ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 7/1 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Èèyàn Ń Wá Ìlàlóye

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Èèyàn Ń Wá Ìlàlóye
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ipasẹ̀ Ìsìn Léèyàn Máa Fi Rí Ìlàlóye?
  • Ṣé Ipasẹ̀ Ìmọnúúrò Léèyàn Máa Fi Rí Ìlàlóye?
  • Bó O Ṣe Lè Rí Ojúlówó Ìlàlóye
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Máa Bá Ètò Àjọ Jèhófà Rìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Jehofa Ọlọrun Ète
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìbéèrè Pọ̀—Àmọ́ Ìdáhùn Ò Tó Nǹkan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 7/1 ojú ìwé 3-4

Àwọn Èèyàn Ń Wá Ìlàlóye

“KÒ SÍGBÀ kan rí tí àìmọ̀kan sàn ju ìmọ̀ lọ.” Ìyá ààfin Laura Fermi, ìyàwó Ọ̀gbẹ́ni Enrico Fermi tí í ṣe gbajúgbajà nínú ẹ̀kọ́ Físíìsì, ló sọ gbólóhùn yìí. Àwọn kan lè má fara mọ́ ohun tó sọ yìí, wọ́n lè sọ pé ohun tá ò bá mọ̀ kì í pani lára. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, èyí kì í sì í ṣe nínú ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nìkan, àmọ́ ó tún kan àwọn ohun mìíràn pàápàá. Àìmọ̀kan, ìyẹn kéèyàn má mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́, ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa táràrà nínú òkùnkùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lórí àwọn ọ̀ràn tó ní i ṣe pẹ̀lú ìwà rere, ọgbọ́n orí, àti ìjọsìn.—Éfésù 4:18.

Èyí ló mú káwọn èèyàn tó mọnúúrò máa wá ìlàlóye. Wọ́n fẹ́ mọ ìdì tá a fi wà láyé àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́jọ́ iwájú. Bí wọ́n sì ti ń wá ìlàlóye yìí, oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ti tọ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà náà yẹ̀ wò ní ṣókí.

Ṣé Ipasẹ̀ Ìsìn Léèyàn Máa Fi Rí Ìlàlóye?

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ẹ̀sìn Búdà ṣe sọ, ìyà tó ń jẹ aráyé àti ikú tó ń pa wọn kó ìdààmú ọkàn bá Siddhārtha Gautama gan-an, ìyẹn ẹni tó dá ẹ̀sìn Búdà sílẹ̀. Ó wá ní káwọn olùkọ́ ẹ̀sìn Híńdù fi “ọ̀nà òtítọ́” han òun. Àwọn kan lára wọn ní kó lọ máa ṣe àṣàrò yoga kó sì máa ṣẹ́ ara rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́ gidi gan-an. Nígbà tó yá, ṣíṣe àṣàrò jinlẹ̀ ni Gautama wá yàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti rí ojúlówó ìlàlóye.

Oògùn tó ń múni ṣèrànrán làwọn kan ń lò gẹ́gẹ́ bí ohun tó máa jẹ́ káwọn rí ìlàlóye. Bí àpẹẹrẹ, lónìí, àwọn tó jẹ́ ara ṣọ́ọ̀ṣì kan tí wọ́n ń pè ní Ṣọ́ọ̀ṣì Ìbílẹ̀ ti Amẹ́ríkà sọ pé irúgbìn kan tó ní ẹ̀gún lára tó ń jẹ́ peyote tó ń múni ṣèrànrán “máa ń ṣí ìmọ̀ tó fara sin payá.”

Ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jean-Jacques Rousseau tó jẹ́ ọ̀mọ̀ràn láwọn ọdún 1900 ní tiẹ̀ gbà pé ẹnikẹ́ni tó bá fi òótọ́ inú ṣèwádìí yóò rí ìṣípayá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Nípa títẹ́tí sí “ohun tí Ọlọ́run ń bá ọkàn èèyàn sọ ni.” Lẹ́yìn náà, ohun tó bá jẹ́ èrò rẹ nípa nǹkan náà, ìyẹn ohun tí ìrònú rẹ àti ẹ̀rí ọkàn rẹ bá sọ fún ọ ni Rousseau sọ pé yóò wá jẹ́ “ìtọ́sọ́nà tó túbọ̀ dájú nínú ọ̀pọ̀ jaburata èrò ẹ̀dá èèyàn tó ta kókó yìí.”—Látinú ìwé History of Western Philosophy.

Ṣé Ipasẹ̀ Ìmọnúúrò Léèyàn Máa Fi Rí Ìlàlóye?

Ọ̀pọ̀ àwọn tó gbé ayé nígbà kan náà pẹ̀lú Rousseau ni kò fara mọ́ ọ̀nà tí Rousseau sọ pé èèyàn lè gbà rí ìlàlóye yìí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gbẹ́ni Voltaire tóun náà jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé gbà pé ìsìn kò la àwọn èèyàn lóye rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìsìn gan-an ni olórí ohun tó mú kí àìmọ̀kan, gbígba ohun asán gbọ́ àti àìráragba-nǹkan-sí, gbilẹ̀ ní Yúróòpù. Èyí sì wà bẹ́ẹ̀ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, ní sáà táwọn òpìtàn kan pè ní ìgbà Ojú Dúdú.

Ọ̀gbẹ́ni Voltaire wá di ara àjọ ilẹ̀ Yúróòpù kan tí wọ́n ń pè ní àjọ Ìlàlóye tó ń fọgbọ́n orí yanjú ọ̀ràn. Ohun táwọn Gíríìkì ayé ọjọ́un gbà gbọ́ làwọn ọmọ àjọ yìí sì padà sí, ohun náà ni pé, èrò èèyàn àti ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni yóò jẹ́ kéèyàn ní ojúlówó ìlàlóye. Ẹlòmíràn tó tún wà nínú àjọ yìí, ìyẹn ọ̀gbẹ́ni Bernard de Fontenelle, gbà pé èrò èèyàn ti tó láti mú aráyé dé “ọ̀rúndún kan táwọn èèyàn á ti túbọ̀ máa ní òye sí i lójoojúmọ́, débi pé, àkókò àìmọ̀kan ni gbogbo ọ̀rúndún tó ti kọjá yóò jẹ́.”—Látinú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica.

Díẹ̀ péré làwọn wọ̀nyí jẹ́ nínú ọ̀pọ̀ èrò títakora táwọn èèyàn ní nípa bá a ṣe lè rí ìlàlóye. Ǹjẹ́ ‘ìtọ́sọ́nà tó dájú’ kankan wà tá a lè yíjú sí bá a ti ń wá òtítọ́? Wo ohun tí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí sọ nípa ibi tó ṣeé gbára lé tá a ti lè rí ìlàlóye.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Láti lè rí ìlàlóye, ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Gautama (Buddha), Rousseau, àti Voltaire tọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́