ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 7/1 ojú ìwé 23-25
  • Àwọn Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ìlú Teli Árádì Ń Jẹ́rìí sí Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ìlú Teli Árádì Ń Jẹ́rìí sí Bíbélì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìlú Árádì
  • Ohun Táwọn Awalẹ̀pìtàn Rí Nílùú Árádì
  • Àwọn Àpáàdì Ayé Ìgbàanì Kín Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Lẹ́yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ǹjẹ́ O Rántí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣé Bó Ṣe Wù Wá La Ṣe Lè Sin Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Orukọ Atọrunwa naa Jálẹ̀ Awọn Sanmanni
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 7/1 ojú ìwé 23-25

Àwọn Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Ìlú Teli Árádì Ń Jẹ́rìí sí Bíbélì

Ìlú kan wà láyé àtijọ́ àmọ́ kò sí mọ́. Tẹ́ńpìlì kan tó ṣàjèjì wà nílùú náà. Ibì kan wà nílùú ọ̀hún tí wọ́n kó àwọn ohun tí wọ́n kọ nǹkan sí lára láyé àtijọ́ pa mọ́ sí. Gbígbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí lè mú kó dà bíi pé èèyàn fẹ́ wo eré alárinrin kan. Àmọ́, kì í ṣọ̀rọ̀ eré o, àwọn nǹkan wọ̀nyí àtàwọn nǹkan mìíràn ti wà lábẹ́ ilẹ̀ aṣálẹ̀ ti ìlú Teli Árádì, lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn kó tó di pé àwọn awalẹ̀pìtàn hú wọn jáde.

Ọ̀PỌ̀ àwọn tó ti ṣèbẹ̀wò sí ìlú Árádì tòde òní sọ pé bí ìlú Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un gan-an ló ṣe rí. Ó wà ní aginjù Jùdíà ní ìwọ̀ oòrùn Òkun Òkú. Iye àwọn èèyàn tó ń gbé ibẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27,000]. Àmọ́, nǹkan bíi kìlómítà mẹ́jọ lápá ìwọ̀ oòrùn Òkun Òkú ni ìlú Árádì tó jẹ́ ìlú kan ní Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un wà. Ibí yìí ni àwọn awalẹ̀pìtàn ti rọra hú àwọn nǹkan àtayébáyé àtàwọn ohun tí wọ́n kọ nǹkan sí lára jáde nínú ilẹ̀.

Àwọn ohun tí wọ́n kọ nǹkan sí lára náà ni àwọn àpáàdì tí wọ́n ń lò gẹ́gẹ́ bí wàláà ìkọ̀wé. Ohun tí wọ́n ń kọ nǹkan sí lára nìyẹn láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Ibi táwọn awalẹ̀pìtàn ti hú àwọn nǹkan jáde nílùú Teli Árádì yìí ni wọ́n sọ pé àpáàdì tí wọ́n ń kọ nǹkan sí lára pọ̀ sí jù lọ lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àmọ́, báwo làwọn ohun tí wọ́n hú jáde náà ti ṣe pàtàkì tó?

Àwọn ohun tí wọ́n rí nílùú Teli Árádì jẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn láàárín àkókò gígùn kan, ìyẹn láti ọjọ́ àwọn Onídàájọ́ Ísírẹ́lì títí di ìgbà tí àwọn ará Bábílónì kógun ja ilẹ̀ Júdà lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nítorí náà, àwọn ohun tí wọ́n rí yìí mú kó túbọ̀ dáni lójú pé òótọ́ pọ́ńbélé làwọn ìtàn inú Bíbélì. Wọ́n tún jẹ́ ká rí àwọn àpẹẹrẹ tó ń lani lóye nípa ojú táwọn èèyàn fi ń wo orúkọ Ọlọ́run nílẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì.

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìlú Árádì

Lóòótọ́, Bíbélì ò sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa ìlú Árádì. Àmọ́ ìlú pàtàkì yìí ti fìgbà kan rí ṣàkóso ọ̀nà kan táwọn oníṣòwò ńlá máa ń gbà kọjá. Abájọ táwọn àkọsílẹ̀ ìtàn àtàwọn ohun táwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde máa ń sọ nípa ìlú àtijọ́ yìí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀tá ti ṣẹ́gun wọn, tí wọ́n pa ibẹ̀ run, tí wọ́n á sì tún ibẹ̀ kọ́. Kíkọ́ tí wọ́n máa ń tún ìlú náà kọ́ nígbà gbogbo mú kó di ìlú olókè.

Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kan ìlú Árádì ni ìgbà tó ń ṣèròyìn nípa apá ìparí ìrìn-àjò ogójì ọdún táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn nínú aginjù. Kété lẹ́yìn ikú Áárónì ẹ̀gbọ́n Mósè, àwọn èèyàn Ọlọ́run kọjá létí ibodè tó wà lápá gúúsù Ilẹ̀ Ìlérí. Ọba ìlú Árádì tó jẹ́ ọmọ Kénáánì yìí rò pé wẹ́rẹ́ báyìí lòun á kàn ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ló bá gbéjà kò wọ́n. Àmọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ìgbésẹ̀ akin, wọ́n dojú ìjà kọ ọ́, wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá náà pátápátá, wọ́n sì pa ìlú Árádì run yán-án yán-án, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jọ pé àwọn kan lára àwọn èèyàn ibẹ̀ yè bọ́.—Númérì 21:1-3.

Kò pẹ́ rárá táwọn ará Kénáánì fi ṣàtúnkọ́ ìlú wọn tó jẹ́ ibi tí oríṣiríṣi ìgbòkègbodò pàtàkì ti máa ń wáyé. Nígbà tí Jóṣúà débẹ̀ lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn náà, tó gbé ogun wọbẹ̀ láti ìhà àríwá tó sì rọra ń pa àwọn ọmọ Kénáánì rẹ́ díẹ̀díẹ̀ láti “ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà àti Négébù,” ọ̀kan lárá àwọn alátakò tó dojú ìjà kọ ọ́ ni “ọba Árádì.” (Jóṣúà 10:40; 12:14) Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ìran Hóbábù ẹni tí í ṣe Kénì, wá fìdí kalẹ̀ sí àgbègbè Négébù yìí. Àwọn ló dára pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n wà ní aginjù.—Onídàájọ́ 1:16.

Ohun Táwọn Awalẹ̀pìtàn Rí Nílùú Árádì

Tá a bá ń sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn tí wọ́n wá kọ sínú Bíbélì, àwọn àpáàdì tó wà ní Teli Árádì pèsè àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà jóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí àwọn ògiri kan. Àwọn kan lára wọn ti wà tipẹ́ láti ìgbà ìṣàkóso Sólómọ́nì Ọba, ẹni táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa fún kíkọ́ àwọn nǹkan pàtàkì sínú ìlú. (1 Ọba 9:15-19) Apá ibì kan tí wọ́n hú jáde jẹ́rìí sí i pé ibì kan wà tí wọ́n fi iná sun látìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹwàá ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Irú àwọn ohun tí wọ́n rí yìí ti wà láti ìgbà tí Ṣíṣákì Ọba Íjíbítì ti gbógun wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ìyẹn sì jẹ́ ọdún márùn-ún péré lẹ́yìn tí Sólómọ́nì kú. Ògiri kan tí wọ́n gbẹ́ àwòrán sí lára, tó wà nílùú Kánákì lápá gúúsù Íjíbítì ni wọ́n ṣe láti máa fi rántí ìṣẹ́gun ọ̀hún, Árádì sì wà lára orúkọ ọ̀pọ̀ ìlú tí wọ́n ṣẹ́gun.—2 Kíróníkà 12:1-4.

Ó gbàfiyèsí gan-an pé ọ̀pọ̀ lára igba [200] àpáàdì tí wọ́n rí níbẹ̀ ló ní àwọn orúkọ Hébérù tó tún wà nínú Bíbélì irú bíi Páṣúrì, Mérémótì àti àwọn ọmọ Kórà. Díẹ̀ lára àwọn àpáàdì náà gbàfiyèsí gan-an nítorí pé orúkọ Ọlọ́run wà lára wọn. Orúkọ náà jẹ́ lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n kọ báyìí: יהוה (YHWH). Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló ń jẹ́ orúkọ yìí. Nígbà tó yá, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé àrífín gbáà ló jẹ́ kéèyàn máa pe orúkọ Ọlọ́run tàbí kó kọ ọ́ sílẹ̀. Àmọ́, àwọn ohun tí wọ́n rí nílùú Teli Árádì yìí, bíi tàwọn tí wọ́n rí níbòmíràn, jẹ́ ẹ̀rí pé lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn èèyàn lo orúkọ Ọlọ́run dáadáa nínú ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́, wọ́n fi ń kí ara wọn, wọ́n sì fi ń súre fáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àkọlé kan sọ pé: “Sí olúwa mi Élíyáṣíbù. Kí Yáwè [Jèhófà] máa fún yín lálàáfíà o. ... Inú tẹ́ńpìlì Yáwè ló ń gbé báyìí.”

Àmọ́, báwo wá ni ti tẹ́ńpìlì tó ṣàjèjì tá a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí? Ilé kan tí wọ́n rí ní Teli Árádì ti mú káwọn èèyàn máa ronú nípa oríṣiríṣi nǹkan. Tẹ́ńpìlì ni ilé náà, ó sì ní pẹpẹ kan tó ti wà níbẹ̀ látìgbà tí ilẹ̀ Júdà ti wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́ńpìlì náà kéré ju tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ló fi jọ tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn mímọ́. Kí nìdí tí wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì Árádì yìí, ìgbà wo sì ni wọ́n kọ́ ọ? Kí ni wọ́n ń lò ó fún? Àwọn awalẹ̀pìtàn àtàwọn òpìtàn kò rí àlàyé tó dájú ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Jèhófà sọ ní pàtó pé tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù nìkan ni ibi tóun fọwọ́ sí pé káwọn èèyàn ti máa ṣayẹyẹ àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún, kí wọ́n sì máa rúbọ sóun níbẹ̀. (Diutarónómì 12:5; 2 Kíróníkà 7:12) Nítorí náà, kíkọ́ tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà nílùú Árádì lòdì sí àṣẹ Ọlọ́run. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pẹpẹ àti ààtò míì tó mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò nínú ìjọsìn mímọ́ ni wọ́n kọ́ ọ. (Ísíkíẹ́lì 6:13) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí Hesekáyà tàbí Jòsáyà ṣe àwọn àtúnṣe gidi kan ní ọ̀rúndún kẹjọ tàbí ìkeje ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ojúkò ayédèrú ìjọsìn yìí pa run.—2 Kíróníkà 31:1; 34:3-5, 33.

Ní kedere, díẹ̀ lára àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tó wà ní ìlú Árádì tó ṣì wà títí dòní ti kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. Lẹ́yìn tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ti kọjá lọ, àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tí wọ́n hú jáde fi hàn pé Bíbélì péye, pé ayédèrú ìjọsìn ti wà rí, ó sì ti pa rẹ́, àti pé àwọn èèyàn àtijọ́ lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nínú ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

JERÚSÁLẸ́MÙ

Òkun Òkú

Árádì

Teli Árádì

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Díẹ̀ lára àwòrán ara ògiri tó wà nílùú Kánákì nílẹ̀ Íjíbítì rèé

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Apákan àkọlé yìí kà pé: “Kí Yáwè [Jèhófà] máa fún yín lálàáfíà o”

[Credit Line]

Àwòrán © Israel Museum, tó wà ní Jerúsálẹ́mù; Israel Antiquities Authority lo yọ̀ǹda ká lo fọ́tò yìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Apá tó ṣe àfihàn pẹpẹ inú tẹ́ńpìlì tó wà ní Teli Árádì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Bí odi tó yí ìlú Teli Árádì ká ṣe rí rèé téèyàn bá wò ó láti apá ìlà oòrùn

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Todd Bolen/BiblePlaces.com

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́