O Lè Múnú Ọlọ́run Dùn
ǸJẸ́ lóòótọ́ la lè múnú Ọlọ́run dùn tàbí ká múnú ẹ̀ bà jẹ́? Ṣé Ọlọ́run máa ń láyọ̀? Èrò àwọn kan ni pé agbára kan lásán ni Ọlọ́run. Ǹjẹ́ a lè retí pé kí agbára kan lásán tí kì í ṣe ẹni gidi láyọ̀? Rárá, kò ṣeé ṣe. Àmọ́, ìwọ wo ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run.
Jésù Kristi sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.” (Jòhánù 4:24) Ẹni ẹ̀mí yàtọ̀ sí ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ran ara. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti rí ẹni tó jẹ́ ẹ̀mí, ẹni ẹ̀mí máa ń ní ara, ìyẹn “ara ti ẹ̀mí.” (1 Kọ́ríńtì 15:44; Jòhánù 1:18) Nípa lílo àkànlò èdè, Bíbélì tiẹ̀ sọ nípa Ọlọ́run pé ó ní ojú, etí, ọwọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.a Ọlọ́run tún ní orúkọ tó ń jẹ́, ìyẹn ni Jèhófà. (Sáàmù 83:18) Nítorí náà, ẹni ẹ̀mí ni Ọlọ́run tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì. (Hébérù 9:24) “Òun ni Ọlọ́run alààyè àti Ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Jeremáyà 10:10.
Níwọ̀n bí Jèhófà ti wà láàyè ní ti gidi, ó lè ronú ó sì lè gbé àwọn nǹkan ṣe. Ó ní àwọn ànímọ́, ó máa ń mọ nǹkan lára, ó sì láwọn ohun tó fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́. Ká sòótọ́, àìmọye gbólóhùn ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó máa ń múnú Ọlọ́run dùn àtàwọn ohun tó máa ń bí i nínú. Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe làwọn ọlọ́run àti òrìṣà táwọn èèyàn fọwọ́ ara wọn dá máa ń ní irú ìṣesí àtàwọn ànímọ́ àwọn èèyàn tó ṣe wọ́n, Ọlọ́run Olódùmarè, tó ń jẹ́ Jèhófà, gan-gan ló jẹ́ Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìmọ̀lára tó dá mọ́ èèyàn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Aísáyà 44:7-11.
Kò sí iyèméjì rárá pé “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà. (1 Tímótì 1:11) Kì í ṣe pé àwọn ohun tó dá máa ń múnú rẹ̀ dùn nìkan ni, ó tún máa ń láyọ̀ láti rí i pé ète òun yọrí sí rere. Nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà, Jèhófà kéde pé: “Gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe . . . Àní mo ti sọ ọ́; èmi yóò mú un wá pẹ̀lú. Mo ti gbé e kalẹ̀, èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.” (Aísáyà 46:9-11) Onísáàmù náà kọrin pé: “Jèhófà yóò máa yọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 104:31) Àmọ́ ohun mìíràn tún wà tó máa ń mú Ọlọ́run láyọ̀. Ó sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀.” (Òwe 27:11) Ronú ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ná—a lè mú Ọlọ́run láyọ̀!
Bí A Ṣe Lè Mú Ọkàn Ọlọ́run Yọ̀
Gbé bí baba ńlá náà, Nóà, ṣe mú ọkàn Jèhófà yọ̀ yẹ̀ wò. Nóà “rí ojú rere ní ojú Jèhófà” nítorí pé “ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀.” Nóà yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn búburú àkókò yẹn. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti ìgbọràn rẹ̀ múnú Ọlọ́run dùn débi pé, Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé, “Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:6, 8, 9, 22) “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà . . . fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn ó sì kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.” (Hébérù 11:7) Inú Jèhófà dùn sí Nóà ó sì bù kún òun àti ìdílé rẹ̀ nípa mímú wọn la àkókò oníyánpọnyánrin yẹn nínú ìtàn ìran èèyàn já.
Ábúráhámù baba ńlá náà pẹ̀lú lóye bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà gan-an. Ìmọ̀ kíkún tó ní nípa bí Ọlọ́run ṣe ń ronú hàn kedere nígbà tí Jèhófà fi tó o létí pé òun máa pa Sódómù àti Gòmórà run nítorí ìwàkíwà wọn. Ábúráhámù mọ Jèhófà dáadáa débi tó fi sọ pé, ká má rí i, Ọlọ́run ò jẹ́ pa olódodo run pẹ̀lú ẹni burúkú. (Jẹ́nẹ́sísì 18:17-33) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Ọlọ́run fún un ní ìtọ́ni kan, ó sì ṣègbọràn. Ńṣe ni “Kí a kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán,” nítorí “ó ṣírò pé Ọlọ́run lè gbé e dìde, àní kúrò nínú òkú.” (Hébérù 11:17-19; Jẹ́nẹ́sísì 22:1-18) Ábúráhámù lóye ìmọ̀lára Ọlọ́run gan-an ó sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó tún ṣègbọràn sí Ọlọ́run débi tó fi “di ẹni tí à ń pè ní ‘ọ̀rẹ́ Jèhófà.’”—Jákọ́bù 2:23.
Ọkùnrin mìíràn tóun náà tún sapá láti mú ọkàn Ọlọ́run yọ̀ ni Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì. Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Èmi ti rí Dáfídì ọmọkùnrin Jésè, ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà mi lọ́rùn, ẹni tí yóò ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́.” (Ìṣe 13:22) Ṣáájú kí Dáfídì tó lọ ko Gòláyátì òmìrán lójú, ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run ní kíkún ó sì sọ fún Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà, ẹni tí ó dá mi nídè kúrò ní àtẹ́sẹ̀ kìnnìún náà àti kúrò ní àtẹ́sẹ̀ béárì náà, òun ni ẹni tí yóò dá mi nídè kúrò ní ọwọ́ Filísínì yìí.” Jèhófà bù kún ìgbẹ́kẹ̀lé tí Dáfídì ní nínú Rẹ̀, ó mú kó ṣeé ṣe fún un láti pa Gòláyátì. (1 Sámúẹ́lì 17:37, 45-54) Láfikún sí àwọn ìṣe rẹ̀, Dáfídì tún fẹ́ kí ‘àwọn àsọjáde ẹnu rẹ̀ àti àṣàrò ọkàn-àyà rẹ̀ dùn mọ́ Jèhófà.’—Sáàmù 19:14.
Àwa náà ńkọ́? Báwo la ṣe lè múnú Jèhófà dùn? Bá a bá ṣe túbọ̀ ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára Ọlọ́run sí i, bẹ́ẹ̀ la óò túbọ̀ máa rí àwọn ohun tá a lè ṣe láti mú ọkàn Ọlọ́run yọ̀. Nítorí náà, bí a ti ń ka Bíbélì, ó ṣe pàtàkì pé ká máa sapá láti lóye ìmọ̀lára Ọlọ́run ká bàa “lè kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí [a] lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” (Kólósè 1:9, 10) Ìmọ̀ yìí ni yóò wá ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́. Èyí ṣe kókó nítorí pé “láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu [Ọlọ́run] dáadáa.” (Hébérù 11:6) Bẹ́ẹ̀ ni, nípa sísapá láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára àti nípa mímú ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ Jèhófà mu, a lè mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. Àmọ́, a tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́.
Má Ṣe Ba Jèhófà Lọ́kàn Jẹ́
Àpẹẹrẹ kan nípa bí ẹ̀dá èèyàn ṣe lè ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ la rí nínú ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Nóà. Ní àkókò yẹn, “ilẹ̀ ayé . . . wá kún fún ìwà ipá. Nítorí náà, Ọlọ́run rí ilẹ̀ ayé, sì wò ó! ó bàjẹ́, nítorí pé gbogbo ẹlẹ́ran ara ti ba ọ̀nà ara rẹ̀ jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” Báwo ló ṣe rí lára Ọlọ́run bó ti ń rí ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ipá náà? Bíbélì sọ pé: “Jèhófà . . . kẹ́dùn pé òun dá àwọn ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6, 11, 12) Ọlọ́run kẹ́dùn ní ti pé, ìwà àwọn èèyàn burú débi pé, ó yí èrò rẹ̀ padà sí ìran búburú tó wà ṣáájú Ìkún Omi yẹn. Nítorí pé inú Ọlọ́run bà jẹ́ látàrí ìwàkiwà wọn, ó yí padà sí wọn. Dípò ọwọ́ tó fi ń mú wọn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wọn, ó dẹni tó pa wọ́n run.
Inú Jèhófà tún bà jẹ́ nígbà tí àwọn èèyàn tirẹ̀ fúnra rẹ̀, ìyẹn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, ń bá a nìṣó láti ṣàìka ìmọ̀lára rẹ̀ àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ sí. Onísáàmù náà dárò pé: “Ẹ wo bí iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù ti pọ̀ tó, wọn a máa mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́ ní aṣálẹ̀! Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò, àní wọ́n ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” Síbẹ̀ “ó jẹ́ aláàánú; òun a sì bo ìṣìnà náà, kì yóò sì mú ìparun wá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sì mú kí ìbínú rẹ̀ yí padà, Kì í sì í ru gbogbo ìhónú rẹ̀ dìde.” (Sáàmù 78:38-41) Àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ ń jẹ, Bíbélì sọ fún wa pé “nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún [Ọlọ́run].”—Aísáyà 63:9.
Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ń fi ìyọ́nú hàn sí wọn, “wọ́n ń bá a lọ ní fífi àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà, títí ìhónú Jèhófà fi jáde wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí ìmúláradá.” (2 Kíróníkà 36:16) Níkẹyìn, nítorí pé wọ́n ń forí kunkun bá ìṣọ̀tẹ̀ nìṣó, wọ́n “ba ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́” débi pé wọ́n pàdánù ojú rere Jèhófà. (Aísáyà 63:10) Kí ni àbájáde rẹ̀? Ọlọ́run ṣe ohun tó yẹ fún wọn, ó mú ààbò rẹ̀ kúrò lórí wọn, àjálù sì dé bá wọn nígbà táwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè Júdà tí wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù run. (2 Kíróníkà 36:17-21) Ohun ìbànùjẹ́ mà ni o táwọn èèyàn bá yàn láti tọ ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀, èyí tó máa ń bí Ẹlẹ́dàá wọn nínú tó sì máa ń bà á lọ́kàn jẹ́!
Bíbélì jẹ́ kó yé wa kedere pé ìwàkiwà máa ń ba Ọlọ́run lọ́kàn jẹ́ gan-an. (Sáàmù 78:41) Lára àwọn ohun tó máa ń bí Ọlọ́run nínú, àní tó ń kó o nírìíra ni ìgbéraga, irọ́ pípa, ìpànìyàn, ṣíṣe iṣẹ́ òkùnkùn, wíwo iṣẹ́, jíjọ́sìn àwọn baba ńlá, ìṣekúṣe, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó, bíbá ìbátan ẹni lò pọ̀ àti níni àwọn aláìní lára.—Léfítíkù 18:9-29; 19:29; Diutarónómì 18:9-12; Òwe 6:16-19; Jeremáyà 7:5-7; Málákì 2:14-16.
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìbọ̀rìṣà? Ẹ́kísódù 20:4, 5 sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n.” Kí nìdí? Ó jẹ́ nítorí pé “ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ni [ère] jẹ́ lójú Jèhófà.” (Diutarónómì 7:25, 26) Àpọ́sítélì Jòhánù kìlọ̀ pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.” (1 Jòhánù 5:21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.”—1 Kọ́ríǹtì 10:14.
Máa Wá Ojú Rere Ọlọ́run
“Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ [Ọlọ́run] wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.” Àwọn tó jẹ́ “aláìlẹ́bi ní ọ̀nà wọn jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.” (Òwe 3:32; 11:20) Àmọ́ ní ti àwọn tó ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́, tí wọ́n ń ṣorí kunkun, tí wọ́n sì ń ṣàìka ìmọ̀lára rẹ̀ tó bá ọ̀nà òdodo mu sí, wọ́n yóò rí ìbínú rẹ̀ láìpẹ́. (2 Tẹsalóníkà 1:6-10) Àní, kò ní pẹ́ mọ́ tí yóò mú gbogbo ìwa ibi tó gbáyé kan lónìí kúrò.—Sáàmù 37:9-11; Sefanáyà 2:2, 3.
Àmọ́ ṣá o, Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Dípò kó máa wù ú láti bínú sáwọn tó kọ̀ láti jáwọ́ nínú ìwàkiwà wọn, ńṣe ló máa ń wù ú láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sáwọn olódodo tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jèhófà kì í dunnú sí “ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí padà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó ní tòótọ́.”—Ìsíkíẹ́lì 33:11.
Nítorí náà kò sí ìdí kankan to fi yẹ kí ẹnikẹ́ni di ẹni tí Jèhófà yóò bínú sí. “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jákọ́bù 5:11) Pẹ̀lú ìdánilójú pé Ọlọ́run á gbọ́ tìrẹ, “kó gbogbo àníyàn [rẹ] lé e, nítorí ó bìkítà fún [ọ].” (1 Pétérù 5:7) Jẹ́ kó dá ọ lójú pé àwọn tó ń mú ọkàn Ọlọ́run yọ̀ ní ìrètí àgbàyànú ti rírí ojú rere rẹ̀ àti jíjẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Nítorí náà, ó ti wá di kánjúkánjú báyìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ láti “máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.”—Éfésù 5:10.
Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu ló jẹ́ pé Ọlọ́run, nínú inú rere rẹ̀ àìlẹ́tọ̀ọ́sí, ṣí àwọn ànímọ́ rẹ̀ ológo àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀ payá fún wa! Ó sì dájú pé o lè mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. Bó o bá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ọ́ láti kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Inú wọn á dùn láti fi ohun tí wọ́n ti rí bí wọ́n ti ń sapá láti múnú Ọlọ́run dùn hàn ọ́, ó sì jẹ́ ohun tó ṣàǹfààní tọ́wọ́ sì lè tẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Kí Nìdí Tí Bíbélì Fi Lo Èdè Èèyàn Nígbà Tó Ń Sọ̀rọ̀ Nípa Ọlọ́run?”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Kí Nìdí Tí Bíbélì Fi Lo Èdè Èèyàn Nígbà Tó Ń Sọ̀rọ̀ Nípa Ọlọ́run?
Níwọ̀n bí “Ọlọ́run [ti] jẹ́ Ẹ̀mí,” a ò lè fi ojúyòójú wa rí i. (Jòhánù 4:24) Èyí ló fà á tí Bíbélì fi lo àwọn àkànlò èdè irú bí àfiwé tààrà, àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ àti èdè èèyàn, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run ká lè lóye agbára Ọlọ́run, ọlá ńlá rẹ̀ àtàwọn ìgbòkègbodò rẹ̀. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ bí ara ẹ̀mí tí Ọlọ́run ní ṣe rí, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní ojú, etí, ọwọ́, apá, ìka, ẹsẹ̀ àti ọkàn-àyà.—Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Ẹ́kísódù 3:20; 31:18; Jóòbù 40:9; Sáàmù 18:9; 34:15.
Irú àwọn èdè àpèjúwe bẹ́ẹ̀ kò wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni ẹ̀mí ní irú ẹ̀ya ara kan náà tí ẹ̀dá èèyàn ní o. Ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ ń jẹ́ kí ẹ̀dá èèyàn túbọ̀ lóye Ọlọ́run dáadáa. Láìlo irú àwọn àkànlò èdè bẹ́ẹ̀, yóò ṣòro gan-an, bó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe rárá, fún ẹ̀dá èèyàn lásánlàsàn láti lóye àpèjúwe kankan nípa Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ẹ̀dá èèyàn ló gbé èrò ara wọn kalẹ̀ nípa irú ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Bíbélì ṣàlàyé lọ́nà tó ṣe kedere pé, èèyàn ni a dá ní àwòrán Ọlọ́run, kì í ṣe Ọlọ́run ni a dá ní àwòrán èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Nítorí pé ‘Ọlọ́run ló mí sí’ àwọn tó kọ Bíbélì, ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ nípa rẹ̀ jẹ́ àpèjúwe tí òun fúnra rẹ̀ ṣe nípa àwọn ànímọ̀ rẹ̀, ìyẹn àwọn ànímọ́ tó fi sínú ẹ̀dá èèyàn tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ní onírúurú ìwọ̀n. (2 Tímótì 3:16, 17) Nítorí náà, dípò tí ì bá fi jẹ́ pé èèyàn ló kàn sọ pé Ọlọ́run ní àwọn ànímọ́ náà, wọ́n jẹ́ ànímọ́ tí Ọlọ́run dá mọ́ èèyàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Nóà rí ojú rere Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ábúráhámù mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Dáfídì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bó o bá ń ka Bíbélì, wàá mọ bó o ṣe lè múnú Ọlọ́run dùn
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Anglo-Australian Observatory, David Malin ló ya fọ́tò rẹ̀