ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 9/1 ojú ìwé 15
  • ‘Jèhófà, Ìwọ Mọ̀ Mí’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Jèhófà, Ìwọ Mọ̀ Mí’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọrun Ha Mọ̀ Ọ́ Níti Gidi Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ọ̀rọ̀ Rẹ Yé Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Jèhófà Jẹ́ “Olùpèsè Àsálà” Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń kọ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Gbára Lé Ẹ̀mí Ọlọ́run Nígbà Tí Ipò Nǹkan Bá Yí Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 9/1 ojú ìwé 15

Sún Mọ́ Ọlọ́run

‘Jèhófà, Ìwọ Mọ̀ Mí’

“OHUN tó lè mú kí èèyàn ní ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀ jù lọ ni téèyàn bá mọ̀ pé, kò sí ẹnì kankan tó bìkítà nípa òun tàbí tó lóye òun.”a Ǹjẹ́ èyí ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Ǹjẹ́ ó ti ṣe ọ́ rí pé, ẹnì kankan kò bìkítà nípa ohun tó ń dà ẹ́ láàmú tàbí pé kò sẹ́ni tó lóye ohun náà, ká máa ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó máa tù ẹ́ nínú ni pé, Jèhófà bìkítà gan-an nípa àwọn olùjọsìn rẹ̀ débi pé, ó ń kíyè sí gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn lójoojúmọ́. Ohun tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 139 fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí.

Ó dá Dáfídì lójú pé, Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí.” (Ẹsẹ 1) Àfiwé tí Dáfídì lò níbí fani mọ́ra gan-an ni. Ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tí wọ́n pè ní ‘yẹ̀ wò látòkè délẹ̀’ nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn tún lè túmọ̀ sí gbígbẹ́ ilẹ̀ láti wa òkúta (Jóòbù 28:3), yíyẹ ilẹ̀ wò (Àwọn Onídàájọ́ 18:2), tàbí ṣíṣe ìwádìí láti mọ òótọ́ tó wà nínú ẹjọ́ kan (Diutarónómì 13:14). Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà mọ̀ wá gan-an bíi pé, ó ti mọ gbogbo nǹkan tó jẹ mọ́ ìgbésí ayé wa. Bí Dáfídì ṣe lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà, “mi,” kọ́ wa pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ó ń ṣàyẹ̀wò wọn, ó sì mọ̀ wọ́n lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

Dáfídì sọ bí àyẹ̀wò tí Ọlọ́run ń ṣe nípa èèyàn ṣe gbòòrò tó, ó ní: “Ìwọ alára ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi. Ìwọ ti gbé ìrònú mi yẹ̀ wò láti ibi jíjìnnàréré.” (Ẹsẹ 2) Ohun tí ìyẹn ń sọ ni pé, ọ̀run tó jẹ́ “ibi jíjìnnàréré,” ni Jèhófà ń gbé. Síbẹ̀, ó mọ ìgbà tí a jókòó, bóyá lẹ́yìn ọjọ́ kan tá a ti ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ ká ṣe tán àti ìgbà tá a dìde láàárọ̀ tá a sì ń bá ìgbòkègbodò wa lọ. Ó tún mọ èrò wa, ohun tó wù wá àtàwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe. Ǹjẹ́ bí Jèhófà ṣe ń ṣàyẹ̀wò Dáfídì kó ìnira bá Dáfídì? Rárá o, inú rẹ̀ dùn sí irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀. (Ẹsẹ 23, 24) Kí nìdí?

Dáfídì mọ̀ pé, èrò tó tọ́ ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn olùjọsìn rẹ̀. Dáfídì sọ nípa èrò tí Ọlọ́run ní yìí nígbà tó sọ pé: “Ìrìn àjò mi àti ìnàtàntàn mi lórí ìdùbúlẹ̀ ni ìwọ ti díwọ̀n, ìwọ sì ti wá mọ gbogbo ọ̀nà mi dunjú.” (Ẹsẹ 3) Jèhófà máa ń rí ‘gbogbo ọ̀nà wa’ lójoojúmọ́, ìyẹn àwọn àṣìṣe wa àtàwọn iṣẹ́ rere wa. Ṣé nǹkan tí kò dára tí a ṣe ló ń wò ni àbí nǹkan tó dára tí a ṣe? Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “díwọ̀n” lè túmọ̀ sí “sẹ́,” ìyẹn bí àgbẹ̀ ṣe ń sẹ́ pàǹtí kúrò nínú nǹkan oníhóró. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “ti wá mọ” tún lè túmọ̀ sí “láti ṣìkẹ́.” Nígbà tí Jèhófà bá ṣàyẹ̀wò ohun tí àwọn olùjọsìn rẹ̀ ń ṣe lójoojúmọ́, ó máa ń mọrírì àwọn ohun rere tí wọ́n bá ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé, ó mọyì ìsapá tí wọ́n ń ṣe láti ṣe ohun tí òun fẹ́.

Ìwé Sáàmù 139 kọ́ wa pé, Jèhófà bìkítà fún àwọn olùjọsìn rẹ̀ gan-an ni. Ó ń ṣàyẹ̀wò wọn látòkèdélẹ̀, ó sì ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí wọn bí wọ́n ti ń bá ìgbòkègbodò wọn lọ lójoojúmọ́. Nítorí náà, ó mọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ní, ó sì mọ ẹ̀dùn ọkàn tí àwọn ìṣòro náà ń fà. Ǹjẹ́ inú rẹ kò dùn láti jọ́sìn irú Ọlọ́run tó bìkítà bẹ́ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé, Jèhófà kò ní “gbàgbé iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́ tí o fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Hébérù 6:10.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún september:

◼ Sáàmù 119-150

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A fa ọ̀rọ̀ yìí yọ látinú ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Arthur H. Stainback tó jẹ́ òǹṣèwé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́