ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 9/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Láyọ̀?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Ṣe Ohun Tá Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára Sí I
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Béèyàn Ṣe Lè Láyọ̀ Nínú Ìgbéyàwó
    Jí!—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 9/1 ojú ìwé 16
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Báwo ni tọkọtaya ṣe lè láyọ̀?

Àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì nípa bí tọkọtaya ṣe lè láyọ̀ wúlò gan-an torí pé Jèhófà Ọlọ́run tó ṣètò ìgbéyàwó ló fún wa ni àwọn ìmọ̀ràn náà. Bíbélì kọ́ wa bí a ṣe lè ní àwọn ìwà tó máa mú kí ìdílé wa láyọ̀, ó sì kọ́ wa bí a ṣe lè yẹra fún àwọn ìwà tó lè da àárín tọkọtaya rú. Ó tún kọ́ wa bí tọkọtaya ṣe lè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ tí àwọn méjèèjì á sì máa láyọ̀.—Ka Kólósè 3:8-10, 12-14.

Ó yẹ kí tọkọtaya máa bọlá fún ara wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Tí àwọn méjèèjì bá ń ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run yàn fún wọn, wọ́n á máa láyọ̀.—Ka Kólósè 3:18, 19.

Kí ló lè jẹ́ kí tọkọtaya máa bá ara wọn gbé títí lọ?

Tí tọkọtaya bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, àjọgbé wọn á dùn. Ọlọ́run kọ́ wa bí a ṣe lè ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Àwòfiṣàpẹẹrẹ ni Ọlọ́run àti Jésù jẹ́ tó bá kan ti ká yááfì nǹkan kan nítorí àwọn èèyàn torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.—Ka 1 Jòhánù 4:7, 8, 19.

Tọkọtaya tó mọyì ètò ìgbéyàwó kò ní jẹ́ kí nǹkan kan yà wọ́n. Ọlọ́run tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ kò fẹ́ kí ìdílé tú ká, ó fẹ́ kí ọkọ àti aya wà pa pọ̀ títí láé. Tọkọtaya lè bá ara wọn kalẹ́, torí pé Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin lọ́nà tí wọ́n fi lè máa ran ara wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì máa gba ti ara wọn rò. Ó tún dá wọn ní àwòrán ara rẹ̀, lọ́nà tí wọ́n fi lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 2:18, 24.

Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 14 nínú ìwé yìí Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

O lè wà á jáde lórí www.jw.org

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́