Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Jẹ́ Ẹni Àlàáfíà
Inú ọmọ ọdún mẹ́jọ kan tó ń jẹ́ Nicole dùn gan-an pé ìdílé òun ń kó lọ sí apá ibòmíràn lórílẹ̀-èdè wọn, ọmọbìnrin yìí sì máa ń sọ gbogbo báwọn ṣe ń palẹ̀ mọ́ fún Gabrielle tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Lọ́jọ́ kan ni Gabrielle ṣàdédé sọ fún Nicole pé òun ò fẹ́ gbọ́ nípa lílọ wọn mọ́. Ọ̀rọ̀ yìí dun Nicole gan-an, ó sì bí i nínú, ó wá sọ fún màmá rẹ̀ pé, “Mi ò fẹ́ rí Gabrielle mọ́ láé!”
AÁWỌ̀ tó máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọmọdé bí irú èyí tó wáyé láàárín Nicole àti Gabrielle sábà máa ń gba pé káwọn òbí bá wọn dá sí i. Kì í ṣe pé kí wọ́n kàn bẹ ọmọ náà pé kó má ṣe bínú nìkan, àmọ́ wọ́n tún ní láti jẹ́ kó mọ ọ̀nà tó máa gbà yanjú ọ̀ràn náà. Àwọn ọmọdé máa ń fi “ìwà ìkókó” hàn, wọn kì í sì í sábà mọ ìpalára tí ọ̀rọ̀ wọn tàbí ìṣesí wọn lè fà. (1 Kọ́ríńtì 13:11) Ó yẹ káwọn òbí ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwọn àtàwọn ará ilé wọn àti láàárín àwọn àtàwọn ẹlòmíràn.
Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń fẹ́ káwọn ọmọ wọn dẹni tó ‘máa ń wá àlàáfíà, tó sì máa ń lépa rẹ̀.’ (1 Pétérù 3:11) Ó yẹ kí ayọ̀ téèyàn máa ń ní téèyàn bá jẹ́ ẹni àlàáfíà múni sa gbogbo ipá ẹni kéèyàn lè borí ìfura, ìbínú, àti ìkórìíra. Bó o bá jẹ́ òbí, báwo lo ṣe lè kọ́ ọmọ rẹ láti jẹ́ ẹni àlàáfíà?
Gbin Ìfẹ́ Láti Múnú “Ọlọ́run Àlàáfíà” Dùn Sọ́kàn Ọmọ Rẹ
Bíbélì pe Jèhófà ní “Ọlọ́run àlàáfíà,” òun sì lẹni “tí ń fúnni ní àlàáfíà.” (Fílípì 4:9; Róòmù 15:33) Nítorí náà, àwọn òbí tó gbọ́n máa ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó gbéṣẹ́ láti gbin ìfẹ́ láti múnú Ọlọ́run dùn sọ́kàn àwọn ọmọ wọn àti ìfẹ́ láti ní irú àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní. Bí àpẹẹrẹ, ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti fojú inú wo ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nínú ìran kan tó kàmàmà. Ó rí òṣùmàrè aláwọ̀ ewé kan tó yí ìtẹ́ Jèhófà ká, òṣùmàrè náà sì mọ́lẹ̀ yòò bí òkúta émírádì.a (Ìṣípayá 4:2, 3) Ṣàlàyé fún un pé òṣùmàrè yìí ṣàpẹẹrẹ àlàáfíà àti ìtòròminimini tó yí ìtẹ́ Jèhófà ká àti pé irú àwọn ìbùkún wọ̀nyí yóò jẹ́ ti gbogbo àwọn tó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run.
Jèhófà tún ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jésù, ẹni tí Bíbélì pè ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” (Aísáyà 9:6, 7) Nítorí náà, ka àwọn ẹsẹ Bíbélì fáwọn ọmọ rẹ, ìyẹn àwọn ẹsẹ tó sọ nípa ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye tí Jésù fi kọ́ni lórí bá a ṣe lè yẹra fún ìjà àti awuyewuye, kó o sì ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn. (Mátíù 26:51-56; Máàkù 9:33-35) Ṣàlàyé ìdí tí Pọ́ọ̀lù, tó ti jẹ́ “aláfojúdi” nígbà kan rí fi yí ìwà rẹ̀ padà tó sì wá kọ̀wé pé “kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, . . . [kí ó jẹ́ ẹni] tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi.” (1 Tímótì 1:13; 2 Tímótì 2:24) Ipa rere tí ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ ọmọ rẹ̀ yìí máa ní lórí rẹ̀ lè yà ọ́ lẹ́nu gan-an.
Evan rántí pé nígbà tóun wà lọ́mọ́ ọdún méje, ọmọdékùnrin kan máa ń fi òun ṣe yẹ̀yẹ́ nínú ọkọ̀ tó máa ń gbé àwọn lọ sílé ìwé. Ó sọ pé: “Inú bí mi gan-an sí ọmọ yẹn débi pé mo fẹ́ bú u padà! Ni mo bá rántí ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n kọ́ mi nílé pé ìjà kò dára. Mo mọ̀ pé Jèhófà kò fẹ́ kí n ‘fi ibi san ibi fún ẹnì kankan’ ó sì fẹ́ kí n ‘jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.’” (Róòmù 12:17, 18) Nítorí pé Evan kò bú ọmọ náà padà, èyí jẹ́ kó ní òkun àti ìgboyà láti yanjú ohun tí ì bá di ìjà ńlá yìí. Ó fẹ́ múnú Ọlọ́run àlàáfíà dùn.
Jẹ́ Òbí Tó Lẹ́mìí Àlàáfíà
Ṣé ilé rẹ jẹ́ ibi tí kì í sí ìjà, tí àlàáfíà jọba níbẹ̀? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ rẹ á kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa béèyàn ṣe lè jẹ́ èèyàn àlàáfíà, kódà bí o kò tiẹ̀ sọ ohunkóhun. Bó o bá ṣe fara wé ọ̀nà àlàáfíà tí Jèhófà àti Kristi gbà ń báni lò tó ni ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ ọmọ rẹ láti jẹ́ èèyàn àlàáfíà ṣe máa gbéṣẹ́ tó.—Róòmù 2:21.
Tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Russ àti Cindy sa gbogbo ipá wọn láti tọ́ àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n bí, wọ́n kọ́ wọn pé kí wọ́n máa fìfẹ́ hàn nígbà táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó bí wọn nínú. Cindy sọ pé: “Ohun témi àti Russ máa ń ṣe nígbà tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín àwa àtàwọn ọmọ wa tàbí láàárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn, wá ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ gan-an láti mọ báwọn náà ṣe lè máa yanjú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀.”
Kódà nígbà tó o bá ṣàṣìṣe, gẹ́gẹ́ bó o ti mọ̀ pé kò sí òbí tí kì í ṣàṣìṣe, o ṣì lè lo àǹfààní yìí láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ láwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye. Stephen sọ pé: “Àwọn ìgbà míì wà témi àti Terry, ìyàwó mi, máa ń bínú kọjá ààlà, tá a ó sì fìyà jẹ àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ká tó wá mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ńṣe la máa ń bẹ̀ wọ́n.” Terry aya rẹ̀ wá fi kún un pé: “A máa ń jẹ́ káwọn ọmọ wa mọ̀ pé aláìpé làwa náà a sì máa ń ṣàṣìṣe. A rí i pé èyí mú kí àlàáfíà wà nínú ilé wa, yàtọ̀ síyẹn, ó tún ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tí àlàáfíà á fi wà láàárín àwọn àtàwọn ẹlòmíràn.”
Báwọn ọmọ rẹ ṣe ń wo ọ̀nà tó o gbà ń bá wọn lò, ǹjẹ́ wọ́n ń kọ́ bí wọn ò ṣe ní máa fara ya nígbà tí ẹlòmíràn bá mú wọn bínú? Jésù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti lè ṣe àwọn àṣìṣe kan, mọ̀ dájú pé ìfẹ́ tó ò ń fi hàn sáwọn ọmọ rẹ àti bó o ṣe ń fi ọ̀yàyà bá wọn lò yóò so èso rere. Tó o bá ń fún àwọn ọmọ rẹ ní ìtọ́sọ́nà tìfẹ́tìfẹ́, yóò rọrùn fún wọn láti gbà á.
Má Ṣe Máa Tètè Bínú
Òwe 19:11 sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè dẹni tó ní irú ìjìnlẹ̀ òye yìí? David sọ ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ gan-an tó ran òun àti Mariann, aya rẹ̀, lọ́wọ́ láti tọ́ ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin. Ó sọ pé: “Tínú bá bí wọn sẹ́nì kan tó sọ ohun kan tàbí tó ṣe ohun kan tó dùn wọ́n, a kọ́ wọn pé kí wọ́n máa fọ̀rọ̀ rora wọn wò. A máa ń bi wọ́n láwọn ìbéèrè pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bíi, ‘Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun kan ti múnú bí ẹni yẹn lọ́jọ́ náà? Àbí ó lè jẹ́ pé ó ń jowú ni? Àbí a rẹ́ni tó sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí i ni.’” Mariann kín ọkọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ní: “Èyí máa ń jẹ́ kí inú àwọn ọmọ náà rọ̀ dípò kí wọ́n máa bínú torí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà tàbí kí wọ́n máa ṣàròyé lórí ẹni tó jẹ̀bi tàbí ẹni tó jàre.”
Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ lè ní àbájáde tó dára gan-an. Wo bí Michelle tó jẹ́ ìyá Nicole tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣe ràn án lọ́wọ́ lọ́nà tó ju pé kí òun àti Gabrielle kàn wulẹ̀ jọ dọ̀rẹ́ padà. Ìyá Nicole sọ pé: “Èmi àti Nicole jọ ka orí kẹrìnlá ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà.b Mo wá ṣàlàyé ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ká dárí ji ẹnì kan ‘títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.’ Lẹ́yìn tí mo ti fara balẹ̀ tẹ́tí sí Nicole bó ṣe ń sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe dùn ún tó, mo ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ kó fi ara rẹ̀ sípò Gabrielle, pé tó bá jẹ́ pé òun náà ni, kó wo bínú òun á ṣe bà jẹ́ tó pé ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́ fẹ́ fi òun sílẹ̀ lọ máa gbé ibi tó jìnnà gan-an.”—Mátíù 18:21, 22.
Òye tí Nicole ṣẹ̀ṣẹ̀ ní lórí ohun tó ṣeé ṣe kó mú kí Gabrielle fara ya bẹ́ẹ̀ wá ràn án lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, ìyẹn sì mú kó fóònù Gabrielle láti bẹ̀ ẹ́ pé kó má ṣe bínú. Ìyá Nicole sọ pé: “Àtìgbà yẹn ni gbígba tàwọn ẹlòmíràn rò àti ṣíṣoore fáwọn èèyàn kínú wọn lè dùn ti máa ń fún Nicole láyọ̀.”—Fílípì 2:3, 4.
Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti má ṣe máa bínú sódì nítorí àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn tàbí nítorí èdèkòyédè tó lè wáyé láàárín àwọn àtàwọn ẹlòmíì. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kínú rẹ máa dùn bó o ṣe ń rí àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n ń ṣe dáadáa sáwọn èèyàn tí wọ́n sì ń fìfẹ́ hàn sí wọn.—Róòmù 12:10; 1 Kọ́ríńtì 12:25.
Kọ́ Ọmọ Rẹ Pé Ó Dára Láti Máa Dárí Jini
Òwe 19:11 sọ pé: ‘Ẹwà ni ó jẹ́ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.’ Ní àkókò tí nǹkan nira jù lọ fún Jésù, ó fara wé Bàbá rẹ̀, ó sì darí ji àwọn tó ṣẹ̀ ẹ́. (Lúùkù 23:34) Àwọn ọmọ rẹ lè rí ẹwà tó wà nínú dídáríjini tí wọ́n bá rí i pé ara máa ń tu àwọn nígbà tí ìwọ náà bá dárí jì wọ́n.
Bí àpẹẹrẹ, inú Willy, tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún máa ń dùn nígbà tóun àti ìyá rẹ̀ àgbà bá ń fi kereyọ́ọ̀nù kun àwọn àwòrán inú ìwé. Lọ́jọ́ kan, ìyá àgbà ṣàdédé fi ìwé tí wọ́n ń kùn sílẹ̀, ó jágbe mọ́ Willy, ó sì dìde lọ. Inú Willy bà jẹ́ gan-an. Sam, bàbá rẹ̀, sọ pé: “Àìsàn ọjọ́ ogbó tó ń mú kéèyàn ṣarán ń yọ ìyá àgbà lẹ́nu. A wá ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Willy lọ́nà tó fi lè yé e dáadáa.” Lẹ́yìn tí wọ́n rán Willy létí pé àwọn ti darí jì í lọ́pọ̀ ìgbà àti pé òun náà gbọ́dọ̀ darí ji àwọn ẹlòmíràn, ohun tí Willy ṣe ya Sam, bàbá rẹ̀, lẹ́nu gan-an. Sam sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ bínú èmi àti ìyàwó mi ṣe dùn tó nígbà tí ọmọ wa kékeré lọ bá ìyá rẹ̀ àgbà tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin ọdún, tó pàrọwà fún un, tó dì í lọ́wọ́ mú, tó sì mú un lọ sídìí tábìlì náà padà?”
Ẹwà ló jẹ́ lóòótọ́ táwọn ọmọdé bá kọ́ béèyàn ṣe ń ‘bá a lọ ní fífara da’ ìkùdíẹ̀-káàtó àti àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n sì ń dárí jì wọ́n. (Kólósè 3:13) Kódà báwọn èèyàn tiẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó lè bí àwọn ọmọ náà nínú, mú un dá ọmọ rẹ lójú pé kò sóun tó dára tó kéèyàn má ṣe gbẹ̀san, nítorí pé “nígbà tí Jèhófà bá ní ìdùnnú nínú àwọn ọ̀nà ènìyàn, ó máa ń mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀.”—Òwe 16:7.
Máa Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Jẹ́ Èèyàn Àlàáfíà
Táwọn òbí bá ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ “lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà,” táwọn fúnra wọn sì jẹ́ ẹni “tí ń wá àlàáfíà,” oore ńlá ni wọ́n ń ṣe àwọn ọmọ wọn. (Jákọ́bù 3:18) Ńṣe ni irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ béèyàn ṣe ń yanjú aáwọ̀ kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tó ń wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Èyí á túbọ̀ jẹ́ káwọn ọmọ náà láyọ̀ gan-an jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, ọkàn wọn á sì balẹ̀.
Tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Dan àti Kathy ní ọmọ mẹ́ta tí wọn ò tíì pé ọmọ ogún ọdún tí wọ́n sì ń ṣe dáadáa gan-an nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Dan sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti tọ́ wọn nígbà tí wọ́n wà ní kékeré, inú wa dùn gan-an pé àwọn ọmọ wa ń ṣe dáadáa nínú ìṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ní báyìí, àjọṣe àárín àwọn àtàwọn ẹlòmíràn gún régé gan-an, ó sì rọrùn fún wọn láti dárí ji àwọn èèyàn nígbà tí èdèkòyédè bá wáyé.” Kathy sọ pé: “Èyí mú ká láyọ̀ gan-an, níwọ̀n bí àlàáfíà ti jẹ́ ara èso ẹ̀mí Ọlọ́run.”—Gálátíà 5:22, 23.
Nítorí náà, ìwọ òbí tó o jẹ́ Kristẹni, má ṣe “juwọ́ sílẹ̀” o tàbí “ṣàárẹ̀” bó o ti ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, kódà bó tiẹ̀ jọ pé àwọn ọmọ náà ò tètè kọbi ara sí ohun tí ò ń kọ́ wọn. Bí ẹ̀yin òbí ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò . . . wà pẹ̀lú yín.”—Gálátíà 6:9; 2 Kọ́ríńtì 13:11.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwòrán yìí lójú ìwé 75 nínú ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
ǸJẸ́ ERÉ ORÍ TẸLIFÍṢỌ̀N Ń ṢENI LÁǸFÀÀNÍ?
Àjọ Tó Ń Ṣàyẹ̀wò Eré Orí Tẹlifíṣọ̀n gbé àtẹ̀jáde kan jáde, tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìwà Ipá Nínú Àwọn Eré Orí Tẹlifíṣọ̀n,” ohun tó sì sọ ni pé: “Ńṣe làwọn ohun tó ń jáde lórí tẹlifíṣọ̀n túbọ̀ ń ti èrò àwọn èèyàn lẹ́yìn pé ìwà ipá lèèyàn fi ń yanjú ìṣòro. Gbogbo ìgbà ló jẹ́ pé ìwà ipá làwọn ọ̀tá àtàwọn tó jẹ́ akọni fi máa ń yanjú èdèkòyédè nínú àwọn eré náà.” Ọ̀kan ṣoṣo péré nínú mẹ́wàá àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n, fíìmù àti fídíò orin tí wọ́n ṣàyẹ̀wò wọn ló fi hàn pé ohun tó ń tìdí ìwà ipá jáde kò dára. Àtẹ̀jáde náà sọ pé, kàkà bẹ́ẹ̀, “ńṣe làwọn tó ń ṣeré ọ̀hún kàn ń fi ìwà ipá hàn bí ohun tó bójú mu, tí kò sóhun tó burú níbẹ̀, pé òun sì ni ọ̀nà tí gbogbo èèyàn rí i pé èèyàn lè gbà yanjú ìṣòro.”
Ǹjẹ́ ẹ rí i pé ó yẹ kẹ́ ẹ wá nǹkan ṣe sí bẹ́ ẹ ṣe ń wo tẹlifíṣọ̀n nínú ilé yín? Má ṣe jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n ṣàkóbá fún gbogbo ìsapá rẹ láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti jẹ́ èèyàn àlàáfíà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Gbin ìfẹ́ láti múnú “Ọlọ́run àlàáfíà” dùn sọ́kàn àwọn ọmọ rẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Fara balẹ̀ kọ́ ọmọ rẹ pé kò dára láti máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ tàbí hùwà tí kò dára sáwọn ẹlòmíràn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ó yẹ káwọn ọmọ rẹ mọ béèyàn ṣe ń tọrọ àforíjì àti béèyàn ṣe ń dárí jini