ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 11/1 ojú ìwé 4-5
  • Ṣé Àmì Tó Ń Ṣàpẹẹrẹ Nǹkan Búburú ni Sátánì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Àmì Tó Ń Ṣàpẹẹrẹ Nǹkan Búburú ni Sátánì?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌGBÀ TÍ SÁTÁNÌ BÁ JÉSÙ SỌ̀RỌ̀
  • ÌGBÀ TÍ SÁTÁNÌ BÁ ỌLỌ́RUN SỌ̀RỌ̀
  • ÒDE ÒNÍ ŃKỌ́?
  • Sátánì
    Jí!—2013
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Olùṣàkóso Ní Ilẹ̀-Àkóso Ẹ̀mí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ta Ni Sátánì? Ṣó Wà Lóòótọ́?
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 11/1 ojú ìwé 4-5
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ SÁTÁNÌ WÀ LÓÒÓTỌ́?

Ṣé Àmì Tó Ń Ṣàpẹẹrẹ Nǹkan Búburú ni Sátánì?

Ó rọrùn láti sọ pé Sátánì kì í ṣe ẹni gidi, àmọ́ ṣé ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn? Tó bá jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí, kí wá ló dé tí Bíbélì fi sọ pé Sátánì bá Jésù Kristi àti Ọlọ́run Olódùmarè sọ̀rọ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì lára irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀.

ÌGBÀ TÍ SÁTÁNÌ BÁ JÉSÙ SỌ̀RỌ̀

Kété tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni Èṣù ti gẹ̀gùn dè é, ó sì dán Jésù wò lọ́nà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àkọ́kọ́ ni ìgbà tí ebi ń pa Jésù, Sátánì ní kí Jésù lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti dọ́gbọ́n sọ́rọ̀ ara rẹ̀ kí ebi má bàa gbẹ̀mí ẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, Èṣù sọ fún Jésù pé kó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu lọ́nà tí kò tọ́ káwọn èèyàn lè kan sárá sí i. Níkẹyìn, Sátánì sọ pé bí Jésù bá lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan péré, òun máa fún un ní gbogbo ìjọba ayé. Jésù ká gbogbo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tí Sátánì lò yìí, ó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pa á lẹ́nu mọ́.​—Mátíù 4:​1-​11; Lúùkù 4:​1-13.

Ta ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà yẹn? Ṣé èrò búburú kan tó wá sí Jésù lọ́kàn ni àbí ẹni gidi kan ló ń bá sọ̀rọ̀? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan dáhùn pé: “A ti dán [Jésù] wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n kò ní ẹ̀ṣẹ̀.” (Hébérù 4:​15) Ẹsẹ Bíbélì míì tún sọ pé: “[Jésù] kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.” (1 Pétérù 2:​22) Èyí fi hàn pé ẹni pípé ni Jésù látòkèdélẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, èrò búburú ò sì fìgbà kankan wá sí i lọ́kan rí. Nígbà náà, ó dájú pé ẹni gidi kan ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀.

Ìjíròrò yẹn tún jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan míì tó fi hàn pé ẹni gidi ni Sátánì.

  • Rántí pé Èṣù lóun máa fún Jésù ní gbogbo ìjọba ayé tó bá jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. (Mátíù 4:​8, 9) Sé o rò pé ìyẹn máa nítumọ̀ ká ní Sátánì kì í ṣe ẹni gidi? Àti pé Jésù kò jiyàn bóyá Sátánì ní ọlá àṣẹ yẹn àbí kò ní in.

  • Lẹ́yìn tí Jésù ti bẹ́gi dí gbogbo àrékérekè tí Sátánì fi dẹ ẹ́ wò, Bíbélì sọ pé “Èṣù fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀.” (Lúùkù 4:​13) Nínú ọ̀rọ̀ yìí, a ti rí i pé Sátánì kì í ṣe àmì kan tó ṣàpẹẹrẹ ohun búburú, àmọ́ ó jẹ́ aléni-má-dẹ̀yìn ọ̀tá tó dìídì dájú sọ Jésù kó lè mú un balẹ̀.

  • Ṣé o rántí pé “àwọn áńgẹ́lì wá ṣe ìránṣẹ́ fún” Jésù? (Mátíù 4:​11) Àwọn áńgẹ́lì tó wá ran Jésù lọ́wọ́ tí wọ́n sì fún un níṣìírí kì í ṣe àmì tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan, àmọ́ wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ní ti gidi. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Sátánì náà ò lè jẹ́ àmì tó ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan búburú, ẹni gidi kan tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí lòun náà.

ÌGBÀ TÍ SÁTÁNÌ BÁ ỌLỌ́RUN SỌ̀RỌ̀

Ìjíròrò kejì tá a fẹ́ gbé yẹ̀ wò dá lórí ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Jóòbù. Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èṣù àti Ọlọ́run jọ sọ̀rọ̀. Ẹ̀ẹ̀mejì yìí náà ni Ọlọ́run yin Jóòbù fún ìdúróṣinṣin rẹ̀. Sátánì sọ pé torí ohun tí Jóòbù ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló ṣe ń sìn ín, ìyẹn ni pé Ọlọ́run ń fún Jóòbù ní ẹ̀gúnjẹ kó lè máa ṣe tiẹ̀. Ohun tí Èṣù fẹ́ fà yọ ni pé òun mọ Jóòbù ju bí Ọlọ́run ṣe mọ̀ ọ́n lọ. Jèhófà wá gba Sátánì láyè láti ṣèfẹ́ inú rẹ̀.a Èṣù kọ́kọ́ sọ Jóòbù di ẹdun arinlẹ̀, gbogbo ohun tó ti fi àárọ̀ ọjọ́ kó jọ ló pa run lójijì. Àwọn ọmọ rẹ̀ ṣán ku lójú ẹ̀mí rẹ̀, àìsàn sì tún gbé e dè. Láìka èyí sí, Jóòbù ò sẹ́ Ọlọ́run, èyí fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa, ó sì dá Jèhófà láre pé òótọ́ ni ohun tó sọ nípa Jóòbù. Níkẹyìn, Ọlọ́run bù kún Jóòbù nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀.​—Jóòbù 1:​6-​12; 2:​1-7.

Nínú àwọn ìjíròrò yìí, ṣé ẹni gidi kan ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀ ni àbí èrò búburú kan tó ń sọ sí i lọ́kàn? Jèhófà kò lè ní èrò búburú kankan lọ́kàn torí ó pé pérépéré láìkù síbì kan. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Ní ti Ọlọ́run tòótọ́, pípé ni ọ̀nà rẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 22:31) Ìwé Mímọ́ tún sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè.” (Ìṣípayá 4:8) Mímọ́ nínú ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí kí nǹkan mọ́ tónítóní, kó jẹ́ aláìlẹ́gbin, aláìní àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kankan.

Lẹ́yìn tí Sátánì bá Ọlọ́run jíròrò tán, Sátánì fa àdánù ńlá bá Jóòbù

Síbẹ̀ àwọn kan ò rò pé Jóòbù pàápàá jẹ́ ẹni gidi, wọ́n sọ pé fàbú ni ìtàn yẹn. Àmọ́ tá a bá wò ó dáadáa, àá rí i pé ìtàn náà kì í ṣe fàbú rárá. Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni gidi ni Jóòbù. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Jákọ́bù 5:​7-​11 sọ pé Jóòbù jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà táwa Kristẹni lónìí lè fara wé nígbà tá a bá kojú àwọn àdánwò tó le koko, ó tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa san èrè fáwọn tó bá ní ìfaradà. Àmọ́ ṣé àpẹẹrẹ yẹn máa wọni lọ́kàn tó bá jẹ́ pé Jóòbù ò gbé láyé rí tí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn sì jẹ́ àròsọ? Bákan náà, ìwé Ìsíkíẹ́lì 14:​14, 20 mẹ́nu kan Jóòbù lára àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì bíi Nóà àti Dáníẹ́lì. Bí Nóà àti Dáníẹ́lì ṣe jẹ́ ẹni gidi, bẹ́ẹ̀ náà ni Jóòbù jẹ́ ẹni gidi tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ó ṣe kedere pé tí Jóòbù bá jẹ́ ẹni gidi, Sátánì ìyẹn ẹni tó fojú Jóòbù gbolẹ̀ tó sì hàn án léèmọ̀, gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni gidi.

Àwọn ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Sátánì jẹ́ ẹni gidi, ẹ̀dá ẹ̀mí sì ni. Àmọ́ o lè máa ronú pé, ‘ayé àtijọ́ nìyẹn, kò dájú pé Sátánì lè ṣe èmi àti ìdílé mi ní jàǹbá lóde òní.’

ÒDE ÒNÍ ŃKỌ́?

Ká sọ pé àwọn jàǹdùkú ṣàdédé ya wọ àdúgbò rẹ tí wọ́n sì sọ ibẹ̀ dilé, ó dájú pé ìwà ìpáǹle á bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀, ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn á sì wà nínú ewu. Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí nìyẹn, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n jọ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ti wà lórí ilẹ̀ ayé. Ìwọ náà fara balẹ̀ wo ohun tí ìyẹn ti fà nínú àwọn ìròyìn tó ń jáde nílé lóko:

  • Ǹjẹ́ o kíyè sí pé àwọn ìwà burúkú tó bùáyà túbọ̀ ń pọ̀ sí i láìka ìsapá ìjọba láti fòpin sí ìwà ipá?

  • Ṣé o rí i pé àwọn fíìmù tó ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ túbọ̀ ń pọ̀ sí i láìka bí ọ̀pọ̀ òbí ṣe kórìíra rẹ̀?

  • Ǹjẹ́ o kíyè sí pé gbogbo àyíká túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i láìka ètò gbálùúmọ́ àtàwọn ìsapá míì tí ìjọba ń ṣe?

  • Ǹjẹ́ o kíyè sí bí ayé yìí ṣe ń dojú rú sí i àfi bíi pé agbára àìrí kan ló ń dà á rú kí gbogbo nǹkan lè pa run pátápátá?

Bíbélì ṣàlàyé ohun tó fa gbogbo rúdurùdu yìí, ó ní: “A fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. . . . Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:​9, 12) Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ, wọ́n wá gbà pé ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú kan ni Sátánì, òun ló sì ń rúná sí ohun tó ń lọ láyé.

O dájú pé ìwọ náà ò ní fẹ́ kó sínú pańpẹ́ Sátánì. Àkòrí tó tẹ̀ lé e máa sọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti dáàbò bò ara rẹ.

a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́