ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 5/15 ojú ìwé 2-3
  • Akitiyan Aráyé Láti Múnú Ọlọ́run Dùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Akitiyan Aráyé Láti Múnú Ọlọ́run Dùn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibo Lo Ti Lè Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Ikú?
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • O Lè Múnú Ọlọ́run Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ta Ni Ó Ní Ojurere Ọlọrun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 5/15 ojú ìwé 2-3

Akitiyan Aráyé Láti Múnú Ọlọ́run Dùn

“KÒ SÍ àwùjọ ẹ̀dá kankan tí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kò ti kó ipa kan tàbí òmíràn. Wọ́n sábà máa ń kà á sí alákòóso àgbáyé àti Ẹlẹ́dàá. Kódà ọ̀rọ̀ kò yàtọ̀ láwọn àwùjọ tó pinnu láti má ṣe da ìsìn pọ̀ mọ́ ohun tó jẹ mọ́ tìlú.” Ohun tí John Bowker sọ nìyẹn nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní God—A Brief History (Ọlọ́run—Ìtàn Ṣókí Nípa Rẹ̀). Lọ́nà kan tàbí òmíràn, akitiyan láti wá Ọlọ́run rí àti láti rí ojú rere rẹ̀ jẹ́ ohun kan tá a sábà máa ń rí nínú ìwà ẹ̀dá. Níbi gbogbo lágbàáyé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló fi tọkàntọkàn fẹ́ láti múnú Ọlọ́run dùn. Àmọ́, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é sinmi lórí ẹ̀sìn kálukú.

Ìgbàgbọ́ àwọn kan ni pé gbogbo ohun téèyàn ní láti ṣe láti lè rí ojú rere Ọlọ́run kò ju pé kó máa gbé ìgbésí ayé rere lọ. Àwọn mìíràn sì gbà gbọ́ pé ìtọrẹ àánú táwọn ń ṣe fáwọn aláìní á jẹ́ káwọn rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. Nígbà tí ayẹyẹ ìsìn àtàwọn ààtò ìsìn sì ṣe pàtàkì gan-an sí ọ̀pọ̀ èèyàn.

Àmọ́ àwọn kan tún wà tí wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kò sí ní sàkáání èèyàn rárá, wọ́n ní ibi tó wà ti jìnnà jù, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ rẹ̀ dí fún àwọn nǹkan mìíràn débi pé kò ráyè tọmọ èèyàn. Epicurus tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí nílẹ̀ Gíríìsì ayé ọjọ́un la gbọ́ pé ó gbà gbọ́ pé ‘ibi táwọn ọlọ́run wà jìnnà débi pé wọn ò lè ṣe ọ́ níbi tàbí kí wọ́n ṣe ọ́ lóore kankan.’ Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ní irú àwọn èrò wọ̀nyí ló jẹ́ onísìn. Àwọn kan tiẹ̀ lè máa rúbọ tàbí kí wọ́n máa ṣe àwọn ààtò ìsìn nírètí àtitu àwọn baba ńlá wọn tó ti kú lójú.

Kí lèrò tìrẹ? Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ ń kíyè sí ìsapá wa láti rí ojú rere rẹ̀? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún wa láti ṣe ohun tó máa wọ Ọlọ́run lọ́kàn gan-an tó sì máa múnú rẹ̀ dùn?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda ROE/⁠Anglo-Australian Observatory, David Malin ló ya fọ́tò rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́