ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp23 No. 1 ojú ìwé 10-11
  • 3 | Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Èèyàn Inú Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 3 | Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Èèyàn Inú Bíbélì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Túmọ̀ Sí
  • Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́
  • Kíkojú Ìṣòro Kí Ìṣesí Ẹni Máa Ṣàdédé Yí Padà
    Jí!—2004
  • Bí Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
    Jí!—2004
  • Má Ṣe Sọ̀rètí Nù
    Jí!—2004
  • 2 | “Ìtùnú Látinú Ìwé Mímọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
wp23 No. 1 ojú ìwé 10-11
Ìdààmú ọkàn bá Mósè, ó gbójú sókè, ó sì ń gbàdúrà sí Ọlọ́run.

3 | Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Èèyàn Inú Bíbélì

BÍBÉLÌ SỌ̀RỌ̀ NÍPA . . . Àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni “tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa.”​—JÉMÍÌSÌ 5:17.

Ohun Tó Túmọ̀ Sí

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìtàn àwọn èèyàn tí oríṣiríṣi nǹkan ṣẹlẹ̀ sí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kì í ṣe ìtàn àròsọ lásán. Tá a bá ka àwọn ìtàn náà, a lè rí ẹnì kan tí ọ̀rọ̀ ẹ̀ jọ tiwa tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀.

Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́

Gbogbo wa la máa ń fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa yé àwọn èèyàn. Ní pàtàkì tá a bá ní àárẹ̀ ọpọlọ. Tá a bá ka ìtàn àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn, àá rí i pé ọ̀rọ̀ tiwa àti tiwọn jọra. Ìyẹn á jẹ́ ká gbà pé ohun tó ń ṣe wá ti ṣe àwọn míì rí, ó sì máa jẹ́ ká lè fara dà á nígbà tá a bá ń ṣàníyàn láṣejù àti nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn.

  • Bíbélì sọ ìtàn àwọn èèyàn tí wọ́n ní ìṣòro ńlá tí nǹkan sì tojú sú wọn. Ṣé o ti níṣòro kan rí tó o wá sọ pé: ‘Wàhálà yìí ti pọ̀ jù, ó ti sú mi’? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí Mósè, Èlíjà àti Dáfídì.​—Nọ́ńbà 11:14; 1 Àwọn Ọba 19:4; Sáàmù 55:4.

  • Àpẹẹrẹ ẹnì kan tí Bíbélì sọ ìtàn ẹ̀ ni Hánà. Inú Hánà “bà jẹ́ gan-an” torí pé kò rọ́mọ bí, orogún ẹ̀ sì máa ń pẹ̀gàn ẹ̀.​—1 Sámúẹ́lì 1: 6,10.

  • Àpẹẹrẹ míì ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jóòbù, èèyàn bíi tiwa lòun náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára, ìgbà kan wà tí ìdààmú ọkàn bá a gan-an, tó sì sọ pé: “Mo kórìíra ayé mi gidigidi; mi ò fẹ́ wà láàyè mọ.”​—Jóòbù 7:16.

Tá a bá mọ ohun táwọn èèyàn yìí ṣe láti borí èrò òdì, ó máa ran àwa náà lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro wa.

Bíbélì Ran Kevin Lọ́wọ́

Mo Ní Àárẹ̀ Ọpọlọ Tí Wọ́n Ń Pè Ní Bipolar Disorder

Kevin ń mu tíì pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì.

“Nígbà tó kù díẹ̀ kí n pé ẹni àádọ́ta (50) ọdún, àwọn dókítà sọ fún mi pé mo ní àárẹ̀ ọpọlọ tí wọ́n ń pè ní bipolar disorder. Ìgbà míì wà tí ara mi á yá gágá, tí ọkàn mi á sì balẹ̀. Àmọ́ kí n tó mọ̀, inú mi á kàn dédé bà jẹ́, gbogbo nǹkan á sì sú mi.”

Bíbélì Ràn Mí Lọ́wọ́

“Àpẹẹrẹ ẹnì kan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ ẹ̀ tó ràn mí lọ́wọ́ ni àpọ́sítélì Pétérù. Ó ṣe àwọn àṣìṣe kan tó mú kó rò pé òun ò wúlò. Àmọ́ dípò tí Pétérù á fi máa ronú ṣáá nípa àwọn àṣìṣe yẹn, ó lọ bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ kí wọ́n lè tù ú nínú. Tí àárẹ̀ ọpọlọ tó ń ṣe mí bá ti ń yọ mí lẹ́nu, ó máa ń mú kí n máa ronú ṣáá nípa àṣìṣe mi, ìyẹn sì máa ń mú kí n rò pé mi ò wúlò. Bíi ti Pétérù, èmi náà máa ń sún mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi kí wọ́n lè tù mí nínú, wọ́n sì máa ń ràn mí lọ́wọ́ kí n má bàa rẹ̀wẹ̀sì.

“Àpẹẹrẹ ẹlòmíì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ ẹ̀ tó tù mí nínú gan-an ni Ọba Dáfídì. Àwọn àṣìṣe tó ṣe dùn ún gan-an, ọ̀pọ̀ ìgbà ni inú ẹ̀ sì máa ń bà jẹ́. Ọ̀rọ̀ wa jọra, torí ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tí kò yẹ, ó sì máa ń dùn mí gan-an. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ ní Sáàmù 51 máa ń tù mí nínú. Ní ẹsẹ 3, Ó sọ pé: ‘Mo mọ àwọn àṣìṣe mi dáadáa, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi nígbà gbogbo.’ Bó ṣe máa ń ṣe mí nìyẹn tí mo bá ní ìdààmú ọkàn tó lágbára gan-an, torí ó máa ń jẹ́ kí n gbà pé mi ò wúlò fún nǹkan kan. Àmọ́ mo fẹ́ràn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì tún sọ ní ẹsẹ 10. Ó sọ pé: ‘Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, Kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sí inú mi, èyí tó fìdí múlẹ̀.’ Èmi náà máa ń fi irú ọ̀rọ̀ yìí bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n lè máa fojú iyì wo ara mi. Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì wá sọ ní ẹsẹ 17 máa ń mára tù mí gan-an. Ó ní: ‘Ìwọ Ọlọ́run, o kò ní pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú tì.’ Ẹsẹ Bíbélì yìí máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi.

“Bí mo ṣe ń ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn àti bí Ọlọ́run ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ báyìí, ó máa ń jẹ́ kí ọkàn mi túbọ̀ balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ó dá mi lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì máa ṣẹ, ìyẹn sì ń jẹ́ kí n lè máa fara da àwọn ìṣòro mi.”

Tó O Bá Fẹ́ Mọ̀ Sí I:

Ka àpilẹ̀kọ náà, “Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Pa Ara Rẹ,” nínú Ilé Ìṣọ́ No. 2 2019, lórí jw.org.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́