ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp19 No. 2 ojú ìwé 10-11
  • Tí Àìsàn Burúkú Bá Ń Ṣe Ẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tí Àìsàn Burúkú Bá Ń Ṣe Ẹ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ RAN ÀWỌN KAN LỌ́WỌ́
  • Àìsàn Bára Kú—Àníyàn Ló Jẹ́ fún Ìdílé
    Jí!—2000
  • Báwo Lo Ṣe Lè Fara Da—Àmódi Tí Ń Ṣe Ọ́?
    Jí!—2001
  • Bí Àwọn Ìdílé Ṣe Lè Kojú Ìṣòro Àìsàn Bára Kú
    Jí!—2000
  • Èé Ṣe Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
wp19 No. 2 ojú ìwé 10-11

Tí Àìsàn Burúkú Bá Ń Ṣe Ẹ́

“Nígbà tí dókítà sọ fún mi pé mo ní àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀fóró àti àrùn jẹjẹrẹ inú ìfun, ṣe ló dà bíi pé wọ́n ti dá ọjọ́ ikú fún mi. Àmọ́, nígbà tí mo délé, mo sọ fún ara mi pé, ‘mi ò mọ̀ pé bó ṣe máa rí rèé, àmọ́ mo gbọ́dọ̀ fara dà á.’”​—Linda, ẹni ọdún 71.

“Mo ní àìsàn kan tó máa ń jẹ́ kí iṣan tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ojú òsì mi máa ro mí goorogo. Nígbà míì, ìrora yẹn máa ń pọ̀ débi pé ó máa ń mú kí n soríkọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń gbà pé kò sẹ́ni tó rí tèmi rò, màá sì máa ronú láti pa ara mi.”​—Elise, ẹni ọdún 49.

Àwọn èèyàn dúró ti ọkùnrin aláìsàn kan tó wà lórí kẹ̀kẹ́ arọ

ÌBÀNÚJẸ́ ńláǹlà ló máa ń jẹ́ tí dókítà bá sọ pé ìwọ tàbí ẹnì kan tó o fẹ́ràn ní àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí kan. Yàtọ̀ sí pé onítọ̀hún á máa jẹ ìrora àìsàn, á tún máa ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára. Ohun míì tó tún máa ń dá kún ìbẹ̀rù àti àníyàn aláìsàn náà ni bó ṣe ń pààrà ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú, àgàgà tí àwọn dókítà bá lọ dá a dúró sílé ìwòsàn, tàbí tó bá ṣòro láti rí oògùn rà, tàbí tí oògùn tó ń lò bá ń ṣiṣẹ́ gbòdì lára rẹ̀. Ká sòóótọ́, ìdààmú ọkàn tí àìsàn burúkú máa ń fà máa ń tánni lókun.

Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́? Ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé ohun tó tu àwọn nínú jù lọ ni pé àwọn máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, àwọn sì máa ń ka ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì. Bákan náà, ó máa ń tuni nínú gan-an tí tẹbí-tọ̀rẹ́ bá fìfẹ́ hàn tí wọ́n sì dúró tini.

OHUN TÓ RAN ÀWỌN KAN LỌ́WỌ́

Robert tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta (58) sọ pé: “Tó o bá nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àìsàn rẹ. Gbàdúrà sí Jèhófà. Sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún un. Bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Sọ fún un pé kó fún ẹ lágbára tí wàá fi fara da àìsàn náà, kó o sì lè ṣe ohun tó máa fún ìdílé rẹ lókun.”

Robert sọ pé: “Ó máa ń dáa gan-an tí ìdílé ẹni bá dúró tini, tí wọ́n sì jẹ́ alábàárò gidi. Lójoojúmọ́, àwọn mọ̀lẹ́bí mi máa ń pè mí láti béèrè nípa ìlera mi. Àwọn ọ̀rẹ́ mi náà ò pa mí tì, wọ́n máa ń fún mi ní ìṣírí. Ìyẹn ti jẹ́ kí n lè máa fara dà á nìṣó.”

Tó o bá ní ọ̀rẹ́ kan tó ń ṣàìsàn, ọ̀rọ̀ tí Linda sọ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó ní: “Ó lè wu onítọ̀hún láti ṣara gírí, kó má sì fẹ́ máa fìgbà gbogbo sọ̀rọ̀ nípa àìlera rẹ̀. Torí náà àwọn ohun tẹ́ ẹ ti jọ máa ń sọ tẹ́lẹ̀ ni kẹ́ ẹ máa sọ.”

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́ àti àdúrótì tẹbí-tọ̀rẹ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ayé rẹ ṣì máa dùn, kódà tó o bá ń ṣàìsàn tó lágbára gan-an.

Ìmọ̀ràn Tó Wúlò Láti Inú Bíbélì

Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.

“Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn. Ó gbà mí sílẹ̀ nínú gbogbo ohun tó ń bà mí lẹ́rù. Aláìní yìí pe Jèhófà, ó sì gbọ́.”​—Sáàmù 34:4, 6.

Linda tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mi ò kí ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí ara mi yá. Ṣe ni mò ń bẹ̀ ẹ́ nígbà gbogbo pé kó fún mi lókun kí n lè fara da àìsàn náà.”

Jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ẹ lókun.

“Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá’”​—Àìsáyà 33:24.

Máa ronú nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, èyí á jẹ́ kó o lè ní okun láti máa fara dà á nìṣó.

Jẹ́ kí tẹbí-tọ̀rẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.

“Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

Elise tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Má ṣe máa dá nìkan wà ṣáá, jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Láwọn ìgbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sẹ́ni tó rí tìẹ rò tàbí pé Ọlọ́run kò ráyè tìẹ, àmọ́ má ṣe ya ara rẹ sọ́tọ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́