ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 1/8 ojú ìwé 8-11
  • Má Ṣe Sọ̀rètí Nù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Sọ̀rètí Nù
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àmì Tá A Lè Fi Dá A Mọ̀
  • Jíja Àjàbọ́
  • Ìtùnú Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
  • Kíkojú Ìṣòro Kí Ìṣesí Ẹni Máa Ṣàdédé Yí Padà
    Jí!—2004
  • Bí Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
    Jí!—2004
  • Báa Ṣe Lè Dá Àwọn Àmì Ìsoríkọ́ Mọ̀
    Jí!—2001
  • Àwọn Aláàárẹ̀ Ọkàn
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 1/8 ojú ìwé 8-11

Má Ṣe Sọ̀rètí Nù

LÁTỌJỌ́ pípẹ́ làwọn èèyàn ti máa ń yẹra fáwọn tí ìṣesí wọn máa ń ṣàdédé yí padà. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ àwọn tí àrùn yìí ń ṣe dẹni tí tajá tẹran ń sá fún. Iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn kan, àwọn míì ò sì rẹ́ni gbà wọ́n síṣẹ́. Nígbà tó jẹ́ pé àwọn kan ò rójú àwọn aráalé wọn nílẹ̀ mọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí wulẹ̀ máa ń dá kún ìṣòro náà ni, kì í sì í jẹ́ káwọn tí àìsàn náà ń ṣe rí ìrànlọ́wọ́.

Àmọ́ ṣá o, láwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí, ìsapá ti pọ̀ sí i láti lóye akọ àárẹ̀ ọkàn àti àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì. A ti wá mọ̀ báyìí pé àwọn ìṣòro náà kì í ṣe èyí tí ò gbóògùn. Àmọ́ ṣá o, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti rí ìrànlọ́wọ́. Kí ló fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Àwọn Àmì Tá A Lè Fi Dá A Mọ̀

Wíwulẹ̀ yẹ ẹ̀jẹ̀ wò tàbí yíya fọ́tò inú ara kò tó láti fi mọ̀ bí ẹnì kan bá ní àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì. Dípò ìyẹn, ńṣe ló yẹ ká fara balẹ̀ kíyè sí ìṣesí, ìrònú àti agbára ìmòye ẹni náà fún àwọn àkókò kan. Ọ̀pọ̀ àmì la gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò ká tó lè sọ pàtó bọ́rọ̀ ṣe rí. Ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni pé nígbà míì, àwọn ará àtọ̀rẹ́ kì í tètè mọ̀ pé ohun táwọn ń rí jẹ́ àmì tó ń fi hàn pé ẹnì kan ní ìṣòro ìṣesí tó ṣàdédé ń yí padà. Ọ̀mọ̀wé David J. Miklowitz sọ pé: “Kódà, nígbà táwọn èèyàn bá gbà pé ìwà ẹnì kan ò jọ ti ará yòókù mọ́, èrò wọn kì í ṣọ̀kan nípa ohun tó mú kí ọ̀rọ̀ onítọ̀hún rí bẹ́ẹ̀.”

Síwájú sí i, nígbà táwọn aráalé onítọ̀hún pàápàá bá ronú pé ọ̀ràn náà le koko, ó lè má rọrùn láti mú kí ẹni tó ní ìṣòro náà gbà pé ó pọn dandan kí òún lọ rí dókítà. Bó bá sì jẹ́ pé ìwọ gan-an lo ní ìṣòro náà, o lè máà fẹ́ gbàtọ́jú. Dókítà Mark S. Gold sọ pé: “Bóyá o máa ń gba èrò tó ń wá sọ́kàn rẹ gbọ́ nígbà tí àárẹ̀ ọkàn bá ń ṣe ọ́. Ìyẹn ni pé o kò já mọ́ nǹkan kan, àti pé kí lo fẹ́ wá ìrànlọ́wọ́ lọ fún nígbà tó jẹ́ pé kò kúkú sí ìrètí kankan fún irú èèyàn bíi tìẹ. Bóyá ó wù ọ́ kó o rí ẹnì kan nípa ọ̀ràn náà, ṣùgbọ́n ò ń ronú pé ohun ìtìjú ló jẹ́ láti ní àárẹ̀ ọkàn, àti pé ìwọ lo ni ẹ̀bi gbogbo ọ̀rọ̀ náà. . . . O lè má mọ̀ pé irú ìmọ̀lára tóò ń ní yẹn gan-an ni àmì tó ń fi hàn pé o ní àárẹ̀ ọkàn.” Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó pọn dandan pé kí àwọn tó ní àárẹ̀ ọkàn tó burú jáì lọ gbàtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa la máa ń rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìyẹn ò sì fi dandan túmọ̀ sí pé a ní ìṣòro ìṣesí tó ṣàdédé ń yí padà. Àmọ́, bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ìrẹ̀wẹ̀sì náà ń le sí i ńkọ́? Ká sọ pé ó ń bá a nìṣó fún àkókò gígùn, bí ọ̀sẹ̀ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ? Síwájú sí i, ká sọ pé láwọn àkókò tó o fi ní ìrẹ̀wẹ̀sì náà o kò lè ṣe àwọn nǹkan dáadáa bó ṣe yẹ ńkọ́, yálà lẹ́nu iṣẹ́, níléèwé, tàbí láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà? Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀ yẹn, yóò jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu pé kó o kàn sí amọṣẹ́dunjú kan tó tóótun kó lè yẹ̀ ọ́ wò kó sì bá ọ tọ́jú àárẹ̀ ọkàn náà.

Bó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan kan tí ò ṣiṣẹ́ dáadáa nínú ọpọlọ ló fa àìsàn náà, wọ́n lè sọ oògùn tí aláìsàn náà máa lò fún un. Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, láti ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ bí yóò ṣe kojú àìsàn tó ń ṣe é, wọ́n lè dábàá pé kó lọ gbàmọ̀ràn níbi ètò kan tó wà fún gbígba àwọn aláàárẹ̀ ọkàn nímọ̀ràn. Nígbà míì sì rèé, lílo oògùn àti gbígba ìmọ̀ràn ti ṣèrànwọ́ gan-an.a Pàtàkì ibẹ̀ ni pé kó lo ìdánúṣe kó lè rí ìrànlọ́wọ́. Lenore, tó ní àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀rù máa ń ba àwọn tí àìsàn yìí ń ṣe, ipò tí wọ́n wà sì máa ń tì wọ́n lójú. Àmọ́ ṣá, ohun tó ń fa ìtìjú jù lọ ni mímọ̀ pé o ní ìṣòro, kó o má sì lè wá bó o ṣe máa rí ìtọ́jú tó o nílò gidigidi.”

Ìrírí tara Lenore fúnra rẹ̀ ló ń sọ fún wa. Ó sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan tí mo fi wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn. Àmọ́, lọ́jọ́ kan tí ara mi yá díẹ̀, mo pinnu láti ké sí dókítà lórí tẹlifóònù, mo sì sọ pé màá wá rí i.” Nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò ohun tó ń ṣe Lenore, wọ́n rí i pé àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì ni, wọ́n sì júwe oògùn fún un. Bí ìyípadà ńláǹlà ṣe dé bá ìgbésí ayé rẹ̀ nìyẹn o. Lenore sọ pé: “Ara mi máa ń balẹ̀ lẹ́yìn tí mo bá ti lo oògùn mi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní láti máa rán ara mi létí lemọ́lemọ́ pé bí mo bá dáwọ́ lílò ó dúró, gbogbo nǹkan tó ń ṣe mí lọ́jọ́sí ló tún máa padà wá.”

Bí ọ̀ràn ti Brandon tóun náà ní àárẹ̀ ọkàn ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo sábà máa ń ronú nípa pípa ara mi nítorí èrò àìjámọ́ nǹkan kan tí mò ń ní ṣáá nípa ara mi. Àfìgbà tí mo lé lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún ni mo tó lọ rí dókítà.” Bíi ti Lenore, oògùn ni Brandon náà ń lò sí àìsàn tiẹ̀. Ṣùgbọ́n, kò mọ síbẹ̀ o. Ó sọ pé: “Kí inú mi lè máa dùn kí ara mi sì máa yá gágá, mo máa ń ṣọ́ ohun tí mò ń fọkàn mi rò, mo sì máa ń bójú tó ara mi. Mo máa ń sinmi, mo sì máa ń ṣọ́ oúnjẹ tí mò ń jẹ. Àwọn èrò tó ń gbéni ró látinú Bíbélì ni mo sì máa ń jẹ́ kó gbà mí lọ́kàn.”

Àmọ́ ṣá o, Brandon ṣàlàyé pé ìṣòro tó nílò ìtọ́jú oníṣègùn ní akọ àárẹ̀ ọkàn, kì í ṣe àìsàn tẹ̀mí. Mímọ èyí ṣe pàtàkì fún ẹnì kan tó bá ń wá ọ̀nà àbáyọ kúrò lọ́wọ́ àìsàn náà. Brandon sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni, tí kò sì ní èrò búburú kankan lọ́kàn, sọ pé níwọ̀n bí Gálátíà 5:22, 23 ti sọ pé ayọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára èso ẹ̀mí Ọlọ́run, ó ní láti jẹ́ pé mò ń ṣe ohun tó ń dí ẹ̀mí náà lọ́wọ́ ni mo ṣe ń ní àárẹ̀ ọkàn. Ìyẹn tún wá jẹ́ kí n túbọ̀ máa dá ara mi lẹ́bi, àárẹ̀ ọkàn náà sì túbọ̀ pọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n gbàrà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí rí ìrànlọ́wọ́, àárẹ̀ ọkàn náà bẹ̀rẹ̀ sí fúyẹ́. Ara mi sì mókun sí i! Ká ní mo mọ̀ ni, ǹ bá ti wá ìrànlọ́wọ́ ṣáájú àkókò yìí.”

Jíja Àjàbọ́

Kódà, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe àyẹ̀wò tí ìtọ́jú sì ti bẹ̀rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìṣòro ìṣesí tó ṣàdédé ń yí padà á ṣì máa dà ọ́ láàmú. Kelly, tó ní àárẹ̀ ọkàn tó burú jáì, fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ìrànlọ́wọ́ àwọn amọṣẹ́dunjú tó bá a bójú tó àìsàn tó ń ṣe é náà. Àmọ́, láfikún sí i, ó ti rí i pé ìtìlẹ́yìn táwọn míì ṣe fún òun ṣe pàtàkì gan-an ni. Lákọ̀ọ́kọ́, Kelly kọ́kọ́ ń lọ́ tìkọ̀ láti tọ àwọn ẹlòmíràn lọ fún ìrànlọ́wọ́ nítorí pé kò fẹ́ kí wọ́n rí òun bí akó-tiẹ̀-báni. Ó sọ pé: “Kì í ṣe pé mo ti kọ́ bá a ṣe ń wá ìrànlọ́wọ́ nìkan ni àmọ́, mo tún ti kọ́ bá a ṣe ń gba irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Ìgbà tí mo tó sọ ohun tó ń ṣe mí jáde ni mo tó fòpin sí ìrẹ̀wẹ̀sì tó ń pọ̀ sí i tí àárẹ̀ ọkàn ń kó bá mi.”

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Kelly máa ń lọ sí ìpàdé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tirẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́ ṣá o, láwọn ìgbà mìíràn pàápàá, ó ṣì máa ń ní ìṣòro láwọn àkókò aláyọ̀ yìí. “Lọ́pọ̀ ìgbà, iná mànàmáná, àwọn èèyàn tó ń lọ tó ń bọ̀ àti ariwo tó wà láyìíká máa ń pàpọ̀jù fún mi. Ni màá bá tún bẹ̀rẹ̀ sí dá ara mi lẹ́bi, àárẹ̀ ọkàn náà á sì máa burú sí i nítorí pé mo máa ń ronú pé ńṣe nìyẹn ń fi hàn pé n kì í ṣe ẹni tẹ̀mí.” Báwo ni Kelly ṣe kojú ìṣòro rẹ̀ yìí? Ó sọ pé: “Ó ti wá yé mi pé ìṣòro tó yẹ kéèyàn fara dà ni àárẹ̀ ọkàn. Kì í ṣe òun ló ń pinnu bí ìfẹ́ mi fún Ọlọ́run tàbí fún àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni ṣe pọ̀ tó. Òun kọ́ ló ń fi hàn bí ipò tẹ̀mí mi ṣe rí ní ti gidi.”

Lucia, tá a mẹ́nu kàn nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, kún fún ìmọrírì nítorí ìtọ́jú gbígbámúṣé tó ti rí. Ó sọ pé: “Rírí tí mo lọ rí oníṣègùn ọpọlọ kan tí ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti mọ bí mo ṣe lè máa fara da ìṣesí mi tó máa ń yí padà bí àìsàn náà bá ti sọ mí wò àti bí mo ṣe lè kojú rẹ̀.” Lucia tún tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa sinmi. Ó sọ pé: “Pàtàkì ni oorun jẹ́ lára ọ̀nà tá a lè máa gbà bójú tó ọ̀ràn kí ara máa yá àyásódì. Bí oorun tí mò ń sùn bá ṣe ń dín kù sí i tó, bẹ́ẹ̀ ni ara mi ṣe máa ń yá àyásódì tó. Kódà, bí oorun ò bá wá pàápàá, dípò kí n dìde, mo ti fi kọ́ra láti dùbúlẹ̀ síbẹ̀ kí n sì máa sinmi.”

Sheila, tá a ti sọ̀rọ̀ òun náà níṣàájú, ti rí i pé ó dára láti ní àkọsílẹ̀ kan tí yóò máa kọ àwọn nǹkan tó bá ń ṣẹlẹ̀ sí i lójoojúmọ́ sí. Òun náà rí i pé ìyípadà kékeré kọ́ ló dé bá ìṣesí òun. Síbẹ̀, àwọn ìṣòro kan ṣì wà o. Sheila sọ pé: “Nítorí àwọn ìdí kan ṣá, àárẹ̀ ara máa ń mú káwọn èrò tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni gbà mí lọ́kàn. Àmọ́, mo ti kọ́ bí mo ṣe lè mú wọn kúrò lọ́kàn tàbí kí n dín wọn kù.”

Ìtùnú Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ìrànlọ́wọ́ tó ń fúnni lókun ni Bíbélì jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ní “ìrònú tí ń gbé [wọn] lọ́kàn sókè.” (Sáàmù 94:17-19, 22) Bí àpẹẹrẹ, Cherie rí i pé ìṣírí tí Sáàmù 72:12, 13 pèsè kò kéré rárá. Níbẹ̀, onísáàmù náà sọ nípa Jésù Kristi, ọba tí Ọlọ́run yàn, pé: “Yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.” Cherie tún rí ìṣírí gbà látinú àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Róòmù 8:38, 39, tó kà pé: “Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.”

Elaine, tó ń gbàtọ́jú nítorí àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì, rí i pé àjọṣe òun pẹ̀lú Ọlọ́run ló ń gbé òun ró. Ó rí ìtùnú ńláǹlà gbà látinú àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà pé: “Ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.” (Sáàmù 51:17) Ó sọ pé: “Lóòótọ́, ohun ìtùnú ló jẹ́ láti mọ̀ pé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, Jèhófà, lóye wa. Sísún mọ́ ọn nínú àdúrà máa ń fúnni lókun, pàápàá jù lọ ní àkókò hílàhílo àti ìrora ọkàn.”

Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, àìsàn ìṣesí tó ṣàdédé ń yí padà máa ń ní àwọn ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ kan. Bó ti wù kó rí, Cherie àti Elaine ti rí i pé gbígbára lé Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà àti gbígba ìtọ́jú tó yẹ ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn láti mú ipò àwọn sunwọ̀n sí i ní ìgbésí ayé. Ṣùgbọ́n, báwo ni àwọn ará àtọ̀rẹ́ ṣe lè ran àwọn tó ní àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì tàbí àárẹ̀ ọkàn lọ́wọ́?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jí! ò sọ pé irú ìtọ́jú kan pàtó ló dára láti gbà o. Àwọn Kristẹni ní láti rí i dájú pé irú ìtọ́jú èyíkéyìí tí wọ́n bá fẹ́ láti gbà kò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

“Gbàrà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí rí ìrànlọ́wọ́, àárẹ̀ ọkàn náà bẹ̀rẹ̀ sí fúyẹ́. Ara mi sì mókun sí i!”—BRANDON

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

Àkíyèsí Tí Ọkọ Kan Ṣe

“Kí àárẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe Lucia, kò sẹ́ni tí ò jàǹfààní látinú ìjìnlẹ̀ òye tó ní. Àní, nísinsìnyí pàápàá, báwọn èèyàn bá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìyàwó mi nígbà tí ara rẹ̀ bá balẹ̀, ó dà bí ẹni pé ọ̀yàyà rẹ̀ máa ń fà wọ́n mọ́ra ṣáá ni. Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ̀ ni pé ńṣe ni ìṣesí Lucia máa ń ṣàdédé yí padà; bó ti ń ní àárẹ̀ ọkàn bẹ́ẹ̀ náà lara rẹ̀ tún máa ń yá sódì. Ohun tí àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì ń fojú ẹni rí nìyẹn, ó sì ti ń fara dà á láti ọdún mẹ́rin sẹ́yìn.

“Nígbà tí ara rẹ̀ bá ń yá sódì, kì í sábà sùn títí di aago kan, aago méjì tàbí aago mẹ́ta òru pàápàá, bẹ́ẹ̀ làwọn èrò ìdánúṣe lóríṣiríṣi á máa wá sí i lọ́kàn. Agbára á kàn máa gùn ún ni ṣáá. Á máa gba gbogbo nǹkan sódì á sì máa náwó ní ìná àpà. Bó bá rí ipò kan tó léwu, á kọrùn bọ̀ ọ́, á sì máa ronú pé kò séwu lẹ́gbẹ̀rún ẹ̀kọ, pé kò sí ohunkóhun tó lè pa òun lára lọ́nà èyíkéyìí. Bó ti ń fi ìkùgbù hùwà yìí, bẹ́ẹ̀ ni yóò tún máa ronú àtipa ara rẹ̀. Bí ara bá ti ń yá a sódì bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ ọkàn ń bọ̀ nìyẹn. Bí ara àyásódì náà bá sì ṣe pọ̀ tó ni àárẹ̀ ọkàn tí yóò tẹ̀ lé e á ṣe le tó.

“Ìgbésí ayé mi ti yí padà pátápátá. Kódà, pẹ̀lú ìtọ́jú tí Lucia ń gbà, ohun táà ń ṣe lónìí lè yàtọ̀ sí tàná, ó sì lè yàtọ̀ sí èyí tá a máa ṣe lọ́la. Ipò tá a bá bára wa ló ń pinnu ohun tá a máa ṣe. Ó wá di dandan fún mi láti jẹ́ ẹni tó mọwọ́ọ́ yí padà ju bí mo ti lérò pé mo lè ṣe lọ.”—Mario.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ó Ṣe Pàtàkì Láti Lo Oògùn Tí Dókítà Júwe

Àwọn kan gbà pé àmì àìlera ni lílo oògùn jẹ́. Ṣùgbọ́n wò ó lọ́nà yìí ná: Ẹnì kan tó ní àrùn àtọ̀gbẹ gbọ́dọ̀ máa gbàtọ́jú déédéé, èyí tó ṣeé ṣe kí gbígba abẹ́rẹ́ insulin wà lára rẹ̀. Ṣé àmì ìkùnà nìyẹn jẹ́? Ó tì o! Ìyẹn wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti mú kí àwọn èròjà inú ara alárùn àtọ̀gbẹ náà wà ní ìwọ̀n tó yẹ ni, kí ara rẹ̀ lè bọ̀ sípò.

Bákan náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú lílo oògùn nítorí akọ àárẹ̀ ọkàn àti àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí ìrànwọ́ látinú àwọn ètò tó wà fún gbígbani nímọ̀ràn, èyí tó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àìsàn wọn, ó ṣì yẹ kí wọ́n ṣọ́ra o. Bó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan kan tí ò ṣiṣẹ́ dáadáa nínú ọpọlọ ló fa àìsàn náà, wíwulẹ̀ báni fèrò wérò kò lè tán ìṣòro náà. Steven, tí àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì ń ṣe, sọ pé: “Onímọ̀ ìṣègùn tó tọ́jú mi ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí: O lè kọ́ ẹnì kan ní gbogbo ẹ̀kọ́ tó wà láyé yìí nípa bí a ṣe ń wakọ̀, ṣùgbọ́n bó o bá gbé ọkọ̀ tí kò ní àgbá ìtọ́kọ̀ tàbí tí kò ní ìjánu fún irú ẹni bẹ́ẹ̀, òtúbáńtẹ́ ni gbogbo ẹ̀kọ́ tó o kọ́ ọ á já sí. Lọ́nà kan náà, gbígba ẹni tó ní àárẹ̀ ọkàn nímọ̀ràn lásán lè máà tu irun kankan lára ìṣòro náà. Mímú kí ọpọlọ ṣiṣẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ ni ìgbésẹ̀ pàtàkì àkọ́kọ́.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ìrànlọ́wọ́ tó ń fúnni lókun ni Bíbélì jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ní èrò tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́