ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 7/1 ojú ìwé 10
  • Báwo Ni Nǹkan Ṣe Ń Rí Lára Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Nǹkan Ṣe Ń Rí Lára Jèhófà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Lè Múnú Ọlọ́run Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bó Ò Ṣe Ní Yẹsẹ̀ Tí Ọmọ Rẹ Bá Kẹ̀yìn sí Ìlànà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run Rẹ, Yóò Di Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Mú”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Báwo Lo Ṣe Lè Borí Èrò Òdì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 7/1 ojú ìwé 10

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Báwo Ni Nǹkan Ṣe Ń Rí Lára Jèhófà?

BÍ A bá sọ pé, bẹ́ẹ̀ ni, ìbéèrè míì ni pé: Ǹjẹ́ ìwà wa lè múnú Ọlọ́run dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́? Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí láyé ìgbàanì sọ pé rárá. Èrò wọn ni pé, kò sí ẹni tó lè múnú Ọlọ́run dùn tàbí bà á nínú jẹ́, nítorí náà, wọ́n sọ pé Ọlọ́run kò lè mọ nǹkan lára. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ sí èrò yìí pátápátá, ó sọ pé, Jèhófà ní ìyọ́nú, ohun tá a sì ń ṣe jẹ ẹ́ lógún gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó wà nínú Sáàmù 78:40, 41.

Sáàmù 78 sọ nípa àjọṣe Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì. Nígbà tí Jèhófà dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní oko ẹrú Íjíbítì, ó ní òun fẹ́ kí àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ wà láàárín òun pẹ̀lú wọn. Ó ṣèlérí pé, tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin òun, wọ́n máa di “àkànṣe dúkìá” òun, òun á sì lò wọ́n lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti mú ìfẹ́ òun ṣẹ. Àwọn èèyàn náà gbà, wọ́n sì dá májẹ̀mú Òfin pẹ̀lú Ọlọ́run. Ǹjẹ́ wọ́n dúró lórí àdéhùn tí wọ́n bá Ọlọ́run ṣe?—Ẹ́kísódù 19:3-8.

Onísáàmù náà sọ pé: “Ẹ wo bí iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù ti pọ̀ tó!” (Ẹsẹ 40) Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e fi kún un pé: “Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò.” (Ẹsẹ 41) Ẹ kíyè sí i pé, ẹni tó kọ sáàmù yìí ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run léraléra. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí Ọlọ́run dá wọn sílẹ̀ ní Íjíbítì, ìyẹn ìgbà tí wọ́n wà ní aginjù ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ọ̀tẹ̀ àti ìwà àìlọ́wọ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Ọlọ́run, wọ́n ń sọ pé àwọn kò rò pé ó lè bójú tó àwọn, àwọn kò sì rò pé ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Númérì 14:1-4) Ìwé kan táwọn atúmọ̀ Bíbélì máa ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, “ọ̀nà míì téèyàn lè gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ‘wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i’ ni pé ‘wọ́n mú ọkàn wọn le sí Ọlọ́run’ tàbí ‘wọ́n sọ pé “Rárá” fún Ọlọ́run.’” Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run àánú máa ń dárí ji àwọn èèyàn rẹ̀ yìí tí wọ́n bá ronú pìwà dà. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà máa ń pa dà sídìí ìwà búburú wọn, wọ́n á sì tún ṣọ̀tẹ̀, bí wọ́n sì ṣe ń bá a nìṣó nìyẹn.—Sáàmù 78:10-19, 38.

Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà nígbà tí àwọn èèyàn tí kò láyọ̀ lé yìí bá ṣọ̀tẹ̀? Ẹsẹ 40 sọ pé, “Wọn a máa mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́.” Ohun tí ìtúmọ̀ Bíbélì míì sọ ni pé, wọ́n “mú kó ní ẹ̀dùn ọkàn.” Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, ìwà àwọn Hébérù yìí mú kó ní ìrora ọkàn, ìyẹn bí ìgbà tí ìwà ọmọ tó jẹ́ aláìgbọràn àti ọlọ̀tẹ̀ ṣe máa ń mú kí òbí rẹ̀ ní ìrora ọkàn.” Bí ọmọ tí kò gbọ́ràn ṣe lè mú kí àwọn òbí rẹ̀ ní ìrora ọkàn, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà ọ̀tẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”—Ẹsẹ 41.

Kí la lè rí kọ́ nínú Sáàmù yìí? Ó fi ní lọ́kàn balẹ̀ pé, Jèhófà kì í fi ọ̀rọ̀ àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ṣeré rárá, kì í sì í tètè sọ ìrètí nù pé wọn kò lè ṣàtúnṣe. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún múni ronú jinlẹ̀ pé, Jèhófà máa ń mọ nǹkan lára, ìyẹn ni pé ìwà wa lè múnú rẹ̀ dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́. Ipa wo ló yẹ kí ohun tó o mọ̀ yìí ní lórí rẹ? Ǹjẹ́ èyí mú kó o fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́?

Dípò tí a ó fi máa ṣe ohun tí kò tọ́ tí a ó sì kó ìrora ọkàn bá Jèhófà, a lè pinnu láti ṣe ohun tó tọ́, ká sì mú inú rẹ̀ dùn. Ohun tí Ọlọ́run sì fẹ́ kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ ṣe gan-an nìyẹn, ó ní: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀.” (Òwe 27:11) Kò sí ohun tó ṣeyebíye tá a lè fún Jèhófà ju pé ká gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó máa mú ọkàn rẹ̀ yọ̀.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún July:

◼ Sáàmù 60-86

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

Kò sí ohun tó ṣeyebíye tá a lè fún Jèhófà ju pé ká gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó máa mú ọkàn rẹ̀ yọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́