ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ọlọ́run dá àwọn abọ̀rìṣà lẹ́jọ́ (1-11)

      • Jerúsálẹ́mù ò ní yè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ (12-23)

        • Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù tó jẹ́ olódodo (14, 20)

Ìsíkíẹ́lì 14:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 33:30, 31

Ìsíkíẹ́lì 14:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 3:13; Ais 1:15; Jer 11:11

Ìsíkíẹ́lì 14:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “mú ilé Ísírẹ́lì nínú ọkàn wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:5

Ìsíkíẹ́lì 14:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 55:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 105

Ìsíkíẹ́lì 14:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:1, 2; Isk 33:31

Ìsíkíẹ́lì 14:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 20:2, 3

Ìsíkíẹ́lì 14:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 22:21, 22; Jer 4:10; 2Tẹ 2:10, 11

Ìsíkíẹ́lì 14:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 24:7; Isk 11:19, 20

Ìsíkíẹ́lì 14:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:26
  • +Ais 3:1; Jer 15:2
  • +Jer 7:20

Ìsíkíẹ́lì 14:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:8, 9; Heb 11:7
  • +Da 10:11
  • +Job 1:8; 42:8
  • +Owe 11:4; Jer 15:1; 2Pe 2:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    2/2018, ojú ìwé 3-7

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    5/2016, ojú ìwé 26

    Jí!,

    4/2009, ojú ìwé 22

Ìsíkíẹ́lì 14:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pa wọ́n lọ́mọ jẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:22; Jer 15:3

Ìsíkíẹ́lì 14:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:25; Jer 25:9; Isk 21:3
  • +Sef 1:3

Ìsíkíẹ́lì 14:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:21, 22

Ìsíkíẹ́lì 14:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:1
  • +Da 10:11
  • +Job 1:8; 42:8
  • +Isk 18:20; Sef 2:3

Ìsíkíẹ́lì 14:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìdájọ́ mi mẹ́rin tó burú jáì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 15:2
  • +Isk 5:17; 33:27
  • +Jer 32:43

Ìsíkíẹ́lì 14:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:31; 2Kr 36:20; Isk 6:8; Mik 5:7

Ìsíkíẹ́lì 14:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 9:33; Jer 22:8, 9; Isk 9:9; Da 9:7

Àwọn míì

Ìsík. 14:1Isk 33:30, 31
Ìsík. 14:32Ọb 3:13; Ais 1:15; Jer 11:11
Ìsík. 14:5Jer 2:5
Ìsík. 14:6Ais 55:7
Ìsík. 14:7Jer 21:1, 2; Isk 33:31
Ìsík. 14:8Le 20:2, 3
Ìsík. 14:91Ọb 22:21, 22; Jer 4:10; 2Tẹ 2:10, 11
Ìsík. 14:11Jer 24:7; Isk 11:19, 20
Ìsík. 14:13Le 26:26
Ìsík. 14:13Ais 3:1; Jer 15:2
Ìsík. 14:13Jer 7:20
Ìsík. 14:14Jẹ 6:8, 9; Heb 11:7
Ìsík. 14:14Da 10:11
Ìsík. 14:14Job 1:8; 42:8
Ìsík. 14:14Owe 11:4; Jer 15:1; 2Pe 2:9
Ìsík. 14:15Le 26:22; Jer 15:3
Ìsík. 14:17Le 26:25; Jer 25:9; Isk 21:3
Ìsík. 14:17Sef 1:3
Ìsík. 14:19Di 28:21, 22
Ìsík. 14:20Jẹ 7:1
Ìsík. 14:20Da 10:11
Ìsík. 14:20Job 1:8; 42:8
Ìsík. 14:20Isk 18:20; Sef 2:3
Ìsík. 14:21Jer 15:2
Ìsík. 14:21Isk 5:17; 33:27
Ìsík. 14:21Jer 32:43
Ìsík. 14:22Di 4:31; 2Kr 36:20; Isk 6:8; Mik 5:7
Ìsík. 14:23Ne 9:33; Jer 22:8, 9; Isk 9:9; Da 9:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 14:1-23

Ìsíkíẹ́lì

14 Àwọn kan lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì jókòó síwájú mi.+ 2 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Ọmọ èèyàn, àwọn ọkùnrin yìí ti pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* wọn, wọ́n sì ti ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú kí àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀. Ṣé kí n jẹ́ kí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?+ 4 Bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá pinnu láti tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀, tó ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú kí àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀, tó sì wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ wòlíì, èmi Jèhófà yóò dá a lóhùn bó ṣe yẹ, bí òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀ bá ṣe pọ̀ tó. 5 Màá mú kí ẹ̀rù ba àwọn èèyàn ilé Ísírẹ́lì,* torí gbogbo wọn ti kẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì ti tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.”’+

6 “Torí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ pa dà wá, ẹ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín sílẹ̀, kí ẹ sì yíjú kúrò nínú gbogbo ohun ìríra tí ẹ̀ ń ṣe.+ 7 Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan tó ń gbé ní Ísírẹ́lì bá kẹ̀yìn sí mi, tó sì pinnu láti tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀, tó ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú kí àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀, tó wá lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ wòlíì mi,+ èmi Jèhófà yóò dá a lóhùn fúnra mi. 8 Màá gbéjà ko ọkùnrin náà, màá fi ṣe àmì àti ẹni àfipòwe, màá sì pa á run láàárín àwọn èèyàn mi;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’

9 “‘Àmọ́ tí a bá tan wòlíì náà, tó sì fún un lésì, èmi Jèhófà ló tàn án.+ Màá wá na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ ẹ́, màá sì pa á run kúrò láàárín àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. 10 Wọ́n á ru ẹ̀bi wọn; ẹni tó lọ wádìí ọ̀rọ̀ àti wòlíì náà yóò jẹ̀bi ohun kan náà, 11 kí ilé Ísírẹ́lì má bàa kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́, kí wọ́n má sì fi ẹ̀ṣẹ̀ sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin mọ́. Wọ́n á di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”

12 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 13 “Ọmọ èèyàn, tí ilẹ̀ kan bá hùwà àìṣòótọ́ tó sì wá ṣẹ̀ mí, màá na ọwọ́ mi kí n lè fìyà jẹ ẹ́, màá sì dáwọ́ oúnjẹ rẹ̀ dúró.*+ Màá mú kí ìyàn mú níbẹ̀,+ màá sì pa èèyàn àti ẹranko inú rẹ̀ run.”+ 14 “‘Bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí bá tiẹ̀ wà níbẹ̀, Nóà,+ Dáníẹ́lì+ àti Jóòbù,+ ara wọn* nìkan ni wọ́n á lè gbà là torí òdodo+ wọn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”

15 “‘Tàbí ká ní mo mú kí àwọn ẹranko burúkú wọ ilẹ̀ náà, tí wọ́n pa àwọn èèyàn ibẹ̀,* tí wọ́n sì mú kí ilẹ̀ náà di ahoro, tí ẹnì kankan ò sì lè gba ibẹ̀ kọjá torí àwọn ẹranko tó wà níbẹ̀,+ 16 bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí bá tiẹ̀ wà níbẹ̀, wọn ò ní lè gba àwọn ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin là; ara wọn nìkan ni wọ́n á gbà là, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro.’”

17 “‘Tàbí ká ní mo fi idà bá ilẹ̀ náà jà,+ tí mo sì sọ pé: “Kí idà lọ káàkiri ilẹ̀ náà,” tí mo sì pa èèyàn àti ẹranko inú rẹ̀ run,+ 18 tí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí bá tiẹ̀ wà níbẹ̀, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘wọn ò ní lè gba àwọn ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin là; ara wọn nìkan ni wọ́n á gbà là.’”

19 “‘Tàbí ká ní mo fi àjàkálẹ̀ àrùn kọ lu ilẹ̀ náà,+ tí mo sì fi ìbínú ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, kí n lè run èèyàn àti ẹranko inú rẹ̀, 20 tí Nóà,+ Dáníẹ́lì+ àti Jóòbù+ bá tiẹ̀ wà níbẹ̀, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘wọn ò ní lè gba àwọn ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin là; ara wọn* nìkan ni wọ́n á gbà là torí òdodo+ wọn.’”

21 “Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Bó ṣe máa rí nìyẹn, nígbà tí mo bá fi oríṣi ìyà mẹ́rin*+ jẹ Jerúsálẹ́mù, ìyẹn idà, ìyàn, àwọn ẹranko burúkú àti àjàkálẹ̀ àrùn,+ kí n lè pa èèyàn àti ẹranko inú rẹ̀ run.+ 22 Àmọ́ àwọn kan tó ṣẹ́ kù nínú rẹ̀ yóò yè bọ́, wọ́n á sì mú wọn jáde,+ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Wọ́n ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín, tí ẹ bá sì rí ìwà àti ìṣe wọn, àjálù tí mo mú wá sórí Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ohun tí mo ṣe sí i máa tù yín nínú.’”

23 “‘Tí ẹ bá rí ìwà àti ìṣe wọn, ó máa tù yín nínú, ẹ ó sì mọ̀ pé ó nídìí tí mo fi ṣe ohun tí mo ṣe sí i,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́