Àwọn Àpáàdì Ayé Ìgbàanì Kín Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Lẹ́yìn
BÍBÉLÌ jẹ́ ìwé tí Ọlọ́run mí sí. (2 Tímótì 3:16) Òótọ́ pọ́ńbélé lohun tó sọ nípa àwọn èèyàn, àwọn àgbègbè tó mẹ́nu kàn, ẹ̀sìn àti báwọn ìjọba kan ṣe rí láyé àtijọ́. Ó dájú pé kò dìgbà táwọn awalẹ̀pìtàn bá ṣàwárí ẹ̀rí tiwọn ká tó mọ̀ pé òótọ́ lọ́rọ̀ inú Bíbélì, síbẹ̀ àwárí wọn máa ń kín ohun tó wà nínú Bíbélì lẹ́yìn tàbí kó mú kí òye rẹ̀ túbọ̀ yéni.
Àpáàdì ló sábà máa ń pọ̀ jù lára ohun táwọn awalẹ̀pìtàn máa ń rí nígbà tí wọ́n bá wa ibi táwọn èèyàn ti gbé rí. Látijọ́, ara àpáàdì yìí làwọn èèyàn máa ń kọ̀wé sí lọ́pọ̀ ibi ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, títí kan ilẹ̀ Íjíbítì àti Mesopotámíà, torí pé ó rọrùn láti rí. Bá a ṣe máa ń kọ nǹkan sínú ìwé pélébé tàbí bébà lóde òní ni wọ́n ṣe máa ń kọ àkọsílẹ̀ àdéhùn iṣẹ́, ìṣirò owó, ọ̀rọ̀ káràkátà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sínú àpáàdì. Yíǹkì ni wọ́n sábà máa fi ń kọ nǹkan sí i lára. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tàbí ọ̀rọ̀ mélòó kan tàbí ọ̀rọ̀ tó máa gba ìlà tó pọ̀.
Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àpáàdì táwọn èèyàn lò láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì làwọn awalẹ̀pìtàn tó walẹ̀ ní Ísírẹ́lì ti wú jáde. Àwọn àpáàdì tí wọ́n rí níbi mẹ́ta kan, ìyẹn Samáríà, Árádì àti Lákíṣì gbàfiyèsí wa. Ìdí ni pé àwọn ohun tó wà lára àwọn àpáàdì náà kín àwọn ìtàn kan nínú Bíbélì lẹ́yìn. Wọ́n ní àwọn àpáàdì yẹn ti wà láti nǹkan bí ọ̀rúndún keje sí ìkẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àkójọ àpáàdì náà yẹ̀ wò.
Àwọn Àpáàdì Tí Wọ́n Rí ní Samáríà
Samáríà ni olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó wà níhà àríwá kó tó di pé àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun ìlú náà lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìwé Àwọn Ọba kìíní orí kẹrìndínlógún ẹsẹ kẹtàlélógún sí ìkẹrìnlélógún sọ bí wọ́n ṣe tẹ ìlú náà dó, ó ní: “Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Ásà ọba Júdà [ìyẹn ọdún 947 ṣáájú Sànmánì Kristẹni], Ómírì di ọba lórí Ísírẹ́lì . . . Ó sì tẹ̀ síwájú láti ra òkè ńlá Samáríà lọ́wọ́ Ṣémérì ní tálẹ́ńtì fàdákà méjì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé sórí òkè ńlá náà, ó sì pe orúkọ ìlú ńlá tí ó tẹ̀ dó ní Samáríà.” Ìlú náà wà títí dìgbà tí ìjọba Róòmù fi wà lójú ọpọ́n gẹ́gẹ́ bí agbára ayé, tí wọ́n sì wá yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sebaste. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹfà Sànmánì Kristẹni, ìlú náà pa rẹ́.
Nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn kan walẹ̀ nílùú Samáríà ìgbàanì lọ́dún 1910, wọ́n ráwọn àpáàdì kan tí wọ́n sọ pé ó ti wà láti nǹkan bí ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àkọsílẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń gbé òróró àti wáìnì wá sílùú Samáríà látàwọn ìlú tó wà lágbègbè rẹ̀ wà lára àwọn àpáàdì tí wọ́n rí. Nígbà tí ìwé kan ń sọ nípa àwọn àpáàdì náà, ó ní: “Òótọ́ pọ́ńbélé ni pé àwọn àpáàdì mẹ́tàlélọ́gọ́ta tí wọ́n rí lọ́dún 1910 . . . jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tó ṣe pàtàkì jù lọ lára àwọn ohun ìṣàkọsílẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò nígbàanì tó ṣì wà dòní olónìí. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa okòwò tó wà nínú àwọn àpáàdì tí wọ́n rí nílùú Samáríà ló mú kí wọ́n ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ . . . bí kò ṣe ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, orúkọ agbo ìdílé àti orúkọ àwọn ibì kan tó wà nínú rẹ̀.” (Ìwé Ancient Inscriptions—Voices From the Biblical World) Báwo làwọn orúkọ yìí ṣe kín àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì lẹ́yìn?
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn tó wà ní Ilẹ̀ Ìlérí, tí wọ́n sì pín ilẹ̀ náà láàárín àwọn ẹ̀yà wọn, ẹ̀yà Mánásè ló gba àgbègbè Samáríà. Ìwé Jóṣúà 17:1-6 fi hàn pé wọ́n pín àgbègbè náà fún agbo ìdílé mẹ́wàá látọ̀dọ̀ Gílíádì ọmọ-ọmọ Mánásè. Àwọn ni agbo ìdílé ti Abi-ésérì, Hélékì, Ásíríélì, Ṣékémù àti ti Ṣẹ́mídà. Héfà ọmọkùnrin Gílíádì kẹfà kò láwọn ọmọ-ọmọ tó jẹ́ ọkùnrin, obìnrin làwọn márùn-ún tó ní, ìyẹn Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. Olúkúlùkù wọn sì gba ilẹ̀ tirẹ̀.—Númérì 27:1-7.
Wọ́n rí méje nínú orúkọ àwọn agbo ìdílé yẹn lára àwọn àpáàdì tí wọ́n wú nílùú Samáríà. Márùn-ún jẹ́ orúkọ àwọn ọmọkùnrin Gílíádì, méjì sì jẹ́ tàwọn ọmọbìnrin Héfà, ìyẹn Hógílà àti Nóà. Ìwé kan sọ pé: “Orúkọ àwọn agbo ìdílé tó wà lára àwọn àpáàdì tí wọ́n rí ní Samáríà jẹ́ ká rí ibòmíì yàtọ̀ sínú Bíbélì tí wọ́n ti dárúkọ àwọn agbo ìdílé Mánásè mọ́ àgbègbè tí Bíbélì sọ pé wọ́n tẹ̀ dó sí.” (NIV Archaeological Study Bible) Báwọn àpáàdì yẹn ṣe kín ìtàn Bíbélì lẹ́yìn nípa bí ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rí láyé ọjọ́un nìyẹn.
Àwọn àpáàdì tí wọ́n wú nílùú Samáríà tún kín ohun tí Bíbélì sọ lẹ́yìn nípa báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń ṣe ìjọsìn. Lásìkò tí wọ́n kọ ohun tó wà lára àwọn àpáàdì náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bọ Báálì, òrìṣà àwọn ará Kénáánì, pa pọ̀ mọ́ ìjọsìn Jèhófà. Hóséà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan, èyí tóun náà kọ ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó lọ́jọ́ ń bọ̀ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ronú pìwà dà, tí wọ́n á pe Jèhófà ní “ọkọ Mi” dípò “báálì Mi,” ìyẹn “olúwa Mi.” (Hóséà 2:16, 17, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Àwọn orúkọ kan tí wọ́n rí lára àwọn àpáàdì tí wọ́n wú ní Samáríà túmọ̀ sí “Báálì ni bàbá mi,” “Báálì ń kọrin,” “Báálì lágbára,” “Báálì rántí,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àní, tá a bá fi máa rí orúkọ èèyàn mọ́kànlá tí wọ́n pè mọ́ Jèhófà, a ó rí méje tí wọ́n pè mọ́ “Báálì.”
Àwọn Àpáàdì Tí Wọ́n Rí ní Árádì
Árádì jẹ́ ìlú kan láyé ìgbàanì, tó wà ní àgbègbè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ má yàtọ̀ sí aṣálẹ̀, tí wọ́n ń pè ní Négébù. Apá gúúsù Jerúsálẹ́mù ló wà. Àwọn awalẹ̀pìtàn tó walẹ̀ nílùú Árádì rí i pé ọ̀wọ́ àwọn ilé olódi mẹ́fà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ síbẹ̀ látìgbà ìjọba Sólómọ́nì (tó jọba lọ́dún 1037 sí 998 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) sígbà táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Árádì yìí làwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ọ̀pọ̀ jù lọ àpáàdì tí wọ́n kọ nǹkan sí, tó ti wà láti ayé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Ó ju igba orúkọ onírúurú ohun èlò tí wọ́n fi èdè Hébérù, Árámáíkì tàbí àwọn èdè míì kọ sára àwọn àpáàdì náà.
Àwọn nǹkan tí wọ́n kọ sára àwọn àpáàdì kan níbẹ̀ kín ohun tí Bíbélì sọ nípa ìdílé àwọn àlùfáà lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n rí ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọmọ Kórà,” tí Ẹ́kísódù 6:24 àti Númérì 26:11 sọ, lára àpáàdì kan. Àkọlé orí Sáàmù 42, 44 sí 49, àti 84, 85, 87 àti 88 fi hàn pé sáàmù wọ̀nyí jẹ́ ti “àwọn ọmọ Kórà.” Orúkọ ìdílé àwọn àlùfáà tó tún wà lára àwọn àpáàdì tí wọ́n rí ní Árádì ni ti “Páṣúrì” àti “Mérémótì.”—1 Kíróníkà 9:12; Ẹ́sírà 8:33.
Tún wo àpẹẹrẹ míì. Àwọn awalẹ̀pìtàn rí àpáàdì kan nínú àwókù ilé olódi kan tí wọ́n gbà pé ó ti wà ṣáájú ìgbà táwọn ará Bábílónì wá pa Jerúsálẹ́mù run. Balógun ilé olódi ní wọ́n kọ nǹkan tó wà nínú àpáàdì náà ránṣẹ́ sí. Ìwé kan sọ pé ara ohun tó wà lára àpáàdì náà ni: “Sí olúwa mi Élíyáṣíbù. Kí Yáwè [Jèhófà] máa fún yín lálàáfíà o. . . . Ní ti nǹkan tẹ́ ẹ pa láṣẹ fún mi: gbogbo nǹkan ti ń lọ déédéé: inú tẹ́ńpìlì Yáwè ló ń gbé báyìí.” (The Context of Scripture) Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé gbà pé tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n kọ́ nígbà ayé Sólómọ́nì, nibí yìí ń tọ́ka sí.
Àwọn Àpáàdì Tí Wọ́n Rí ní Lákíṣì
Lákíṣì, ìlú olódi kan láyé ìgbàanì, wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́tàlélógójì sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù. Nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn walẹ̀ níbẹ̀ lọ́dún 1930, wọ́n rí ọ̀wọ́ àwọn àpáàdì kan, wọ́n sì rí méjìlá lára wọn ó kéré tán, tí wọ́n sọ pé “ó ṣe pàtàkì gan-an . . . nítorí bí wọ́n ṣe jẹ́ ká mọ ipò tí àkóso ilẹ̀ Júdà wà, àti pákáǹleke tó bá àwọn ará ibẹ̀ nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Nebukadinésárì [ọba Bábílónì] ò ní pẹ́ gbógun jà wọ́n.”
Èyí tó ṣe pàtàkì jù lára àwọn lẹ́tà náà ni èyí tí ọmọ ogun kan kọ sí ọ̀gá rẹ̀ Yaosh, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀gágun tó wà ní Lákíṣì. Èdè tí wọ́n lò nínú lẹ́tà náà jọ èyí tí Jeremáyà wòlíì tó gbé ayé lásìkò yẹn lò nínú àwọn ìwé tó kọ. Wo bí méjì lára àwọn lẹ́tà náà ṣe kín ohun tí Bíbélì sọ nípa bí nǹkan ṣe rí lákòókò líle koko yẹn lẹ́yìn.
Nínú ìwé Jeremáyà 34:7, Jeremáyà sọ̀rọ̀ nípa ìgbà “tí ẹgbẹ́ ológun ọba Bábílónì ń bá Jerúsálẹ́mù jà àti gbogbo ìlú ńlá Júdà tí ó ṣẹ́ kù, Lákíṣì, àti Ásékà; nítorí àwọn, èyíinì ni àwọn ìlú ńlá olódi, ni ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ nínú àwọn ìlú ńlá Júdà.” Ó jọ pé ẹni tó kọ ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tí wọ́n rí ní Lákíṣì náà sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ó ní: “Àwọn àmì [ìyẹn iná] ti Lákíṣì là ń retí . . . torí a ò rí Ásékà.” Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé gbà pé èyí fi hàn pé àwọn ará Bábílónì ti ṣẹ́gun Ásékà àti pé Lákíṣì ló kàn. Ohun kan tó gbàfiyèsí ni, “àmì iná” tí ibí yìí mẹ́nu kàn. Jeremáyà 6:1 fi hàn pé wọ́n ń lo irú àmì bẹ́ẹ̀ láti fi bára wọn sọ̀rọ̀ láyé ọjọ́un.
Àwọn awalẹ̀pìtàn gbà pé lẹ́tà míì lára àwọn tí wọ́n rí yẹn kín ohun tí wòlíì Jeremáyà àti Ìsíkíẹ́lì sọ lẹ́yìn nípa bí ọba Júdà ṣe wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí Íjíbítì nígbà tó ṣọ̀tẹ̀ sí Bábílónì. (Jeremáyà 37:5-8; 46:25, 26; Ìsíkíẹ́lì 17:15-17) Lẹ́tà yẹn kà pé: “Wàyí o, ohun tí ìránṣẹ́ rẹ gbọ́ ni pé: Ọ̀gágun Konyahu ọmọ Élínátánì ti lọ sí apá gúúsù kó lè wọ ilẹ̀ Íjíbítì.” Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ńṣe lèyí túmọ̀ sí pé wọ́n fẹ́ lọ bẹ àwọn ọmọ ogun Íjíbítì kí wọ́n wá ran àwọn lọ́wọ́.
Wọ́n tún rí ọ̀pọ̀ orúkọ tó wà nínú ìwé Jeremáyà lára àwọn àpáàdì tí wọ́n rí ní Lákíṣì. Àwọn orúkọ yẹn ni Neráyà, Jaasánáyà, Gemaráyà, Élínátánì, Hóṣáyà. (Jeremáyà 32:12; 35:3; 36:10, 12; 42:1) Bóyá àwọn orúkọ tinú Bíbélì yìí náà ni wọ́n ń tọ́ka sí nínú àwọn àpáàdì yẹn, a ò lè sọ. Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àkókò yẹn kan náà ni Jeremáyà gbé ayé, bó ṣe jẹ́ pé orúkọ kan náà ni wọ́n mẹ́nu kàn gbàfiyèsí gan-an.
Ohun Tó Jọra Nínú Àkójọ Àpáàdì Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta
Àwọn àpáàdì tí wọ́n rí wú ní Samáríà, Árádì àti Lákíṣì kín ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó wà nínú Bíbélì lẹ́yìn. Ara àwọn nǹkan tó kín lẹ́yìn ni orúkọ àwọn ìdílé kan, àwọn àgbègbè kan tí Bíbélì dárúkọ, àti bí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti ètò ìjọba ṣe rí láyé ìgbà yẹn. Ṣùgbọ́n nǹkan pàtàkì kan wà tó jọra nínú àkójọ àpáàdì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
Àwọn gbólóhùn bíi “Kí àlàáfíà Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ” wà nínú àwọn lẹ́tà tí wọ́n kọ sára àwọn àpáàdì tí wọ́n rí ní Árádì àti Lákíṣì. Méje lára àwọn lẹ́tà tí wọ́n rí ní Lákíṣì mẹ́nu kan orúkọ Ọlọ́run nígbà mọ́kànlá. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ nínú àwọn orúkọ Hébérù tó wà lára àwọn àpáàdì tí wọ́n rí lọ́nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n pè mọ́ Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn àpáàdì wọ̀nyí fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń lo orúkọ Ọlọ́run dáádáá láyé ìgbà yẹn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àpáàdì tí wọ́n rí nínú àwókù ìlú Árádì, èyí tí wọ́n fi kọ lẹ́tà sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Élíyáṣíbù
[Credit Line]
Photograph © Israel Museum, Jerusalem; nípa ìyọ̀ǹda Israel Antiquities Authority
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Orúkọ Ọlọ́run rèé nínú lẹ́tà kan tí wọ́n fi àpáàdì kọ, èyí tí wọ́n rí nílùú Lákíṣì
[Credit Line]
British Museum ló yọ̀ǹda ká ya fọ́tò yìí