ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 7/1 ojú ìwé 4-9
  • Bó O Ṣe Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Túmọ̀ sí Láti Ní Ẹ̀dùn Ọkàn?
  • Bá A Ṣe Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run
  • Ìrètí Àjíǹde
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbé Pẹ̀lú Ẹ̀dùn-Ọkàn Mi?
    Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • ‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ìrànlọ́wọ́ Fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀
    Jí!—2018
  • Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀
    Jí!—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 7/1 ojú ìwé 4-9

Bó O Ṣe Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà

“Gbogbo awọn ọmọ [Jékọ́bù] ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ obinrin dide lati ṣìpẹ̀ fun un; ṣugbọn o kọ lati gbìpẹ̀; o si wi pe, ‘Ninu ọ̀fọ̀ ni emi o sa sọkalẹ tọ ọmọ mi lọ si isà-okú.’ Bayìí ni baba rẹ̀ sọkun rẹ̀.”—JẸ́NẸ́SÍSÌ 37:35, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

JÉKỌ́BÙ tó jẹ́ baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọkàn jẹ́ gan-an nígbà tó gbọ́ ìròyìn pé ọmọ rẹ̀ kú. Ó ti gbà pé inú ọ̀fọ̀ yẹn lòun máa kú sí. Bíi ti Jékọ́bù, téèyàn tìrẹ náà bá kú, o lè rò pé ìbànújẹ́ yẹn pọ̀ gan-an débi pé kò ní tán lọ́kàn rẹ. Ṣé téèyàn bá fàyè gba ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára tó bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé onítọ̀hún ò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ni? Rárá o!

Ohun tí Bíbélì sọ nípa Jékọ́bù fi hàn pé ó jẹ́ ẹnì kan tó nígbàgbọ́. Bíbélì sọ̀rọ̀ tó wúni lórí nípa ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí òun àti Ísákì bàbá rẹ̀ àti Ábúráhámù bàbá bàbá rẹ̀ ní. (Hébérù 11:8, 9, 13) Kódà, ìgbà kan wà tó fi gbogbo òru bá áńgẹ́lì kan wọ̀yá ìjà kó bàa lè gba ìbùkún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! (Jẹ́nẹ́sísì 32:24-30) Ó dájú pé Jékọ́bù jẹ́ ẹni tó ní àjọṣe tó lágbára pẹ̀lú Jèhófà. Kí wá la lè rí kọ́ látinú bí Jékọ́bù ṣe bọkàn jẹ́? Ẹ̀kọ́ náà ni pé téèyàn bá nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run, ìyẹn kò fi hàn pé kò lè ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ tó pọ̀ gan-an nígbà tí èèyàn rẹ̀ kan bá kú. Kò burú kí ẹni téèyàn rẹ̀ tó fẹ́ràn bá kú ní ẹ̀dùn ọkàn.

Kí Ló Túmọ̀ sí Láti Ní Ẹ̀dùn Ọkàn?

Ohun tó máa ń ṣe olúkúlùkù nígbà tó bá ní ẹ̀dùn ọkàn torí èèyàn rẹ̀ tó kú máa ń yàtọ̀ síra. Àmọ́ èyí tó lágbára jù nínú ohun tó lè bá ọ̀pọ̀ èèyàn lákòókò yẹn ni ìbànújẹ́ tó pọ̀ gan-an. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Leonardo. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni nígbà tí àrùn ọkàn pa bàbá rẹ̀. Leonardo ò ní gbàgbé ọjọ́ tí àbúrò ìyá rẹ̀ túfọ̀ fún un. Kò kọ́kọ́ gbà pé òótọ́ ni obìnrin yẹn ń sọ. Àní nígbà tó rí òkú bàbá rẹ̀ lọ́jọ́ tí wọ́n ń sin ín, kò tún tíì gbà pé bàbá òun ti kú. Fún odindi oṣù mẹ́fà, Leonardo kò lè sunkún. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń rí i pé òun ń retí pé kí bàbá òun ti ibi iṣẹ́ dé. Odindi ọdún kan kọjá kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé e dáadáa pé òun ò ní bàbá mọ́. Nígbà tó wá gbà wàyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára pé òun àti etí òun ló kù. Àwọn ohun tí ò tó nǹkan, bíi kó délé kó má bá ẹnì kankan nínú ilé, máa ń mú kó rántí pé bàbá òun ò sí mọ́. Nírú àwọn àkókò yẹn, ṣe ló máa ń bú sẹ́kún gbẹ̀ẹ́. Ó mà ṣe fọ́mọ tí kò ní bàbá mọ́ o!

Ohun tó ṣe Leonardo jẹ́ ká rí bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe máa ń lágbára tó nígbà tí èèyàn ẹni bá kú. A dúpẹ́ pé ó ṣeé ṣe láti borí ẹ̀dùn ọkàn yẹn, ó kàn jẹ́ pé ó lè gba àkókò díẹ̀ ni. Téèyàn bá ní ọgbẹ́ tí ojú ẹ̀ jìn, ó máa gba àkókò tó pọ̀ kó tó jinná, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa ń gba àkókò tó pọ̀ kí èèyàn tó lè gbọnra nù tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹ̀ ẹ́. Ó lè gba ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún mélòó kan tàbí kó tiẹ̀ pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá kí èèyàn tó lè gbé e kúrò lára. Àmọ́ bí ìbànújẹ́ ṣe lágbára tó níbẹ̀rẹ̀ kọ́ láá máa rí lọ. Tó bá yá ó máa dín kù, ìgbésí ayé olúwarẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí í nítumọ̀, á sì máa gbádùn mọ́ ọn.

Wọ́n tiẹ̀ sọ pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn má ṣe gbìyànjú láti bo ẹ̀dùn ọkàn tó bá ní mọ́ra tó bá fẹ́ kí ọkàn òun tètè balẹ̀, kó sì lè máa bá ìgbésí ayé ẹ̀ lọ nínú ipò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bá ara rẹ̀. Àyè odindi èèyàn kan ló ṣáà ti ṣófo báyìí. A gbọ́dọ̀ gbà pé ẹni tó ti kú ti kú, ká sì mọ bá a ó ṣe máa bá ìgbésí ayé wa lọ. Téèyàn ò bá bo ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ mọ́ra, ó ṣeé ṣe kó lè sọ bóhun tó ṣẹlẹ̀ náà ṣe dùn ún tó. Ó yẹ ká mọ̀ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni bí kálukú ṣe máa ń ṣe nígbà tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹ̀ ẹ́. Àmọ́ òótọ́ kan rèé: Téèyàn bá ń bo ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ mọ́ra, ó lè fa nǹkan míì sí i lára, ó lè ṣàkóbá fún ìrònú àti ọpọlọ rẹ̀, ó tiẹ̀ lè dá àìsàn sí i lára pàápàá. Àwọn ọ̀nà wo wá lo lè gbà fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn tí kò ní pa ọ́ lára? Bíbélì fúnni láwọn ìmọ̀ràn pàtàkì kan.a

Bá A Ṣe Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà

Ọ̀pọ̀ àwọn tó pàdánù èèyàn wọn ti rí i pé táwọn bá ń sọ̀rọ̀, ó máa ran àwọn lọ́wọ́ láti tètè túra ká. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ohun tí Jóòbù tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ sọ lẹ́yìn tí ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kú mọ́ ọn lójú táwọn àjálù míì sì tún dé bá a. Ó sọ pé: “Dájúdájú, ọkàn mi kórìíra ìgbésí ayé mi tẹ̀gbintẹ̀gbin. Èmi yóò tú ìdàníyàn nípa ara mi jáde. Èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú ìkorò ọkàn mi!” (Jóòbù 1:2, 18, 19; 10:1) Kíyè sí i pé Jóòbù ní láti “tú ìdàníyàn” rẹ̀ jáde. Báwo ló ṣe sọ pé òun máa ṣe é? Ó ṣàlàyé pé, “Èmi yóò sọ̀rọ̀.”

Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Paulo tí ìyá rẹ̀ kú sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó ràn mí lọ́wọ́ ni bí mo ṣe máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìyá mi.” Torí náà, tó o bá ń sọ bó ṣe ń ṣe ọ́ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o fọkàn tán, ara lè tù ọ́ díẹ̀. (Òwe 17:17) Lẹ́yìn tí ìyá arábìnrin kan tó ń jẹ́ Yone kú, ó sọ fáwọn ará pé kí wọ́n máa wá sọ́dọ̀ òun lemọ́lemọ́ ju bí wọ́n ṣe ń wá tẹ́lẹ̀ lọ. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń rẹ́ni bá sọ̀rọ̀ yẹn ń jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn mi máa dín kù.” Ó ṣeé ṣe kíwọ náà rí i pé tó o bá ń sọ bó ṣe ń ṣe ọ́ fáwọn èèyàn tó ṣe tán láti tẹ́tí sí ọ, á túbọ̀ rọrùn fún ọ láti borí ẹ̀dùn ọkàn.

Ṣíṣàkọsílẹ̀ ìmọ̀lára èèyàn tún lè jẹ́ kí èèyàn tètè túra ká. Àwọn tó ṣòro fún láti sọ bó ṣe ń ṣe wọ́n lè rí i pé ó rọrùn fáwọn láti kọ ọ́ sílẹ̀. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì kú, Dáfídì adúróṣinṣin ṣàkọsílẹ̀ orin arò kan tó fi sọ bí ìbànújẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tó. Ohun tó kọ sílẹ̀ lákòókò yẹn padà wá di ara ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì, a óò rí i nínú ìwé Sámúẹ́lì Kejì.—2 Sámúẹ́lì 1:17–27.

Sísunkún pẹ̀lú lè mú kéèyàn tètè túra ká. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní . . . ìgbà sísunkún.” (Oníwàásù 3:1, 4) Ó dájú pé ìgbà téèyàn wa kan bá kú ni “ìgbà sísunkún.” Kò yẹ kó ti èèyàn lójú pé ó ń sunkún nígbà téèyàn rẹ̀ kú. A rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn èèyàn adúróṣinṣin lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n sunkún ní gbangba láti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn. (Jẹ́nẹ́sísì 23:2; 2 Sámúẹ́lì 1:11, 12) Jésù Kristi “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé” nígbà tó sún mọ́ ibojì Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú.—Jòhánù 11:33, 35.

Ó gba sùúrù kéèyàn tó lè borí ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ tán pátápátá torí pé nígbà míì, ó lè máa ṣe èèyàn bíi pé bí ìbànújẹ́ yẹn ṣe ń lọ lọ́kàn èèyàn ló tún ń padà wá. Rántí pé kò yẹ kójú máa tì ọ́ torí pé ò ń da omijé lójú. Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ èèyàn ló ti rí i pé ara ohun tó dáa kẹ́ni tó bá ní ẹ̀dùn ọkàn ṣe ni pé kó da omijé lójú, ó sì wà lára ohun tó máa jẹ́ kó tètè borí rẹ̀.

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Ọ̀nà pàtàkì kan téèyàn lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run ni nípasẹ̀ àdúrà. Má fojú kéré àdúrà o! Bíbélì ṣe ìlérí tó ń fúnni ní ìtùnú yìí pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:18) Ó tún sọ̀rọ̀ ìdánilójú yìí fún wa pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Ronú lórí èyí ná. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ọ́ lẹ́ẹ̀kan, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé, ó ṣàǹfààní fáwọn láti sọ bó ṣe ń ṣe àwọn fún ọ̀rẹ́ kan táwọn lè fọkàn tán. Ṣé kò wá ní ṣe wá láǹfààní jù bẹ́ẹ̀ lọ tá a bá sọ bó ṣe ń ṣe wá fún Ọlọ́run tó ti ṣèlérí fún wa pé òun á tu ọkàn wa nínú?—2 Tẹsalóníkà 2:16, 17.

Paulo tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí mo bá rí i pé ìbànújẹ́ yìí pọ̀ kọjá ohun tí mo lè fara dà, tí mo sì rí i pé ó ṣòro fún mi láti gbé e kúrò lọ́kàn, mo máa ń wólẹ̀ láti gbàdúrà sí Ọlọ́run. Mo máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́.” Ó dá Paulo lójú pé àdúrà tóun gbà ran òun lọ́wọ́. Ìwọ náà lè rí i pé tó o bá ń fi bó ṣe ń ṣe ọ́ báyìí sínú àdúrà lemọ́lemọ́, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” á fún ọ nígboyà àti okun láti fara dà á.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Róòmù 12:12.

Ìrètí Àjíǹde

Jésù sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” (Jòhánù 11:25) Bíbélì fi kọ́ni pé àwọn òkú ṣì máa padà wà láàyè.b Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun lágbára láti jí òkú dìde. Ìgbà kan wà tó jí ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá dìde. Báwo làwọn òbí ọmọbìnrin yẹn ṣe ṣe nígbà yẹn? “Wọn kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.” (Máàkù 5:42) Lábẹ́ Ìjọba Jésù Kristi Ọba ọ̀run, yóò jí àìmọye òkú dídè sórí ilẹ̀ ayé, àmọ́ ayé kan tí àlàáfíà àti òdodo ti gbilẹ̀ ni o. (Ìṣe 24:15; 2 Pétérù 3:13) Wo bí ayọ̀ yẹn á ti pọ̀ tó nígbà táwọn òkú bá padà jí dìde sáyé tí wọ́n sì padà wá bá àwọn èèyàn wọn!

Claudete tí ọmọ rẹ̀ kú nínú jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú, gbé fọ́tò Renato ọmọ rẹ̀ sórí fìríìjì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń wo fọ́tò yẹn táá sì máa dá sọ̀rọ̀ pé, ‘A óò tún pàdé nígbà àjíǹde.’ Leonardo máa ń fojú inú wo ọjọ́ tí bàbá rẹ̀ máa padà wá sí ìyè nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Ká sòótọ́, ìrètí àjíǹde jẹ́ orísun kan táwọn wọ̀nyí àti àìmọye àwọn míì téèyàn wọn ti kú ti ń rí ìtùnú gbà. Ìrètí yìí lè tu ìwọ náà nínú!

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìjíròrò nípa báwọn ọmọdé ṣe lè borí ẹ̀dùn ọkàn ti ikú fà fún wọn wà nínú àpilẹ̀kọ náà “Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kó Lè Borí Ẹdùn Ọkàn Tí Ikú Fà,” tó wà lójú ewé 18 sí 20 nínú ìwé ìròyìn yìí.

b Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí ìrètí àjíǹde, wo orí keje nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”

“Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́ríńtì 1:3.

Ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé Ọlọ́run lè ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fara da ìṣòro èyíkéyìí tí wọ́n bá dojú kọ. Ọ̀nà kan tí Jèhófà lè gbà fún wa ní ìtùnú ni nípasẹ̀ ọ̀rẹ́ wa kan tàbí ẹnì kan tá a jọ ń sin Ọlọ́run.

Leonardo tí bàbá ẹ̀ kú rántí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó fún un lókun àti ìtùnú. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé ni lọ́jọ́ yẹn, bó ṣe rántí pé kò séèyàn kankan nínú ilé báyìí, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í wa ẹkún mu. Ó lọ sí ibi ìgbafẹ́ kan tó wà nítòsí, ó jókòó sórí bẹ́ǹṣì kan níbẹ̀, ó tún ń bá ẹkùn rẹ̀ lọ. Bó ṣe ń sunkún lọ́wọ́, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́. Òjijì ni ọkọ̀ akẹ́rù kan dédé dúró nítòsí ibi tó wà. Leonardo dá awakọ̀ yẹn mọ̀ pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin òun. Arákùnrin yẹn ń fi mọ́tò já ẹrù kiri ni kó tó ṣìnà débẹ̀. Bí arákùnrin yẹn ṣe dúró ti Leonardo lásán ti tó láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún.

Ìgbà kan wà tí arákùnrin kan tí ìyàwó rẹ̀ ti kú nímọ̀lára pé òun dá nìkan wà, èyí sì da ọkàn rẹ̀ láàmú gan-an ni. Kò yé sunkún torí pé ó dà bíi pé kò sírètí fún un mọ́. Ló bá bẹ Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́. Bó ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, ẹ̀rọ tẹlifóònù rẹ̀ dún. Ọmọ ọmọ rẹ̀ ló tẹ̀ ẹ́ láago. Bàbá yẹn sọ pé: “Ìwọ̀nba ìjíròrò ráńpẹ́ tá a ní yẹn túbọ̀ fún mi nígboyà. Mo lè sọ pé ìpè ọmọbìnrin yẹn ni ìdáhùn àdúrà tí mo gbà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

Bí Wọ́n Ṣe Ń Tu Àwọn Míì Nínú

“[Ọlọ́run] ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa, kí àwa lè tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.”—2 Kọ́ríńtì 1:4.

Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tòótọ́ ló ti nírìírí ohun tí gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí. Lẹ́yìn táwọn fúnra wọn ti rí ìtùnú gbà tí wọ́n fi lè fara da ikú èèyàn wọn, wọ́n lọ fáwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí àti ìtùnú.

Wo àpẹẹrẹ Claudete tó máa ń lọ fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn lóhun tó gbà gbọ́. Kó tó di pé ọmọ rẹ̀ kú, ó máa ń lọ sọ́dọ̀ obìnrin kan tí àrùn sẹ̀jẹ̀ domi pa ọmọ rẹ̀. Obìnrin yẹn máa ń gbádùn ìbẹ̀wò rẹ̀, àmọ́ ó gbà pé Claudete ò lè mọ bóhun tó ṣẹlẹ̀ sóun yìí ṣe ń dun òun tó. Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn ni ọmọ Claudete náà kú, ni obìnrin yẹn bá lọ kí i, ó wá sọ fún arábìnrin Claudete pé òun fẹ́ mọ̀ bóyá ó ṣì gba Ọlọ́run gbọ́ tó bó ṣe gbà á gbọ́ tẹ́lẹ̀ nísinsìnyí tí ọmọ rẹ̀ ti kú. Ó jọ ọ́ lójú bí ìgbàgbọ́ Claudete ṣì ṣe lágbára síbẹ̀. Bó ṣe gbà kí Claudete bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nìyẹn, ó sì ń rí ìtùnú tó pọ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Lẹ́yìn tí bàbá Leonardo kú, Leonardo lọ kọ́ èdè àwọn adití kó bàa lè máa fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tu àwọn adití nínú. Ó wá rí i pé ìsapá òun láti ran àwọn adití lọ́wọ́ ti ṣe òun láǹfààní púpọ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun tó jẹ́ kí n lè borí ẹ̀dùn ọkàn mi ni bí mo ṣe fẹ́ láti ran àwọn adití lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Mo ti lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun ara mi láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìbànújẹ́ mi wá dayọ̀ nígbà tí mo rí ẹni àkọ́kọ́ tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ṣèrìbọmi! Àní sẹ́, ìgbà àkọ́kọ́ rèé lẹ́yìn ikú bàbá mi tí ayọ̀ tòótọ́ wọnú ọkàn mi.”—Ìṣe 20:35.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Sísọ bó ṣe ń ṣe ọ́ lè tù ọ́ lára díẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ṣíṣàkọsílẹ̀ bí ẹ̀dùn ọkàn rẹ ṣe rí lè ràn ọ́ lọ́wọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Kíkà nípa àjíǹde lè jẹ́ orísun ìtùnú tòótọ́ fún ọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Jésù ṣèlérí pé òun á jí àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú òun dìde

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́