ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 10/1 ojú ìwé 8-11
  • Àwọn Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò Tí wọn Ò Láyọ̀ Ló “Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò Tí wọn Ò Láyọ̀ Ló “Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àjèjì Kan Wà Nídìí Kànga
  • Ìdílé Kan Tí Kò Láyọ̀
  • Àwọn Ọmọ Rákélì
  • Ikú àti Ogún
  • Jékọ́bù Ní Ìdílé Ńlá
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Jékọ́bù Lọ Sí Háránì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Jékọ́bù Mọyì Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìgbà Wo Ni Jèhófà Máa Ń Bù Kún—Ìsapá Tí A Fi Taratara Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 10/1 ojú ìwé 8-11

Àwọn Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò Tí wọn Ò Láyọ̀ Ló “Kọ́ Ilé Ísírẹ́lì”

BÍ ILẸ̀ ṣe ń mọ́ bọ̀, Léà mọ̀ pé àṣírí ò ní pẹ́ tú. Jékọ́bù ò ní pẹ́ mọ̀ pé Léà ló sùn ti òun kì í ṣe Rákélì àbúrò rẹ̀. Ó ní láti jẹ́ pé Léà faṣọ bojú gan-an, ó sì wá dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn tí wọ́n ṣètò fún Jékọ́bù àti Rákélì ní òru mọ́jú ọjọ́ tá à ń wí yìí. Ó sì dájú pé bàbá rẹ̀ ló ní kó ṣe bẹ́ẹ̀.

Fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ náà ti ní láti rí lára Jékọ́bù nígbà tí ilẹ̀ mọ́ tó rí i pé wọ́n ti tan òun jẹ! Tìbínú-tìbínú ló fi lọ bá Lábánì, bàbá Léà. Gbogbo àkókò yìí ni Léà yóò ti máa ronú lórí ipa tóun kó nínú ìtànjẹ náà àti ohun tó lè yọrí sí bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Ìtàn Léà àti Rákélì jẹ́ apá pàtàkì kan nínú Bíbélì. Ó tún jẹ́ ká rídìí tí ìgbéyàwó ọkọ-kan-aya-kan fi bọ́gbọ́n mu, kí ọkọ àti aya sì jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn.

Àjèjì Kan Wà Nídìí Kànga

Ọdún méje ṣáájú àkókò yẹn ni Rákélì sáré wálé tó wá sọ fún bàbá rẹ̀ pé òun rí àjèjì kan nídìí kànga tó sọ pé ìbátan àwọn lòun. Jékọ́bù ni àjèjì yìí, ìyẹn ọmọ obìnrin kan, tó jẹ́ àbúrò bàbá Rákélì, tó sì tún jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà. Oṣù kan lẹ́yìn ìyẹn ni Jékọ́bù sọ fún Lábánì pé òun á bá a ṣiṣẹ́ fún ọdún méje gbáko kóun lè gbé Rákélì níyàwó. Nígbà tí Lábánì rí i pé ọmọ àbúrò òun yìí ń ṣiṣẹ́ dáadáa tó sì tún mọ̀ pé àṣà tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn òun ni pé káwọn ìbátan fẹ́ ara wọn, ó fara mọ́ ohun tí Jékọ́bù sọ yìí.—Jẹ́nẹ́sísì 29:1-19.

Ìfẹ́ tí Jékọ́bù ní fún Rákélì kì í ṣe ìfẹ́ tí kò dénú. Ńṣe ni ọdún méje tí wọ́n fi fẹ́ ara wọn sọ́nà yẹn “dà bí ọjọ́ díẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ̀ fún ọmọbìnrin náà.” (Jẹ́nẹ́sísì 29:20) Níwọ̀n bí Jékọ́bù ti nífẹ̀ẹ́ Rákélì títí dìgbà tí Rákélì kú, ó fi hàn pé Rákélì ní láti ní ọ̀pọ̀ ànímọ́ tó fani mọ́ra gan-an.

Ṣé Léà náà ní in lọ́kàn pé ẹni tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn lóun máa fẹ́? Bíbélì ò sọ̀yẹn fún wa. Ohun tí ìtàn náà kàn jẹ́ ká mọ̀ dáadáa ni èrò Lábánì nípa ọ̀ràn náà. Lẹ́yìn tí iye ọdún tí Jékọ́bù fi fẹ́ Rákélì sọ́nà pé, Lábánì se àsè ìgbéyàwó. Ìtàn inú Bíbélì yìí sọ pé, àmọ́ nígbà tó di alẹ́, ó mú Léà wá sọ́dọ̀ Jékọ́bù “kí ó lè ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 29:23.

Ṣé Léà àti bàbá rẹ̀ jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti tan Jékọ́bù jẹ ni? Àbí ńṣe ló di dandan kí Léà ṣègbọràn sí bàbá rẹ̀? Ibo ni Rákélì wà lákòókò yẹn? Ǹjẹ́ ó mọ ohun tó ń lọ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀? Ṣé apàṣẹwàá ni bàbá rẹ̀ tó fi jẹ́ pé ohun tó bá sọ pé kó ṣe ló gbọ́dọ̀ ṣe? Bíbélì ò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Ohun yòówù kí Rákélì àti Léà rò nípa ọ̀ràn náà, ohun tá a mọ̀ ni pé ọ̀rọ̀ náà bí Jékọ́bù nínú gan-an. Jékọ́bù ò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí, Lábánì ló lọ bá tó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kì í ha ṣe nítorí Rákélì ni mo fi sìn ọ́? Nítorí náà, èé ṣe tí o fi ṣe àgálámàṣà sí mi?” Báwo ni Lábánì ṣe dá a lóhùn? O ní: “Kì í ṣe àṣà . . . láti fi obìnrin tí ó jẹ́ àbúrò fúnni ṣáájú àkọ́bí. Ṣe ayẹyẹ ọ̀sẹ̀ obìnrin yìí pé. Lẹ́yìn ìyẹn, a ó sì fi obìnrin kejì yìí fún ọ pẹ̀lú fún iṣẹ́ ìsìn tí ìwọ bá lè ṣe fún mi fún ọdún méje sí i.” (Jẹ́nẹ́sísì 29:25-27) Bí wọ́n ṣe jẹ́ kí Jékọ́bù di oníyàwó méjì nìyẹn, èyí sì fa owú burúkú.

Ìdílé Kan Tí Kò Láyọ̀

Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Rákélì gan-an. Nígbà tí Ọlọ́run rí i pé Jékọ́bù “kórìíra” Léà, ó ṣí ilé ọlẹ̀ rẹ̀, àmọ́ Rákélì yàgàn. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ọmọ nìkan ni Léà fẹ́, ó tún fẹ́ kí Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ òun pẹ̀lú. Nígbà tó rí i pé Rákélì nìkan ní Jékọ́bù fẹ́ràn, ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́. Síbẹ̀, Léà rò pé Jékọ́bù á nífẹ̀ẹ́ òun nígbà tó bí àkọ́bí ọmọkùnrin fún un tó pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì, èyí tó túmọ̀ sí “Ọmọkùnrin kan rèé!” Ó nídìí tí Léà fi sọ ọmọ rẹ̀ lórúkọ yìí, ó ní: “Ó jẹ́ nítorí pé Jèhófà ti wo ipò ìráre mi, ní ti pé, nísinsìnyí, ọkọ mi yóò bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ mi.” Àmọ́ Jékọ́bù ò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kò sì tún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nígbà tó bí ọmọkùnrin mìíràn pàápàá. Léà pe orúkọ ọmọ yẹn ní Síméónì, tó túmọ̀ sí “Gbígbọ́.” Ó sọ pé: “Ó jẹ́ nítorí pé Jèhófà ti fetí sílẹ̀, ní ti pé a kórìíra mi, nítorí náà, ó tún fi eléyìí fún mi.”—Jẹ́nẹ́sísì 29:30-33.

Bó ṣe sọ pé Ọlọ́run ti gbọ́ yẹn fi hàn pé ó ti ní láti gbàdúrà nípa ìṣòro rẹ̀ yìí. Ó dà bíi pé obìnrin tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ni. Síbẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn tó ní kò lọ, kódà lẹ́yìn tó bí Léfì, tó jẹ́ ọmọkùnrin kẹta pàápàá. Orúkọ ọmọ náà, tó túmọ̀ sí “Rọ̀ mọ́” tàbí “Dara pọ̀ mọ́” fi ohun tó wà lọ́kàn Léà hàn, ó sọ pé: “Wàyí o, lọ́tẹ̀ yìí, ọkọ mi yóò dara pọ̀ mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un.” Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, ó hàn gbangba pé Jékọ́bù ò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kíyẹn wá mú kí Léà gbà pé kò sóhun tóun lè ṣe sọ́ràn náà mọ́, nítorí pé orúkọ ọmọ rẹ̀ kẹrin kò sọ ohunkóhun tó fi hàn pé ó ṣì nírètí pé Jékọ́bù á nífẹ̀ẹ́ òun tó bá yá. Dípò ìyẹn, ńṣe ni pípè tó pe orúkọ ọmọ náà ní Júdà fi hàn pé ó ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run. Orúkọ náà “Júdà” túmọ̀ sí “Gbé lárugẹ,” tàbí “Ohun téèyàn ń gbé lárugẹ.” Léà kàn sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, èmi yóò gbé Jèhófà lárugẹ.”—Jẹ́nẹ́sísì 29:34, 35.

Lóòótọ́ ni ọkàn Léà gbọgbẹ́, àmọ́ inú Rákélì pàápàá ò dùn. Kódà ó bẹ Jékọ́bù pé: “Fún mi ní àwọn ọmọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò di òkú.” (Jẹ́nẹ́sísì 30:1) Rákélì mọ̀ pé Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ òun, àmọ́ ó wù ú láti di ìyá ọlọ́mọ. Léà láwọn ọmọ, àmọ́ ó fẹ́ kí ọkọ òun nífẹ̀ẹ́ òun. Ohun tí ẹnì kìíní ní ló ń wu ẹnì kejì, àwọn méjèèjì ò sì láyọ̀. Àwọn méjèèjì ló nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù tí wọ́n sì fẹ́ bímọ fún un. Àwọn méjèèjì sì ń jowú ara wọn. Ìbànújẹ́ wá jọba nínú ilé yẹn.

Àwọn Ọmọ Rákélì

Láyé ìgbà yẹn, ìṣòro ńlá ni wọ́n ka àìlèbímọ sí. Ọlọ́run ti ṣèlérí fún Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù pé látinú ìdílé wọn ni “irú ọmọ” tí gbogbo ìdílé ayé yóò tipasẹ̀ rẹ̀ bù kún ara wọn ti máa jáde wá. (Jẹ́nẹ́sísì 26:4; 28:14) Síbẹ̀, Rákélì ò bímọ. Jékọ́bù gbà pé Ọlọ́run nìkan ló lè fún Rákélì lọmọ, kó bàa lè nípìn-ín nínú irú ìbùkún bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ojú ń kán Rákélì. Ó sọ fún Jékọ́bù pé: “Bílíhà ẹrúbìnrin mi rèé. Ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí ó lè bímọ lórí eékún mi àti pé kí èmi, àní èmi, lè ní àwọn ọmọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 30:2, 3.

Ó lè má rọrùn fún wa láti lóye ohun tí Rákélì ṣe yìí. Àmọ́, àwọn àdéhùn ìgbéyàwó ayé ìgbàanì tí wọ́n rí láwọn àgbègbè Ìlà Oòrùn ayé fi hàn pé àṣà tí gbogbo èèyàn tẹ́wọ́ gbà ni pé kí aya tó bá yàgàn mú ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún ọkọ rẹ̀ kó lè bímọ tó máa jogún wọn.a (Jẹ́nẹ́sísì 16:1-3) Nígbà míì, ìyàwó ni wọ́n á sì gbà pé ó ní àwọn ọmọ tí ẹrúbìnrin náà bá bí.

Nígbà tí Bílíhà bí ọmọkùnrin kan, inú Rákélì dùn gan-an, ó sì sọ pé: “Ọlọ́run ti ṣe bí onídàájọ́ fún mi, ó sì tún ti fetí sí ohùn mi, tí ó fi jẹ́ pé ó fi ọmọkùnrin kan fún mi.” Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì, tó túmọ̀ sí “Onídàájọ́.” Èyí fi hàn pé òun náà ti gbàdúrà nípa ìṣòro tó ní. Nígbà tí Bílíhà bí Náfútálì, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kejì, tórúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Ìjàkadì mi,” Rákélì sọ pé: “Gídígbò tí a jà ní àjàkú-akátá ni mo bá arábìnrin mi jà. Mo sì ti mókè!” Àwọn orúkọ wọ̀nyẹn fi hàn pé ìjà orogún wà láàárín wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 30:5-8.

Ó ṣeé ṣe kí Rákélì rò pé òun ń ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tóun gbà nígbà tó mú Bílíhà fún Jékọ́bù, àmọ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run máa gbà fún un lọ́mọ kọ́ nìyẹn. Ẹ̀kọ́ kan lèyí jẹ́ fún wa. A ò gbọ́dọ̀ kánjú nígbà tá a bá ń bẹ Jèhófà fún ohun kan. Ó lè dáhùn àdúrà wa láwọn ọ̀nà tá ò fọkàn sí àti nígbà tá ò retí rẹ̀ rárá.

Léà kò fẹ́ kí Rákélì fìyẹn ju òun lọ, ló bá mú Sílípà, ìránṣẹ́bìnrin tiẹ̀ náà fún Jékọ́bù. Sílípà kọ́kọ́ bí Gádì, lẹ́yìn náà ó bí Áṣérì.—Jẹ́nẹ́sísì 30:9-13.

Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ tó túbọ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé àárín Rákélì àti Léà ò gún ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn máńdírékì kan tí Rúbẹ́nì, ọmọ Léà rí he. Àwọn èèyàn rò pé èso yìí máa ń jẹ́ kéèyàn lóyún. Nígbà tí Rákélì ní kó fóun ní díẹ̀ níbẹ̀, tìbínú-tìbínú ni Léà fi dáhùn pé: “Ohun kékeré ha nìyí, lẹ́yìn tí ìwọ ti gba ọkọ mi, o tún fẹ́ gba àwọn máńdírékì ọmọkùnrin mi pẹ̀lú?” Ohun táwọn kan gbà pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí túmọ̀ sí ni pé Jékọ́bù máa ń wà lọ́dọ̀ Rákélì lọ́pọ̀ ìgbà ju ọ̀dọ̀ Léà lọ. Ó ṣeé ṣe kí Rákélì rí i pé ó yẹ kí Léà bínú lóòótọ́, nítorí ó fèsì pé: “Nítorí ìdí yẹn, òun yóò sùn tì ọ́ ní òru òní ní pàṣípààrọ̀ fún àwọn máńdírékì ọmọkùnrin rẹ.” Látàrí èyí, bí Jékọ́bù ṣe ń dé lálẹ́ ọjọ́ náà ni Léà ti ń sọ fún un pé: “Èmi ni ìwọ yóò bá ní ìbálòpọ̀, nítorí pé mo ti fi àwọn máńdírékì ọmọkùnrin mi háyà rẹ pátápátá.”—Jẹ́nẹ́sísì 30:15, 16.

Léà wá bí Ísákárì, ọmọkùnrin kárùn-ún, ó tún bí Sébúlúnì, ọmọkùnrin kẹfà. Lẹ́yìn ìyẹn, ó wá sọ pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ọkọ mi yóò fi àyè gbà mí, nítorí pé mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́fà fún un.”b—Jẹ́nẹ́sísì 30:17-20.

Àwọn máńdírékì yìí kò ṣèrànwọ́ kankan. Ẹ̀yìn ọdún mẹ́fà tí Rákélì ti wà lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ ló tó wá lóyún tó sì bí Jósẹ́fù, ohun tó sì mú kíyẹn ṣeé ṣe ni pé Jèhófà “rántí” rẹ̀, ó sì dáhùn àdúrà rẹ̀. Ìgbà yẹn ni Rákélì tó lè sọ pé: “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn mi kúrò!”—Jẹ́nẹ́sísì 30:22-24.

Ikú àti Ogún

Rákélì kú níbi tó ti ń rọbí Bẹ́ńjámínì, ọmọkùnrin tó bí ṣìkejì. Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Rákélì tọkàntọkàn, bẹ́ẹ̀ ló sì fẹ́ràn àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tó bí fún un bí ojú. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tóun fúnra rẹ̀ fẹ́ kú, ó tún rántí ikú òjijì tó pa Rákélì olólùfẹ́ rẹ̀ ní rèwerèwe. (Jẹ́nẹ́sísì 30:1; 35:16-19; 48:7) A ò mọ ohunkóhun nípa ikú Léà ju pé Jékọ́bù sin ín sínú hòrò tó fẹ́ kí wọ́n sin òun náà sí.—Jẹ́nẹ́sísì 49:29-32.

Nígbà tí Jékọ́bù darúgbó, òun alára gbà pé ìgbésí ayé òun, títí kan àwọn ọ̀ràn ìdílé òun, kún fún wàhálà. (Jẹ́nẹ́sísì 47:9) Ó sì dájú pé nǹkan ò rọgbọ fún Léà àti Rákélì náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí jẹ́ ká rí ìbànújẹ́ tí ìkóbìnrinjọ máa ń fà, ó tún jẹ́ ká rídìí tí Jèhófà fi sọ pé aya kan ṣoṣo ni ọkùnrin kan gbọ́dọ̀ ní. (Mátíù 19:4-8; 1 Tímótì 3:2, 12) Owú jíjẹ ló máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ tí ọkàn ọkọ tàbí aya bá ń fà sí ẹlòmíì yàtọ̀ sí ara wọn tàbí tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn. Ìyẹn sì jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé àwọn èèyàn òun kò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè tàbí panṣágà.—1 Kọ́ríńtì 6:18; Hébérù 13:4.

Bó ti wù kó rí, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó jẹ́ aláìpé, síbẹ̀ tí wọ́n jólóòótọ́, ni Ọlọ́run ṣì ń lò láti mu àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Bíi tiwa náà làwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí ṣe níbi tí wọ́n kù díẹ̀ káàtó sí. Síbẹ̀, nípasẹ̀ àwọn obìnrin wọ̀nyí ni Jèhófà ti mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé Rákélì àti Léà ló “kọ́ ilé Ísírẹ́lì.”—Rúùtù 4:11.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú Nuzi, lórílẹ̀-èdè Iraq kà pé: “Wọ́n ti mú Kelim-ninu fún Shennima láti fi ṣaya. . . . Tí Kelim-ninu ò bá bímọ, Kelim-ninu yóò ra obìnrin kan [ẹrúbìnrin kan] tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Lullu gẹ́gẹ́ bí aya fún Shennima.”

b Dínà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ tí Léà bí nìkan ni ọmọbìnrin kan ṣoṣo tá a mọ orúkọ rẹ̀ lára àwọn ọmọbìnrin Jékọ́bù.—Jẹ́nẹ́sísì 30:21; 46:7.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ohun tí Léà ní wu Rákélì, ohun tí Rákélì náà ní wu Léà, àwọn méjèèjì ò sì láyọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àtọ̀dọ̀ àwọn ọmọkùnrin méjìlá tí Jékọ́bù bí ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti jáde

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́