Bó o Ṣe Lè Láwọn Ànímọ́ Tí Wàá Fi Lè Sọni Dọmọ Ẹ̀yìn
“Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—MÁTÍÙ 28:19.
1. Kí làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan nígbà láéláé ní láti mọ̀ kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, àwọn ànímọ́ wo sì ni wọ́n nílò?
LÁWỌN ìgbà míì, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní láti fúnra wọn wá ọ̀nà tí wọ́n máa gbà ṣe nǹkan tó pa láṣẹ fún wọn kí wọ́n sì tún láwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ábúráhámù àti Sárà ṣí kúrò ní Úrì tó jẹ́ ìlú tó lọ́rọ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún wọn, wọ́n ní láti wá kọ́ báwọn tó ń gbé inú àgọ́ ṣe ń ṣe. (Hébérù 11:8, 9, 15) Bákan náà, kí Jóṣúà tó lè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, ó ní láti ní ìgboyà, kó gbọ́kàn lé Jèhófà, kó sì mọ Òfin rẹ̀. (Jóṣúà 1:7-9) Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù ńkọ́? Ńṣe ni ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí wọ́n túbọ̀ mọṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe dunjú kí wọ́n bàa lè bójú tó iṣẹ́ kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn kí wọ́n sì tún ṣe lára iṣẹ́ náà àtàwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ọn.—Ẹ́kísódù 31:1-11.
2. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò lórí ọ̀rọ̀ sísọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn?
2 Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, Jésù Kristi pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn táwọn èèyàn máa láǹfààní láti ṣe irú iṣẹ́ ńláǹlà bẹ́ẹ̀. Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ ká ní bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn? Báwo la sì ṣe lè láwọn ànímọ́ náà?
Fi Hàn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Gan-an
3. Kí ni àṣẹ tí Jésù pa pé ká máa sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn jẹ́ ká láǹfààní láti ṣe?
3 A ní láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an ká tó lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ká sì máa gbìyànjú láti yí wọn lérò padà pé kí wọ́n jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́. Láyé ọjọ́un, ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ṣe láti fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni pé kí wọ́n máa fi gbogbo ọkàn wọn pa òfin rẹ̀ mọ́, kí wọ́n máa rú ẹbọ tó fẹ́, kí wọ́n sì máa fi orin yìn ín. (Diutarónómì 10:12, 13; 30:19, 20; Sáàmù 21:13; 96:1, 2; 138:5) Àwa tá à ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn pẹ̀lú ń pa òfin Ọlọ́run mọ́, àmọ́ ohun mìíràn tá a tún ń ṣe láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé à ń wàásù fáwọn èèyàn nípa rẹ̀ àtàwọn ohun tó pinnu láti ṣe. Ó yẹ ká máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa fi hàn pé ohun tá à ń sọ dá wa lójú, ká máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí ìrètí tí Ọlọ́run fún wa ṣe rí lọ́kàn wa.—1 Tẹsalóníkà 1:5; 1 Pétérù 3:15.
4. Kí nìdí tó fi máa ń dùn mọ́ Jésù láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà?
4 Nítorí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà jinlẹ̀, inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an tó bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe, nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ìjọsìn tòótọ́. (Lúùkù 8:1; Jòhánù 4:23, 24, 31) Àní ó tiẹ̀ sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:34) Jésù sì ni ọ̀rọ̀ onísáàmù náà ń tọ́ka sí, pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi. Mo ti sọ ìhìn rere òdodo nínú ìjọ ńlá. Wò ó! Èmi kò ṣèdíwọ́ fún ètè mi. Jèhófà, ìwọ alára mọ ìyẹn ní àmọ̀dunjú.”—Sáàmù 40:8, 9; Hébérù 10:7-10.
5, 6. Ànímọ́ pàtàkì wo ló yẹ káwọn tó ń sọni dọmọ ẹ̀yìn ní?
5 Ìfẹ́ táwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní fún Ọlọ́run máa ń mú kí wọ́n bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. Wọ́n sì máa ń fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ débi pé nígbà míì, wọ́n máa ń yí àwọn èèyàn lérò padà láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. (Jòhánù 1:41) Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run lohun pàtàkì tó ń mú ká máa sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé ká sì máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a bá kà kí iná ìfẹ́ yìí lè máa jó lọ́kàn wa.—1 Tímótì 4:6, 15; Ìṣípayá 2:4.
6 Kò sí àní-àní pé ìfẹ́ tí Jésù Kristi ní fún Jèhófà ló mú kó jẹ́ olùkọ́ tó nítara. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ló mú kó ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ kíkéde Ìjọba Ọlọ́run. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ànímọ́ míì tó mú kí Jésù kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn?
Fi Hàn Pé O Bìkítà Gan-an Nípa Àwọn Èèyàn
7, 8. Báwo ni Jésù ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn?
7 Jésù bìkítà nípa àwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún. Kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé pàápàá, ìyẹn nígbà tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, ìfẹ́ tó ní sáwọn nǹkan tó kan àwọn ọmọ èèyàn pọ̀ gan-an. (Òwe 8:30, 31) Nígbà tó sì wá sórí ilẹ̀ ayé, ó yọ́nú sáwọn èèyàn, ó máa ń mú kára tu àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Mátíù 11:28-30) Jésù fi ìfẹ́ àti ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn bíi ti Jèhófà, ìyẹn sì mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Onírúurú èèyàn máa ń gbọ́rọ̀ Jésù torí pé ó bìkítà gan-an nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún wọn.—Lúùkù 7:36-50; 18:15-17; 19:1-10.
8 Nígbà tí ọkùnrin kan bi Jésù léèrè nípa ohun tóun ní láti ṣe kóun tó lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun, “Jésù wò ó, ó sì ní ìfẹ́ fún un.” (Máàkù 10:17-21) A tún kà nípa àwọn kan tí Jésù kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ní Bẹ́tánì pé: “Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.” (Jòhánù 11:1, 5) Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ Jésù lógún débi pé lákòókò kan, ó yááfì ìsinmi kó bàa lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ ara rẹ̀ ń fẹ́ ìsinmi lákòókò náà. (Máàkù 6:30-34) Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jésù ní fáwọn èèyàn àti bó ṣe bìkítà gan-an nípa wọn mú kó jẹ́ ẹni tó mọ bá a ṣe ń fa èèyàn wá sínú ìsìn tòótọ́ ju ẹnikẹ́ni míì lọ.
9. Irú ẹ̀mí wo ni Pọ́ọ̀lù ní bó ṣe ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn?
9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú bìkítà gan-an nípa àwọn tó ń wàásù fún. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fáwọn tó di Kristẹni ní Tẹsalóníkà pé: “Ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.” Nítorí pé Pọ́ọ̀lù sapá tìfẹ́tìfẹ́ láti kọ́ àwọn tó ń gbé ìlú Tẹsalóníkà lẹ́kọ̀ọ́, àwọn kan lára wọn ‘yí padà kúrò nínú òrìṣà wọn láti sìnrú fún Ọlọ́run alààyè.’ (1 Tẹsalóníkà 1:9; 2:8) Tá a bá bìkítà nípa àwọn èèyàn gan-an bíi ti Jésù àti Pọ́ọ̀lù, inú àwa náà yóò dùn nígbà tí ìhìn rere bá wọ àwọn tí wọ́n “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” lọ́kàn.—Ìṣe 13:48.
Múra Tán Láti Yááfì Àwọn Nǹkan Kan
10, 11. Kí nìdí tó fi yẹ ká múra tán láti yááfì àwọn nǹkan kan bá a ṣe ń sapá láti sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn?
10 Àwọn tó ń ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn máa ń múra tán láti yááfì àwọn nǹkan kan. Ó dájú pé kíkó ọrọ̀ jọ kọ́ ló ṣe pàtàkì jù lójú wọn. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún àwọn tí wọ́n ní owó láti wọ ìjọba Ọlọ́run!” Ẹnu ya àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó tún fi kún un pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro láti wọ ìjọba Ọlọ́run! Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.” (Máàkù 10:23-25) Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe máa lépa ọrọ̀ kí wọ́n bàa lè pọkàn pọ̀ sórí sísọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 6:22-24, 33) Kí nìdí tí mímúra tán láti yááfì àwọn nǹkan fi máa jẹ́ ká lè sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn?
11 Ó gba ìsapá gidi ká tó lè kọ́ àwọn èèyàn ní gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ. Àwọn tó ń fẹ́ láti sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn Jésù sábà máa ń sapá láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Káwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run kan bàa lè túbọ̀ láǹfààní láti rí àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́, wọ́n fi iṣẹ́ tó máa ń gba gbogbo àkókò wọn sílẹ̀, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́. Bákan náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ èdè míì kí wọ́n lè wàásù fáwọn tó ń sọ èdè náà ládùúgbò wọn. Àwọn kan tiẹ̀ ti kó lọ ságbègbè míì tàbí orílẹ̀-èdè míì kí wọ́n bàa lè ṣe iṣẹ́ ìkórè náà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. (Mátíù 9:37, 38) Gbogbo èyí ló gba pé kéèyàn yááfì àwọn nǹkan kan. Àmọ́, àwọn nǹkan míì wà téèyàn ní láti ṣe kó tó lè dẹni tó ń ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn.
Ní Sùúrù, Síbẹ̀ Má Fàkókò Ṣòfò
12, 13. Kí nìdí tí sùúrù fi ṣe pàtàkì gan-an lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?
12 Sùúrù ni ànímọ́ míì tó máa ń jẹ́ ká lè sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. Lóòótọ́, ńṣe ló yẹ káwọn èèyàn máa tara ṣàṣà ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́ nínú ìwàásù wa, síbẹ̀, sísọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn máa ń gba àkókò gan-an ó sì tún gba sùúrù. (1 Kọ́ríńtì 7:29) Ńṣe ni Jésù mú sùúrù fún Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó hàn gbangba pé Jákọ́bù mọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù ń ṣe dáadáa, síbẹ̀ nǹkan kan dí i lọ́wọ́ fún àkókò kan tí kò fi di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Jòhánù 7:5) Àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé kò pẹ́ lẹ́yìn ikú Jésù ni Jákọ́bù dọmọ ẹ̀yìn, ìyẹn láàárín ìgbà tí Kristi kú sí Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, torí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ fi hàn pé òun náà wà níbi tí ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àtàwọn àpọ́sítélì kóra jọ pọ̀ sí láti gbàdúrà. (Ìṣe 1:13, 14) Jákọ́bù tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run débi pé nígbà tó yá, ó dẹni tí wọ́n gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta lé lọ́wọ́ nínú ìjọ Kristẹni.—Ìṣe 15:13; 1 Kọ́ríńtì 15:7.
13 Bíi tàwọn àgbẹ̀, àwọn nǹkan tó máa ń dàgbà díẹ̀díẹ̀ làwa Kristẹni ń gbìn sínú àwọn èèyàn, ìyẹn sì ni òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìfẹ́ fún Jèhófà àti níní irú ẹ̀mí tí Kristi ní. Ó sì gba sùúrù ká tó lè ṣe èyí. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ mú sùúrù, ẹ̀yin ará, títí di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa. Wò ó! Àgbẹ̀ a máa dúró de èso ṣíṣeyebíye ilẹ̀ ayé, ní mímú sùúrù lórí rẹ̀ títí yóò fi rí òjò àkọ́rọ̀ àti òjò àrọ̀kúrò. Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fìdí ọkàn-àyà yín múlẹ̀ gbọn-in, nítorí wíwàníhìn-ín Olúwa ti sún mọ́lé.” (Jákọ́bù 5:7, 8) Jákọ́bù rọ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ pé kí wọ́n ‘mú sùúrù títí di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa.’ Tí nǹkan kan ò bá yé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, ńṣe ló máa ń fi sùúrù ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn tàbí kó lo àpèjúwe. (Mátíù 13:10-23; Lúùkù 19:11; 21:7; Ìṣe 1:6-8) Ní báyìí tí Jésù sì ti ‘wà níhìn-ín,’ àwa náà ní láti mú sùúrù bá a ṣe ń sapá láti sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. A ní láti máa ṣe sùúrù tá a bá ń kọ́ àwọn tó ń di ọmọ ẹ̀yìn Jésù lóde òní lẹ́kọ̀ọ́.—Jòhánù 14:9.
14. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń mú sùúrù, báwo la ṣe lè fọgbọ́n lo àkókò wa lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń mú sùúrù, ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run kì í sèso nínú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Mátíù 13:18-23) Nítorí náà, tá a bá ti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́, àmọ́ tó jẹ́ pé ibi pẹlẹbẹ náà lọ̀bẹ fi ń lélẹ̀, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká má fàkókò ṣòfò lọ́dọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, dípò ìyẹn, ká wá àwọn tó mọyì òtítọ́ lọ. (Oníwàásù 3:1, 6) Àmọ́ ṣá o, ẹ máà jẹ́ ká gbàgbé pé ó máa ń gba àkókò káwọn tó mọyì òtítọ́ pàápàá tó lè yí èrò wọn, ànímọ́ wọn àtàwọn ohun tí wọ́n fi ṣáájú nígbèésí ayé padà. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń mú sùúrù bí Jésù ṣe mú sùúrù fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọn ò tètè yí èrò wọn tí kò tọ́ padà.—Máàkù 9:33-37; 10:35-45.
Mọ Onírúurú Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
15, 16. Kí nìdí tí àlàyé tó rọrùn láti lóye àti ìmúrasílẹ̀ fi ṣe pàtàkì láti lè sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn?
15 Lóòótọ́, ká tó lè sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn, ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká bìkítà nípa àwọn èèyàn, ká múra tán láti yááfì àwọn nǹkan kan, ká sì máa ní sùúrù. Àmọ́ ó tún yẹ ká mọ onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ká lè máa ṣàlàyé nǹkan lọ́nà tó ṣe kedere, tó sì rọrùn láti yéni. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun tí Jésù Kristi Olùkọ́ Ńlá náà sọ wọni lọ́kàn dáadáa nítorí pé wọ́n rọrùn láti lóye. Ó ṣeé ṣe kó o rántí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ, irú bí: “Ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run.” “Ẹ má ṣe fi ohun tí ó jẹ́ mímọ́ fún àwọn ajá.” “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 6:20; 7:6; 11:19; 22:21) Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ ṣókí nìkan kọ́ ni Jésù máa ń sọ o. Ó máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere, ó sì máa ń ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nígbà tó bá yẹ. Báwo lo ṣe lè máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ bíi ti Jésù?
16 Ohun pàtàkì tó máa jẹ́ kó o lè kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó rọrùn láti lóye tó sì ṣe kedere ni pé kó o máa múra sílẹ̀ dáadáa. Òjíṣẹ́ tí kò bá múra sílẹ̀ sábà máa ń sọ̀rọ̀ jù. Ó lè fi àpọ̀jù ọ̀rọ̀ bo àwọn kókó pàtàkì mọ́lẹ̀ níbi tó ti ń gbìyànjú láti sọ gbogbo ohun tó mọ̀ lórí kókó tí wọ́n ń gbé yẹ̀ wò. Àmọ́, òjíṣẹ́ tó múra sílẹ̀ dáadáa yóò ronú nípa ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ àti àkòrí tí wọ́n fẹ́ gbé yẹ̀ wò, á wá sọ ìwọ̀nba ohun tónítọ̀hún nílò. (Òwe 15:28; 1 Kọ́ríńtì 2:1, 2) Yóò fi ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ti mọ̀ àtàwọn kókó tó yẹ kóun tẹnu mọ́ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sọ́kàn. Ó ṣeé ṣe kó mọ ọ̀pọ̀ àlàyé tóun lè ṣe lórí kókó tí wọ́n ń gbé yẹ̀ wò, àmọ́ ẹ̀kọ́ náà á ṣe kedere tó bá yẹra fún ṣíṣe àlàyé tí kò pọn dandan.
17. Báwo la ṣe lè mú káwọn èèyàn ronú lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ?
17 Jésù tún máa ń mú káwọn èèyàn ronú fúnra wọn dípò táá fi ṣe gbogbo àlàyé fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó béèrè pé: “Kí ni ìwọ rò, Símónì? Lọ́wọ́ ta ni àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn ni tàbí lọ́wọ́ àwọn àjèjì?” (Mátíù 17:25) Ó ṣeé ṣe ká gbádùn ṣíṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì débi pé a máa ní láti kóra wa níjàánu ká bàa lè fún ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láyè láti sọ èrò rẹ̀ tàbí láti ṣàlàyé nǹkan kan nínú ohun tó ń kọ́ lọ́wọ́. A mọ̀ pé kò yẹ ká máa da ìbéèrè bo àwọn èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè fi ọgbọ́n, àpèjúwe tó dára àti ìbéèrè tó múná dóko mú káwọn èèyàn lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó wà nínú àwọn ìwé wa.
18. Kí ni lílo “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” gba pé ká ṣe?
18 Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.” (2 Tímótì 4:2; Títù 1:9) Lílo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kọjá pé ká kàn mú káwọn èèyàn há ẹ̀kọ́ Bíbélì sórí. Ńṣe ni ká gbìyànjú láti ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kó lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ẹ̀kọ́ òtítọ́ àti ẹ̀kọ́ èké, láàárín rere àti búburú, àti ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìwà ọlọ́gbọ́n àti ìwà òmùgọ̀. Bá a bá ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ tá a sì ń sapá láti gbin ìfẹ́ Jèhófà sọ́kàn rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó rí ìdí tó fi yẹ kóun máa ṣègbọràn sí Jèhófà.
Máa Fìtara Ṣe Iṣẹ́ Sísọni Dọmọ Ẹ̀yìn
19. Báwo ló ṣe jẹ́ pé gbogbo àwa Kristẹni là ń lọ́wọ́ nínú báwọn èèyàn ṣe ń dọmọ ẹ̀yìn?
19 Ìjọ tó ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn Kristi ni ìjọ Kristẹni jẹ́. Tẹ́nì kan bá dọmọ ẹ̀yìn, Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá a lọ tó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan kọ́ ló máa láyọ̀. Ńṣe ló dà bí ìgbà táwọn kan bá ń wá ọmọ tó sọ nù. Ó lè jẹ́ ọ̀kan lára wọn ló máa rí i. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá mú ọmọ náà padà sọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, gbogbo àwọn tó jọ wá a ni inú wọn máa dùn. (Lúùkù 15:6, 7) Bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn rí. Tẹ́nì kan bá dọmọ ẹ̀yìn, gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ la jọ ṣiṣẹ́ yẹn. Gbogbo àwa Kristẹni la jọ ń wá àwọn tó ṣeé ṣe kó dọmọ ẹ̀yìn Jésù. Tẹ́nì kan bá wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ náà lá máa ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè mọyì ìjọsìn tòótọ́. (1 Kọ́ríńtì 14:24, 25) Nítorí náà, gbogbo àwa Kristẹni ló yẹ ká máa yọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ń dọmọ ẹ̀yìn lọ́dọọdún.
20. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn?
20 Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni olóòótọ́ ló fẹ́ láti kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ìjọsìn tòótọ́, àmọ́ ó lè má tíì ṣeé ṣe fún wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní sí Jèhófà máa jinlẹ̀ sí i, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ ọ́ lógún, múra tán láti yááfì àwọn nǹkan kan, máa ní sùúrù kó o sì mọ onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máa fi sádùúrà pé ìfẹ́ ọkàn rẹ ni láti fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn. (Oníwàásù 11:1) Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn níwọ̀n bó o ti mọ̀ pé gbogbo nǹkan tó ò ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà jẹ́ ara iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn, èyí tó ń gbé Ọlọ́run ga.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Báwo ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn ṣe ń fi bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó hàn?
• Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ kí àwa tá à ń sọni dọmọ ẹ̀yìn ní?
• Kí ni ẹni tó bá ń lo “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” ní láti ṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Báwa Kristẹni ṣe ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn, à ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kí nìdí táwọn tó ń sọni dọmọ ẹ̀yìn fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ àwọn lógún?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ káwọn tó ń sọni dọmọ ẹ̀yìn ní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Gbogbo àwa Kristẹni ni inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí èso rere tí iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn ń so