ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 10/15 ojú ìwé 13-17
  • Ẹ̀yin Yóò Di “Ìjọba Àwọn Àlùfáà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Yóò Di “Ìjọba Àwọn Àlùfáà”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÁJẸ̀MÚ KAN TÓ DÁÀBÒ BO IRÚ-ỌMỌ NÁÀ
  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ TUNTUN WÁ SÓJÚTÁYÉ
  • MÁJẸ̀MÚ TUNTUN BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́
  • MÁJẸ̀MÚ KAN TÓ MÚ KÓ ṢEÉ ṢE FÁWỌN MÍÌ LÁTI ṢÀKÓSO PẸ̀LÚ KRISTI
  • NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÓ FẸSẸ̀ MÚLẸ̀ ṢINṢIN NÍNÚ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN
  • Majẹmu Titun Ti Ọlọrun Ń Súnmọ́ Àṣeparí Rẹ̀
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • You Can Benefit From the New Covenant
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ìbùkún Púpọ̀ Sí I Nípasẹ̀ Májẹ̀mú Tuntun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Májẹ̀mú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 10/15 ojú ìwé 13-17

Ẹ̀yin Yóò Di “Ìjọba Àwọn Àlùfáà”

“Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.”—Ẹ́KÍS. 19:6.

ǸJẸ́ O LÈ ṢÀLÀYÉ?

Lo àpótí tó ní àkòrí náà, “Bí Ọlọ́run Ṣe Máa Mú Ìfẹ́ Rẹ̀ Ṣẹ” láti fi ṣàlàyé . . .

  • májẹ̀mú Òfin.

  • májẹ̀mú tuntun.

  • májẹ̀mú Ìjọba.

1, 2. Ààbò wo ni irú-ọmọ obìnrin náà nílò, kí sì nìdí?

ÀSỌTẸ́LẸ̀ àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì kó ipa pàtàkì nínú bí Jèhófà ṣe máa mú ète rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ ń ṣe ìlérí ní ọgbà Édẹ́nì, ó sọ pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ [Sátánì] àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀.” Báwo ni ìṣọ̀tá yìí ṣe máa gbóná tó? Jèhófà sọ pé: “Òun [irú-ọmọ obìnrin náà] yóò pa ọ́ [Sátánì] ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́n. 3:15) Ìṣọ̀tá tó wà láàárín ejò náà àti obìnrin náà máa gbóná débi pé Sátánì máa sa gbogbo ipá rẹ̀ láti pa irú-ọmọ obìnrin náà run pátápátá.

2 Abájọ tí onísáàmù kan fi gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn èèyàn Rẹ̀ tó yàn, ó ní: “Wò ó! àní àwọn ọ̀tá rẹ wà nínú ìrọ́kẹ̀kẹ̀; àní àwọn tí ó kórìíra rẹ lọ́nà gbígbóná janjan ti gbé orí wọn sókè. Wọ́n ń bá ọ̀rọ̀ àṣírí wọn lọ lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí lòdì sí àwọn ènìyàn rẹ; wọ́n sì di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí àwọn tí ìwọ fi pa mọ́. Wọ́n ti wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a pa wọ́n rẹ́ kúrò ní jíjẹ́ orílẹ̀-èdè.’” (Sm. 83:2-4) Ààbò tó péye gbọ́dọ̀ wà lórí ìdílé tí irú-ọmọ obìnrin náà ti máa wá kí Sátánì má bàa pa ìdílé náà run tàbí kó sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin. Kí Jèhófà lè pèsè ààbò yìí, ó dá àwọn májẹ̀mú kan kó lè fi ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn pé ohun tí òun ṣèlérí máa ṣẹ.

MÁJẸ̀MÚ KAN TÓ DÁÀBÒ BO IRÚ-ỌMỌ NÁÀ

3, 4. (a) Ìgbà wo ni májẹ̀mú Òfin bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí sì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà láti máa ṣe? (b) Kí ni iṣẹ́ tí májẹ̀mú Òfin ṣe?

3 Bí àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ṣe ń dirú-digba, Jèhófà sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan, ìyẹn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì. Nípasẹ̀ Mósè, Jèhófà fún orílẹ̀-èdè náà ní Òfin, ó tipa bẹ́ẹ̀ dá májẹ̀mú àrà ọ̀tọ̀ kan pẹ̀lú wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gbà láti ṣe gbogbo ohun tí májẹ̀mú náà ní kí wọ́n ṣe. Bíbélì sọ pé: “[Mósè] mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á ní etí àwọn ènìyàn náà. Nígbà náà, wọ́n wí pé: ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe, a ó sì jẹ́ onígbọràn.’ Nítorí náà, Mósè mú ẹ̀jẹ̀ [àwọn akọ màlúù tí wọ́n fi rúbọ] náà, ó sì wọ́n ọn sára àwọn ènìyàn náà, ó sì wí pé: ‘Ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú náà rèé tí Jèhófà bá yín dá ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.’”—Ẹ́kís. 24:3-8.

4 Májẹ̀mú Òfin bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ní orí Òkè Sínáì. Ọlọ́run lo májẹ̀mú tó bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì dá láti fi sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè àyànfẹ́. Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ di, ‘Onídàájọ́ wọn, Ẹni tí ń fún wọn ní ìlànà àgbékalẹ̀ àti Ọba wọn.’ (Aísá. 33:22) Ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá pa ìlànà òdodo Ọlọ́run mọ́ àti ìgbà tí wọn ò bá pá a mọ́. Òfin náà sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn Kèfèrí, wọn kò sì gbọ́dọ̀ dá sí ìjọsìn èké wọn, torí náà, Òfin yìí máa dáàbò bo ìlà ìran Ábúráhámù, kó má bàa di ẹlẹ́gbin.—Ẹ́kís. 20:4-6; 34:12-16.

5. (a) Àǹfààní wo ló ṣí sílẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi kọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀?

5 Májẹ̀mú Òfin tún ní ìṣètò fún àlùfáà, èyí sì ń ṣàpẹẹrẹ ìṣètò kan tó ga jù lọ tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 7:11; 10:1) Kódà májẹ̀mú yẹn mú kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan, wọ́n máa di “ìjọba àwọn àlùfáà” tí wọ́n bá ń ṣègbọràn sí àwọn òfin Jèhófà. (Ka Ẹ́kísódù 19:5, 6.) Àmọ́, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ò pa òfin Jèhófà mọ́. Kàkà kí orílẹ̀-èdè náà gba Mèsáyà tó jẹ́ apá àkọ́kọ́ lára irú-ọmọ Ábúráhámù tayọ̀tayọ̀, ńṣe ni wọ́n kọ̀ ọ́. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi kọ orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ti pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn kò túmọ̀ sí pé májẹ̀mú Òfin ti kùnà (Wo ìpínrọ̀ 3 sí 6)

6. Kí ni Òfin náà wà fún?

6 Ti pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kùnà láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, tí wọn kò sì di ìjọba àwọn àlùfáà kò túmọ̀ sí pé Òfin náà ti kùnà. Ohun tí Òfin náà wà fún ni pé kó dáàbò bo irú-ọmọ náà kó sì mú káwọn èèyàn mọ Mèsáyà. Nígbà tí Kristi dé, táwọn èèyàn sì ti dá a mọ, Òfin yẹn ti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run tìtorí rẹ̀ gbé e kalẹ̀ nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Kristi ni òpin Òfin.” (Róòmù 10:4) Àmọ́, ìbéèrè kan ṣì wà tí kò tíì níyanjú: Àwọn wo ló máa láǹfààní láti di ìjọba àwọn àlùfáà? Jèhófà Ọlọ́run dá májẹ̀mú míì tó fìdí múlẹ̀ tó máa fi mú orílẹ̀-èdè tuntun kan jáde.

ORÍLẸ̀-ÈDÈ TUNTUN WÁ SÓJÚTÁYÉ

7. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jèhófà tipasẹ̀ Jeremáyà sọ nípa májẹ̀mú tuntun?

7 Tipẹ́tipẹ́ kí Jèhófà tó fagi lé májẹ̀mú Òfin, ó tipasẹ̀ wòlíì Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Òun máa bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá “májẹ̀mú tuntun.” (Ka Jeremáyà 31:31-33.) Májẹ̀mú yìí yàtọ̀ pátápátá, kò ní sí pé èèyàn ń fi ẹran rúbọ kí Ọlọ́run tó lè dárí jì í gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú májẹ̀mú Òfin. Báwo lèyí ṣe máa ṣẹlẹ̀?

8, 9. (a) Kí ni ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rúbọ mú kó ṣeé ṣe? (b) Àǹfààní wo ló ṣí sílẹ̀ fún àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

8 Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ ní Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ mọ́kànlá pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.” (Lúùkù 22:20) Ohun tí àkọsílẹ̀ Mátíù jẹ́ ká mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Jésù yìí ni pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.”—Mát. 26:27, 28.

9 Ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rúbọ ló fìdí májẹ̀mú tuntun múlẹ̀. Bákan náà, ẹ̀jẹ̀ Jésù yìí mú kó ṣeé ṣe láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo àti títí láé. Jésù kò sí lára àwọn tí májẹ̀mú tuntun kàn. Ìdí ni pé kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, torí náà, kò nílò ìdáríjì. Àmọ́, Ọlọ́run lo ìtóye ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rúbọ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù. Jèhófà tún sọ àwọn kan tó yà sọ́tọ̀ nínú aráyé di “ọmọ,” ó ṣe èyí nípa fífi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. (Ka Róòmù 8:14-17.) Lójú Ọlọ́run, wọn kò lẹ́ṣẹ̀ kankan lọ́rùn, torí náà, lọ́nà kan wọn yóò dà bí Jésù, Ọmọ Ọlọ́run tí kò dẹ́ṣẹ̀ kankan. Àwọn ẹni àmì òróró yìí yóò di “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi,” wọ́n á sì láǹfààní láti di “ìjọba àwọn àlùfáà,” àǹfààní tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú Òfin gbé sọ nù. Àpọ́sítélì Pétérù sọ ohun kan nípa àwọn tó máa jẹ́ “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi,” ó ní: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pét. 2:9) Ẹ ò rí i pé májẹ̀mú tuntun yìí ṣe pàtàkì gan-an! Ó mú kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti di apá kejì lára irú-ọmọ Ábúráhámù.

MÁJẸ̀MÚ TUNTUN BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́

10. Ìgbà wo ni májẹ̀mú tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí sì nìdí tí kò fi bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn?

10 Ìgbà wo ni májẹ̀mú tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́? Kò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn. Kí májẹ̀mú tuntun tó lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, Jésù gbọ́dọ̀ fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rúbọ, kó sì gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ náà lọ síwájú Jèhófà lókè ọ̀run. Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ gbọ́dọ̀ bà lé àwọn “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.” Torí náà, májẹ̀mú tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Pẹ́ńtíkọ́ọ̀sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà ti Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin.

11. Báwo ni májẹ̀mú tuntun ṣe mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí láti di apá kan lára Ísírẹ́lì tẹ̀mí, àwọn mélòó ló sì máa wà nínú májẹ̀mú tuntun náà?

11 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé májẹ̀mú Òfin ti di “aláìbódemu” mọ́ nígbà tí Jèhófà sọ nípasẹ̀ Jeremáyà pé òun máa dá májẹ̀mú tuntun pẹ̀lú Ísírẹ́lì, májẹ̀mú Òfin kò ṣíwọ́ iṣẹ́ títí dìgbà tí májẹ̀mú tuntun fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. (Héb. 8:13) Ìgbà tí májẹ̀mú tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni Ọlọ́run tó lè fojú kan náà wo àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ tí wọ́n di onígbàgbọ́ torí pé ‘ìdádọ̀dọ́ wọn jẹ́ ti ọkàn-àyà nípasẹ̀ ẹ̀mí, kì í sì í ṣe nípasẹ̀ àkójọ òfin tí a kọ sílẹ̀.’ (Róòmù 2:29) Nígbà tí Ọlọ́run sì bá wọn dá májẹ̀mú tuntun, ńṣe ló máa fi òfin rẹ̀ “sínú èrò inú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni . . . yóò kọ wọ́n sí.” (Héb. 8:10) Iye àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun yẹn yóò jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], àwọn ló máa di orílẹ̀-èdè tuntun tí a mọ̀ sí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí.—Gál. 6:16; Ìṣí. 14:1, 4.

12. Ìfiwéra wo ló wà láàárín májẹ̀mú Òfin àti májẹ̀mú tuntun?

12 Ìfiwéra wo ló wà láàárín májẹ̀mú Òfin àti májẹ̀mú tuntun? Májẹ̀mú Òfin wà láàárín Jèhófà àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, májẹ̀mú tuntun náà wà láàárín Jèhófà àti Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Mósè ni alárinà májẹ̀mú Òfin, Jésù sì jẹ́ Alárinà májẹ̀mú tuntun. Májẹ̀mú Òfin fẹsẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ẹran, májẹ̀mú tuntun fẹsẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rúbọ. Bí Mósè ṣe jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù, tó jẹ́ Orí ìjọ ṣe jẹ́ aṣáájú fún àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun.—Éfé. 1:22.

13, 14. (a) Kí ni májẹ̀mú tuntun ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba náà? (b) Kí ló ṣe pàtàkì kí Ísírẹ́lì tẹ̀mí tó lè ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run?

13 Àjọṣe wà láàárín májẹ̀mú tuntun àti Ìjọba Ọlọ́run torí pé májẹ̀mú yẹn ló pèsè orílẹ̀-èdè mímọ́ tó láǹfààní láti di àwọn ọba àti àlùfáà nínú Ìjọba ọ̀run. Orílẹ̀-èdè yẹn ló sì para pọ̀ di apá kejì lára irú-ọmọ Ábúráhámù. (Gál. 3:29) Torí náà, májẹ̀mú tuntun túbọ̀ mú kí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá fẹsẹ̀ múlẹ̀.

14 Àmọ́, ó ṣì ku apá kan nínú Ìjọba Ọlọ́run tí kò tíì fìdí múlẹ̀. Májẹ̀mú tuntun ló mú Ísírẹ́lì Ọlọ́run jáde, òun ló sì mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó wà nínú májẹ̀mú yìí láti di “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.” Àmọ́ kí wọ́n tó lè dara pọ̀ mọ́ Jésù nínú Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba àti àlùfáà ní ọ̀run, májẹ̀mú tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọ́dọ̀ wà.

MÁJẸ̀MÚ KAN TÓ MÚ KÓ ṢEÉ ṢE FÁWỌN MÍÌ LÁTI ṢÀKÓSO PẸ̀LÚ KRISTI

15. Májẹ̀mú wo ni Jésù fúnra rẹ̀ bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ dá?

15 Lẹ́yìn tí Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwá sílẹ̀, ó dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́, májẹ̀mú náà la sábà máa ń pè ní májẹ̀mú Ìjọba. (Ka Lúùkù 22:28-30.) Májẹ̀mú yìí yàtọ̀ sáwọn yòókù, torí pé Jèhófà wà lára àwọn tí májẹ̀mú yòókù kàn. Àmọ́, májẹ̀mú Ìjọba wà láàárín Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. Nígbà tí Jésù sọ pé, “gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan,” ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí májẹ̀mú tí Jèhófà dá pẹ̀lú rẹ̀ pé ó máa jẹ́ “àlùfáà títí láé ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì.”—Héb. 5:5, 6.

16. Kí ni májẹ̀mú Ìjọba náà mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn?

16 Àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ‘ti dúró ti Jésù gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò rẹ̀.’ Májẹ̀mú Ìjọba mú kó dá wọn lójú pé wọ́n máa wà pẹ̀lú Jésù lókè ọ̀run, wọ́n á sì jókòó lórí ìtẹ́ kí wọ́n lè ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba àti àlùfáà. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn mọ́kànlá náà nìkan ló máa ní àǹfààní yẹn. Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo bá àpọ́sítélì Jòhánù sọ̀rọ̀ nínú ìran, ó sì sọ fún un pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, àní gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.” (Ìṣí. 3:21) Torí náà, gbogbo àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], ni Jésù bá dá májẹ̀mú Ìjọba náà. (Ìṣí. 5:9, 10; 7:4) Májẹ̀mú yìí ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. Ńṣe ló dà bí obìnrin kan tí ọba fi ṣe aya, gbàrà tí wọ́n bá ṣègbéyàwó ni obìnrin náà ti láǹfààní láti máa ṣàkóso pẹ̀lú ọba. Kódà, Ìwé Mímọ́ pe àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ni “ìyàwó” Kristi, ó ní wọ́n jẹ́ “wúńdíá oníwàmímọ́” tí ó ń fojú sọ́nà láti fẹ́ Kristi.—Ìṣí. 19:7, 8; 21:9; 2 Kọ́r. 11:2.

NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÓ FẸSẸ̀ MÚLẸ̀ ṢINṢIN NÍNÚ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN

17, 18. (a) Ṣàlàyé ní ṣókí bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn májẹ̀mú mẹ́fà tá a ti jíròrò ṣe jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (b) Kí nìdí tá a fi ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ìjọba Ọlọ́run?

17 Àwọn májẹ̀mú tá a ti jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjì yìí dá lórí apá kan pàtàkì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Wo àpótí tó ní àkòrí náà, “Bí Ọlọ́run Ṣe Máa Mú Ìfẹ́ Rẹ̀ Ṣẹ.”) Àwọn ohun tá a ti kọ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba náà fìdí múlẹ̀ ṣinṣin lórí àwọn májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá. Torí náà, a ní ìdí tó ṣe pàtàkì tó fi yẹ ká fọkàn tán Ìjọba Mèsáyà pátápátá, torí a mọ̀ pé òun ni Ọlọ́run ń lò láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún ayé àti ìran èèyàn.—Ìṣí. 11:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Jèhófà máa lo Ìjọba Mèsáyà láti fi mú ohun tó ní lọ́kàn fún ayé ṣẹ (Wo ìpínrọ̀ 15 sí 18)

18 Láìsí àní-àní, àwọn ohun tí Ìjọba Ọlọ́run ń gbé ṣe máa yọrí sí ìbùkún ayérayé fún ìran èèyàn. Torí náà, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún tí a ní nínú Jèhófà, a lè polongo láìsí iyèméjì pé Ìjọba Ọlọ́run ni ojútùú kan ṣoṣo tó máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé títí láé. Ǹjẹ́ ká máa fìtara wàásù òtítọ́ yìí fáwọn èèyàn!—Mát. 24:14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́