ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp23 No. 1 ojú ìwé 8-9
  • 2 | “Ìtùnú Látinú Ìwé Mímọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2 | “Ìtùnú Látinú Ìwé Mímọ́”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Túmọ̀ Sí
  • Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ní Ìdààmú Ọkàn
    Jí!—2017
  • Báwo Lo Ṣe Lè Borí Èrò Òdì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • 3 | Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Èèyàn Inú Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
  • Ìsoríkọ́
    Jí!—2013
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
wp23 No. 1 ojú ìwé 8-9
Bàbá àgbàlagbà kan ń ronú lórí ohun tó ń kà nínú Bíbélì.

2 | “Ìtùnú Látinú Ìwé Mímọ́”

BÍBÉLÌ SỌ PÉ: “Gbogbo ohun tí a kọ ní ìṣáájú ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí á lè ní ìrètí nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.”​—RÓÒMÙ 15:4.

Ohun Tó Túmọ̀ Sí

Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì máa ń fún wa lókun, ó sì máa ń jẹ́ ká lè fara dà á tí èrò òdì bá ń wá sí wa lọ́kàn. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé láìpẹ́, gbogbo ìṣòro tó ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún wa ò ní sí mọ́.

Àǹfààní Tó Máa Ṣe Ẹ́

Gbogbo wa ni nǹkan máa ń tojú sú nígbà míì, àmọ́ ní tàwọn tó ní ìdààmú ọkàn tàbí tí àníyàn máa ń gbà lọ́kàn, ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an. Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

  • Bíbélì jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan rere tá a lè máa ronú lé lórí tí ò ní jẹ́ ká máa ro èrò òdì. (Fílípì 4:8) Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì máa ń tù wá nínú, ó máa ń tù wá lára, kò sì ní jẹ́ ká ṣinú rò.​—Sáàmù 94:18, 19.

  • Tá a bá ń ronú pé a ò wúlò fún nǹkan kan, Bíbélì á jẹ́ ká gbé èrò náà kúrò lọ́kàn.​—Lúùkù 12:6, 7.

  • Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì ló fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wa wà pẹ̀lú wa, àti pé ó mọ gbogbo bó ṣe ń ṣe wá.​—Sáàmù 34:18; 1 Jòhánù 3:19, 20.

  • Bíbélì sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí Ọlọ́run máa mú gbogbo èrò tó ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún wa kúrò. (Àìsáyà 65:17; Ìfihàn 21:4) Tá a bá ń rántí ìlérí yìí nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn, ó máa fún wa lókun.

Bíbélì Ran Jessica Lọ́wọ́

Mo Máa Ń Ní Ìdààmú Ọkàn Tó Lágbára

Jessica ṣí Bíbélì rẹ̀, ó gbé e sáyà, ó sì ti sùn lọ fọnfọn.

“Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), mo ní ìṣòro ọpọlọ kan tó mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìdààmú ọkàn tó lágbára. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ṣàdédé rántí àwọn nǹkan tí ò dáa tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi, èyí sì máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an. Àwọn dókítà sọ fún mi pé àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi ló jẹ́ kí n máa ní èrò òdì, ìyẹn ló sì fà á tí mo fi ní ìdààmú ọkàn. Kí n lè borí ìṣòro yìí, wọ́n ní kí n máa lo àwọn oògùn kan, kí n sì tún gba àwọn ìtọ́jú kan táá jẹ́ kí n mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro mi gangan.”

Bíbélì Ràn Mí Lọ́wọ́

“Tí ìdààmú ọkàn tó ń ṣe mí bá le gan-an, ó máa ń jẹ́ kí àyà mi ṣàdédé já, ọkàn mi ò ní balẹ̀, mi ò sì ní róorun sùn. Lọ́pọ̀ ìgbà lóru, oríṣiríṣi èrò ló máa ń wá sí mi lọ́pọlọ, tí kò sì ní jẹ́ kí ara mi balẹ̀. Bí Sáàmù 94:19 ṣe sọ, tí àníyàn bá bò wá mọ́lẹ̀, Ọlọ́run máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń tù wá lára. Torí náà, mo máa ń fi Bíbélì àti ìwé kan tí mo kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó ń tuni nínú sí sítòsí bẹ́ẹ̀dì mi. Tí mi ò bá róorun sùn, tí mo bá ti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa ń tù mí nínú.

“Bíbélì sọ pé ká má ṣe fàyè gba àwọn èrò tó ta ko ohun tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́lẹ̀, mo gbà pé mi ò wúlò fún nǹkan kan, kò sì sẹ́ni tó rí tèmi rò. Àmọ́ mo ti wá kẹ́kọ̀ọ́ pé irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ ò bá Bíbélì mu, torí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ Baba onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú, ó sì nífẹ̀ẹ́ gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Dípò kí n máa fàyè gba èrò òdì, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé e kúrò lọ́kàn. Ní báyìí, mo ti wá gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi. Ìyẹn ti mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú iyì wo ara mi.

“Inú mi máa ń dùn tí mo bá rántí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí mi ò ní máa ní èrò òdì mọ́, tí mi ò sì ní máa ro àròkàn. Mo mọ̀ pé láìpẹ́, kò ní sí àìlera ọpọlọ, ìyẹn ló ń jẹ́ kí n lè máa fara da ohun tó ń ṣe mí báyìí, kí n sì máa fayọ̀ retí ìgbà tí mi ò ní máa ní ìdààmú ọkàn mọ́.”

Tó O Bá Fẹ́ Mọ̀ Sí I:

Ka àpilẹ̀kọ náà, “Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìrẹ̀wẹ̀sì Ọkàn?” lórí jw.org.

Tẹ́tí sí ìwé Sáàmù lórí jw.org.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́