ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 7/1 ojú ìwé 4-7
  • Bó O Ṣe Lè Rí Ojúlówó Ìlàlóye

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Rí Ojúlówó Ìlàlóye
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ìwé Mímọ́ Tó Lè Mú Ọ Rí Ìgbàlà’
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì
  • Máa Fara Balẹ̀ Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́
  • Kí Nìdí Tó Fi Jọ Pé Ìgbésí Ayé Yìí Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
    “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
  • Ó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Gbọ́ Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Idi ti A Fi Tún Awọn Kan Bí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 7/1 ojú ìwé 4-7

Bó O Ṣe Lè Rí Ojúlówó Ìlàlóye

ỌJỌ́ kejìdínlógún oṣù December ọdún 1810 ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé. Ilẹ̀ ti ń ṣú lọ́jọ́ náà. Bí àwọn Ọmọ Ogun Ojú Omi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti wà lójú òkun nínú ọkọ̀ òkun kékeré tó ń jẹ́ HMS Pallas, níbi tí kò jìnnà sí etíkun tó wà ní ìlà oòrùn ilẹ̀ Scotland, bẹ́ẹ̀ ni òkun ń ru gùdù, wọ́n sì ti ṣìnà. Ilẹ̀ tó túbọ̀ ń ṣú sí i àti òjò yìnyín tó ń rọ̀, mú kó túbọ̀ ṣòro gan-an fáwọn atukọ̀ náà láti mọ ibi tí iná tó máa tọ́ wọn sọ́nà wà kí ọkọ̀ wọn lè dé èbúté láìséwu. Fojú inú wo bára ṣe tù wọ́n tó nígbà tí wọ́n jàjà rí àwọn iná kan tí wọ́n sì darí ọkọ̀ wọn gba apá ibi táwọn iná náà wà! Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn iná yẹn kì í ṣe iná afinimọ̀nà tí wọ́n nílò. Iná táwọn òṣìṣẹ́ kan dá tó ń jó ní tòsí etíkun ni. Ọkọ̀ òkun Pallas náà fi àyà sọ àpáta ó sì fọ́ sí wẹ́wẹ́. Báwọn atukọ̀ òkun mọ́kànlá ṣe pa rẹ́ sínú omi nìyẹn. Ohun ìbànújẹ́ gbáà lèyí jẹ́!

Àṣìṣe ló fa jàǹbá tó ṣẹlẹ̀ sí ọkọ̀ òkun Pallas yẹn. Àmọ́ nígbà míì, àwọn atukọ̀ òkun máa ń bára wọn nínú ewu tó le jùyẹn lọ, ìyẹn ewu iná tó máa ń ṣì wọ́n lọ́nà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú ìwé kan tó ṣàlàyé nípa ọ̀rọ̀ yìí, ìyẹn ìwé Wrecks, Wreckers and Rescuers, àwọn kan máa ń mọ̀ọ́mọ̀ tan irú àwọn iná bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ láti tan àwọn ọkọ̀ òkun lọ sáwọn etíkun tó ní àpáta kí àwọn ọkọ̀ náà lè fọ́ sí wẹ́wẹ́ kí wọ́n sì kó gbogbo ẹrù inú rẹ̀.

‘Ìwé Mímọ́ Tó Lè Mú Ọ Rí Ìgbàlà’

Bí ìwọ náà ti ń wá ìlàlóye, o lè bára rẹ nínú irú ewu táwọn atukọ̀ yẹn bára wọn. O lè tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ tí ń ṣini lọ́nà tàbí káwọn kan tiẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ tàn ọ́ jẹ. Kò sí èyí tí kò lè yọrí sí jàǹbá nínú méjèèjì. Kí lo lè ṣe láti yọ ara rẹ nínú ewu yìí? Rí i dájú pé ibi tó o ti ń gba ìlàlóye jẹ́ ojúlówó ó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Ó ti lé lọ́dún márùnlélọ́gọ́fà [125] tí ìwé ìròyìn yìí ti ń gbé Bíbélì lárugẹ, ìyẹn Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Ó ń jẹ́ ká mọ̀ pé Bíbélì ni orísun ìlàlóye tá a lè fọkàn tán jù lọ, nítorí pé ‘Ìwé Mímọ́ tó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà’ ló wà nínú rẹ̀.—2 Tímótì 3:15-17, Bibeli Mimọ.

Lóòótọ́, kó o tó lè fọkàn tán Bíbélì pé ìmọ́lẹ̀ tí ń tọ́ni sọ́nà tó sì ṣe é gbára lé ni, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o ṣàyẹ̀wò bó ṣe jóòótọ́ sí. (Sáàmù 119:105 Òwe 14:15) Má ṣe lọ́ra láti kọ̀wé sáwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn yìí kó o lè túbọ̀ rí àlàyé tó mú kó dá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lójú pé òótọ́ ni Ọlọ́run mí sí Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ka ìwé pẹlẹbẹ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn.a Ó ṣe ọ̀pọ̀ àlàyé tó fi hàn pé Bíbélì péye, pé òtítọ́ lohun tó wà nínú rẹ̀, àti pé Ọlọ́run mí sí i.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì

Kí wá ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú “Ìwé Mímọ́” yìí? Gbé àwọn àpẹerẹ tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò.

Ọlọ́run Olódùmarè kan ṣoṣo ló wà, òun tún ni Ẹlẹ́dàá tó dá ohun gbogbo. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Dídá tí “[Ọlọ́run] dá ohun gbogbo” tó sì fún wa ní ìwàláàyè ló jẹ́ ká wà láàyè. (Ìṣípayá 4:11) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé òun nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn. Ẹlẹ́dàá ni Orísun tó ga jù lọ tó lè fún èèyàn ní ìlàlóye. (Sáàmù 36:9; Aísáyà 30:20, 21; 48:17, 18) Ó ní orúkọ kan tó fẹ́ ká máa lò. (Ẹ́kísódù 3:15) Nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje ni orúkọ yẹn fara hàn nínú Bíbélì. Lẹ́tà èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ ọ́, òun ni wọ́n sì yí sí àwọn lẹ́tà mẹ́rin tá à ń pé ní YHWH. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ń lo orúkọ náà, “Jèhófà,” lédè Yorùbá.—Sáàmù 83:18.

Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin kí wọ́n lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè, lórí ilẹ̀ ayé níbí. Ó fún àwọn èèyàn láwọn ànímọ́ tẹ̀mí tó jọ àwọn ànímọ́ tiẹ̀ fúnra rẹ̀. Ó fún wọn láwọn ẹ̀bùn àbínibí àti ọgbọ́n táá jẹ́ kí wọ́n lè gbádùn ìgbésí ayé wọn títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28) Kò ní in lọ́kàn pé kí ayé jẹ́ ibi ìdánrawò, ìyẹn ibi tó ti máa múra tọkùnrin tobìnrin sílẹ̀ láti lè lọ máa gbé lọ́run, bí ẹni pé ibẹ̀ nìkan ni àjọṣe ti lè wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run.

Nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn, kò dá ohunkóhun tó jẹ́ ibi mọ́ wọn. Ìgbà táwọn kan lára àwọn ẹ̀dá Ọlọ́run, ìyẹn àwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì kan ṣi òmìnira tí Ọlọ́run fún wọn lò tí wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ni ibi dé. (Diutarónómì 32:5) Àwọn òbí wa àkọ́kọ́ gbà pé àwọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti máa dá pinnu bóyá ohun kan dára tàbí kò dára. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:1-5) Èyí ló fà á tí èèyàn fi ń kú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Róòmù 5:12) Láti yanjú àwọn ohun tí ọ̀tẹ̀ yẹn dá sílẹ̀, Jèhófà pinnu láti fàyè gba ìwà ibi fúngbà díẹ̀. Àmọ́ ohun tó ní lọ́kàn nípa ilẹ̀ ayé àti ẹ̀dá èèyàn kò yí padà rárá. (Aísáyà 45:18) Àwọn ọkùnrin àti obìnrin ṣì máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run yóò fọ̀ mọ́ tó máa wá di Párádísè.—Mátíù 6:10; Ìṣípayá 21:1-5.

Jésù Kristi kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè, Ọmọ Ọlọ́run ni. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Kò fìgbà kan rí sọ pé òun àti Ọlọ́run dọ́gba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Baba tóbi jù mí lọ.”—Jòhánù 14:28.

Jésù kó ipa tó ṣe pàtàkì gan-an nínú mímú ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé ṣẹ. Ọlọ́run rán an wá “gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ sínú ayé, kí olúkúlùkù ẹni tí ń ní ìgbàgbọ́ nínú [rẹ̀] má bàa wà nínú òkùnkùn.” (Jòhánù 12:46) Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pétérù ṣe sọ, “kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn.” (Ìṣe 4:12) Òótọ́ lèyí, nítorí pé orí ẹ̀jẹ̀ Kristi tó ṣeyebíye ni ìgbàlà wa sinmi lé. (1 Pétérù 1:18, 19) Jésù Kristi fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà láti ra aráyé padà nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, kó ìran èèyàn sí. (Mátíù 20:28; 1 Tímótì 2:6) Bákan náà, Ọlọ́run tún lo Jésù láti jẹ́ ká mọ ohun tí òun fẹ́ àti ohun tí òun ní lọ́kàn láti ṣe.—Jòhánù 8:12, 32, 46, 47; 14:6; Ìṣe 26:23.

Ọlọ́run ti gbé Ìṣàkóso tàbí Ìjọba kan kalẹ̀ ní ọ̀run, Jésù Kristi àtàwọn tí Ọlọ́run yàn látinú àwọn èèyàn ló sì wà nínú Ìjọba náà. Ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba yìí fara hàn léraléra nínú Bíbélì. Ìjọba yìí ni Ọlọ́run máa lò láti rí i dájú pé ìfẹ́ òun di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run. (Mátíù 6:10) Ọlọ́run kò ní in lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ pé kí ẹnì kankan lára ẹ̀dá èèyàn lọ sí ọ̀run. Ayé ló dá fún wọn láti máa gbé. Àmọ́ ìgbà tí èèyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọ́run ṣètò ohun mìíràn tó jẹ́ tuntun. Ó ṣètò láti mú àwọn èèyàn “láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè” kí wọ́n lè “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba” pẹ̀lú Kristi nínú ìjọba ọ̀run. (Ìṣípayá 5:9, 10) Láìpẹ́, Ìjọba yẹn yóò ‘fọ́ gbogbo onírúurú ìjọba èèyàn túútúú yóò sì fi òpin sí’ wọn nítorí pé wọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbànújẹ́ àti ìnira bá ìran èèyàn.—Dáníẹ́lì 2:44.

Ọkàn máa ń kú. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ẹ̀kọ́ inú Bíbélì tó ṣe pàtàkì yìí mú ṣe kedere nípa ẹ̀dá èèyàn àti ìrètí tó wà fún wọn lọ́jọ́ iwájú. Ó tún ti jẹ́ káwọn èèyàn bọ́ lọ́wọ́ àṣìlóye àti irọ́ tí kò jẹ́ kí wọ́n lóye ipò táwọn òkú wà.

Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ fún wa pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí? Ọkàn kì í ṣe ohun kan bí òjìji tó ń gbénú ara èèyàn. Kì í ṣe pé èèyàn ní ọkàn. Èèyàn gan-an ni ọkàn, ìyẹn àpapọ̀ “ekuru ilẹ̀” àti ẹ̀mí ìyè tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Ọkàn kì í ṣe ohun tí kò lè kú. Nígbà tí èèyàn bá kú, ọkàn ló kú yẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Oníwàásù 9:5, 10.

Àwọn tó ti kú tún lè padà wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde. Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi fúngbà díẹ̀ bá dópin, “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tí wọ́n sọ ohun búburú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.” (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Àjíǹde yóò mú káwọn èèyàn tún padà wà láàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì máa gbé irú ìgbésí ayé tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ìran èèyàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Máa Fara Balẹ̀ Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́

Ǹjẹ́ o rí i bí níní ìmọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe kókó wọ̀nyí ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Láwọn àkókò lílekoko tó kún fún wàhálà yìí, irú ìmọ̀ yìí lè gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ‘ohun táwọn kan ń fi èké pè ní “ìmọ̀”’ èyí tí Sátánì Èṣù ń tàn kálẹ̀. Ó máa ń díbọ́n bíi “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀,” àwọn aṣojú rẹ̀ náà sì máa ń ṣe bí “òjíṣẹ́ òdodo.” (1 Tímótì 6:20; 2 Kọ́ríńtì 11:13-15) Ìmọ̀ tó péye látinú Bíbélì lè mú kó o bọ́ lọ́wọ́ ayédèrú ìlàlóye, èyí tí wọ́n gbé karí ìmọ̀ “àwọn ọlọ́gbọ́n àtàwọn amòye” ayé yìí, ìyẹn àwọn tó ti “kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà” sílẹ̀.—Mátíù 11:25; Jeremáyà 8:9.

Nítorí pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ tó ń ṣini lọ́nà ló wà nígbà ayé àpọ́sítélì Jòhánù, ó kìlọ̀ fáwọn Kristẹni ọ̀rúndún Kìíní pé: “Ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́.” Ó ní: “Ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:1) Wò ó lọ́nà yìí ná. Ká ní o gba ìsọfúnni kan tó lè yí ìgbésí ayé rẹ padà, ṣé ńṣe ni wàá kàn gbà á láìronú lé e lórí dáadáa nítorí pé ó dà bíi pé ọ̀dọ̀ ẹnì kan tó o lè fọkàn tán ló ti wá? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Wàá wádìí ibi tó ti wá, wàá sì gbé ohun tó wà nínú rẹ̀ yẹ̀ wò dáadáa kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í mú un lò.

Ọlọ́run ti mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe irú ìwádìí bẹ́ẹ̀. Ó pèsè àkọsílẹ̀ kan tó mí sí, èyí tó ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú. Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o lè rí i “dájú” pé ojúlówó ni àwọn ìmọ́lẹ̀ tàbí iná atọ́nisọ́nà tó ò ń tẹ̀ lé. (1 Tẹsalóníkà 5:21) Ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n yin àwọn èèyàn kan tí wọ́n lọ́kàn rere nítorí pé “wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́” láti rí i dájú pé ohun tí wọ́n kọ́ wọn jẹ́ òtítọ́. (Ìṣe 17:11) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kí Bíbélì, tó dá bíi “fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn” ṣamọ̀nà rẹ lọ sí ibi ààbò. (2 Pétérù 1:19-21) Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá “rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an,” èyí tó ń fúnni ní ojúlówó ìlàlóye.—Òwe 2:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Bíi fìtílà ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Kí ni orúkọ Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Báwo lọjọ́ ọ̀la èèyàn ṣe máa rí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ṣé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ibo làwọn òkú wà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àjíǹde àwọn òkú jẹ́ ara àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Bíbélì fi kọ́ni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́