ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 12/1 ojú ìwé 4-7
  • Kí Ló Ń Mú Káwọn Èèyàn Kan Wà Níṣọ̀kan Kárí Ayé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ń Mú Káwọn Èèyàn Kan Wà Níṣọ̀kan Kárí Ayé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbẹ̀rù Àwọn Nǹkan Ìjà Runlérùnnà Kò Jẹ́ Kí Ìṣọ̀kan Wà
  • Ẹni Tó Máa Mú Ojúlówó Ìṣọ̀kan Wá
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Mú Káwọn Èèyàn Wà Níṣọ̀kan
  • Ẹ Ní “Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín”
  • Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Kí Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Má Jà?
    Jí!—2004
  • Ìṣọ̀kan La Fi Ń dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ǹjẹ́ Ayé Lè Ṣọ̀kan?
    Jí!—2000
  • Ìṣọ̀kan Ìjọsìn ní Àkókò Wa—Kí Ló Túmọ̀ Sí?
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 12/1 ojú ìwé 4-7

Kí Ló Ń Mú Káwọn Èèyàn Kan Wà Níṣọ̀kan Kárí Ayé?

KÍ LO lè sọ pé ìṣọ̀kan jẹ́? Àwọn kan rò pé tí kò bá ṣáà ti síjà, ìṣọ̀kan wà nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, tí orílẹ̀-èdè méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ bá fọwọ́ sí ìwé àdéhùn àlàáfíà tí wọ́n sì gbà pé kí àlàáfíà wà láàárín àwọn, a lè sọ pé wọ́n wà níṣọ̀kan. Àmọ́, ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Kò dájú.

Ìwọ wò ó ná: Kì í ṣèní kì í ṣàná táwọn orílẹ̀-èdè ti máa ń fọwọ́ sí ìwé àdéhùn àlàáfíà tí wọn kì í sì í mú ìlérí wọn ṣẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé, lọ́pọ̀ ìgbà, dípò àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ayé, ohun tó jẹ àwọn aṣáájú ayé lógún ni bí ipò àṣẹ tí wọ́n wà kò ṣe ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ làwọn orílẹ̀-èdè kan sì tún ń bẹ̀rù ohun tó lè ṣẹlẹ̀ táwọn ò bá láwọn nǹkan ìjà bíi tàwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

Nítorí náà, pé àwọn orílẹ̀-èdè méjì kò bá ara wọn jà kò túmọ̀ sí pé àlàáfíà wà láàárín wọn. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a lè sọ pé àlàáfíà wà láàárín àwọn ọkùnrin méjì tó kọjú ìbọn síra wọn kìkì nítorí pé wọn ò tíì yìnbọn ọwọ́ wọn? Rárá o! Bẹ́ẹ̀, ipò tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wà lónìí nìyẹn. Báwọn orílẹ̀-èdè ò ṣe fọkàn tán ara wọn ti mú káwọn èèyàn máa bẹ̀rù pé lọ́jọ́ kan, àwọn tó kó ohun ìjà jọ yóò lò wọ́n. Kí làwọn aláṣẹ ti ṣe kí irú jàǹbá bẹ́ẹ̀ má bàa wáyé?

Ìbẹ̀rù Àwọn Nǹkan Ìjà Runlérùnnà Kò Jẹ́ Kí Ìṣọ̀kan Wà

Ọ̀pọ̀ ló gbọ́kàn lé àdéhùn kan tí wọ́n pè ní Àdéhùn Fífòpin sí Pípọ̀ Tí Ohun Ìjà Runlérùnnà Ń Pọ̀ Sí I. Ọdún 1968 ni wọ́n tẹ́wọ́ gbà á, àdéhùn yìí sì fòfin de ṣíṣe àwọn nǹkan ìjà runlérùnnà láwọn orílẹ̀-èdè tí kò tíì ní wọn, bẹ́ẹ̀ ló tún fòfin de àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ní wọn lọ́wọ́ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe ohun ìjà mọ́. Ìdí tí wọ́n fi ṣe àdéhùn yìí ni pé kí ohun ìjà lè kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá. Àwọn orílẹ̀-èdè tó lé ní ọgọ́sàn-án sì ti fọwọ́ sí àdéhùn náà báyìí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn orílẹ̀-èdè tó ṣe àdéhùn yìí ní lọ́kàn dára gan-an, ojú táwọn tí kò fara mọ́ àdéhùn náà fi wò ó ni pé, ọgbọ́n tí wọ́n ń dá ni pé wọn ò fẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè tí kò tíì ní ohun ìjà wà lára àwọn tó ti ní in. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù tó wá ń ba àwọn aṣáájú ayé ni pé àwọn tó ti fọwọ́ sí àdéhùn náà tẹ́lẹ̀ tún lè lọ yí èrò wọn padà. Àní sẹ́, àwọn orílẹ̀-èdè kan gbà pé ìwà ìrẹ́jẹ ni pé wọn ò jẹ́ káwọn ṣe ohun ìjà tí wọ́n gbà pé yóò jẹ́ káwọn lè dáàbò bo ara àwọn.

Ohun tó túbọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà le sí i, bóyá tó tiẹ̀ jẹ́ kó túbọ̀ léwu sí i pàápàá ni pé, wọn ò fòfin de orílẹ̀-èdè kankan pé kó má ṣe ohun tó ń mú iná mànàmáná jáde. Èyí ti mú káwọn kan máa bẹ̀rù pé àwọn orílẹ̀-èdè tó sọ pé àwọn ń lo ohun tó ń mú iná mànàmáná jáde fún àǹfààní àwọn èèyàn lè tún máa fi ṣe àwọn nǹkan ìjà runlérùnnà lábẹ́lẹ̀.

Kódà, àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ní ohun ìjà runlérùnnà lọ́wọ́ lè kọ̀ láti ṣe ohun tí àdéhùn náà sọ. Àwọn tó ń ṣàríwísí àdéhùn yìí sì sọ pé kò bọ́gbọ́n mu láti rò pé àwọn orílẹ̀-èdè tó ti kó ohun ìjà jọ pelemọ yóò kó wọn dà nù tàbí pé wọ́n á dín wọn kù. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àdéhùn yìí sọ pé, ‘kí èyí tó lè ṣeé ṣe . . . àjọṣe tó dára gan-an gbọ́dọ̀ wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bára wọn jà lọ́wọ́lọ́wọ́, wọ́n sì ní láti fọkàn tán ara wọn gan-an, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó ṣòro láti gbà pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀.’

Gbogbo ipa tí ẹ̀dá èèyàn ń sà pé kí aráyé lè wà níṣọ̀kan ti já sí pàbó, bó ti wù kí wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe é tó. Èyí kò ya àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu, nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Bíbélì tún là á mọ́lẹ̀ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” (Òwe 16:25) Fún ìdí yìí, ìwọ̀nba làwọn ìjọba èèyàn lè ṣe láti mú kí ìṣọ̀kan wà. Àmọ́ ṣá o, ìrètí wà.

Ẹni Tó Máa Mú Ojúlówó Ìṣọ̀kan Wá

Nínú Bíbélì, Ọlọ́run ṣèlérí pé ayé yóò wà níṣọ̀kan, àmọ́ kì í ṣe nípa agbára èèyàn. Ẹlẹ́dàá, tó ti ní in lọ́kàn pé àwọn èèyàn yóò máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà jákèjádò ayé, yóò ṣe ohun tí èèyàn kò lè ṣe. Èyí lè dà bí ohun tí kò lè ṣeé ṣe lójú àwọn kan. Síbẹ̀, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn látìbẹ̀rẹ̀ ni pé kí aráyé máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan.a Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ṣì ní in lọ́kàn láti mú kí gbogbo èèyàn wà níṣọ̀kan. Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀:

• “Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”—SÁÀMÙ 46:8, 9.

• “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—AÍSÁYÀ 11:9.

• “Ní ti tòótọ́, òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn. Ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun yóò sì mú kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.”—AÍSÁYÀ 25:8.

• “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 PÉTÉRÙ 3:13.

• “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—ÌṢÍPAYÁ 21:4.

Àwọn ìlérí wọ̀nyí ṣeé gbára lé. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ní agbára láti mú kí aráyé wà níṣọ̀kan. (Lúùkù 18:27) Ó sì tún wù ú láti ṣe é. Kódà Bíbélì sọ pé ó jẹ́ “ìdùnnú rere [Ọlọ́run] . . . láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.”—Éfésù 1:8-10.

Ìlérí Ọlọ́run pé “ayé tuntun” kan ń bọ̀ èyí tí “òdodo yóò . . . máa gbé” inú rẹ̀ kì í ṣe àlá lásán. (2 Pétérù 3:13) Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run sọ nípa ìlérí tó ṣe ni pé: “Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:11.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Mú Káwọn Èèyàn Wà Níṣọ̀kan

Gẹ́gẹ́ bá a ti sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìsìn ti fa ìpínyà dípò kó mú àwọn èèyàn wà níṣọ̀kan. Ó yẹ ká ronú lórí kókó yìí gan-an, nítorí pé tá a bá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mú ká gbà pé àlàáfíà àti ìṣọ̀kan yóò wà láàárín àwọn tó ń sìn ín? Ó bọ́gbọ́n mu!

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsìn ń pín àwọn èèyàn níyà, kò túmọ̀ sí pé ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ò fara mọ́ àwọn ìsìn tó ń ṣètìlẹyìn fáwọn àjọ èèyàn. Àwọn ìsìn wọ̀nyí gbà pé àwọn àjọ táwọn èèyàn dá sílẹ̀ ló máa mú ìṣọ̀kan wá dípò kí wọ́n fara mọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe. Jésù pe àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ ní “alágàbàgebè,” ó sì sọ fún wọn pé: “Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nípa yín, nígbà tí ó wí pé, ‘Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, síbẹ̀ ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni bí ẹ̀kọ́.’”—Mátíù 15:7-9.

Àmọ́ ìsìn tòótọ́ yàtọ̀ pátápátá, ńṣe ló máa ń mú káwọn èèyàn wà níṣọ̀kan. Wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ pé òkè ńlá ilé Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀. Dájúdájú, òun yóò ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:2, 4.

Ó ju igba ilẹ̀ ó lé ọgbọ̀n [230] táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà Ọlọ́run ń fúnni nípa ọ̀nà téèyàn fi ń wà níṣọ̀kan. Kí ló mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò fún “ìrẹ́pọ̀” lè tọ́ka sí àwọn iṣan ara èèyàn. Irú àwọn iṣan bẹ́ẹ̀ máa ń lágbára bí okùn, iṣẹ́ méjì pàtàkì ni wọ́n sì ń ṣe. Wọ́n máa ń jẹ́ káwọn ẹ̀yà ara wà ní àyè wọn, wọ́n sì tún máa ń so àwọn eegun pa pọ̀.

Bí ìfẹ́ ṣe rí náà nìyẹn. Ó ń ṣe ju pé kì í jẹ́ káwọn èèyàn pa ara wọn. Téèyàn bá ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní, á jẹ́ kó ṣeé ṣe fúnni láti máa báwọn èèyàn tó yàtọ̀ síra ní onírúurú ọ̀nà ṣe nǹkan pọ̀ ní àlàáfíà. Bí àpẹẹrẹ, ó ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti máa gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bá ọ̀kan lára àwọn ìlànà pàtàkì tí Jésù fi lélẹ̀ mu. Ohun tí Jésù Kristi sọ nínú Mátíù 7:12 ni pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” Títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn borí ẹ̀tanú.

Ẹ Ní “Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà múra tán láti fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi làwọn nípa ṣíṣe ohun tí Jésù sọ, ó ní: “Gbogbo ènìyàn yóò . . . mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn lọ́nà tó jọni lójú gan-an láwọn àkókò tí ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tàbí rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ ìṣèlú bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an nígbà táwọn kan fẹ́ pa odindi ẹ̀yà kan run nílẹ̀ Rwanda lọ́dún 1994. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Hutu fi ẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Tutsi!

Lóòótọ́, èèyàn ò lè retí pé káwọn orílẹ̀-èdè ayé nífẹ̀ẹ́ ara wọn débi pé gbogbo ayé á wà níṣọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, Ọlọ́run yóò mú kí èyí ṣeé ṣe nígbà tí àkókò bá tó lójú rẹ̀. Kódà lákòókò tá a wà yìí pàápàá, àwọn èèyàn lè nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan.

Lọ́dún tó kọjá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí láti lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn kí wọ́n sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì àti bó ṣe ń ṣeni láǹfààní lóde òní. Ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti so àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn pọ̀ ṣọ̀kan, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn kan lára wọn ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀tá ara wọn. Àwọn Árábù àtàwọn Júù, àwọn ará Áméníà àtàwọn ará Tọ́kì, àwọn ará Jámánì àtàwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà, wà lára àwọn tá a ń sọ yìí.

Ṣé wàá túbọ̀ fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣe ń so àwọn èèyàn pọ̀ ṣọ̀kan? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó bá yẹ nínú èyí tá a tò sí ojú ìwé 2 ìwé ìròyìn yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá túbọ̀ fẹ́ mọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé, wo orí 3 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Kì í ṣèní kì í ṣàná táwọn orílẹ̀-èdè ti máa ń fọwọ́ sí ìwé àdéhùn àlàáfíà tí wọn kì í sì í mú ìlérí wọn ṣẹ

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Fífi ìlànà Bíbélì sílò ti mú kí ohun tí ìjọba èèyàn ò lè ṣe di èyí tó ṣeé ṣe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ Ẹni tó máa mú ojúlówó ìṣọ̀kan wá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ẹ̀yà Hutu àtàwọn tó jẹ́ ẹ̀yà Tutsi jọ ń kọ́ ilé ìjọsìn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́