ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp19 No. 2 ojú ìwé 12-13
  • Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Pa Ara Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Pa Ara Rẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • IBO LO TI LÈ RÍ ÌRÀNLỌ́WỌ́?
  • ṢÉ ÌṢÒRO YÌÍ LÈ DÓPIN?
  • Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí Gbogbo Wa Yin Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ní Ìdààmú Ọkàn
    Jí!—2017
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ń Sorí Kọ́?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ṣé Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mó Bá Ń Ronú Àtipa Ara Mi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
wp19 No. 2 ojú ìwé 12-13
Obìnrin kan ṣí Bíbélì, ó gbé e dání, ó jókòó sídìí tábìlì, ó sì ń wo ọ̀ọ́kán

Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Pa Ara Rẹ

Adriana tó wá láti Brazil sọ pé: “Mo máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn ṣáá. Torí náà, mo pinnu pé á dáa kí n kúkú pa ara mi.”

ṢÉ ÌṢÒRO ti mu ẹ́ lómi rí débi tó o fi ronú pé ó sàn kó o kú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Adriana yé ẹ. Dókítà sọ fún Adriana pé ó ní àìsàn tó ń fa ìdààmú ọkàn tí kì í lọ bọ̀rọ̀. Èyí ló mú kí ayé sú u, ó sì dà bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan fún un.

Àpẹẹrẹ míì tún ni ti ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Japan kan tó ń jẹ́ Kaoru, tó ń tọ́jú àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n ń ṣàìsàn tí wọ́n sì ti darúgbó. Kaoru sọ pé: “Nígbà yẹn, wàhálà tí mò ń kojú níbi iṣẹ́ mú kí ayé sú mi. Oúnjẹ kì í wù mí jẹ, mi ò sì ń rí oorun sùn dáadáa. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ó sàn kí n kú.”

Ọmọ Nàìjíríà kan tó ń jẹ́ Ojebode sọ ní tiẹ̀ pé: “Inú mi máa ń bà jẹ́ débi pé màá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà láti pa ara mi.” Àmọ́ a dúpẹ́ pé Ojebode, Kaoru, àti Adriana kò pa ara wọn. Síbẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń gbẹ̀mí ara wọn lọ́dọọdún.

IBO LO TI LÈ RÍ ÌRÀNLỌ́WỌ́?

Ọkùnrin ló pọ̀ jù nínú àwọn tó máa ń pa ara wọn, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì jẹ́ pé ìtìjú ni kò jẹ́ kí wọ́n wá ìrànlọ́wọ́. Jésù sọ pé àwọn tó ń ṣàìsàn nílò oníṣègùn. (Lúùkù 5:31) Torí náà, tí ìdààmú ọkàn tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì bá mú kó o máa ronú láti pa ara rẹ, má ṣe jẹ́ kí ojú tì ẹ́ láti wá ìrànlọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìṣòrò ìdààmú ọkàn ti wá rí i pé àwọn lè rí ìtọ́jú nílé ìwòsàn tó máa jẹ́ kí ìlera àwọn sunwọ̀n sí i. Ohun tí Ojebode, Kaoru, àti Adriana ṣe nìyẹn, ìtọ́jú tí wọ́n gbà nílé ìwòsàn ló jẹ́ kí ìlera wọn sunwọ̀n sí i.

Àwọn dókítà lè fún ẹ ní oògùn, tàbí kí wọ́n sọ ohun tó máa ràn ẹ lọ́wọ́, wọ́n sì lè lo ọ̀nà méjéèjì. Àwọn tó ní irú ìsòro yìí nílò ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí tó máa jẹ́ alábàárò wọn, táá sì fìfẹ́ bójú tó wọn lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run ni ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ téèyàn lè ní, torí pé òun ló ń pèsè ìrànwọ́ tó dáa jù lọ nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

ṢÉ ÌṢÒRO YÌÍ LÈ DÓPIN?

Àwọn tó ní ìṣòro ìdààmú ọkàn sábà máa ń gba ìtọ́jú fún àkókò tó gùn, wọ́n sì ní láti ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn. Tí ìdààmú ọkàn bá ń bá ẹ fínra, fọkàn balẹ̀ ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Ó dá Ojebode lójú pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ẹ̀dùn ọkàn òun máa lọ pátápátá. Ó sọ pé: “Mò ń retí ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Àìsáyà 33:24 máa ṣẹ, èyí tó sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní sí ẹnì kankan lórí ilẹ̀ ayé tó máa sọ pé ‘ara mi ò yá.’” Bíi ti Ojebode, jẹ́ kí àwọn ìlérí Ọlọ́run tù ẹ́ nínú pé nínú “ayé tuntun,” kò ní sí “ìrora” mọ́. (Ìfihàn 21:1, 4) Ìlérí yẹn túmọ̀ sí pé kò ní sí ìrora, ìdààmú ọkàn àti ìrẹ̀wẹ̀sì mọ́. Gbogbo ẹ̀dùn ọkàn rẹ ló máa di ohun ìgbàgbé títí láé. Gbogbo ohun tó ń fa àròkàn fún ẹ báyìí máa di ohun àtijọ́, wọn ò ní wá sí ìrántí mọ́, wọn ò sì ní wá sí ọkàn rẹ.​—Àìsáyà 65:17.

Ìmọ̀ràn Tó Wúlò Láti Inú Bíbélì

Ọ̀rọ̀ rẹ yé Ọlọ́run.

‘Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú. Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’​—Àìsáyà 41:13.

Ọ̀rọ̀ rẹ yé Jèhófà ju ẹnikẹ́ni lọ, ó sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Máa ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

“[Èlíjà] béèrè pé kí òun kú. Ó sọ pé: ‘ . . . Jèhófà, gba ẹ̀mí mi.’”​—1 Àwọn Ọba 19:4.

Ojebode sọ pé: “Mo máa ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Ó jẹ́ kí n rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà náà.”

Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì.

“Mo [Jésù] ti bá [ọ] (Pétérù) bẹ̀bẹ̀, kí ìgbàgbọ́ [rẹ] má bàa yẹ̀.”​—Lúùkù 22:32.

Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù sẹ́ Jésù nígbà mẹ́ta, ìdààmú ọkàn bá Pétérù gidigidi, ó sì sunkún kíkorò. Kaoru sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ Pétérù, wọ́n sì lóye ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Èyí fún èmi náà lókun.”

Gbogbo ohun tó ń fa àròkàn fún ẹ báyìí máa di ohun àtijọ́, ‘wọn ò ní wá sí ìrántí mọ́, wọn ò sì ní wá sí ọkàn rẹ.’​—Àìsáyà 65:17

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́