3 | Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Èèyàn Inú Bíbélì
BÍBÉLÌ SỌ̀RỌ̀ NÍPA . . . Àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni “tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa.”—JÉMÍÌSÌ 5:17.
Ohun Tó Túmọ̀ Sí
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìtàn àwọn èèyàn tí oríṣiríṣi nǹkan ṣẹlẹ̀ sí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kì í ṣe ìtàn àròsọ lásán. Tá a bá ka àwọn ìtàn náà, a lè rí ẹnì kan tí ọ̀rọ̀ ẹ̀ jọ tiwa tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀.
Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́
Gbogbo wa la máa ń fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa yé àwọn èèyàn. Ní pàtàkì tá a bá ní àárẹ̀ ọpọlọ. Tá a bá ka ìtàn àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn, àá rí i pé ọ̀rọ̀ tiwa àti tiwọn jọra. Ìyẹn á jẹ́ ká gbà pé ohun tó ń ṣe wá ti ṣe àwọn míì rí, ó sì máa jẹ́ ká lè fara dà á nígbà tá a bá ń ṣàníyàn láṣejù àti nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn.
Bíbélì sọ ìtàn àwọn èèyàn tí wọ́n ní ìṣòro ńlá tí nǹkan sì tojú sú wọn. Ṣé o ti níṣòro kan rí tó o wá sọ pé: ‘Wàhálà yìí ti pọ̀ jù, ó ti sú mi’? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí Mósè, Èlíjà àti Dáfídì.—Nọ́ńbà 11:14; 1 Àwọn Ọba 19:4; Sáàmù 55:4.
Àpẹẹrẹ ẹnì kan tí Bíbélì sọ ìtàn ẹ̀ ni Hánà. Inú Hánà “bà jẹ́ gan-an” torí pé kò rọ́mọ bí, orogún ẹ̀ sì máa ń pẹ̀gàn ẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 1: 6,10.
Àpẹẹrẹ míì ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jóòbù, èèyàn bíi tiwa lòun náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára, ìgbà kan wà tí ìdààmú ọkàn bá a gan-an, tó sì sọ pé: “Mo kórìíra ayé mi gidigidi; mi ò fẹ́ wà láàyè mọ.”—Jóòbù 7:16.
Tá a bá mọ ohun táwọn èèyàn yìí ṣe láti borí èrò òdì, ó máa ran àwa náà lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro wa.