ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 12/15 ojú ìwé 4-7
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Rántí Jésù Kristi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Rántí Jésù Kristi?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ayẹyẹ Táwọn Èèyàn Fi Ń Ṣe Afẹ́ Tí Wọ́n sì Fi Ń Pa Owó
  • A Ti Bí Ọmọ Kan Fún Wa
  • Keresimesi—Eeṣe Ti Ó Fi Gbajúmọ̀ Tobẹẹ ni Japan?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Orísun Kérésìmesì Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Kérésìmesì—Èé Ṣe Táwọn Ará Ìlà Oòrùn Ayé Pàápàá Fi Ń Ṣe É?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 12/15 ojú ìwé 4-7

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Rántí Jésù Kristi?

“Ó dájú pé [Jésù Kristi] jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn pàtàkì tó ti gbé ayé rí.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ “The World Book Encyclopedia.”

OHUN táwọn ẹni ńlá bá gbélé ayé ṣe la sábà fi ń rántí wọn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìbí Jésù làwọn èèyàn fi ń rántí rẹ̀ dípò àwọn nǹkan tó gbélé ayé ṣe? Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ló mọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìbí Jésù. Àmọ́, mélòó nínú wọn ló rántí àwọn ẹ̀kọ́ àtàtà tí Jésù fi kọ́ni nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè? Mélòó nínú wọn ló sì ń fi àwọn ẹ̀kọ́ náà ṣèwà hù?

Òótọ́ ni pé ìbí Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí gbà pé àwọn ohun tí Jésù ṣe àtàwọn ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni ṣe pàtàkì ju ìbí rẹ̀ lọ. Ó sì dájú pé kì í ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run pé káwọn èèyàn máa sọ̀rọ̀ nípa ìbí Jésù kí wọ́n wá gbàgbé irú ìgbé ayé tó gbé nígbà tó di géńdé. Ṣùgbọ́n, ọdún Kérésìmesì ò jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Kristi jẹ́ mọ́ nítorí ìtàn àtẹnudẹ́nu nípa ìbí rẹ̀.

Ìbéèrè mìíràn tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò jẹ mọ́ ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń ṣayẹyẹ ọdún Kérésìmesì. Ká ní Jésù padà wá sórí ilẹ̀ ayé lónìí, ojú wo ló máa fi wo òwò ṣíṣe tó ń wáyé lásìkò Kérésì? Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó rí àwọn tó ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó àtàwọn òǹtajà tí wọ́n ń fi àjọ̀dún àwọn ẹlẹ́sìn Júù pa owó sápò ara wọn, inú bí i gan-an. Ó gbójú mọ́ wọn, ó ní: “Ẹ kó nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín! Ẹ dẹ́kun sísọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà!” (Jòhánù 2:13-16) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn kedere pé Jésù ò fẹ́ káwọn èèyàn máa da òwò ṣíṣe pọ̀ mọ́ ìsìn.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì lórílẹ̀-èdè Sípéènì tí wọn ò kì í bo nǹkan tí kò dáa ló ń kọminú sí ọ̀rọ̀ òwò ṣíṣe tó máa ń wáyé nígbà ọdún Kérésì. Àmọ́, ó dà bí ẹni pé àwọn èèyàn ò ní jáwọ́ nínú ṣíṣòwò elérè gọbọi yìí nítorí pé bí ọ̀pọ̀ lára àṣà ọdún Kérésìmesì ṣe rí nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Akọ̀ròyìn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Juan Arias sọ pé: “Àwọn Kristẹni kan ta ko bí àwọn èèyàn ṣe ‘sọ ọdún Kérésì di ti Kèfèrí,’ wọ́n ní kò dára bí wọ́n ṣe pa ẹ̀sìn tì tó wá jẹ́ pé afẹ́ àti òwò nìkan ló wà lórí ẹ̀mí wọn. Àmọ́ ohun kan tí wọ́n gbàgbé ni pé, látìgbà tí ọdún Kérésì ti bẹ̀rẹ̀ làwọn èèyàn ti mú . . . ọ̀pọ̀ lára àwọn àṣà àjọ̀dún [oòrùn] ti ilẹ̀ Róòmù, irú bíi afẹ́ àti òwò ṣíṣe, wọnú rẹ̀.”—Ìwé ìròyìn El País, December 24, 2001.

Láti ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń kọ ìwé ìròyìn àti ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ilẹ̀ Sípéènì sọ pé àwọn Kèfèrí ló bẹ̀rẹ̀ àwọn àṣà ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì, títí kan àṣà òwò ṣíṣe tó máa ń wáyé lásìkò náà. Ní ti ọjọ́ táwọn èèyàn máa ń ṣọdún Kérésì, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Enciclopedia de la Religión Católica sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an, ó ní: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí pé Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì fẹ́ fi ọdún Kérésì rọ́pò ọdún táwọn Kèfèrí máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ṣe fi sí ọjọ́ tí wọ́n ń ṣe é yìí. . . . A mọ̀ pé láyé àtijọ́ nílẹ̀ Róòmù, December 25 làwọn Kèfèrí yàn gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ mímọ́ fún ṣíṣe ọdún natalis invicti, ìyẹn ọjọ́ ìbí ‘oòrùn tí kò tètè wọ̀.’”

Bákan náà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ti Enciclopedia Hispánica sọ pé: “Kì í ṣe pé àwọn èèyàn dìídì ṣírò ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù láti mọ ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n ṣe ń ṣayẹyẹ ọdún Kérésìmesì ní December 25, àmọ́ ọjọ́ táwọn ará Róòmù ń ṣe àjọ̀dún ìbí oòrùn ni wọ́n kàn gbé wọnú ẹ̀sìn Kristẹni.” Báwo làwọn ará Róòmù ṣe ń ṣọdún yíyọ oòrùn nígbà òtútù? Ńṣe ni wọ́n máa ń filé pọn ọtí tí wọ́n á fọ̀nà rokà, wọ́n á pagbo àríyá, wọ́n á tún máa há ẹ̀bùn fún ara wọn. Nítorí pé àwọn olórí ẹ̀sìn ò fẹ́ fagi lé ayẹyẹ tí gbogbo èèyàn fẹ́ràn yìí, “wọ́n sọ ọ́ di ọdún Kristẹni,” wọ́n pè é ní ọjọ́ ìbí Jésù dípò ọjọ́ ìbí oòrùn.

Níbẹ̀rẹ̀, ìyẹn ní ọ̀rúndún kẹrin àti ọ̀rúndún karùn-ún, àwọn èèyàn ò yéé ṣọdún ìbí oòrùn, wọn ò sì fi àwọn àṣà tó so mọ́ ọn sílẹ̀ bọ̀rọ̀. Augustine “Mímọ́” ti ìjọ Kátólíìkì tó gbé láyé láàárín ọdún 354 sí ọdún 430 Sànmánì Tiwa gba àwọn ara ìjọ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n má ṣe ṣayẹyẹ ọdún tó ń wáyé ní December 25 gẹ́gẹ́ bí àwọn Kèfèrí ṣe máa ń ṣe láti fi yẹ́ oòrùn sí. Lóde òní pàápàá, ó dà bí ẹni pé àjọ̀dún àwọn ará Róòmù ìgbàanì làwọn èèyàn gba tiẹ̀ jù.

Ayẹyẹ Táwọn Èèyàn Fi Ń Ṣe Afẹ́ Tí Wọ́n sì Fi Ń Pa Owó

La ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún já, ohun púpọ̀ ló ti mú kí ayẹyẹ Kérésì di ayẹyẹ táwọn èèyàn gba tiẹ̀ àti ayẹyẹ tí wọ́n fi ń ṣe fàájì tí wọ́n sì fi ń pawó jù lọ. Nígbà tó yá, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn àṣà ayẹyẹ mìíràn tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún nígbà òtútù, àgàgà èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní Àríwá Yúróòpù, wọnú ayẹyẹ ọdún Kérésì tó bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Róòmù yìí.a Ní ọ̀rúndún ogún, ńṣe làwọn oníṣòwò àtàwọn ògbógi nídìí okòwò máa ń ṣe ìgbélárugẹ àṣà èyíkéyìí tó bá máa mú kí ọjà wọn tà kí wọ́n sì rí èrè gọbọi.

Kí ni àbájáde èyí? Àbájáde rẹ̀ ni pé dípò tí olórí ìdí tí wọ́n fi bí Kristi ì bá fi gbawájú lọ́kàn àwọn èèyàn, ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ ló jẹ wọ́n lógún jù. Ọ̀pọ̀ ibi ló sì wà tó jẹ́ pé wọn kì í dárúkọ Kristi rárá nígbà ọdún Kérésì. Ìwé ìròyìn El País ti orílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé: “[Ọdún Kérésì] jẹ́ ayẹyẹ kan táwọn ìdílé máa ń ṣe, bó bá sì ṣe wu kálukú ní wọ́n ṣe máa ń ṣe é.”

Ohun tí ìwé ìròyìn yìí sọ jẹ́ ká mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Sípéènì àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn kárí ayé. Bí ayẹyẹ ọdún Kérésì ṣe túbọ̀ ń gbèrú sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ nípa Kristi ń dín kù sí i. Lẹ́nu kan ṣáá, ọdún Kérésì ti padà sí bó ṣe rí nílẹ̀ Róòmù láyé àtijọ́, ìyẹn àríyá aláriwo, tí wọ́n ti máa ń se àsè ńlá tí wọ́n sì máa ń fúnra wọn lẹ́bùn.

A Ti Bí Ọmọ Kan Fún Wa

Tí ọdún Kérésì ò bá ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Kristi, báwo ló wá ṣe yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ máa rántí ìbí àti ìgbésí ayé Kristi? Ní ọgọ́rùn-ún ọdún méje ṣáájú ìbí Jésù, Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa rẹ̀ pé “A ti bí ọmọ kan fún wa, a ti fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.” (Aísáyà 9:6) Kí nìdí tí Aísáyà fi sọ pé ìbí Jésù àtàwọn nǹkan tó máa ṣe lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé Jésù máa di alákòóso tó lágbára. A óò máa pè é ní Ọmọ Aládé Àlàáfíà, àlàáfíà ìjọba rẹ̀ kò ní lópin, bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣàkóso rẹ̀ yóò wà títí láé. Láfikún sí i, ‘ìdájọ́ òdodo àti òdodo’ ni yóò gbé ìṣàkóso Jésù ró.—Aísáyà 9:7.

Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì tún ọ̀rọ̀ Aísáyà sọ nígbà tó lọ sọ fún Màríà pé ó máa bí Jésù. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ tí Kristi máa ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run yàn ṣe Ọba Ìjọba Ọlọ́run ló mú kí ìbí Jésù ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀. Ìṣàkóso Kristi lè ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní, ó lè ṣe ìwọ alára àtàwọn èèyàn rẹ láǹfààní pẹ̀lú. Kódà, àwọn áńgẹ́lì sọ pé ìbí Jésù yóò yọrí sí “alaafia ní ayé láàrin àwọn ẹni tí inú Ọlọ́run dùn sí.”—Lúùkù 2:14, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀.

Ta ni kò fẹ́ láti máa gbé nínú ayé tí àlàáfíà ti jọba, tí nǹkan ti ń lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ? Àmọ́, ká tó lè gbádùn àlàáfíà tí ìṣàkóso Kristi yóò mú wá, a ní láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Jésù sọ pé tá a bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti Kristi. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.

Tá a bá ti wá mọ irú ẹni tí Jésù jẹ́ dáadáa, a ò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní máa ronú lórí bó ṣe fẹ́ ká máa rántí òun. Ṣé ká máa jẹ, ká máa mu, ká sì máa fúnra wa lẹ́bùn lọ́jọ́ tó bọ́ sí ọjọ́ àjọ̀dún àwọn abọ̀rìṣà ayé àtijọ́ ni ọ̀nà tó fẹ́ ká máa gbà rántí òun? Rárá o. Kí Jésù tó kú, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bó ṣe fẹ́ kí wọ́n máa rántí òun. Ó ní: “Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ó nífẹ̀ẹ́ mi. Ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni Baba mi yóò nífẹ̀ẹ́, ṣe ni èmi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 14:21.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ jinlẹ̀, èyí sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àṣẹ Ọlọ́run àti ti Jésù. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn àṣẹ pàtàkì náà kó o bàa lè máa rántí Jésù bó ṣe yẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Méjì lára àwọn àṣà ọ̀hún ni òdòdó Kérésì àti Baba Kérésì.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ Pé Ká Má Jẹ Àsè Ká Má sì Fúnra Wa Lẹ́bùn?

Fífún Ara Wa Lẹ́bùn

Bíbélì ò sọ pé ká máà fúnra wa lẹ́bùn, àní ó tiẹ̀ sọ pé Jèhófà ni Ẹni tó ń fúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Jésù fi hàn pé àwọn òbí rere kì í ṣaláì fún àwọn ọmọ wọn lẹ́bùn. (Lúùkù 11:11-13) Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fún un lẹ́bùn nígbà tí ara rẹ̀ yá tán. (Jóòbù 42:11) Ṣùgbọ́n, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn tá a mẹ́nu kan yìí tó jẹ́ pé ọjọ́ ayẹyẹ tá a yà sọ́tọ̀ ni wọ́n fúnni lẹ́bùn. Ńṣe ló ti ọkàn wọn wá.—2 Kọ́ríńtì 9:7.

Kò Burú Kí Ìdílé Kóra Jọ

Tí ìdílé bá ń kóra jọ, èyí lè mú kí okùn ìfẹ́ tó wà láàárín wọn túbọ̀ lágbára sí i, àgàgà bí wọn ò bá gbé níbi kan náà mọ́. Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ síbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ìgbéyàwó kan nílùú Kánà, ó sì dájú pé àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ ló kóra wọn jọ síbi ayẹyẹ ọ̀hún. (Jòhánù 2:1-10) Nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa ọmọ onínàákúnàá, nígbà tí ọmọ náà padà wálé, bàbá rẹ̀ ṣe àsè ńlá, ó kó ìdílé rẹ̀ jọ láti ṣe àríyá, wọ́n kọrin wọ́n sì jó.—Lúùkù 15:21-25.

Gbígbádùn Oúnjẹ Pa Pọ̀

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ aládùn pẹ̀lú àwọn ìbátan, ọ̀rẹ́, tàbí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Nígbà táwọn áńgẹ́lì mẹ́ta lọ sọ́dọ̀ Ábúráhámù, ó se àsè ńlá fún wọ́n, ó pa màlúù fún wọn, ó fún wọn ní mílíìkì, bọ́tà, àti àkàrà. (Jẹ́nẹ́sísì 18:6-8) Sólómọ́nì sọ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ‘kí ènìyàn máa jẹ, kó sì máa mu.’—Oníwàásù 3:13; 8:15.

Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwa, àwọn ọ̀rẹ́ wa, àtàwọn ará ilé wa jọ máa gbádùn oúnjẹ pa pọ̀, Ọlọ́run ò sì sọ pé ká máà fúnra wa lẹ́bùn. Kò sì sígbà kan tá ò lè ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ọdún.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́