ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 7/1 ojú ìwé 30
  • Ǹjẹ́ ó Dára Kéèyàn Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ ó Dára Kéèyàn Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run àti Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lò Ó
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
  • Ó Ha Lòdì Láti Máa Pe Orúkọ Ọlọ́run Bí?
    Jí!—1999
  • A4 Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 7/1 ojú ìwé 30

Ǹjẹ́ ó Dára Kéèyàn Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?

NÍNÚ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, táwọn èèyàn ń pè ní “Májẹ̀mú Láéláé,” orúkọ Ọlọ́run fara hàn ní nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000]. Lẹ́tà Hébérù ni wọ́n fi kọ ọ́, bí wọ́n sì ṣe kọ ọ́ rèé ‏) יהוהláti ọwọ́ ọ̀tún sí òsì(‏.‏ Ohun tá à ń sọ ni pé,‏ lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run ni Yohdh, He, Waw, àti He, tí wọ́n sábà máa ń kọ báyìí: YHWH.

Láyé ọjọ́un, àwọn Júù ní ìgbàgbọ́ asán kan pé kò dáa kéèyàn máa lo orúkọ Ọlọ́run. Nítorí èyí, wọn kì í pe orúkọ Ọlọ́run, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ọ̀rọ̀ míì láti fi rọ́pò orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìwé wọn. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn atúmọ̀ Bíbélì ti túmọ̀ orúkọ náà sí “Yáwè,” tàbí “Jèhófà.” Lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ ni Jerusalem Bible ti àwọn Kátólíìkì. Ìtumọ̀ Bíbélì yìí sọ pé, nígbà tí Mósè béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kí ni kóun sọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá béèrè pé ta ló rán òun sí wọn, Ọlọ́run fèsì pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Yáwè, Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù ló rán mi sí i yín.’ Èyí ni Orúkọ mi títí láé; èyí ni orúkọ tí ẹ ó fi mọ̀ mi láti ìran dé ìran.”—Ẹ́kísódù 3:15, JB.

Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà, ó sọ nípa bí òun ṣe lo orúkọ Ọlọ́run, ó ní: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, èmi yóò sì máa báa nìṣó ní jíjẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n.” Bákan náà, nínú àdúrà kan tí Jésù gbà, tí wọ́n máa ń pè ní Àdúrà Olúwa, Jésù sọ pé: “Baba wa ti mbẹ lí ọ̀run; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ.”—Jòhánù 17:26, JB; Mát. 6:9, Bíbélì Mímọ́.

Ó lè wá yani lẹ́nu pé nígbà tí Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún ń sọ̀rọ̀ nípa lílo orúkọ Ọlọ́run, nínú ìwé kan tó kọ nípa Jésù lẹ́nu àìpẹ́ yìí, tó pe àkọlé rẹ̀ ní Jesus of Nazareth, ó ní: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tọ̀nà dáadáa pẹ̀lú bí wọn kò ṣe ń pe orúkọ tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń jẹ́, tí wọ́n sì wá ń lo ọ̀rọ̀ náà YHWH, kí wọ́n má bàa rẹ orúkọ náà wálẹ̀ bíi tàwọn òrìṣà táwọn abọ̀rìṣà ń jọ́sìn. Bákan náà, kò dáa rárá bí àwọn tó túmọ̀ Bíbélì lẹ́nu àìpẹ́ yìí ṣe ṣàkọsílẹ̀ orúkọ Ọlọ́run, àfi bíi pé orúkọ àtijọ́ kan lásán ni. Orúkọ tó jẹ́ pé àdììtú làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kà á sí tí wọ́n sì wò ó gẹ́gẹ́ bí orúkọ tí kò yẹ kéèyàn máa pè rárá.”

Kí lèrò tìẹ? Ǹjẹ́ ó dáa kéèyàn máa lo orúkọ Ọlọ́run àbí kò dáa? Níwọ̀n bí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ pé: “Èyí ni Orúkọ mi títí láé; èyí ni orúkọ tí ẹ ó fi mọ̀ mí láti ìran dé ìran,” ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ohun tí Ọlọ́run sọ yẹn kò tọ̀nà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Jésù lo orúkọ Ọlọ́run nínú àdúrà rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́