Bí Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
BÓYÁ o mọ ẹnì kan tó ní àárẹ̀ ọkàn tàbí àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́? Ọ̀gbẹ́ni D. J. Jaffe ti Iléeṣẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Àwọn Alárùn Ọpọlọ, pèsè àbá wíwúlò yìí: “Ẹ má ṣe fi ojú àìsàn náà wo ẹni tó ń ṣe o; kàkà bẹ́ẹ̀, àìsàn náà ni kẹ́ ẹ kórìíra, ṣùgbọ́n kẹ́ ẹ fẹ́ràn aláìsàn náà.”
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Susanna ní sùúrù àti ìfẹ́ tó pọ̀ tó láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó ní ọ̀rẹ́ kan tó ní àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì. Susanna sọ pé: “Àwọn ìgbà kan máa ń wà tí kì í fẹ́ kí n wà ní sàkáání òun rárá.” Dípò kó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí sú òun, Susanna ṣe ìwádìí láti mọ̀ nípa àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì. Ó sọ pé: “Nísinsìnyí, mo ti wá mọ bí ohun tó ń ṣe ọ̀rẹ́ mi yìí ṣe ń nípa lórí ìṣarasíhùwà rẹ̀ tó.” Susanna ronú pé sísapá láti lóye aláìsàn náà lè mú èrè ńláǹlà wá. Ó sọ pé: “Ó lè mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ aláìsàn náà kó o sì ní ìmọrírì fún àwọn ànímọ́ rere rẹ̀.”
Bó bá jẹ́ ẹnì kan nínú ìdílé rẹ ni àìsàn náà ń ṣe, fífi tọkàntọkàn ṣètìlẹ́yìn fún un ṣe kókó. Ohun tí Mario, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, ṣe nìyẹn nígbà tí àìsàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìyàwó rẹ̀. Ìyàwó rẹ̀ náà Lucia, tá a ti sọ̀rọ̀ òun náà níṣàájú, ń gbàtọ́jú nítorí àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì. Ó sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, ohun tó ràn mí lọ́wọ́ ni pé mo máa ń bá ìyàwó mi lọ sọ́dọ̀ dókítà rẹ̀, mo sì máa ń kà nípa àìsàn abàmì yìí kí n bàa lè mọ ìṣòro náà gan-an tó dojú kọ wá. Èmi àti Lucia tún máa ń bá ara wa sọ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀, a sì ń fara da ipò èyíkéyìí tó bá dìde bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́.”
Ìtìlẹ́yìn Látinú Ìjọ Kristẹni
Bíbélì gba gbogbo àwọn Kristẹni níyànjú láti máa “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́,” kí wọ́n sì máa “ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Báwo lo ṣe lè ṣe èyí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ṣe pàtàkì láti lóye ìyàtọ̀ tó wà láàárín àìsàn ọpọlọ àti àìsàn tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Jákọ́bù, sọ pé àdúrà lè mú ẹni tó jẹ́ aláàárẹ̀ nípa tẹ̀mí lára dá. (Jákọ́bù 5:14, 15) Síbẹ̀, Jésù gbà pé àwọn tí ń ṣòjòjò nípa tara nílò oníṣègùn. (Mátíù 9:12) Àmọ́ ṣá o, ní gbogbo ìgbà, ohun tó tọ́ tó sì lè ṣèrànwọ́ ni pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà nípa ohunkóhun tá a bá ń ṣàníyàn lé lórí, títí kan ìlera wa. (Sáàmù 55:22; Fílípì 4:6, 7) Ṣùgbọ́n, Bíbélì kò sọ pé ìgbòkègbodò tẹ̀mí tó pọ̀ sí i ni yóò wo àwọn ìṣòro ìlera tó wà nísinsìnyí sàn.
Nítorí èyí, àwọn Kristẹni olóye máa ń ṣọ́ra láti má ṣe mú kí àwọn tó ní àárẹ̀ ọkàn máa ronú pé àwọn ló fọwọ́ ara wọn fa ohun tó ń ṣe wọ́n. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ á wulẹ̀ dà bí ọ̀rọ̀ tí àwọn olùtùnú èké wọ̀nyẹn sọ fún Jóòbù ni, kò sì lè ṣèrànwọ́ kankan. (Jóòbù 8:1-6) Òtítọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé, lọ́pọ̀ ìgbà, àárẹ̀ ọkàn kì í lọ àyàfi bí a bá lo oògùn sí i. Àgàgà tó bá jẹ́ àárẹ̀ ọkàn tó le gan-an ni ẹnì kan ní, bóyá tó tiẹ̀ tún máa ń ronú láti pa ara rẹ̀. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì kí àwọn amọṣẹ́dunjú wá nǹkan ṣe sí i.
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni lè ṣe láti ṣètìlẹ́yìn. Àmọ́ ṣá o, ó gba sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni kan lè má rọrùn rárá fún ẹni tó ní ìṣòro ìṣesí tó ṣàdédé ń yí padà. Diane, tó ní àìsàn tó ń mú un hùwà lódìlódì, sọ pé: “Agídí ni mo fi ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Etí wo ló ń gbọ́ ọ pé mò ń lọ wàásù ìhìn rere Bíbélì tó ń fúnni láyọ̀ fáwọn ẹlòmíràn nígbà tó jẹ́ pé èmi fúnra mi ò láyọ̀.”
Láti lè ran àwọn aláìsàn náà lọ́wọ́, sakun láti jẹ́ ẹni tó ń fi ọ̀ràn ro ara rẹ̀ wò. (1 Kọ́ríńtì 10:24; Fílípì 2:4) Gbìyànjú láti má ṣe fi ojú tìrẹ wo àìsàn náà, ojú tí aláìsàn náà fi ń wò ó ni kí ìwọ náà fi wò ó. Má ṣe kó ìdààmú bá aláìsàn náà nípa ríretí pé kó ṣe ohun tí kò lè ṣe. Carl, tó ní ìṣòro àárẹ̀ ọkàn, sọ pé: “Bí àwọn èèyàn bá gbà mí bí mo ṣe rí nísinsìnyí, á fi mi lọ́kàn balẹ̀ pé èmi náà bẹ́gbẹ́ mu. Nítorí ìrànlọ́wọ́ tí àwọn ọ̀rẹ́ bíi mélòó kan tó dàgbà jù mí lọ ń fi sùúrù pèsè, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti ní àjọṣe tó túbọ̀ ṣe pẹ́kípẹ́kí sí i pẹ̀lú Ọlọ́run, mo sì ti rí ayọ̀ tó pọ̀ gan-an nínú ríran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀.”
Bí àwọn aláìsàn náà bá rí ìtìlẹ́yìn, wọ́n lè rí ìtura ńláǹlà. Gbé ọ̀ràn ti Brenda, Kristẹni obìnrin kan tí òun náà ní àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì, yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi nínú ìjọ máa ń ṣètìlẹ́yìn fún mi gan-an, wọ́n sì máa ń lóye bó ṣe ń ṣe mí nígbà tó bá sọ mí wò, wọn kì í kà mí sí aláìlera nípa tẹ̀mí. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n máa ń jẹ́ kí n bá àwọn lọ sóde ẹ̀rí tí màá kàn máa tẹ́tí sí ohun tí wọ́n bá ń sọ. Àwọn ìgbà míì sì wà tí wọ́n á gba àyè sílẹ̀ fún mi ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kí n bàa lè wọlé wá jókòó lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ará bá ti wà níkàlẹ̀.”
Bí àwọn alàgbà ìjọ ṣe ń fi ìfẹ́ ṣètìlẹ́yìn, tí wọ́n sì tún jẹ́ ẹlẹ́mìí ìfọ̀ràn-rora-ẹni-wò, ti ṣèrànwọ́ gan-an fún Cherie, ẹni tó ní àárẹ̀ ọkàn, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí. Ó sọ pé: “Nígbà táwọn alàgbà bá mú un dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi, tí wọ́n ka àwọn apá kan nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún mi, tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ète Jèhófà láti mú párádísè alálàáfíà àti onílera pípé wá, tí wọ́n sì gbàdúrà pẹ̀lú mi, àní lórí tẹlifóònù pàápàá, bí ìgbà tí wọ́n mú ìṣòro náà kúrò ló máa ń rí lára mi. Mo mọ̀ pé Jèhófà àtàwọn arákùnrin mi ò pa mí tì, okun ńlá gbáà ni ìyẹn sì ń fún mi.”
Kò sí iyèméjì pé nípa pípèsè ìtìlẹ́yìn yíyẹ, àwọn ará àtọ̀rẹ́ lè kópa pàtàkì nínú ìlera aláìsàn náà. Lucia sọ pé: “Mo ronú pé mo lè bójú tó ìgbésí ayé mi dáadáa báyìí. Èmi àti ọkọ mi ti ṣiṣẹ́ kára láti kojú ìṣòro náà, nǹkan sì ti wá sàn fún wa báyìí ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.”
Ọ̀pọ̀ àwọn tí onírúurú àìsàn ọpọlọ ń yọ lẹ́nu báyìí mọ̀ pé ìjà tí yóò máa bá a lọ fún ọjọ́ pípẹ́ ní ìjà táwọn ń bá àwọn àìsàn tó ń ko ìpayà báni wọ̀nyí jà. Síbẹ̀, Bíbélì ṣèlérí pé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Àwọn àìsàn tí ń hanni léèmọ̀ àti àwọn ìṣòro tí ń gbógun ti ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí á ti dàwátì nígbà yẹn. Ohun amọ́kànyọ̀ gbáà ló jẹ́ láti máa ronú nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ayé tuntun kan nínú èyí tí gbogbo àìlera, títí kan ìṣòro ìṣesí tó ṣàdédé ń yí padà, á ti di ohun tí ò ní sí mọ́ láéláé. Bíbélì sọ pé nígbà yẹn, kò ní sí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.—Ìṣípayá 21:4.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Jésù gbà pé àwọn tí ń ṣòjòjò nílò oníṣègùn.—MÁTÍÙ 9:12
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
Bíbélì ṣèlérí pé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—AÍSÁYÀ 33:24