ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 12/1 ojú ìwé 3
  • “Yóò Ti Pẹ́ Tó . . . Tí Èmi Yóò Fi Kígbe fún Ìrànlọ́wọ́?”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Yóò Ti Pẹ́ Tó . . . Tí Èmi Yóò Fi Kígbe fún Ìrànlọ́wọ́?”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O Lè Wà Láàyè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Báwo Ni Àkókò Tó Ṣẹ́ Kù Fún Àwọn Olubi Ti Pọ̀ Tó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Kíkún Fún Ìdùnnú Nínú Ọlọ́run Ìgbàlà Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • O Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 12/1 ojú ìwé 3

“Yóò Ti Pẹ́ Tó . . . Tí Èmi Yóò Fi Kígbe fún Ìrànlọ́wọ́?”

Pẹ̀lú omijé lójú ni Jayne fi sọ pé, “Kí n tiẹ̀ bọ́ nínú ìrora yìí!” Jayne ní àrùn jẹjẹrẹ, àrùn náà sì ti ń tàn ká gbogbo ara rẹ̀. Ó ṣe ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bíi pé kí wọ́n lè mú àìsàn àti ìrora rẹ̀ kúrò. Wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn án lọ́wọ́. Ṣé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà wọn? Ṣé ó bìkítà?

ỌLỌ́RUN ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo èèyàn. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Ọlọ́run mọ̀ pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn bíi ti Jayne ni wọ́n ń jẹ̀rora ní ojoojúmọ́, ìrora tí wọ́n ń jẹ lè jẹ́ torí àìsàn tó ń ṣe wọ́n, ó lè jẹ́ pé ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìdààmú ló bá wọn. Ọlọ́run ń rí àwọn ẹgbẹ̀rin [800] mílíọ̀nù èèyàn tí wọ́n ń sùn lébi lálaalẹ́, ó ń rí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì tí wọ́n ń fi ìyà jẹ nínú ilé àti ọ̀pọ̀ òbí tí wọ́n ń kọminú nípa ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ wọn àti bí nǹkan ṣe máa rí fún wọn. Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé ṣé Ọlọ́run máa ṣe ohun kan láti yanjú àwọn ìṣòro yìí? Tó bá ń ṣe wá bíi pé ká ran àwọn èèyàn wa lọ́wọ́, ṣé kò ní wu Ọlọ́run náà pé kó ran àwa èèyàn tá a jẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ lọ́wọ́?

Tí irú ìbéèrè yìí bá ti wá sí ẹ lọ́kàn rí, kì í ṣe ìwọ nìkan. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlá [2,600] ọdún sẹ́yìn, ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Hábákúkù náà ronú bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń ronú lónìí, ó wá bi Ọlọ́run pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́? Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là? Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú? Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi, èé sì ti ṣe tí aáwọ̀ fi ń ṣẹlẹ̀, èé sì ti ṣe tí gbọ́nmi-si omi-ò-to fi ń bẹ?” (Hábákúkù 1:2, 3) Hábákúkù tó jẹ́ wòlíì Hébérù fojú ara rẹ̀ rí àwọn ìwà ipá tó ń dáyà jáni àti bí àwọn èèyàn ṣe ń bínú sódì nígbà ayé rẹ̀. Lónìí, kò sí ọjọ́ kan téèyàn kì í gbọ́ nípa irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, èyí sì máa ń kó àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú nírìíra.

Ṣé Ọlọ́run fojú kéré bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Hábákúkù? Rárá o. Ó fetí sí àwọn ìbéèrè àtọkànwá tí Hábákúkù bi í, lẹ́yìn náà, ó tù ú nínú, ó sì fún ọkùnrin tí ẹ̀dùn ọkàn ti bá yìí ní ìṣírí. Jèhófà Ọlọ́run fún ìgbàgbọ́ Hábákúkù ní okun pẹ̀lú ìlérí tó ṣe pé Òun máa mú òpin dé bá ìjìyà. Ìlérí Ọlọ́run lè jẹ́ kí ọkàn tìẹ náà balẹ̀, bó ṣe jẹ́ kí ọkàn Jayne àti ìdílé rẹ̀ balẹ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ló ṣe dá wa lójú pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run bìkítà nípa wa? Kí ni Ọlọ́run máa ṣe láti fi òpin sí ìjìyà, ìgbà wo ló sì máa ṣe é?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́