ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 1/8 ojú ìwé 4-7
  • Kíkojú Ìṣòro Kí Ìṣesí Ẹni Máa Ṣàdédé Yí Padà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkojú Ìṣòro Kí Ìṣesí Ẹni Máa Ṣàdédé Yí Padà
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àárẹ̀ Ọkàn—Ìbànújẹ́ Tó Ń Dorí Ẹni Kodò
  • Àìsàn Bipolar—Àìsàn Tó Ń Mú Kí Ìṣesí Máa Yí Padà Ṣáá
  • Báa Ṣe Lè Dá Àwọn Àmì Ìsoríkọ́ Mọ̀
    Jí!—2001
  • Má Ṣe Sọ̀rètí Nù
    Jí!—2004
  • Bí Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
    Jí!—2004
  • Àwọn Aláàárẹ̀ Ọkàn
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 1/8 ojú ìwé 4-7

Kíkojú Ìṣòro Kí Ìṣesí Ẹni Máa Ṣàdédé Yí Padà

WÍWỌ́PỌ̀ tí ìṣòro ìṣesí tó ṣàdédé ń yí padà ń wọ́pọ̀ sí i ti ń bani lẹ́rù báyìí o. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fojú bù ú pé ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún àti ọgbọ̀n mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé tó ní àárẹ̀ ọkàn tó le gan-an. Ìṣòro yìí máa ń mú kí ìbànújẹ́ dorí àwọn tó ń ṣe kodò, gbogbo nǹkan tí wọ́n ń dáwọ́ lé lójoojúmọ́ kì í sì í fún wọn láyọ̀ rárá. Wọ́n ti fojú bù ú pé ní ogún ọdún sígbà tá a wà yìí, bá a bá yọwọ́ àrùn tó jẹ mọ́ ọkàn àti òpójẹ̀, àárẹ̀ ọkàn ló máa wọ́pọ̀ jù lọ. Abájọ táwọn kan fi sọ pé òun ló wọ́pọ̀ jù lọ nínú onírúurú àìsàn ọpọlọ.

Láwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn ti túbọ̀ ń mọ̀ sí i nípa àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì. Lára àwọn àmì àrùn yìí ni kí ìmọ̀lára máa yí padà, látorí àárẹ̀ ọkàn dórí kí ara máa yá sódì. Ìwé kan tí Ẹgbẹ́ Oníṣègùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe jáde láìpẹ́ yìí sọ pé: “Nígbà tí àárẹ̀ ọkàn bá ń ṣe ọ́, èrò tó máa gbà ọ́ lọ́kàn ni pé kó o fọwọ́ ara ẹ para ẹ. Àmọ́, bí àìsàn náà bá yí sí kí ara rẹ máa yá sódì, o ò ní lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, o ò sì ní lè rí ewu tó wà nínú àwọn ohun tó o bá ń ṣe.”

Wọ́n fojú bù ú pé ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tó ń gbé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì ń ṣe, èyí tó túmọ̀ sí pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni àìsàn náà ń ṣe lórílẹ̀-èdè yẹn nìkan ṣoṣo. Àmọ́ ṣá o, iye yìí nìkan kò tó láti ṣàlàyé bí ìṣòro kí ìṣesí ẹni máa ṣàdédé yí padà ṣe ń han àwọn tó ní in léèmọ̀ tó.

Àárẹ̀ Ọkàn—Ìbànújẹ́ Tó Ń Dorí Ẹni Kodò

Gbogbo wa la mọ bó ṣe máa ń rí bí ohun kan bá kó ìbànújẹ́ bá wa. Láìpẹ́, bóyá láàárín wákàtí díẹ̀ tàbí ọjọ́ mélòó kan, ìbànújẹ́ náà á ti wábi gbà. Àmọ́ ṣá o, akọ àárẹ̀ ọkàn le jùyẹn lọ. Lọ́nà wo? Ọ̀mọ̀wé Mitch Golant ṣàlàyé pé: “Àwa tá ò ní àárẹ̀ ọkàn mọ̀ pé bó ti wù kí ìmọ̀lára wa máa yí padà tó, bópẹ́ bóyá, ara wa á balẹ̀, ṣùgbọ́n ti ẹni tó ní àárẹ̀ ọkàn kò rí bẹ́ẹ̀. Bí ara ẹ̀ bá yá gágá díẹ̀, ìbànújẹ́ á tún dorí ẹ̀ kodò, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀lára rẹ̀ á máa ṣàdédé yí padà láìmọ ibi tó máa já sí bíi tẹni tó wà nínú ọkọ̀ ojú irin tó ti fẹ́ yí ṣubú tí kò sì mọ bí òun ṣe lè jáde nínú ọkọ̀ náà tàbí ìgbà tí òun máa tóó lè jáde. Tàbí bóyá òun á tiẹ̀ lè jáde nínú ọkọ̀ náà.”

Onírúurú ọ̀nà ni akọ àárẹ̀ ọkàn pín sí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn kan máa ń ní àárẹ̀ ọkàn tó máa ń wáyé ní àkókò kan pàtó nínú ọdún, pàápàá nígbà òtútù. Ìwé kan tí ẹgbẹ́ oníṣègùn tó ń jẹ́ People’s Medical Society gbé jáde sọ pé: “Àwọn tó ní irú àárẹ̀ ọkàn yìí sọ pé ńṣe ló máa ń légbá kan sí i bí ibi táwọn ń gbé bá ṣe sún mọ́ ìhà àríwá ilẹ̀ ayé tó àti bójú ọjọ́ bá ṣe ṣú dùdù tó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà òtútù tójú ọjọ́ máa ń dá gùdẹ̀ ni wọ́n sọ pé àárẹ̀ ọkàn yìí sábà máa ń wáyé, nínú àwọn ọ̀ràn kan, kí ibi téèyàn ti ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ilé ṣókùnkùn, kí ojú ọjọ́ ṣú dùdù nígbà tí kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, tàbí kéèyàn má lè ríran kedere máa ń fà á.”

Kí ló ń fa akọ àárẹ̀ ọkàn? Ìdáhùn náà ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere. Nígbà tó jẹ́ pé nínú àwọn ọ̀ràn kan ó dà bí ẹni pé ohun àjogúnbá ni, lọ́pọ̀ ìgbà ó dà bí ẹni pé ohun tójú ẹni ti rí nínú ìgbésí ayé ló máa ń kópa tó pọ̀ jù lọ. Wọ́n tún ti kíyè sí i lẹ́yìn àyẹ̀wò pé ní ìpíndọ́gba, bí àìsàn náà bá ṣe ọkùnrin kan á ṣe obìnrin méjì.a Ṣùgbọ́n èyí ò fi hàn pé kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe àwọn ọkùnrin o. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ti fojú bù ú pé láàárín ìpín márùn-ún sí méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọkùnrin ló máa ní akọ àárẹ̀ ọkàn bó bá tó àkókò kan nínú ìgbésí ayé wọn.

Nígbà tí irú akọ àárẹ̀ ọkàn yìí bá kọ lu ẹnì kan, kò ní da apá kankan sí lára rẹ̀, á sì nípa lórí gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ pátá. Sheila, tó ní akọ àárẹ̀ ọkàn, sọ pé: “Á gbò ẹ́ jìgìjìgì, o ò ní nígbọkànlé mọ́ nínú ara rẹ, o ò ní já mọ́ nǹkan kan mọ́ lójú ara rẹ, o ò ní lè ronú lọ́nà tó já gaara, o ò sì ní lè dá ìpinnu ṣe mọ́. Bó bá wá wọra tán pátápátá, á máa mú kí ara ni ẹ́ gan-an, á wá dà bíi pé o ò ní lè fara dà á.”

Àmọ́, àwọn ìgbà míì wà tí ẹni tó ní akọ àárẹ̀ ọkàn lè rí ìtura nípa sísọ bó ṣe ń ṣe é fún ẹnì kan tí yóò gba tirẹ̀ rò. (Jóòbù 10:1) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbà pé bó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan kan tí ò ṣiṣẹ́ dáadáa nínú ọpọlọ ló fa àárẹ̀ ọkàn, níní èrò rere lọ́kàn nìkan kò tó láti lé e lọ. Bí ọ̀ràn bá sì ti rí báyìí, kò sí ohun tí aláàárẹ̀ ọkàn lè ṣe láti mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tó ń bá àìsàn náà rìn kúrò. Àti pé àárẹ̀ ọkàn náà lè máa ṣe é ní kàyéfì bó ti ń ṣe àwọn ará àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní kàyéfì.

Gbé ọ̀ràn ti Kristẹni kan tó ń jẹ́ Paulab yẹ̀ wò. Ó ti fara da ìrẹ̀wẹ̀sì tó ń kó àárẹ̀ bá a ṣáá kí àyẹ̀wò tó fi hàn pé àárẹ̀ ọkàn ló ń ṣe é. Ó sọ pé: “Nígbà míì, lẹ́yìn tí ìpàdé ìjọ bá parí, màá sáré lọ sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi màá sì máa sọkún, láìsí ìdí gúnmọ́ kan. Ńṣe ni mo kàn máa ń ronú ṣáá pé mo dá nìkan wà, inú mi sì máa ń bà jẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí fi hàn pé mo ní àwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ tó bìkítà nípa mi, kò ṣeé ṣe fún mi láti rí i bẹ́ẹ̀.”

Ohun tó fara jọ èyí ló ṣẹlẹ̀ sí Ellen, tí àárẹ̀ ọkàn rẹ̀ le débi pé wọ́n ní láti dá a dúró sílé ìwòsàn. Ó sọ pé: “Mo ní ọmọkùnrin méjì, àwọn aya wọn méjèèjì tí wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún mi àti ọkọ mi, ó sì dá mi lójú pé gbogbo wọn ló nífẹ̀ẹ́ mi gidigidi.” Ó yẹ kí Ellen mọ̀ pé òun ò ní olódì kankan àti pé ẹni ọ̀wọ́n lòún jẹ́ sí ìdílé òun. Ṣùgbọ́n, bí àárẹ̀ ọkàn bá bẹ̀rẹ̀ báyìí, aláàárẹ̀ ọkàn náà lè bẹ̀rẹ̀ sí ro àwọn èròkerò tí ò lórí tí ò nídìí.

Kò tún yẹ ká gbójú fò ó pé àárẹ̀ ọkàn ẹnì kan lè nípa gan-an lórí àwọn yòókù nínú ìdílé rẹ̀. Ọ̀mọ̀wé Golant kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ bá ní àárẹ̀ ọkàn, ìbẹ̀rù ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí i nígbàkigbà lè máa dà ọ́ láàmú, nítorí àìmọ ìgbà tí àárẹ̀ ọkàn náà máa fi í sílẹ̀ tàbí ìgbà tó tún máa ṣe é. Gbogbo nǹkan lè tojú sú ọ, tàbí kó o tiẹ̀ ní ẹ̀dùn ọkàn kí inú sì máa bí ọ pé ó ṣeé ṣe kí ìgbésí ayé máà rí bákan náà mọ́ fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.”

Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ lè mọ̀ bí òbí bá ní àárẹ̀ ọkàn. Ọ̀mọ̀wé Golant sọ pé: “Ọmọ kan tí ìyá rẹ̀ bá ní àárẹ̀ ọkàn máa ń mọ̀ nípa ìmọ̀lára ìyá rẹ̀ gan-an, á máa ṣọ́ ìyípadà èyíkéyìí nínú ìṣesí rẹ̀, bó ti wù kó kéré mọ.” Dókítà Carol Watkins ṣàkíyèsí pé ọmọ àwọn òbí tó bá ní àárẹ̀ ọkàn “lè ní ìṣòro tó jẹ mọ́ ìwà híhù, kíkẹ́kọ̀ọ́ àti níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ó sì ṣeé ṣe kí àwọn fúnra wọn ní àárẹ̀ ọkàn.”

Àìsàn Bipolar—Àìsàn Tó Ń Mú Kí Ìṣesí Máa Yí Padà Ṣáá

Ìṣòro líle koko gbáà ni akọ àárẹ̀ ọkàn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ara àyásódì bá kún un ló ń di ohun táà ń pè ní àìsàn bipolar, tó ń múni hùwà lódìlódì.c Lucia tí àìsàn yìí ń ṣe sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo tó dájú hán-únhán-ún nípa àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì ni pé ìgbà gbogbo ṣáá ló máa ń jẹ́ kí ìṣesí ẹni yí padà. Ìwé ìròyìn The Harvard Mental Health Letter sọ pé nígbà tí ara àwọn tí àìsàn yìí ń ṣe bá bẹ̀rẹ̀ sí yá sódì, “wọ́n lè máa dá sí ọ̀ràn tí ò kàn wọ́n kí wọ́n sì máa fẹ́ láti gbawájú nínú ohun gbogbo. Àmọ́, yíyọ̀ tí wọ́n ń yọ àyọ̀sódì bí aláágànná yìí lè yí padà bìrí kí wọ́n sì máa kanra tàbí kí wọ́n máa bínú.”

Lenore rántí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tí ara ẹ̀ bá ń yá sódì. Ó sọ pé: “Eegun mi máa ń le gan-an. Àwọn kan á máa sọ pé obìnrin bí ọkùnrin ni mí. Àwọn èèyàn kan á ní, ‘Ì bá sì wù wá o, ká ní a lè dà bíi tìẹ.’ Ńṣe ni agbára á máa gùn mí ṣáá, bí ẹni pé kò sí ohun tó kọ́ja agbára mi láti ṣe. Mò ń ṣeré ìdárayá kíkankíkan. Ìwọ̀nba oorun díẹ̀ ni mò ń sùn, nǹkan bíi wákàtí méjì sí mẹ́ta. Síbẹ̀, bí mo bá jí, eegun mi á ṣì le bó ti wà kí n tó sùn.”

Àmọ́, tó bá tún yá, àárẹ̀ ọkàn á tún kọlu Lenore. Ó sọ pé: “Nígbà tí ayọ̀ bá kún inú mi jù lọ, màá bẹ̀rẹ̀ sí nímọ̀lára pé ohun kan ń jà gùdù nínú mi lọ́hùn-ún, bí ọkọ̀ kan tó ń sáré tí kò sì ṣeé paná mọ́ lẹ́nu. Lójú ẹsẹ̀, ìṣesí mi tó bá taráyé mu á yí padà di ti ẹhànnà, màá sì máa da igbá pọ̀ máwo. Mo lè máa hó lé ọ̀kan lára àwọn aráalé lórí láìsí ìdí gúnmọ́ kankan. Màá máa bínú gan-an, ìkórìíra á kún inú ọkàn mi, mi o sì ní mọ oun tí mò ń ṣe mọ́. Lẹ́yìn gbogbo èyí, á kàn rẹ̀ mí wá ni, omijé á máa dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú mi, àárẹ̀ ọkàn á sì dà bò mí. Màá ka ara mi sí ẹni tí kò já mọ́ ohunkóhun àti ẹni búburú. Láìka gbogbo ìyẹn sí, mo lè yí padà bìrí kí n sì máa láyọ̀, bí ẹni pé kò sí ohunkóhun rárá.”

Bí àwọn tó ń hùwà lódìlódì ṣe máa ń ṣe wánranwànran máa ń kó ìdààmú bá àwọn yòókù nínú ìdílé. Mary, tí àìsàn yìí ń ṣe ọkọ rẹ̀, sọ pé: “Kì í yé wa bó ṣe jẹ́ pé ọkọ mi tó ń láyọ̀ tá a sì jọ ń sọ̀rọ̀ á kàn ṣàdédé sorí kọ́, kò sì ní dá sí ẹnikẹ́ni mọ́. Kò rọrùn fún wa láti gbà pé kì í ṣẹ̀bi rẹ̀.”

Ohun tó jẹ́ ìyàlẹ́nu níbẹ̀ ni pé àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì máa ń kó ìrora ọkàn bá àwọn tó ń yọ lẹ́nu bíi tará yòókù, tàbí kó tiẹ̀ ju tará yòókù lọ. Gloria, tí àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì ń ṣe, sọ pé: “Mo máa ń jowú àwọn tí ìṣesí wọn kì í ṣadédé yí padà. Ní ti àwa tí àìsàn yìí ń ṣe, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ìṣesí wa máa ń wà déédéé.”

Kí ló ń fa àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì? Apilẹ̀ àbùdá ẹni wà lára ohun tó ń fà á, ìyẹn sì lágbára ju ohun tó ń fa àárẹ̀ ọkàn lọ. Ẹgbẹ́ Oníṣègùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ṣe fi hàn, àwọn ìbátan àwọn tó ń hùwà lódìlódì, bí àwọn òbí, àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n, àtàwọn ọmọ sábà máa ń ní àrùn náà ju àwọn tó wá látinú ìdílé tí ara wọ́n dá ṣáṣá lọ. Ní àfikún sí èyí, bí ẹnì kan tó ní àárẹ̀ ọkàn tó ń nípa lórí ìmọ̀lára bá wà nínú ìdílé rẹ, ìyẹn lè mú kí ìwọ náà ní àárẹ̀ ọkàn tó burú jáì.”

Àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì yàtọ̀ sí àárẹ̀ ọkàn ní ti pé ní ìpíndọ́gba, iye ọkùnrin àti obìnrin kan náà ló ń ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbà téèyàn bá ń bàlágà ni àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì máa ń bẹ̀rẹ̀, àmọ́ àyẹ̀wò fi hàn pé ó ń ṣe àwọn ọ̀dọ́langba àtàwọn ọmọdé pàápàá. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ṣòro láti ṣàyẹ̀wò àwọn àmì téèyàn ń rí kéèyàn sì wá parí èrò pé àìsàn náà ló ń yọ ẹnì kan lẹ́nu, àní, ó ṣòro fún oníṣègùn kan tó mọṣẹ́ dunjú pàápàá. Dókítà Francis Mark Mondimore ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìṣègùn ní Yunifásítì Johns Hopkins sọ pé: “Bí ọ̀gà tó máa ń pàwọ̀ dà ni àìsàn tó ń múni hùwà lódìlódì rí nínú àwọn ìṣòro tó ń nípa lórí ìrònú àti ìhùwà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àmì tí a fi ń dá àrùn náà mọ̀ lára ẹnì kan máa ń yàtọ̀ sí ti ara ẹlòmíràn, ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì máa ń gbà wá, kódà lára ẹnì kan náà pàápàá. Ńṣe ni àìsàn ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí máa ń wọlé wá wẹ́rẹ́, táá sì mú kí ìbànújẹ́ dorí ẹni tó ń ṣe kodò; lẹ́yìn náà, ó lè fi onítọ̀hún sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́, dídé tó bá tún máa padà dé báyìí ńṣe ni ara onítọ̀hún á máa yá àyásódì táá sì máa ṣe bí aláágànná.”

Dájúdájú, ó ṣòro láti fi àyẹ̀wò mọ̀ bí ẹnì kan bá ní ìṣòro ìṣesí tó ṣàdédé ń yí padà, èyí tó sì tún ṣòro jù ni fífara dà á. Àmọ́ o, ìrètí wà fún àwọn tó ní ìṣòro yìí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ohun kan tó ṣeé ṣe kó fà á tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn obìnrin máa ń ní àárẹ̀ ọkàn tó máa ń wáyé lẹ́yìn ìbímọ. Ohun mìíràn ni pé lẹ́yìn tí nǹkan oṣù bá mọ́wọ́ dúró, àwọn ohun kan nínú ara tó ń nípa lórí ìmọ̀lára ẹni lè pọ̀ sí i tàbí kó dín kù. Láfikún sí i, àwọn obìnrin máa ń sábà lọ rí dókítà, nítorí náà, wọ́n máa ń ṣe àyẹ̀wò fún wọn.

b A ti yí díẹ̀ lára àwọn orúkọ tó wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ yìí padà.

c Àwọn dókítà ròyìn pé lọ́pọ̀ ìgbà, ìṣesí kọ̀ọ̀kan sábà máa ń wà bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù. Àmọ́ ṣá o, wọ́n tún kíyè sí àwọn kan tí ìṣesí wọn máa ń yí padà lemọ́lemọ́. Ara wọn máa ń yá sódì, wọ́n sì tún máa ń ní àárẹ̀ ọkàn lọ́pọ̀ ìgbà lọ́dún. Àyàfi nínú àwọn ọ̀ràn kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ni ìṣesí àwọn kan tó ń hùwà lódìlódì ti máa ń yí padà láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Ní ti àwa tí àìsàn yìí ń ṣe, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ìṣesí wa máa ń wà déédéé.”—GLORIA

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn Àmì Tá A Lè Fi Mọ Àárẹ̀ Ọkàn Tó Burú Jáìd

● Kéèyàn máa sorí kọ́, lọ́pọ̀ ìgbà lójúmọ́, ní èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ojoojúmọ́, fún ọ̀sẹ̀ méjì ó kéré tán

● Kí àwọn ìgbòkègbodò tó ti ń gbádùn mọ́ni tẹ́lẹ̀ máa súni

● Kéèyàn joro gan-an tàbí kó sanra gan-an

● Oorun àsùnjù tàbí àìróorunsùn rárá

● Kí ara máa ṣiṣẹ́ sódì tàbí kó má fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán

● Kó máa rẹni tẹnutẹnu, láìsí ìdí gúnmọ́ kan

● Kéèyàn máa ronú pé òun ò já mọ́ nǹkan kan tàbí kó máa ní ìdálẹ́bi ọkàn láìyẹ, tàbí kí méjèèjì máa ṣẹlẹ̀ sí i

● Kéèyàn má lè fi bẹ́ẹ̀ pọkàn pọ̀

● Ríronú ṣáá nípa gbígbẹ̀mí ara ẹni

Àwọn kan lára àwọn àmì àrùn wọ̀nyí tún lè fi hàn pé ẹnì kan ní dysthymia—irú àárẹ̀ ọkàn kan tó jẹ́ pé àwọn àmì tá a lè fi mọ̀ ọ́n kò le tó ti àárẹ̀ ọkàn tó burú jáì

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

d Àkópọ̀ lásán làwọn kókó tá a tò sókè yìí, wọn kì í ṣe ohun tá a lè lò láti fi mọ ohun tó ń ṣeni. Bákan náà, díẹ̀ lára wọn lè jẹ́ àmì tá a fi ń mọ àwọn ìṣòro mìíràn yàtọ̀ sí àárẹ̀ ọkàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́