ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 10/1 ojú ìwé 15
  • Ṣé Ẹni Gidi Ni Èṣù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ẹni Gidi Ni Èṣù?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sátánì
    Jí!—2013
  • Ta Ni Sátánì? Ṣó Wà Lóòótọ́?
    Jí!—2007
  • Ṣé Àmì Tó Ń Ṣàpẹẹrẹ Nǹkan Búburú ni Sátánì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ṣọ́ra! Sátánì Fẹ́ Pa Ọ́ Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 10/1 ojú ìwé 15

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣé Ẹni Gidi Ni Èṣù?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni gidi ni Sátánì Èṣù. Àmọ́ àwọn tó ń ta ko Bíbélì kò gbà pé Èṣù jẹ́ ẹni gidi. Ohun tí wọ́n ń sọ ni pé èrò ibi tó ń gbénú àwa èèyàn ni Sátánì.

Ṣó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn èèyàn kò mọ irú ẹni tí Sátánì jẹ́ níti gidi? Kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ: Adigunjalè kan lè fi nǹkan bojú níbi tó ti lọ jalè kí àwọn èèyàn má bàa dá a mọ̀, á sì tipa bẹ́ẹ̀ máa bá iṣẹ́ ibi rẹ̀ lọ láìsí pé ọwọ́ tẹ̀ ẹ́. Bákan náà, olórí àwọn oníwàkiwà ni Sátánì, ọ̀nà tí àwọn èèyàn kò fura sí ló sì ń gbà ti ìwà ibi lẹ́yìn. Kedere ni Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì ló jẹ́ kí nǹkan dojúrú fún àwọn èèyàn nínú ayé. Jésù pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé yìí.”—Jòhánù 12:31.

Níbo ni Èṣù ti wá? Ẹ̀dá ẹ̀mí pípé ni Ọlọ́run dá a, ọ̀run ló sì ń gbé tẹ́lẹ̀, àmọ́ áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí sọ ara rẹ̀ di Èṣù nígbà tó fàyè gba èrò òdì lọ́kàn ara rẹ̀, ìyẹn ni pé ó fẹ́ kí àwa èèyàn máa jọ́sìn òun dípò Ọlọ́run. Bíbélì ṣàkọsílẹ̀ ìjíròrò kan tó wáyé lákòókò kan láàárín Jésù àti Sátánì lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn sì túbọ̀ jẹ́ ká mọ èrò búburú tó wà lọ́kàn Èṣù. Sátánì fẹ́ kí Jésù ‘wólẹ̀, kó sì jọ́sìn òun.’—Mátíù 4:8, 9.

Bákan náà, Sátánì tún jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ nígbà tó ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Jóòbù. Ó sì ti pinnu pé ohun tó bá gbà ni òun máa fún un láti jẹ́ kí àwọn èèyàn kẹ̀yìn sí Ọlọ́run.—Jóòbù 1:13-19; 2:7, 8.

Gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò: Bí Sátánì bá bá Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi sọ̀rọ̀, báwo ló ṣe máa wá jẹ́ èrò ibi tó kàn máa ń wà lọ́kàn ẹni? Ó dájú pé kò sí èrò ibi lọ́kàn Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀! Èyí fi hàn nígbà náà pé ẹni gidi ni Sátánì, ìyẹn ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tàbí Jésù.

Ìwà ìbàjẹ́ àwọn èèyàn tún jẹ́rìí sí i pé ẹni gidi ni Èṣù lóòótọ́. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nínú ayé ló máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ bàjẹ́ nígbà tó sì jẹ́ pé ebi ń pa àwọn èèyàn wọn. Wọ́n tún ń tọ́jú àwọn ohun ìjà runlérùnnà tó lè pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn run lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n ń ba afẹ́fẹ́, omi àti ilẹ̀ jẹ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ni kò mọ ẹni tó jẹ́ orísun ìwà ìkórìíra àti ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Kí nìdí?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì “ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Sátánì gbé ètò kan tí kò ṣeé fojú rí kalẹ̀ láti máa darí àwọn èèyàn. Òun ni “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Mátíù 12:24) Bí olórí ẹgbẹ́ ọ̀daràn kan ṣe lè máa darí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ láìjẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tí òun jẹ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Sátánì ṣe ń lo àwùjọ àwọn áńgẹ́lì búburú tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ láti máa darí ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò mọ ipa burúkú tí Èṣù ń kó nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn.

A mà dúpẹ́ o pé Bíbélì ṣàlàyé irú ẹni tí Èṣù jẹ́ fún wa, ó sì túdìí àṣírí ètò tó ń lò! Èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti kọjú ìjà sí àwọn ètekéte Èṣù. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Jákọ́bù 4:7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́