ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 2/1 ojú ìwé 3
  • Aráyé Fẹ́ Mọ Ìdáhùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aráyé Fẹ́ Mọ Ìdáhùn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òbí
    Jí!—2019
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
    Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?
  • Ṣé O Ti Béèrè Àwọn Ìbéèrè Yìí Rí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
  • Àwọn Èèyàn Ń Wá Ìdáhùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 2/1 ojú ìwé 3

Aráyé Fẹ́ Mọ Ìdáhùn

“Ní báyìí tọ́mọ aráyé ti jágbọ́n oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n lè máa gbà gbọ́ bùkátà wọn, tí wọ́n ti láwọn ohun amáyédẹrùn téèyàn ò tiẹ̀ lálàá ẹ̀ rí pó ṣeé ṣe, irú bí ẹ̀rọ amúlétutù àti onírúurú ẹ̀rọ amìjìnjìn ìgbàlódé, tí wọ́n sì tún ti jágbọ́n báwọn ṣe lè máa rí àwọn èso kan jẹ yí po ọdún, ohun tó kù tá a wá ń rò ni ìdí tá a fi wà láàyè. Kí nìdí gbogbo kìràkìtà ọmọ aráyé? Kí ni wọ́n ń ṣe gbogbo ìyẹn fún?”—David G. Myers, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ìrònú àti ìhùwàsí ẹ̀dá tó wà ní ilé ìwé Hope College, Holland, Michigan, nílẹ̀ Amẹ́ríkà.

KÍ NI ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè ọ̀jọ̀gbọ́n yìí? Àwọn kan lè sọ pé kò sídìí láti máa fàkókò ṣòfò lórí pé à ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yẹn. Àmọ́ tá a bá ní ká pa ìbéèrè yìí tì, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tẹ́nì kan mọ̀ọ́mọ̀ fi òkúta tó kó sínú bàtà rẹ̀ bó ṣe ń rìn lọ sílẹ̀ tí kò yọ ọ́. Onítọ̀hún lè máa lọ o, àmọ́ kò ní gbádùn ìrìn rẹ̀.

Tó o bá ń ronú nípa ìdí tí Ọlọ́run fi dá èèyàn, mọ̀ pé ìwọ nìkan kọ́ lò ń rò ó. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tó tíì gbòòrò jù nípa ìhùwàsí ọmọ èèyàn lágbàáyé, ìyẹn World Values Survey, ṣe fi hàn, àwọn èèyàn tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ń ṣe kàyéfì nípa “ìdí tá a fi wà láàyè àti ìtumọ̀ ìgbésí ayé.”

Kéèyàn tó lè ní ojúlówó ìbàlẹ̀ ọkàn, èèyàn ní láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta yìí:

Ibo lèèyàn ti wá?

Kí nìdí tá a fi wà láàyè?

Kí ni ká máa retí lọ́jọ́ ọ̀la?

Ibo lo ti lè rí ìdáhùn tó tẹ́rùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì yìí? Wàá rí ìdáhùn tí kì í ṣe ìméfò tàbí èrò èèyàn lásán nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, torí pé inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwọn ìdáhùn yẹn ti wá. A rọ̀ ọ́ pé kó o máa wo inú Bíbélì tìrẹ, kó o lè fúnra rẹ rí ohun tó sọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́