ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 5/1 ojú ìwé 14-15
  • Dúró Lórí Ohun Tó O Gbà Gbọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dúró Lórí Ohun Tó O Gbà Gbọ́!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Sódómù àti Gòmórà Ṣe Pa Run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jésù Borí Ìdẹwò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ọ̀rọ̀ Bẹ́yìn Yọ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 5/1 ojú ìwé 14-15

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Dúró Lórí Ohun Tó O Gbà Gbọ́!

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Jeremáyà, Ebedi-mélékì àti Ọba Sedekáyà

Àkópọ̀: Jeremáyà dojú kọ àtakò tó le gan-an nígbà tó ń polongo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé kí àwọn èèyàn Júdà juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ará Kálídíà.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JEREMÁYÀ 38:1-5.

Báwo lo ṣe rò pé ọ̀rọ̀ náà ti rí lára Jeremáyà nígbà tó ń bá àwọn èèyàn Júdà sọ̀rọ̀?

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú ohùn Jeremáyà bó ṣe kéde ìkìlọ̀ Jèhófà?

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Ìdánilójú wo ni Jeremáyà ní tó mú kó lè fi ìgboyà kéde bẹ́ẹ̀?

․․․․․

2 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JEREMÁYÀ 38:6-13.

Lo ojú inú rẹ, ṣàpèjúwe bí ìkùdu ṣe rí, bó ṣe fẹ̀ tó, bó ṣe jìn tó àti irú òórùn tó ní.

․․․․․

Èrò wo ló ti lè wá sọ́kàn Jeremáyà nígbà tó “bẹ̀rẹ̀ sí rì sínú ẹrẹ̀ náà”? (Tún ẹsẹ 6 kà.)

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Lo àwọn ìwé ìwádìí tó o mọ̀, ṣèwádìí nípa ohun tí o kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa irú ìkùdu tí wọ́n ń lò lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì.

․․․․․

Ìdánilójú wo ni Ebedi-mélékì ní kó tó bẹ̀rẹ̀ yíyọ Jeremáyà nínú ewu? (Tún ẹsẹ 7 sí 9 kà.)

․․․․․

Kí nìdí tí Sedekáyà fi tètè juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ọmọ aládé àti lẹ́yìn náà fún Ebedi-mélékì? (Tún ẹsẹ 5 àti 10 kà.) Kí ni èyí fi hàn nípa irú ẹni tó jẹ́? bí kì í ṣeé lè dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀?

․․․․․

Ta ni kò dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ìtàn yìí, ta ló sì dúró lórí ọ̀rọ̀ tiẹ̀? Kí nìdí tó o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ìgboyà.

․․․․․

Ìdánilójú.

․․․․․

Bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn tí wọ́n ń ṣègbọràn sí i láìbẹ̀rù.

․․․․․

Nígbà tó o bá dojú kọ wàhálà, báwo ni ìdánilójú tó o ní ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́?

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA BÍBÉLÌ LÓRÍ ÌKÀNNÌ WA www.watchtower.org àti www.jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́