Àwọn Aláàárẹ̀ Ọkàn
LÁTỌMỌ ọdún mẹ́rìnlá ni ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ti máa ń bá Nicole. Àmọ́, nígbà tó dọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ohun mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ sí i, ìyẹn ni kó kàn ṣàdédé máa yọ̀ ṣìnkìn kí agbára sì máa gùn ún. Oríṣiríṣi èrò á máa wá sí i lọ́kàn, kò ní lè sọ̀rọ̀ já geere, kò ní rí oorun sùn, ara á sì tún máa fu ú láìnídìí pé àwọn ọ̀rẹ́ òun ń kó òun nífà. Lẹ́yìn èyí, Nicole sọ pé òún lè yí àwọ̀ tó bá wà lára àwọn nǹkan padà nígbàkigbà tó bá wu òun. Ọ̀rọ̀ tí Nicole sọ yìí ló mú kí ìyá rẹ̀ mọ̀ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń fẹ́ àbójútó, bó ṣe mú un lọ sí ilé ìwòsàn nìyẹn. Lẹ́yìn tí àwọn dókítà ti fara balẹ̀ kíyè sí bí ìṣesí Nicole ṣe ń yí padà, wọ́n sọ pé àìsàn bipolar tó ń múni hùwà lódìlódì ló ń dà á láàmú.a
Bíi ti Nicole, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé ló ní ìṣòro híhùwà lódìlódì tàbí irú akọ àárẹ̀ ọkàn kan. Ìṣòro wọ̀nyí sì máa ń fojú àwọn tó bá ń ṣe rí màbo. Steven, tó ń gbàtọ́jú nítorí ìṣòro híhùwà lódìlódì, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi wà nínú ìrora. Bí mo ṣe ń ní àárẹ̀ ọkàn, bẹ́ẹ̀ náà ni ara mi ń yá sódì. Ìtọ́jú àti lílo oògùn ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ ẹnu ẹ̀ náà ni mo ṣì wà.”
Kí ló ń fa ìṣòro ìṣesí tó ṣàdédé ń yí padà? Kí lojú àwọn tó ní àárẹ̀ ọkàn tàbí ìṣòro híhùwà lódìlódì máa ń rí? Báwo làwọn tí àìsàn yìí ń ṣe àtàwọn tó ń tọ́jú wọn ṣe lè rí ìtìlẹ́yìn tí wọ́n nílò gbà?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jọ̀wọ́, kíyè sí i pé a tún lè fi díẹ̀ lára àwọn àmì wọ̀nyí mọ ìsínwín, ìjoògùnyó tàbí ìyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà ìbàlágà pàápàá. Nítorí náà, ká tó lè sọ pé ẹnì kan ní àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì ó yẹ kí amọṣẹ́dunjú kan tó tóótun kọ́kọ́ yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa.