ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 10/15 ojú ìwé 18-22
  • Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nígbèésí Ayé Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nígbèésí Ayé Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÍ ÌDÍLÉ WA ṢE KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́
  • IṢẸ́ ÌSÌN TÍ ÌDÍLÉ WA ṢE
  • MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN MÍṢỌ́NNÁRÌ
  • ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ TÁWỌN ÈÈYÀN BỌ̀WỌ̀ FÚN DI ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ
  • MI Ò KÁBÀÁMỌ̀ ÀWỌN ÌPINNU TÍ MO ṢE
  • Pípa Gbogbo Àfiyèsí Pọ̀ Sórí Ẹ̀bùn náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Jèhófà Ti Ràn Mí Lọ́wọ́ Ní Ti Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Mo Láyọ̀ Nítorí Pé Mi Ò Jáwọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • ‘Alayọ ni Gbogbo Awọn Wọnni Ti Nduro De Jehofa’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 10/15 ojú ìwé 18-22

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nígbèésí Ayé Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

Gẹ́gẹ́ bí Mildred Olsonṣe sọ ọ́

Ní ọdún 1947, àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní ìlú Santa Ana, lórílẹ̀-èdè El Salvador, fẹ́ dá iná ìjàngbọ̀n sílẹ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà táwọn ará ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lọ́wọ́, àwọn ọmọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ òkúta ńláńlá sínú ilé àwọn míṣọ́nnárì láti ẹnu ilẹ̀kùn tó ṣí sílẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn ni àwọn àlùfáà wá kó àwọn èrò sòdí wá sí ilé àwọn míṣọ́nnárì. Àwọn kan láàárín èrò náà gbé ògùṣọ̀ dání, àwọn míì mú ère dání. Wákàtí méjì gbáko ni wọ́n fi ń sọ òkúta lu ilé náà, wọ́n sì ń pariwo gèè, wọ́n ní: “Kí ẹ̀mí Wúńdíá náà gùn!” wọ́n á tún ní, “Kí Jèhófà kú!” Ńṣe ló yẹ kí ohun tí wọ́n ṣe yìí dẹ́rù ba àwọn míṣọ́nnárì kí wọ́n sì kúrò ní ìlú náà. Mo mọ̀ pé bó ṣe rí lára wọn nìyẹn torí pé mo wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà. Ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] sẹ́yìn ni ìpàdé yẹn wáyé.a

ỌDÚN méjì ṣáájú kí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn tó wáyé ni mo kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹrin ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ìlú Ithaca, ní ìpínlẹ̀ New York ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí nígbà yẹn. Èmi àti Evelyn Trabert ni wọ́n gbé lọ sí ìlú Santa Ana lórílẹ̀-èdè El Salvador. Ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [29] ni mo fi ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì níbẹ̀. Àmọ́ kí n tó sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìsìn mi, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ìdí tí mo fi pinnu láti ṣe iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì.

BÍ ÌDÍLÉ WA ṢE KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́

Ọdún 1923 ni wọ́n bí mi ní ìlú Spokane ní ìpínlẹ̀ Washington lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. John àti Eva Olson lorúkọ àwọn òbí mi. Ọmọ ìjọ Luther làwọn òbí mi, àmọ́ wọn ò gba ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì gbọ́, torí ẹ̀kọ́ yìí ta ko ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́. (1 Jòh. 4:8) Ilé iṣẹ́ búrẹ́dì ni bàbá mi ti ń ṣiṣẹ́. Lálẹ́ ọjọ́ kan, ọkùnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sọ fún bàbá mi pé Bíbélì kò kọ́ni pé ibi téèyàn ti ń joró ni hẹ́ẹ̀lì. Kò pẹ́ sígbà yẹn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn òbí mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìgbà yẹn ni wọ́n tó mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa ipò táwọn òkú wà.

Mi ò ju ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lọ nígbà yẹn, àmọ́ mo rántí bí àwọn òbí mi ṣe máa ń fi ìtara sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nínú Bíbélì. Ìtara wọn túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ náà, wọ́n wá rí i pé ẹ̀kọ́ èké ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lóye àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ dáadáa, ńṣe ló dà bí ìgbà tí tìmùtìmù bá fa omi mu, bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe ń lóye ẹ̀kọ́ ‘òtítọ́ tí ń dáni sílẹ̀ lómìnira.’ (Jòh. 8:32) Ní tèmi, kì í sú mi láti ka Bíbélì, mo fẹ́ràn kí n máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú máa ń tì mí, mo máa ń tẹ̀ lé àwọn òbí mi lọ sí òde ẹ̀rí. Ọdún 1934 làwọn òbí mi ṣèrìbọmi, èmi náà sì ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún lọ́dún 1939.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Èmi rèé láàárín Mọ́mì àti Dádì mi ní àpéjọ tá a ṣe lọ́dún 1941 ní ìlú St.  Louis, ní ìpínlẹ̀ Missouri

Ní oṣù July ọdún 1940, àwọn òbí mi ta ilé wọn, a sì jọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, à ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní àgbègbè Coeur d’Alene, ní ìpínlẹ̀ Idaho. Inú ilé kan táwọn òbí mi rẹ́ǹtì ni à ń gbé, ilé náà wà lókè ṣọ́ọ̀bù kan tí wọ́n ti ń tún mọ́tò ṣe. Wọ́n máa ń ṣe ìpàdé ìjọ ní ilé wa, torí pé nígbà yẹn ìwọ̀nba ìjọ díẹ̀ ló ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń ṣe ìpàdé nílé àwọn ará tàbí nílé tí wọ́n bá rẹ́ǹtì.

Lọ́dún 1941, èmi àti àwọn òbí mi lọ sí àpéjọ kan ní ìlú St.  Louis, ní ìpínlẹ̀ Missouri lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. “Ọjọ́ Àwọn Ọmọdé” ni ọjọ́ Sunday àpéjọ náà, àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ ọdún márùn-ún sí ọdún méjìdínlógún ló jókòó sí ọwọ́ iwájú pèpéle náà. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Arákùnrin Joseph F. Rutherford parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó bá àwa ọmọdé sọ̀rọ̀, ó ní: “Gbogbo yín . . . ẹ̀yin ọmọdé . . . tẹ́ ẹ ti gbà láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti Ọba rẹ̀, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dìde dúró!” Gbogbo àwa ọmọdé dìde dúró. Lẹ́yìn ìyẹn Arákùnrin Rutherford sọ ní ohùn rara pé: “Ẹ wò ó, àwọn tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000] ẹlẹ́rìí tuntun fún Ìjọba náà!” Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ló mú kí n túbọ̀ pinnu pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni màá fi ìgbésí ayé mi ṣe.

IṢẸ́ ÌSÌN TÍ ÌDÍLÉ WA ṢE

Oṣù mélòó kan lẹ́yìn àpéjọ tí a ṣe ní ìlú St. Louis, ìdílé wa kó lọ sí apá gúúsù ìpínlẹ̀ California. A lọ sí ìlú Oxnard ká lè lọ dá ìjọ tuntun sílẹ̀ níbẹ̀. Inú ọkọ̀ àfiṣelé kékeré kan là ń gbé, bẹ́ẹ̀dì kan ló wà nínú rẹ̀. Alaalẹ́ la máa ń palẹ̀ orí tábìlì tí a ti máa ń jẹun mọ́, torí orí rẹ̀ ni mò ń tẹ́ ohun tí màá fi sùn lé, èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìgbà tí mo ní yàrá tèmi!

Ṣáájú kí a tó kó lọ sí ìpínlẹ̀ California, orílẹ̀-èdè Japan ju bọ́ǹbù sí àgbègbè Pearl Harbor ní ìpínlẹ̀ Hawaii ní December 7, ọdún 1941. Ọjọ́ kejì ni Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn aláṣẹ pàṣẹ pé kí ibi gbogbo máa wà nínú òkùnkùn biribiri, torí náà a kì í tan iná nínú ilé tó bá ti di alẹ́. Àwọn ọkọ̀ abẹ́ omi ti orílẹ̀-èdè Japan ń lọ káàkiri etíkun California, àmọ́ òkùnkùn tó ṣú biribiri kò jẹ́ kí wọ́n lè rí ibi ṣọṣẹ́ fáwọn tó wà lórí ilẹ̀.

Oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, ní oṣù September ọdún 1942, a lọ sí ìlú Cleveland ní ìpínlẹ̀ Ohio láti lọ ṣe Àpéjọ ti Ayé Tuntun Lábẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Arákùnrin Nathan H. Knorr sọ àsọyé kan níbẹ̀, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Àlàáfíà—Ǹjẹ́ Ó Lè Wà Pẹ́?” Ó ṣàlàyé ìwé Ìṣípayá orí 17, tó ṣàpèjúwe “ẹranko ẹhànnà” tó “ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí, síbẹ̀ ó máa tó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” (Ìṣí. 17:8, 11) Arákùnrin Knorr ṣàlàyé pé àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni “ẹranko ẹhànnà” náà, àmọ́ nígbà tó máa fi di ọdún 1939 kò sí mọ́. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àjọ míì máa rọ́pò Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn á sì mú kí àlàáfíà díẹ̀ wà. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, Ogun Àgbáyé Kejì dópin lọ́dún 1945. Lẹ́yìn náà, “ẹranko ẹhànnà” pa dà wá gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Nígbà yẹn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere náà kárí ayé, ìbísí náà ò sì dáwọ́ dúró títí dòní!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ìwé ẹ̀rí tí mo gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì rèé

Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ kí n mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Inú mi dùn nígbà tí wọ́n ṣe ìfilọ̀ pé Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì máa bẹ̀rẹ̀ lọ́dún tó tẹ̀ lé e, torí ó wù mí gan-an láti di míṣọ́nnárì. Ní ọdún 1943, wọ́n ní kí n lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Portland, ní ìpínlẹ̀ Oregon. Tí a bá lọ sóde ẹ̀rí nígbà yẹn, tí a bá dé ẹnu ọ̀nà onílé, a máa ń ní kí wọ́n tẹ́tí sí ìwàásù tí a gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ sínú ẹ̀rọ giramafóònù. Lẹ́yìn ìyẹn a máa fún wọn ní ìwé ìròyìn tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ní gbogbo ọdún yẹn, ìrònú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ló gbà mí lọ́kàn.

Lọ́dún 1944, inú mi dùn gan-an nígbà tí èmi àti ọ̀rẹ́ mi Evelyn Trabert gba ìwé ìkésíni sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Oṣù márùn-ún gbáko làwọn olùkọ́ wa fi kọ́ wa bí a ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí a sì gbádùn rẹ̀. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wọn wú wa lórí gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nígbà míì tí a bá ń jẹun, àwọn ló máa ń gbé oúnjẹ fún wa. A kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní January 22, ọdún 1945.

MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN MÍṢỌ́NNÁRÌ

Lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ náà, ètò Ọlọ́run rán èmi, Evelyn, Leo àti Esther Mahan lọ sí orílẹ̀-èdè El Salvador, a sì dé síbẹ̀ ní oṣù June ọdún 1946. Nígbà tí a débẹ̀, a rí i pé pápá náà “funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35) Ìṣẹ̀lẹ̀ tí mo sọ pé ó wáyé nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi fi hàn pé inú ń bí àwọn àlùfáà burúkú-burúkú. Ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú kí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn tó wáyé ni a ṣe àpéjọ àyíká àkọ́kọ́ ní ìlú Santa Ana. Ṣáájú àpéjọ yẹn, a polongo àsọyé náà káàkiri, inú wa dùn pé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èèyàn ló wá sí àpéjọ náà. Dípò kí ẹ̀rù bà wá ká sì kúrò ní ìlú náà, ńṣe la túbọ̀ pinnu láti ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ lọ́wọ́. Yàtọ̀ sí pé àwọn àlùfáà ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé wọn kò gbọ́dọ̀ ka Bíbélì, tó sì jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn kéréje lo lówó tó máa fi ra Bíbélì, ọ̀pọ̀ ni ebi tẹ̀mí ń pa. Inú àwọn èèyàn náà dùn nígbà tí wọ́n rí i pé à ń kọ́ èdè Sípáníìṣì torí ká lè kọ́ wọn nípa Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ àti ìlérí àgbàyanu tó ṣe láti mú kí ayé pa dà di Párádísè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwa márùn-ún nínú àwa tí a jọ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ni wọ́n rán lọ sí orílẹ̀-èdè El Salvador. Láti apá òsì lọ sí apá ọ̀tún: Evelyn Trabert, Millie Brashier, Esther Mahan, èmi, àti Leo Mahan

Rosa Ascencio lorúkọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè El Salvador. Lẹ́yìn tí obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó pínyà kúrò lọ́dọ̀ ọkùnrin tó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n ṣègbéyàwó, lẹ́yìn ìyẹn wọ́n ṣèrìbọmi, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi ìtara wàásù. Rosa Ascencio ni aṣáájú-ọ̀nà àkọ́kọ́ ní ìlú Santa Ana.b

Rosa Ascencio ní ilé ìtajà kékeré kan. Rosa máa ń ti ilé ìtajà rẹ̀ pa tó bá ń lọ sóde ẹ̀rí, ó ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà máa pèsè ohun tí òun nílò. Tó bá dé láti òde ẹ̀rí tó wá ṣí ilé ìtajà rẹ̀, ńṣe làwọn oníbàárà máa ń rọ́ wá ra ọjà. Rosa rí i fúnra rẹ̀ pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nínú ìwé Mátíù 6:33. Ó sì jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú.

Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí àlùfáà lọ bá ọkùnrin kan tí àwa míṣọ́nnárì mẹ́fà rẹ́ǹtì ilé lọ́wọ́ rẹ̀, àlùfáà náà sọ fún onílé wa pé tí kò bá lé wa jáde nínú ilé rẹ̀, wọ́n máa lé e kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì. Oníṣòwò tó gbajúmọ̀ ni onílé wa yìí. Kò tiẹ̀ jẹ́ kí gbogbo bí wọ́n ṣe ń dún mọ̀huru-mọ̀huru dẹ́rù bà á àti pé ìwàkiwà tí àwọn àlùfáà yẹn ń hù ti sú u. Kódà, ó sọ fún àlùfáà náà pé òun ò kọ kí wọ́n lé òun kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ó sọ fún wa pé òun gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ títí dìgbà tó bá wù wá láti kúrò nílé òun.

ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ TÁWỌN ÈÈYÀN BỌ̀WỌ̀ FÚN DI ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n kọ́ lọ́dún 1955

Ní olú ìlú orílẹ̀-èdè tí a ti ń sìn, ìyẹn San Salvador, arábìnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì ń kọ́ ìyàwó ẹnjiníà kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Baltasar Perla lorúkọ ẹnjiníà náà. Ọkùnrin yìí ní ọkàn tó dáa, àmọ́ ìwà àgàbàgebè tó rí táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń hù ló fà á tí kò fi gba Ọlọ́run gbọ́. Nígbà tí wọ́n fẹ́ kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí orílẹ̀-èdè El Salvador, Ọ̀gbẹ́ni Baltasar sọ pé òun máa ya àwòrán ilé náà, òun sì máa kọ́ ọ láìgba owó iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀gbẹ́ni yìí ò sì tíì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà yẹn.

Bí Ọ̀gbẹ́ni Baltasar ṣe bá àwọn èèyàn Jèhófà ṣiṣẹ́ tó sì rí i bí wọ́n ṣe ń hùwà mú kó dá a lójú pé òun ti rí ẹ̀sìn tòótọ́. Ó ṣèrìbọmi ní July 22, ọdún 1955, láìpẹ́ sígbà yẹn Paulina ìyàwó rẹ̀ náà ṣèrìbọmi. Kódà, ọmọ wọn méjèèjì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn báyìí. Ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta [49] ni ọmọkùnrin wọn tó ń jẹ́ Baltasar, Jr., fi ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn, níbi tó ti ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Ní báyìí, ó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.c

Nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àpéjọ àgbègbè ní ìlú San Salvador, Arákùnrin Perla bá wa ṣètò gbọ̀ngàn eré ìdárayá ńlá kan tí a ti ṣe àpéjọ náà. Torí pé a ò pọ̀, ìwọ̀nba ìjókòó díẹ̀ la máa ń lò nínú gbọ̀ngàn yẹn nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó, àmọ́ a rí ìbùkún Jèhófà torí pé ọdọọdún ni iye wa ń pọ̀ sí i, títí tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún inú gbọ̀ngàn náà. Kódà nígbà tó yá, inú gbọ̀ngàn yẹn ò gba iye èrò tó ń wá ṣèpàdé mọ́! Nírú àwọn àkókò aláyọ̀ bẹ́ẹ̀, mo máa ń pàdé àwọn tí mo ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ayọ̀ kún inú ọkàn mi nígbà tí àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi àwọn tí mo lè pè ní ọmọ-ọmọ mi nípa tẹ̀mí hàn mí, ìyẹn àwọn tí wọ́n kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ náà!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Arákùnrin F. W. Franz ń bá àwa míṣọ́nnárì sọ̀rọ̀ ní àpéjọ kan

Ní àpéjọ kan tá a ṣe, arákùnrin kan wá bá mi, ó ní òun fẹ́ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ òun. Mi ò mọ arákùnrin yìí, àmọ́ mo fẹ́ gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ. Ó ní, “Mo wà lára àwọn ọmọkùnrin tó ń sọ òkúta lù yín ní ìlú Santa Ana.” Ní báyìí òun náà ti ń sin Jèhófà. Ayọ̀ mi kún gan-an. Ọ̀rọ̀ tí èmi àti arákùnrin yẹn jọ sọ mú kó dá mi lójú pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni ohun tó dára jù lọ téèyàn lè fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àpéjọ àyíká tí a kọ́kọ́ ṣe lórílẹ̀-èdè El Salvador

MI Ò KÁBÀÁMỌ̀ ÀWỌN ÌPINNU TÍ MO ṢE

Nǹkan bí ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [29] ni mo fi ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè El Salvador, ìlú Santa Ana ni mo ti bẹ̀rẹ̀, mo wa lọ sí ìlú Sonsonate, lẹ́yìn ìyẹn mo lọ sìn ní Santa Tecla, ìlú San Salvador ni mo sì ti sìn kẹ́yìn. Lọ́dún 1975, mo pinnu láti fi iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì sílẹ̀ lẹ́yìn tí mo ti gbàdúrà dáadáa nípa rẹ̀, mo sì pa dà sí ìlú Spokane. Àwọn òbí mi tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà ti darúgbó báyìí, wọ́n sì nílò àmójútó.

Lẹ́yìn tí Bàbá mi kú lọ́dún 1979, èmi ni mò ń tọ́jú Màmá mi torí wọn ò lè dá ṣe nǹkan kan mọ́, ara wọn sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Màmá mi ṣì lo ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn tí Bàbá mi kú. Ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [94] ni Màmá mi nígbà tí wọ́n kú. Nǹkan ò rọrùn fún mi rárá ní gbogbo ìgbà yẹn, ó máa ń rẹ̀ mí gan-an, ọkàn mi ò sì pa pọ̀. Bí mo ṣe dààmú gan-an nígbà yẹn dá àìsàn kan tó dà bí ìgbóná sí mi lára, wọ́n ń pe orúkọ àìsàn náà ni Shingles. Àmọ́, mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì rí okun gbà, èyí tó jẹ́ kí n lè fara da àkókò tí ó nira yẹn. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún mi pé, ‘títí di ìgbà orí ewú . . . , èmi fúnra mi yóò gbé ọ, èmi fúnra mi yóò rù ọ́, èmi yóò sì pèsè àsálà fún ọ.’—Aísá. 46:4.

Lọ́dún 1990, mo kó lọ sí ìlú Omak, ní ìpínlẹ̀ Washington lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tí mo débẹ̀, mò ń wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì, mo sì rí i pé mo ṣì wúlò gan-an, kódà àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi. Nígbà tó fi máa di oṣù November ọdún 2007, ìlera mi ò gbé e mọ́ kí n máa dá tọ́jú ilé tí mò ń gbé ní ìlú Omak, torí náà, mo kó lọ sí ilé kan ní ìtòsí ìlú Chelan, ní ìpínlẹ̀ Washington. Ìjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì níbí ló ń tọ́jú mi látìgbà yẹn, mo sì dúpẹ́ gan-an fún bí wọ́n ṣe ń ràn mí lọ́wọ́. Èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí tó dàgbà jù lọ níbí, àwọn ará nífẹ̀ẹ́ mi gan-an, wọ́n sì mú mi bí ìyá wọn àgbà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pinnu pé mi ò ní lọ́kọ mi ò sì ní bímọ torí kí n lè sin Jèhófà ní kíkún “láìsí ìpínyà-ọkàn,” mo ní ọ̀pọ̀ ọmọ nípa tẹ̀mí. (1 Kọ́r. 7:34, 35) Mo mọ̀ pé mi ò lè ní gbogbo nǹkan láyé yìí. Ìdí nìyẹn tí mo fi fi ohun tó ṣe pàtàkì jù ṣáájú ní ìgbésí ayé mi, ìyẹn bí mo ṣe ya ara mi sí mímọ́ kí n lè máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Mo mọ̀ pé nínú ayé tuntun mo máa láǹfààní láti gbádùn gbogbo nǹkan tí mo bá fẹ́. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo fẹ́ràn jù lọ ni Sáàmù 145:16, Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé òun yóò “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà mú kí n dà bí ọ̀dọ́

Mo ti pé ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91] báyìí, síbẹ̀ ara mi ṣì le díẹ̀, ìyẹn jẹ́ kí n ṣì lè máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ńṣe ni iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà mú kí n dà bí ọ̀dọ́, ó sì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi ní ìtumọ̀. Iṣẹ́ ìwàásù ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni nígbà tí mo dé orílẹ̀-èdè El Salvador. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì kò dáwọ́ inúnibíni tó ń ṣe dúró, àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn báyìí lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógójì [39,000]. Ìbísí yìí mú kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára sí i. Ó dá mi lójú hán-ún pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń ti àwọn èèyàn Jèhófà lẹ́yìn!

a Wo ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, 1981 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 45 sí 46.

b Wo ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, 1981 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 41 sí 42.

c Wo ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, 1981 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 66 sí 67 àti 74 sí 75.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́