ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 7/1 ojú ìwé 8-12
  • Mo Láyọ̀ Nítorí Pé Mi Ò Jáwọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Láyọ̀ Nítorí Pé Mi Ò Jáwọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Látẹnu Iṣẹ́ Awakọ̀ sí Iṣẹ́ Ajíhìnrere
  • Inúnibíni Tí Mo Kọ́kọ́ Fojú Winá Rẹ̀
  • Ohun Tí Mò Ń Lé
  • Ìpèsè Ọlọ́làwọ́
  • Bí Mo Ṣe Kojú Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun Tó Bà Mí Lẹ́rù
  • Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, Ẹṣin, àti Ẹranko Ajeèrà
  • Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Mo Ní Olùrànlọ́wọ́
  • Mi Ò Jàwọ́ Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Àìsàn Ń Bá Mi Fínra
  • Ìgbọ́kànlé Mi Nínú Jèhófà Mú Mi Dúró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìforítì Ń Yọrí Sí Ìtẹ̀síwájú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Títẹ́wọ́gba Ìkésíni Látọ̀dọ̀ Jèhófà Ń Mú Èrè Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nígbèésí Ayé Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 7/1 ojú ìwé 8-12

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mo Láyọ̀ Nítorí Pé Mi Ò Jáwọ́

GẸ́GẸ́ BÍ MÁRIO ROCHA DE SOUZA ṢE SỌ Ọ́

“Kò dájú pé bá a bá ṣiṣẹ́ abẹ fún ọ̀gbẹ́ni Rocha yóò rù ú là.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé dókítà kan sọ ọ̀rọ̀ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ mú mi sọ̀rètí nù yìí, lónìí, ìyẹn ogún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, mo ṣì wà láàyè mo sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí ló ràn mí lọ́wọ́ tí kò jẹ́ kí n juwọ́ sílẹ̀ láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá?

OKO kan nítòsí abúlé Santo Estêvão ní ìpínlẹ̀ Bahia, ní àríwá ìlà oòrùn ilẹ̀ Brazil ni mo dàgbà sí. Ìgbà ti mo ti pé ọmọ ọdún méje ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá bàbá mi ṣiṣẹ́ lóko. Ojoojúmọ́ tí mo bá ti dé láti iléewé ló máa ń yan iṣẹ́ tí màá ṣe fún mi. Nígbà tó sì yá, èmi ni bàbá mi máa ń ní kó mójú tó oko náà nígbàkígbà tó bá lọ ṣiṣẹ́ nílùú Salvador tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ yẹn.

Kò síná mànàmáná, kò sómi ẹ̀rọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sáwọn nǹkan amáyédẹrùn tó wọ́pọ̀ lóde òní, síbẹ̀ a láyọ̀. Mo máa ń ta káìtì tàbí kí n máa fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ onígi ṣeré, èyí témi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi jọ ṣe. Mo tún máa ń fun fèrè nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì wa bá ń yíde ìsìn kiri. Mo wà nínú ẹgbẹ́ akọrin ní ṣọ́ọ̀ṣì àgbègbè wa, ibẹ̀ ni mo sì ti rí ìwé kan tó ń jẹ́ História Sagrada (Ìtàn Mímọ́), èyí tó mú kó wù mí láti fẹ́ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì.

Lọ́dún 1932, nígbà tí mo wà lọ́mọ ogún ọdún, ọ̀dá kan tó burú jáì ṣẹlẹ̀ lápá ìlà oòrùn àríwá ilẹ̀ Brazil, ọ̀dá náà kò sì lọ bọ̀rọ̀. Àwọn màlúù wa kú, irè oko wa kò sì ṣe dáadáa, ni mo bá ṣí lọ sílùú Salvador, níbi tí mo ti ń wa bọ́ọ̀sì ojú irin tí wọ́n fi ń kó èrò. Lẹ́yìn náà, mo háyà ilé kan, mo sì ní kí bàbá mi, ìyá mi àtàwọn àbúrò mi wá máa gbé lọ́dọ̀ mi. Lọ́dún 1944, bàbá mi kú, ó sì wá di iṣẹ́ mi láti máa bójú tó màmá mi àtàwọn àbúrò mi obìnrin mẹ́jọ pẹ̀lú àwọn àbúrò mi ọkùnrin mẹ́ta.

Látẹnu Iṣẹ́ Awakọ̀ sí Iṣẹ́ Ajíhìnrere

Lára ohun àkọ́kọ́ tí mo ṣe nígbà tí mo dé ìlú Salvador ni pé mo ra Bíbélì kan. Lẹ́yìn tí mo ti lọ sí ìjọ Onítẹ̀bọmi fún ọdún díẹ̀, èmi àti Durval tá a jọ ń ṣiṣẹ́ awakọ̀ di ọ̀rẹ́. A sábà jọ máa ń sọ̀rọ̀ gan-an nípa Bíbélì. Lọ́jọ́ kan, ó fún mi ní ìwé kékeré kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Where Are the Dead?a (Ibo Làwọn Òkú Wà?) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo nígbàgbọ́ pé ẹ̀dá èèyàn ní ẹ̀mí tí kò lè kú, ó wù mí lọ́pọ̀lọpọ̀ láti yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fà yọ nínú ìwé kékeré yẹn wò. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé Bíbélì pàápàá sọ pé ọkàn tó bá ṣẹ̀ yóò kú.—Ìsíkíẹ́lì 18:4.

Nígbà tí Durval rí i pé mo nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí mò ń kà yẹn, ló bá ní kí Antônio Andrade tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ nílé. Lẹ́yìn tí Antônio ti wá fún ìgbà mẹ́ta, ó ní kí n tẹ̀ lé òun ká jọ lọ sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn. Lẹ́yìn tó ti sọ̀rọ̀ ní ilé méjì tá a kọ́kọ́ dé, ló bá sọ pé: “Ó yá, ó kàn ẹ́ láti sọ̀rọ̀.” Ẹ̀rù bà mí gan-an, àmọ́ inú mi dùn pé ìdílé kan tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, wọ́n sì gba ìwé ńlá méjì tí mo fi lọ̀ wọ́n. Títí dòní ni inú mi ṣì máa ń dùn gan-an tí mo bá bá ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sóhun tó wà nínú Bíbélì pàdé.

Lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù April ọdún 1943, mo ṣèrìbọmi nínú Òkun Àtìláńtíìkì tí kò jìnnà sí ìlú Salvador, ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìrántí ikú Kristi lọ́dún náà. Nítorí pé kò fi bẹ́ẹ̀ sáwọn arákùnrin tó ti pẹ́ nínú òtítọ́, wọ́n yàn mí láti máa ran àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń pàdé nílé Arákùnrin Andrade lọ́wọ́. Ilé náà wà ní ọ̀kan lára àwọn òpópónà tó so apá òkè àti apá ìsàlẹ̀ ìlú Salvador pọ̀.

Inúnibíni Tí Mo Kọ́kọ́ Fojú Winá Rẹ̀

Àwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù àwa Kristẹni láwọn ọdún tí Ogun Àgbáyé Kejì jà (1939 sí 1945). Àwọn tó ń ṣamí fún ilẹ̀ Amẹ́ríkà làwọn aláṣẹ kan kà wá sí nítorí pé àtibẹ̀ ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìwé wa ti ń wá. Nípa bẹ́ẹ̀, ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń mú wa tí wọ́n á sì máa fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò. Tá ò bá ti rí i kí Ẹlẹ́rìí kan padà dé láti òde ẹ̀rí, a gbà pé àwọn aláṣẹ ti mú un nìyẹn, a ó sì lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ gbà á sílẹ̀.

Lóṣù August ọdún 1943, Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adolphe Messmer tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì, dé sí Salvador láti wá bá wa ṣètò ìpàdé àyíká wa àkọ́kọ́. Lẹ́yìn tá a ti gba àṣẹ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ láti ṣe àpéjọ náà, a polongo àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Òmìnira Nínú Ayé Tuntun” sínú àwọn ìwé ìròyìn tó ń jáde lágbègbè náà, a sì lẹ àwọn bébà tó ń sọ nípa àsọyé náà mọ́ ara àwọn wíńdò ilé ìtajà àti ẹ̀gbẹ́ àwọn bọ́ọ̀sì ojú irin. Àmọ́ lọ́jọ́ kejì àpéjọ náà, ọlọ́pàá kan wá sọ fún wa pé wọ́n ti fagi lé àṣẹ tí wọ́n fún wa láti pàdé pọ̀. Bíṣọ́ọ̀bù àgbà fún ìlú Salvador ló lọ fúngun mọ́ ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá pé kó dá àpèjọ wa dúró. Àmọ́ lóṣù April ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n fún wa láyè láti ṣe àpéjọ náà a sì sọ àsọyé tá a ti polongo rẹ̀ yẹn.

Ohun Tí Mò Ń Lé

Lọ́dún 1946, wọ́n ké sí mi láti lọ sí Ìpàdé Àgbègbè Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Àwọn Orílẹ̀-Èdè Aláyọ̀ ní ìlú São Paulo. Ọ̀gákọ̀ ọkọ̀ òkun kan tí wọ́n fi ń kẹ́rù nílùú Salvador gbà kí àwa kan bá ọkọ̀ náà rìn tá a bá ti lè sùn ní òkè ọkọ̀ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjì jà lójú òkun náà, tí ara gbogbo wa kò sì yá, síbẹ̀ a gúnlẹ̀ láyọ̀ sí èbúté ìlú Rio de Janeiro lẹ́yìn tá a ti lo ọjọ́ mẹ́rin lójú òkun. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú Rio gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ sínú ilé wọn láti sinmi fún ọjọ́ díẹ̀ ká tó wá máa bá ìrìn àjò wa lọ nínú ọkọ̀ ojú irin. Àwọn ará kan, tí wọ́n gbé àkọlé kan dání tó sọ pé, “Ẹ Káàbọ̀, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà,” wá kí wa káàbọ̀ nígbà tí ọkọ̀ ojú irin wa gúnlẹ̀ sí ìlú São Paulo.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tá a padà sí ìlú Salvador ni mo bá arákùnrin Harry Black tó jẹ́ míṣọ́nnárì láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀ pé ó wù mí kí n di aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn orúkọ tí wọ́n máa ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin Harry rán mi létí pé mo ní bùkátà ìdílé tí mo ní láti bójú tó, ó sì rọ̀ mí pé kí n ṣì ní sùúrù. Nígbà tó wá di oṣù June ọdún 1952, tí gbogbo àwọn àbúrò mi ti lè dá gbọ́ bùkátà ara wọn, wọ́n ní kí n lọ máa ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìjọ kékeré kan ní ìlú Ilhéus, tó jẹ́ igba ó lé mẹ́wàá [210] kìlómítà sí etíkun tó wà ní ìhà gúúsù ìlú Salvador.

Ìpèsè Ọlọ́làwọ́

Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n yàn mí sí ìlú kan tó tóbi díẹ̀ tó ń jẹ́ Jequié, tó wà ní àárín gbùngbùn ìpínlẹ̀ Bahia. Kò sí Ẹlẹ́rìí kankan níbẹ̀. Àlùfáà ibẹ̀ sì lẹni àkọ́kọ́ tí mo wàásù fún. Ó ṣàlàyé fún mi pé ìpínlẹ̀ òun ni ìlú yẹn mi ò sì gbọ́dọ̀ wàásù níbẹ̀. Ó sọ fáwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ pé “wòlíì èké” kan ti wọ̀lú àti pé kí wọ́n ṣọ́ra, ó sì fi àwọn kan ṣe amí káàkiri ìlú náà pé kí wọ́n máa ṣọ́ gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe. Síbẹ̀, àádọ́rùn-ún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mo fi sóde lọ́jọ́ yẹn mo sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rin. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ìlú Jequié ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tirẹ̀ àtàwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ mẹ́rìndínlógójì! Lónìí, ìjọ mẹ́jọ àti nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] Ẹlẹ́rìí ló wà nílùú Jequié.

Láwọn oṣù tí mo kọ́kọ́ lò nílùú Jequié, ilé kékeré kan tí mo háyà lẹ́yìn ìlú ni mò ń gbé. Nígbà tó yá, mo bá ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Miguel Vaz de Oliveira pàdé, òun ló ni òtẹ́ẹ̀lì kan tó ń jẹ́ Hotel Sudoeste, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òtẹ́ẹ̀lì tó dára jù lọ nílùú Jequié. Miguel gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ó sì ní dandan kí n wá máa gbé yàrá kan nínú òtẹ́ẹ̀lì náà. Miguel àti ìyàwó rẹ̀ wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn ìgbà náà.

Ohun mìíràn tó tún ṣẹlẹ̀ sí mi nígbà tí mo wà ní Jequié tó máa ń múnú mi dùn ni ti olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama kan tó ń jẹ́ Luiz Cotrim tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Luiz sọ pé òun fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ ní ìmọ̀ èdè Potogí àti ìmọ̀ ìṣirò sí i. Ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan ni mo lọ, kíákíá ni mo sì gbà pé kó kọ́ mi. Àwọn ohun tí Luiz ń kọ́ mi lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yìí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti tẹ́wọ́ gba àfikún iṣẹ́ ìsìn tí ètò Jèhófà fún mi láìpẹ́ sígbà náà.

Bí Mo Ṣe Kojú Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun Tó Bà Mí Lẹ́rù

Lọ́dún 1956, mo gba lẹ́tà kan tí wọ́n fi pè mí sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà nílùú Rio de Janeiro nígbà yẹn. Wọ́n ní kí n wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti di alábòójútó àyíká, gẹ́gẹ́ bá a ṣe ń pe àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Oṣù kan péré àti ọjọ́ díẹ̀ ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí gbà. Èmi àtàwọn arákùnrin mẹ́jọ mìíràn la jọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí. Bó ti ń parí lọ ni wọ́n yàn mí sí ìpínlẹ̀ São Paulo, èyí tó mú kẹ́rù máa bà mí. Mo bi ara mi pé: ‘Kí lèmi tí mo jẹ́ èèyàn dúdú fẹ́ lọ ṣe láàárín gbogbo àwọn ará Ítálì yẹn? Ṣé wọ́n á gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀?’b

Ní ìjọ àkọ́kọ́ tí mo bẹ̀ wò lágbègbè Santo Amaro, inú mi dùn nígbà tí mo rí i bí àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tèmi àtàwọn tó ń fìfẹ́ hàn ṣe kúnnú Gbọ̀ngàn Ìjọba fọ́fọ́. Ohun tó fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé kò sídìí fún mi láti bẹ̀rù ni pé, gbogbo àwọn mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún tó wà nínú ìjọ yẹn la jọ jáde òde ẹ̀rí lópin ọ̀sẹ̀ náà. Mo wá sọ nínú ọkàn mi pé, ‘Arákùnrin mi ni wọ́n dájúdájú.’ Ìfẹ́ táwọn arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n yìí fi hàn sí mi fún mi nígboyà láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò náà lọ láìjáwọ́.

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, Ẹṣin, àti Ẹranko Ajeèrà

Ọ̀kan lára ìṣòro tó le jù lọ tó ń dojú kọ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lákòókò yẹn ni rírin ìrìn ọ̀nà jíjìn láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ kéékèèké tí wọ́n wà láwọn ìgbèríko. Láwọn àgbègbè yẹn, ọkọ̀ akérò kò láyọ̀lé tàbí kó má tiẹ̀ sí nígbà mìíràn, bẹ́ẹ̀ ló sì jẹ́ pé ọ̀nà eléruku tó rí tóóró ló pọ̀ jù lára àwọn ọ̀nà náà.

Ohun táwọn àyíká kan ṣe láti yanjú ìṣòro yìí ni pé wọ́n ra kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí ẹṣin fún alábòójútó àyíká láti máa lò. Lọ́jọọjọ́ Monday, mo máa ń di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí ẹṣin náà ní gàárì, màá de àwọn ẹrù mi mọ́ ọn lẹ́yìn, màá sì gùn ún fún bíi wákàtí méjìlá lọ sí ìjọ tó bá kàn. Nílùú Santa Fé do Sul, àwọn Ẹlẹ́rìí ibẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Dourado (Goldie) tó mọ̀nà dé ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ kéékèèké tó wà ní ìgbèríko. Tí Dourado bá dé ibi àbáwọlé abà kan, á rọra dúró kí n wá ṣí i. Tí ìbẹ̀wò náà bá sì parí, èmi àti Dourado á tún kọjá sọ́dọ̀ àwùjọ tó kàn.

Àìsí ọ̀nà tó ṣeé gbára lé láti kàn sí àwọn ìjọ tún mú kí iṣẹ́ àyíká ṣòro nígbà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, láti bẹ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kékeré kan tí wọ́n ń pàdé pọ̀ ní oko kan ní Ìpínlẹ̀ Mato Grosso wò, mo ní láti wọ ọkọ̀ ojú omi kọjá lórí Odò Araguaia kí n sì tún gun ẹṣin tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fún bíi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n la àárín igbó kọjá. Nígbà kan, mo kọ lẹ́tà sí àwùjọ yìí pé mò ń bọ̀ wá bẹ̀ wọ́n wò, àmọ́ ó dájú pé wọn ò rí lẹ́tà yẹn gbà, torí pé kò sẹ́nì kankan tó ń dúró dè mí nígbà tí mo dé òdìkejì odò náà. Ìrọ̀lẹ́ ni mo débẹ̀, ni mo bá sọ fún ẹni tó ń ta ọtí nínú ṣọ́ọ̀bù kékeré kan pé kó bá mi wo ẹ̀rù mi. Ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹsẹ̀ rìn lọ, báàgì ìfàlọ́wọ́ mi nìkan ni mo sì gbé dání.

Kò pẹ́ tí ilẹ̀ fi ṣú. Bí mo ti ń forí jágbó lọ nínú òkùnkùn, ẹran ajeèrà kan bẹ̀rẹ̀ sí í kùn. Mo ti gbọ́ pé ẹranko yìí lè dìde kó sì fi àwọn ọwọ́ iwájú rẹ̀ tó lágbára pààyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, ìgbàkigbà tí nǹkankan bá ti dún lábẹ́ ewé, màá rọra máa tẹlẹ̀ jẹ́jẹ́ màá sì gbé báàgì mi síwájú mi láti fi dáàbò bo ara mi. Lẹ́yìn tí mo ti rìn fún ọ̀pọ̀ wákàtí, mo débi tí odò kékeré kan wà. Àmọ́ nínú òkùnkùn yẹn mi ò mọ̀ pé wáyà ẹlẹ́gùn-ún tí wọ́n ta yí ọgbà kan ká wà ní òdìkejì odó kékeré náà. Mo gbìyànjú láti fo odò náà dá lẹ́ẹ̀kan, àmọ́ orí ọgbà yẹn ni mo balẹ̀ sí, ó sì gé mi lára!

Nígbà tó yá, mo dé oko yẹn, ariwo àwọn ajá tó ń gbó ló sì kí mi káàbọ̀. Àwọn olè tó máa ń wá jí àgùntàn lóru wọ́pọ̀ lákòókò yẹn. Nítorí náà bí wọ́n ṣe ṣílẹ̀kùn fún mi báyìí ni mo yáa tètè sọ ẹni tí mo jẹ́ fún wọn. Kò sí àní-àní pé àánú mi ṣe àwọn arákùnrin yẹn bí wọ́n ti rí i tí aṣọ mi ya tó sì lẹ́jẹ̀ lára, àmọ́ inú wọn dùn láti rí mi.

Láìka àwọn ìṣòro wọ̀nyẹn sí, àkókò aláyọ̀ làwọn àkókò yẹn jẹ́. Mo máa ń gbádùn àwọn ìrìn ọ̀nà jíjìn yẹn lórí ẹṣin àti nígbà tí mo bá ń fẹsẹ̀ rìn. Ìgbà míì wà tí màá máa sinmi lábẹ́ ibòji àwọn igi, mo máa ń gbọ́ báwọn ẹyẹ ṣe ń kọrin, mo sì máa ń wo àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bí wọ́n ti ń sáré kọjá níwájú mi láwọn ojú ọ̀nà táwọn èèyàn kì í sábà gbà wọ̀nyẹn. Ohun mìíràn tó tún máa ń fún mi láyọ̀ gan-an nígbà yẹn ni mímọ̀ tí mo mọ̀ pé àwọn ìbẹ̀wò mi yẹn ń ran àwọn ará lọ́wọ́ gan-an. Ọ̀pọ̀ ló máa ń kọ̀wé sí mi láti fi ìmọrírì wọn hàn. Àwọn mìíràn sì máa ń wá bá mi, tí wọ́n á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ mi nígbà tá a bá pàdé láwọn àpéjọ wa. Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá rí i táwọn èèyàn borí àwọn ìṣòro tí wọ́n ní, tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run!

Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Mo Ní Olùrànlọ́wọ́

Láwọn ọdún tí mò ń ṣiṣẹ́ arìnrìn-àjò yẹn, èmi nìkan ni mo sábà máa ń dá lọ dá bọ̀, èyí sì kọ́ mi láti gbára lé Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi.” (Sáàmù 18:2) Ìyẹn nìkan kọ́, mo tún rí i pé bí mo ṣe jẹ́ àpọ́n yẹn jẹ́ kí n lè pa gbogbo ọkàn mi pọ̀ sórí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

Àmọ́ lọ́dún 1978, mo pàdé arábìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, Júlia Takahashi lorúkọ rẹ̀. Ó ti fi iṣẹ́ nọ́ọ̀sì tó ń mówó wọlé fún un ní ọsibítù ńlá kan nílùú São Paulo sílẹ̀ kó lè lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run gan-an. Àwọn alàgbà tó mọ̀ ọ́n sọ̀rọ̀ ẹ̀ dáadáa pé ó ní àwọn ànímọ́ tẹ̀mí àti pé aṣáájú ọ̀nà tó dáǹgájíá ni. Bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀, nígbà tí mo pinnu láti ṣègbéyàwó lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn kan. Ó ṣòro fún ọ̀rẹ́ mi kan tó sún mọ́ mi gan-an láti gbà gbọ́, ó sì sọ pé òun á fún mi ní odindi ẹran màlúù ńlá kan tí n bá ṣègbéyàwó lóòótọ́. Màlúù yẹn la sun tá a sì fi ṣàlejò níbi tá a ti kó àwọn èèyàn lẹ́nu jọ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa ní July 1, ọdún 1978.

Mi Ò Jàwọ́ Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Àìsàn Ń Bá Mi Fínra

Èmi àti Júlia wá jọ ń ṣe iṣẹ́ arìnrìn-àjò. Ọdún mẹ́jọ gbáko làwa méjèèjì sì jọ fi ń bẹ àwọn ìjọ wò ní apá gúúsù àti ní ìlà oòrùn gúúsù ilẹ̀ Brazil. Àkókò yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní àìsàn ọkàn. Ẹ̀ẹ̀mejì ni mo dákú níbi tí mo ti ń wàásù fáwọn èèyàn. Nítorí àìlera mi yìí, a gbà láti lọ máa ṣe aṣáájú ọ̀nà àkànṣe nílùú Birigüi, ní ìpínlẹ̀ São Paulo.

Àkókò yìí làwọn Ẹlẹ́rìí ní Birigüi sọ pé àwọn á fi mọ́tò gbé mi lọ rí dókítà kan nílùú Goiânia, tó wà ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìlómítà sí Birigüi. Bí ara mi sì ṣe yá díẹ̀ ni mo ṣe iṣẹ́ abẹ kan tí wọ́n ti fi ẹ̀rọ tó ń mú ọkàn ṣiṣẹ́ sínú mi. Ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tún ti ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn fún mi lẹ́ẹ̀méjì lẹ́yìn náà, mo ṣì ń kópa déédéé nínú iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn aya olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni, Júlia máa ń fún mi lókun àti ìṣírí nígbà gbogbo.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn kò jẹ́ kí n lè ṣe tó bí mo ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ tí èyí sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi nígbà míì, síbẹ̀ ó ṣì ṣeé ṣe fún mi láti máa ṣe aṣáájú ọ̀nà nìṣó. Mo máa ń rán ara mi létí pé Jèhófà ò ṣèlérí fún wa pé ìgbésí ayé wa nínú ètò àwọn nǹkan tó ti gbó yìí kò ní níṣòro rárá. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni mìíràn láyé ọjọ́un tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ kò bá jáwọ́, ṣé ó wá yẹ káwa náà jáwọ́?—Ìṣe 14:22.

Láìpẹ́ yìí, mo rí Bíbélì tí mo kọ́kọ́ rà láwọn ọdún 1930 yẹn. Mo kọ ọ́ sínú rẹ̀ nígbà yẹn pé iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ní Brazil nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé lọ́dún 1943 jẹ́ àádọ́ta dín nírínwó [350]. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé gbà gbọ́ pé wọ́n ti lé ní ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] báyìí. Àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ ló jẹ́ fún mi pé mo lè kópa díẹ̀ nínú pípọ̀ tá a ti pọ̀ sí i yìí! Dájúdájú, Jèhófà ti bù kún mi gan-an nítorí pé mi ò jáwọ́. Bíi ti onísáàmù yẹn, èmi náà lè sọ pé: “Jèhófà ti ṣe ohun ńlá nínú ohun tí ó ṣe fún wa. Àwa ti kún fún ìdùnnú.”—Sáàmù 126:3.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.

b Láàárín ọdún 1870 sí 1920, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan àwọn ará Ítálì tó ṣí wá sí orílẹ̀-èdè Brazil ló fìdí kalẹ̀ sí ìlú São Paulo.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwa Ẹlẹ́rìí ń kéde àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àpéjọ àkọ́kọ́ nílùú Salvadòr lọ́dún 1943

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn Ẹlẹ́rìí ń dé sílùú São Paulo fún Àpéjọ Àgbègbè Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Àwọn Orílẹ̀-Èdè Aláyọ̀, ọdún 1946

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]

Nígbà tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò lópin àwọn ọdún 1950

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Èmi àti Júlia, aya mi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́