dá abẹ̀mí, tó jẹ́ pé táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n bá bọ́rọ̀ débẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń há tí wọn kì í rí àlàyé ṣe mọ́. Ká sòótọ́, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n yìí gan-an, tó gbẹ́kẹ̀ lé àwọn àbá tí kò ní ojúlówó ẹ̀rí ló ń lo ẹfolúṣọ̀n gẹ́gẹ́ bí “ohun àfi-dígẹrẹwú” tó bá ti di pé wọ́n há tí wọn ò rí àlàyé tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu ṣe.
Ẹlẹ́dàá tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kì í ṣe “ohun àfi-dígẹrẹwú” níbi téèyàn ò bá ti rí àlàyé ṣe o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ẹni gidi tá a rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá látòkèdélẹ̀. Onísáàmù náà sọ pé gbogbo ìṣẹ̀dá pátá jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà, ó ní: “Ìwọ ni orísun gbogbo ìwàláàyè, nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ sì ni àwa ń rí ìmọ́lẹ̀.” (Sáàmù 36:9, Bíbélì Today’s English Version) Bíbélì ṣàpèjúwe Jèhófà lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú pé òun ni Ẹni “tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.” (Ìṣe 4:24; 14:15; 17:24) Òótọ́ ọ̀rọ̀ sì ni olùkọ́ kan ní ọ̀rúndún kìíní sọ nínú ìwé tó kọ pé Ọlọ́run ló “dá ohun gbogbo.”—Éfésù 3:9.
Láfikún, Ọlọ́run fi “àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run” lélẹ̀, ìyẹn àwọn òfin tó ń ṣàkóso gbogbo agbára tó gbé ilé ayé àti ìsálú ọ̀run ró, èyí tó jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣì ń ṣèwádìí nípa rẹ̀. (Jóòbù 38:33) Àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run tá a rí nínú ìṣẹ̀dá pé pérépéré ó sì nídìí tó fi ṣe wọ́n. Wọ́n ń mú kí ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, ìyẹn ni pé kí ilé ayé jẹ́ ibi tí ọ̀kẹ́ àìmọye onírúurú ẹ̀dá alààyè ń gbé.
Iṣẹ́ Ọnà àti Làákàyè
Lákòótán, ó yẹ ká ronú nípa ohun táwa èèyàn náà mọ̀ pé ó bọ́gbọ́n mu. Nígbà tí òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ John Horgan ń sọ̀rọ̀ nípa bí àbá táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń dá ṣe lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ sí, ó ní: “Tí ẹ̀rí kan ò bá tíì dájú, kì í ṣe ohun àbùkù rárá tá a bá lo làákàyè wa láti fi mọ ohun tó tọ̀nà.”
Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ńṣe ni ìwàláàyè gbogbo ohun abẹ̀mí kàn ṣèèṣì wáyé, pé kò sí ẹlẹ́dàá kankan níbikíbi tó dá a? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbilẹ̀, síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olóye èèyàn, títí kan àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan, ló gbà pé Ẹlẹ́dàá kan tó jẹ́ olóye wà. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò “gbà dájúdájú pé ẹnì kan ló dìídì ṣẹ̀dá àwọn ohun abẹ̀mí, èrò wọn yìí sì bọ́gbọ́n mu.” Kí nìdí tí wọ́n fi gbà bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló máa gbà láìjanpata pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan.” (Hébérù 3:4) Pọ́ọ̀lù wá fi àlàyé tó bọ́gbọ́n mu parí ọ̀rọ̀ yẹn báyìí pé: “Ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” Ohun tí Bíbélì sọ yìí fi hàn pé kò bọ́gbọ́n mu rárá pé kí ẹni tó gbà pé ilé ò lè dá ara rẹ̀ kọ́, pé èèyàn ló máa yàwòrán rẹ̀ tó sì máa kọ́ ọ, tún máa wá sọ pé ńṣe ni sẹ́ẹ̀lì ara ẹ̀dá abẹ̀mí, tó jẹ́ pé ó díjú gan-an, kàn ṣèèṣì wáyé.
Bíbélì sọ nǹkan kan nípa àwọn tí kò gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó ṣe àwọn iṣẹ́ àrà tó wà nínú ìṣẹ̀dá, ó ní: “Òpònú sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: ‘Jèhófà kò sí.’” (Sáàmù 14:1) Ńṣe ni onísáàmù náà ń fi ọ̀rọ̀ yìí bá àwọn tí ò tíì gbà pé Ẹlẹ́dàá wà wí. Ní tàwọn èèyàn kan, èrò ọkàn tiwọn nìkan ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé dípò kí wọ́n fara balẹ̀ wo ohun tó bọ́gbọ́n mu. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n àti olóye èèyàn máa ń gbà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé Ẹlẹ́dàá wà.—Aísáyà 45:18.
Ní tàwọn onílàákàyè ẹ̀dá, ẹ̀rí rẹpẹtẹ tí wọ́n rí níbi gbogbo jẹ́ kó dá wọn lójú hán-ún pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó jẹ́ oníṣẹ́ àrà tó ga jù.
O Lè Mọ Ẹlẹ́dàá Tó Jẹ́ Oníṣẹ́ Àrà Náà
Tá a bá gbà pé ẹnì kan ló ṣẹ̀dá wa, kí nìdí tó fi dá wa? Kí ló fẹ́ ká fi ìwàláàyè wa ṣe? Ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì nìkan ò lé dáhùn àwọn ìbéèrè yìí lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ó yẹ ká rí ìdáhùn tó yéni tó sì tẹ́ni lọ́rùn sáwọn ìbéèrè yìí. Orí kókó yìí gan-an ni Bíbélì ti ṣèrànlọ́wọ́ fún wa. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé, yàtọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ Ẹlẹ́dàá, ó tún jẹ́ ẹni tó ní ìdí tó yé kooro tó fi ń ṣe àwọn nǹkan. Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn tó fi dá ọmọ èèyàn, ìyẹn sì ń jẹ́ ká rí i pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa lọ́jọ́ ọ̀la.
Ta ni Jèhófà? Irú Ọlọ́run wo ló jẹ́? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rọ̀ ọ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ Ẹlẹ́dàá wa, oníṣẹ́ àrà náà dáadáa. O lè mọ orúkọ rẹ̀ àti àwọn ànímọ́ rẹ̀ àtàwọn ọ̀nà tó ti gbà bá àwọn ọmọ aráyé lò. Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò jẹ́ kó o rí ìdí tó fi jẹ́ pé, kì í ṣe kí iṣẹ́ àrà tó ṣe kàn wú wa lórí nìkan ni, ó tún yẹ ká fògo fún òun tó jẹ́ Oníṣẹ́ Àrà náà.—Sáàmù 86:12; Ìṣípayá 4:11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Michelangelo
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ó bá ojúlówó ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì mu láti gbà pé Ẹni olóye kan ló ṣe iṣẹ́ àrà tó wà nínú ìṣẹ̀dá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Bí àwọn ẹ̀dá tó jẹ́ irú kan náà ṣe yàtọ̀ síra lónírúurú ọ̀nà tí wọ́n sì lè mú ara wọn bá àyíká wọn mu jẹ́ ẹ̀rí pé olóye kan ló dìídì ṣe wọ́n lọ́nà bẹ́ẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Iṣẹ́ àrà kò lè ṣe ara rẹ̀, ẹnì kan ló ṣe é