ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 12/15 ojú ìwé 3-4
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Kan
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Táwọn Ará Sípéènì Gbà Ń Ṣayẹyẹ Ọdún Kérésìmesì
  • ‘Ìgbà Tínú Àwọn Èèyàn Máa Ń Dùn Jù Tí Ọwọ́ Wọn sì Tún Máa Ń Dí Jù Nínú Ọdún’
  • Ǹjẹ́ Àwọn Ọba Mẹ́ta Bẹ Jésù Wò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù?
    Jí!—1999
  • Àwọn Àṣà Kérésìmesì—Ṣé Wọ́n Bá Ìsìn Kristẹni Mu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Rántí Jésù Kristi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 12/15 ojú ìwé 3-4

Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Kan

“Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, tí iṣe Kristi Oluwa.”—Lúùkù 2:11, “Bibeli Mimọ.”

NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, obìnrin kan bí ọmọkùnrin kan ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nínú àwọn tó ń gbé nílùú náà, ọ̀pọ̀ jù lọ ni ò mọ̀ nípa ìbí ọmọ náà. Àmọ́, àwọn darandaran tó ń kó ẹran wọn jẹ̀ ní pápá gbọ́ ìròyìn lóru nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ áńgẹ́lì tí ń kọrin pé: “Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.”—Lúùkù 2:8-14.

Nígbà táwọn darandaran náà wá Màríà àti Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ lọ, wọ́n rí wọn ní ibùjẹ ẹran gẹ́gẹ́ bí àwọn áńgẹ́lì náà ṣe sọ fún wọn. Màríà ló sọ ọmọ náà ni Jésù, ó sì tẹ́ ọmọ náà sórí ibi tí wọ́n máa ń kó oúnjẹ ẹran sí. (Lúùkù 1:31; 2:12) Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì báyìí tí ohun tá à ń sọ yìí ti ṣẹlẹ̀. Lónìí, nǹkan bí ìdá mẹ́ta èèyàn ló gbà pé ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi làwọn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìbí Jésù ló sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun táwọn èèyàn fi ń pìtàn jù láyé yìí.

Orílẹ̀-èdè Sípéènì jẹ́ ibì kan tí àṣà ẹ̀sìn Kátólíìkì ti gbilẹ̀ gan-an, àwọn ará ibẹ̀ sì fẹ́ràn ayẹyẹ púpọ̀. Wọ́n tiẹ̀ ní oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣayẹyẹ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó wáyé ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù yẹn.

Ọ̀nà Táwọn Ará Sípéènì Gbà Ń Ṣayẹyẹ Ọdún Kérésìmesì

Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn tí àwọn ará Sípéènì ti máa ń ṣe ẹ̀dà àwòrán ìbí Jésù tó bá ti dìgbà ọdún Kérésì. Ọ̀pọ̀ ìdílé ló máa ń ṣe ibi kékeré kan láti ṣàpẹẹrẹ ibùjẹ ẹran tí wọ́n tẹ́ Jésù sórí rẹ̀. Wọ́n á fi amọ̀ mọ àwòrán àwọn darandaran àtàwọn Amòye (tàbí “àwọn ọba mẹ́ta”) náà. Wọ́n á tún fi amọ̀ mọ àwòrán Jósẹ́fù, Màríà, àti ti Jésù náà pẹ̀lú. Wọ́n á tún ya àwòrán ìbí Jésù tó tóbi gan-an, wọ́n á wá gbé e lọ sítòsí gbọ̀ngàn ìlú lákòókò ọdún Kérésì. Ó jọ pé ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Francis nílùú Assisi ní orílẹ̀-èdè Ítálì ló bẹ̀rẹ̀ àṣà yíya àwòrán yìí. Ó fẹ́ káwọn èèyàn máa rántí ìtàn tí Ìwé Ìhìn Rere sọ nípa ìbí Jésù. Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà nínú ẹgbẹ́ tí Francis dá sílẹ̀ wá gbé àṣà yìí lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Sípéènì àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn.

Àwọn Amòye máa ń kó ipa pàtàkì nígbà tí wọ́n bá ń ṣayẹyẹ ọdún Kérésì lórílẹ̀-èdè Sípéènì bí àwọn Baba Kérésì ṣe rí láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Ní Sípéènì, àwọn Amòye máa ń fún àwọn ọmọdé ní ẹ̀bùn ní ọjọ́ kẹfà oṣù January, èyí tí wọ́n ń pè ní Día de Reyes (ìyẹn Ọjọ́ Àwọn Ọba). Wọ́n ń ṣe èyí nítorí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn pé àwọn Amòye mú ẹ̀bùn wá fún Jésù nígbà tó wà lọ́mọ ọwọ́. Àmọ́, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló mọ̀ pé Ìwé Ìhìn Rere ò sọ iye àwọn Amòye tó wá kí Jésù. Ìwé Ìhìn Rere sọ irú àwọn ẹni tó wá sọ́dọ̀ Jésù, awòràwọ̀ ló pè wọ́n, kì í ṣe ọba.a Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́yìn táwọn Amòye náà lọ tán, Hẹ́rọ́dù gbẹ̀mí gbogbo àwọn ọmọ ọwọ́ tó jẹ́ ọkùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù “láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀,” nítorí pé ó fẹ́ pa Jésù. Èyí fi hàn pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bí Jésù làwọn amòye náà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.—Mátíù 2:11, 16.

Láti ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn ni wọ́n ti máa ń fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìbí Jésù àtohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìbẹ̀wò àwọn darandaran àtèyí tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìbẹ̀wò àwọn Amòye ṣeré orí ìtàgé ní àwọn ìlú kan lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Láyé ìsinsìnyí, ọ̀pọ̀ jù lọ ìlú tó wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì ni wọ́n ti sábà máa ń ṣe ohun tí wọ́n ń pè ní cabalgata, tàbí ìwọ́de lọ́dọọdún ní ọjọ́ karùn-ún oṣù January. Nígbà ìwọ́de yìí, àwọn “ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta” á jókòó sínú ọkọ̀ kan tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì, wọ́n á wá gbé wọn wọ́de lọ sáàárín ìlú, “àwọn ọba” náà á sì máa há midinmíìdìn fáwọn òǹwòran. Àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ yinrinyinrin tí wọ́n máa ń lò nígbà Kérésì àti orin Kérésì (ìyẹn villancicos) máa ń mú kí ayẹyẹ náà lárinrin.

Ní orílẹ̀-èdè Sípéènì, tí ọdún bá ku ọ̀la (ìyẹn ní December 24), ọ̀pọ̀ ìdílé ló máa ń fẹ́ ṣe àsè ńlá lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Wọ́n á pèsè àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ bíi turrón, ìyẹn midinmíìdìn tí wọ́n fi èso álímọ́ńdì àti oyin ṣe, oúnjẹ tí wọ́n fi àpòpọ̀ ẹyin àti ṣúgà ṣe, àwọn èso gbígbẹ, ẹran àgùntàn tí wọ́n sun, àti àwọn ẹran omi lóríṣiríṣi. Gbogbo ìdílé ló máa ń sapá láti péjú pésẹ̀ síbi ayẹyẹ yìí, kódà àwọn tó wà lọ́nà jíjìn pàápàá máa ń sa gbogbo ipá wọn láti wà níbẹ̀. Tó bá tún wá di ìgbà àsè mìíràn, ìyẹn ní January 6, gbogbo ìdílé á tún jẹ oúnjẹ tí wọ́n ń pè ní roscón de reyes, ìyẹn àkàrà òyìnbó ti “àwọn Ọba” tí wọ́n fi sorpresa (ìyẹn nǹkan kékeré kan) pa mọ́ sínú rẹ̀. Àwọn ará Róòmù náà máa ń dá irú àṣà yẹn, ẹni tó bá sì mú àkàrà tí wọ́n fi nǹkan kékeré yẹn pa mọ́ sínú rẹ̀ yóò jẹ “ọba” fún ọjọ́ kan.

‘Ìgbà Tínú Àwọn Èèyàn Máa Ń Dùn Jù Tí Ọwọ́ Wọn sì Tún Máa Ń Dí Jù Nínú Ọdún’

Ọdún Kérésìmesì ni ayẹyẹ táwọn èèyàn gba tiẹ̀ jù lọ láyé òde òní láìka àṣà yòówù tí wọn ì báà máa tẹ̀ lé sí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé ìgbà ọdún Kérésì ni “inú àìmọye Kristẹni àtàwọn kan tí kì í ṣe Kristẹni máa ń dùn jù, ìgbà yẹn sì lọ́wọ́ wọn máa ń dí jù.” Ṣé ìyẹn wá sọ ayẹyẹ yìí di ohun tó dára?

Kò sí iyèméjì pé mánigbàgbé ni ìbí Kristi. Kíkéde tí àwọn áńgẹ́lì kéde rẹ̀ pé òun ló máa mú “àlàáfíà [wà] láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà” fi hàn kedere pé ìbí rẹ̀ ṣe pàtàkì.

Síbẹ̀, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Juan Arias sọ pé “nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, wọn ò kì í ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù.” Tí ọ̀ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, ibo ni Kérésìmesì ti wá? Ọ̀nà wo ló dáa jù láti gbà máa rántí ìbí àti ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé? Wàá rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé La Sagrada Escritura—Texto y comentario por profesores de la Compañía de Jesús (Ẹsẹ àti Àlàyé Ìwé Mímọ́ Láti Ọwọ́ Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Tó Sọ̀rọ̀ Nípa Jésù) sọ pé “àwọn kan lára àwọn ará Páṣíà, Mídíà àti Kálídíà làwọn Amòye yẹn, wọ́n di ẹgbẹ́ àlùfáà tó ń gbé iṣẹ́ òkùnkùn, iṣẹ́ awòràwọ̀ àti iṣẹ́ ìṣègùn lárugẹ.” Àmọ́ o, ṣáájú ọ̀rúndún karùn-ún ni àwọn èèyàn ti sọ àwọn Amòye tó lọ sọ́dọ̀ Jésù nígbà tó wà lọ́mọ ọwọ́ di ẹni mímọ́, wọ́n sì fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn amòye náà lórúkọ. Orúkọ tí wọ́n fún wọn rèé: Melchior, Gaspar, àti Balthasar. Àwọn èèyàn sọ pé inú kàtídírà tó wà nílùú Cologne, lórílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n tọ́jú òkú àwọn Amòye náà sí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́