ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 12/1 ojú ìwé 10
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Àwọn Ọba Mẹ́ta Bẹ Jésù Wò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù?
    Jí!—1999
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àwọn Wo Ni “Amòye Mẹ́ta Náà”? Ṣé “Ìràwọ̀” Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Ni Wọ́n Tẹ̀ Lé?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 12/1 ojú ìwé 10

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Àwọn wo ni Amòye tó wá kí Jésù nígbà tó wà ní kékeré?

▪ Ìwé Ìhìn Rere Mátíù sọ nípa ìbí Jésù pé, àwọn àlejò kan láti “apá ìlà-oòrùn” rí ìràwọ̀ kan tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n ti bí ọba tuntun kan, wọ́n sì fún Jésù lẹ́bùn nígbà tó wà ní kékeré. Nínú èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Ìwé Ìhìn Rere yìí, maʹgoi, tó túmọ̀ sí “amòye,” ni wọ́n pe àwọn àlejò náà. (Mátíù 2:1) Kí la mọ̀ nípa wọn?

Ìwé tí òpìtàn Herodotus tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kọ nípa àwọn Amòye náà ló tíì pẹ́ jù lọ, òun ló sì ṣeé gbára lé jù lọ. Ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Herodotus gbé láyé, ó kọ̀wé pé, àwọn Amòye yìí jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà ilẹ̀ Páṣíà, iṣẹ́ wọn sì ni, wíwo ìràwọ̀, títúmọ̀ àlá àti fífi èèdì dini. Lákòókò tí Herodotus gbé láyé, ẹ̀sìn Zoroaster làwọn ará Páṣíà ń ṣe. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àlùfáà ẹ̀sìn Zoroaster làwọn Amòye tí ọ̀gbẹ́ni yìí sọ nípa wọ́n jẹ́. Ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì náà, The International Standard Bible Encyclopedia, sọ pé: “Èrò àwọn èèyàn ní ilẹ̀ Gíríìsì àtijọ́ ni pé, amòye kan ní ìmọ̀ àti agbára tó ju ti ẹ̀dá èèyàn lọ, nígbà míì, ó sì máa ń pidán.”

Ọ̀pọ̀ àwọn alálàyé tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn ní ayé àtijọ́, àwọn bí ọ̀gbẹ́ni Justin Martyr, Origen àti Tertullian, sọ pé awòràwọ̀ làwọn Amòye tó wá kí Jésù. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìbọ̀rìṣà, ìyẹn On Idolatry, èyí tí ọ̀gbẹ́ni Tertullian kọ, ó sọ pé: “A mọ àjọṣe tó wà láàárín idán pípa àti wíwo ìràwọ̀. Àwọn tó ń túmọ̀ ohun tí wọ́n rí nínú ìràwọ̀ nígbà yẹn ló kọ́kọ́ . . . fún Un [Jésù] ‘lẹ́bùn.’” Àwọn àlàyé yìí ló mú kí ọ̀pọ̀ atúmọ̀ Bíbélì pe àwọn amòye náà ní “awòràwọ̀.”

Kí nìdí tí Mátíù fi sọ pé wòlíì Jeremáyà ló sọ ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ pé inú ìwé Sekaráyà ni ọ̀rọ̀ náà wà?

▪ Inú Mátíù 27:9, 10, ni ọ̀rọ̀ tá à ń sọ yìí wà, níbi tí ẹni tó kọ Ìwé Ìhìn Rere náà ti sọ̀rọ̀ nípa owó tí wọ́n fún Júdásì Ísíkáríótù fún dídà tó da Jésù. Àwọn ẹsẹ náà kà pé: “Nígbà náà ni ohun tí a sọ nípasẹ̀ Jeremáyà wòlíì ní ìmúṣẹ, pé: ‘Wọ́n sì mú ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà, iye owó lórí ọkùnrin tí a dá iye owó lé, . . . wọ́n sì fi wọ́n ra pápá amọ̀kòkò.’” Sekaráyà ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà kì í ṣe Jeremáyà.—Sekaráyà 11:12, 13.

Nígbà kan, ó jọ pé ìwé Jeremáyà ni wọ́n fi ṣe àkọ́kọ́ nínú àkójọ àwọn ìwé tí wọ́n pè ní “àwọn Wòlíì” kì í ṣe ìwé Aísáyà. (Mátíù 22:40) Nítorí náà, àpapọ̀ ìwé àwọn wòlíì yẹn ni Mátíù ní lọ́kàn nígbà tó dárúkọ “Jeremáyà” tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ nínú àkójọ àwọn Ìwé Mímọ́ náà. Ìwé Sekaráyà sì wà lára àkójọ àwọn Ìwé Mímọ́ náà.

Lọ́nà kan náà, Jésù pe àwọn ìwé Bíbélì mélòó kan ní “Sáàmù,” àwọn ìwé yìí la tún ń pè ní Àwọn Ìwé. Nítorí náà, gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé gbogbo nǹkan tí wọ́n kọ nípa òun “nínú òfin Mósè àti nínú àwọn Wòlíì àti àwọn Sáàmù” ní láti ṣẹ.—Lúùkù 24:44.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́