Ìforítì Ń Yọrí Sí Ìtẹ̀síwájú
GẸ́GẸ́ BÍ JOSÉ MAGLOVSKY ṢE SỌ Ọ́
Nígbà tí ọlọ́pàá náà gbá mi lọ́wọ́ mú, mo ń fojú wá bàbá mi kiri. Bí ó ti wù kí ó rí, n kò mọ̀ rárá pé, wọ́n ti mú un lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Nígbà tí mo dé ibẹ̀, àwọn ọlọ́pàá gba gbogbo ìtẹ̀jáde wa, títíkan Bibeli wa, wọ́n sì tò wọ́n jọ gègèrè sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀. Rírí tí bàbá mi rí èyí, ó béèrè pé: “Ẹ gbé Bibeli pàápàá sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀?” Ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá náà tọrọ àforíjì, ó sì kó àwọn Bibeli náà ó sì tò wọ́n jọ sí orí tábìlì.
BÁWO ni a ṣe di èrò àgọ́ ọlọ́pàá? Kí ni a ṣe? A ha ń gbé lábẹ́ ìjọba aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀ tí kò gba wíwà Ọlọrun gbọ́ bí, tóbẹ́ẹ̀ tí a fi níláti gba Bibeli pàápàá kúrò lọ́wọ́ wa? Láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, a óò níláti padà sẹ́yìn sí 1925, ṣáájú kí a tó bí mi pàápàá.
Ní ọdún yẹn bàbá mi, Estefano Maglovsky, àti màmá mi, Juliana, fi ibi tí a ń pè ní Yugoslavia nígbà yẹn sílẹ̀ wọ́n sì ṣí lọ sí Brazil, wọ́n fìdí kalẹ̀ sí São Paulo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onísìn Protẹstanti ni Bàbá tí Màmá sì jẹ́ onísìn Katoliki, ìsìn kò fa ìyapa láàárín wọn. Ní tòótọ́, ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà ohun kan ṣẹlẹ̀ tí ó so wọ́n papọ̀ níti ìsìn. Àna Bàbá tí ó jẹ́ ọkùnrin mú ìwé pẹlẹbẹ aláwọ̀ mèremère tí a kọ ní èdè Hungary tí ó jíròrò nípa ipò tí àwọn òkú wà wá fún un. A fi ìwé pẹlẹbẹ náà ta á lọ́rẹ ni, ó sì ní kí Bàbá kà á kí ó sì sọ èrò rẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ fún òun, ní pàtàkì apá tí ó dá lórí “hẹ́ẹ̀lì.” Dádì lo gbogbo òru láti ka ìwé pẹlẹbẹ náà ni àkàtúnkà, ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àna rẹ̀ ọkùnrin wá láti gbọ́ èrò rẹ̀, Bàbá polongo láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ pé: “Òtítọ́ rè é!”
Ìbẹ̀rẹ̀ Kékeré
Níwọ̀n bí ìtẹ̀jáde náà ti ti ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wá, àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí wá wọn kiri kí wọ́n baà lè kẹ́kọ̀ọ́ síi nípa èrò-ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ wọn. Nígbà tí wọ́n rí wọn nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, mélòókan lára mẹ́ḿbà ìdílé wa bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí. Ní ọdún yẹn kan náà, 1935, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé ní èdè Hungarian, ẹni mẹ́jọ sì ń pésẹ̀ ní ìpíndọ́gba, láti ìgbà náà wá a ti ń ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní ilé wa.
Lẹ́yìn ọdún méjì tí Bàbá ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó ṣe ìrìbọmi ní 1937 ó sì di Ẹlẹ́rìí onítara fún Jehofa, ó ń lọ́wọ́ nínú wíwàásù láti ilé dé ilé ó sì ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tí a yàn sípò àti olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́. Ó ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní São Paulo, ní apá Vila Mariana. A kó ìjọ náà lọ sí àárín gbùngbùn ìlú-ńlá lẹ́yìn náà a sì wá mọ̀ ọ́n sí Ìjọ Central. Ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà a dá ìjọ kejì sílẹ̀, ní agbègbè Ypiranga, a sì yan Bàbá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìjọ níbẹ̀. Ní 1954 a dá ìjọ kẹta sílẹ̀, ní apá Moinho Velho, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìjọ.
Bí àwùjọ yìí ti ń fìdí múlẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ran àwùjọ itòsí kan ní São Bernardo do Campo lọ́wọ́. Ọpẹ́ ni fún ìbùkún Jehofa lórí ìsapá àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kékeré wọ̀nyí láti àwọn ọdún yìí wá, ìdàgbàsókè ti jẹ́ ohun àrà, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ní 1994 akéde tí ó lé ní 70,000 ti wà ní ìjọ 760 ní São Paulo tí ó ti tóbi síi. Ó ṣeni láàánú pé, Bàbá kò sí láàyè mọ láti rí ìdàgbàsókè yìí. Ó kú ní 1958 ni ẹni ọdún 57.
Lílàkàkà Láti Tẹ̀lé Àpẹẹrẹ Bàbá
Ànímọ́ títayọ kan tí bàbá mi ní, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń rí pẹ̀lú àwọn Kristian tí wọ́n dàgbàdénú, ni aájò àlejò. (Wo 3 Johannu 1, 5-8.) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, a ní àǹfààní láti gba Antonio Andrade àti aya rẹ̀ àti ọmọkùnrin rẹ̀, tí wọ́n wá sí Brazil láti United States pẹ̀lú Arákùnrin àti Arábìnrin Yuille ní 1936 lálejò. A tún gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege méjì ti Watchtower Bible School of Gilead, Harry Black àti Dillard Leathco lálejò, àwọn tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí a yàn sí Brazil ní 1945. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tún wá. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyí jẹ́ orísun ìṣírí nígbà gbogbo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ìdílé wa. Ní ìmọrírì èyí àti àǹfààní tí ìdílé mi jẹ, mo ti làkàkà láti ṣàfarawé àpẹẹrẹ bàbá mi níti ànímọ́ Kristian ti níní aájò àlejò.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́sàn-án péré nígbà tí Bàbá mi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní 1935, gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin tí ó dàgbà jùlọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí bá a lọ sí àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọrun. Gbogbo wa máa ń bá a lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà ní orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ní São Paulo ní Òpópónà Eça de Queiroz, Ojúlé 141. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀kọ́ àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Bàbá fún mi, mo mú ìfẹ́-ọkàn gbígbóná dàgbà láti ṣiṣẹ́sin Jehofa, àti ní 1940, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jehofa, ní fífi àpẹẹrẹ èyí hàn nípa ìrìbọmi ní Odò Tietê tí a ti bàjẹ́ báyìí, tí ń ṣàn kọjá ní àárín gbùngbùn São Paulo.
Kò pẹ́ púpọ̀ tí mo fi kọ́ nípa ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ti ìhìnrere, tí ń gbìn tí ó sì ń bomirin ìhìn-iṣẹ́ òtítọ́ náà nínú àwọn ẹlòmíràn tí ó sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé pẹ̀lú wọn. Nísinsìnyí, bí mo ti ń rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùṣèyàsímímọ́ Ẹlẹ́rìí fún Jehofa ní Brazil, mo ń nímọ̀lára ìdùnnú-ayọ̀ jíjinlẹ̀ ti mímọ̀ pé a ti lò mí nípasẹ̀ Rẹ̀ láti ran púpọ̀ lára wọn lọ́wọ́ láti wá sí ìmọ̀ òtítọ́ tàbí kí wọ́n mú ìmọrírì wọn fún un jinlẹ̀ síi.
Lára àwọn tí mo ràn lọ́wọ́ ni Joaquim Melo, ẹni tí mo bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé. Mo ń bá àwọn ọkùnrin mẹ́ta mìíràn tí wọ́n ń tẹ́tísílẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọn kò ní ọkàn-ìfẹ́ púpọ̀ sọ̀rọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni mo kíyèsí ọmọdékùnrin kan tí ó darapọ̀ mọ́ wa tí ó sì ń tẹ́tísílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́. Ní rírí ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀, mo darí àfiyèsí mi sí i, lẹ́yìn ìjẹ́rìí tí ó jíire, mo késí i fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Kò wá sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ṣùgbọ́n ó wá sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun lẹ́yìn náà ó sì ń wá sí àwọn ìpàdé déédéé. Ó ní ìtẹ̀síwájú tí ó dára, ó ṣe ìrìbọmi, ó sì ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò fún ọdún mélòókan, papọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀.
Arnaldo Orsi náà wà lára wọn, ẹni tí mo bá pàdé ní ibi iṣẹ́ mi. Mo máa ń jẹ́rìí fún òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan déédéé ṣùgbọ́n mo ṣàkíyèsí pé ọkùnrin onírungbọ̀n kan máa ń tẹ́tísílẹ̀ nígbà gbogbo, nítorí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Ó wá láti inú ìdílé tí ó jẹ́ alátìlẹ́yìn gbágbágbá fún ìsìn Katoliki ṣùgbọ́n ó ń béèrè àwọn ìbéèrè púpọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn bíi sìgá mímu, wíwo fíìmù tí ń fi ìbálòpọ̀ hàn, àti lílo ọgbọ́n ìdáàbòbo ara-ẹni ti judo. Mo fi ohun tí Bibeli sọ hàn án, sí ìyàlẹ́nu tí ó mú ìdùnnú-ayọ̀ wá fún mi, ó késí mi ní ọjọ́ kejì láti wá wo bí òun yóò ṣe kán ìkòkò àti ìtanná-sìgá òun papọ̀ pẹ̀lú àgbélébùú òun, bí òun yóò ṣe ba fíìmù òun tí ń fi ìbálòpọ̀ hàn jẹ́, tí òun yóò sì fá irungbọ̀n òun kúrò. Láàárín àkókò díẹ̀ ẹ wo bí ọkùnrin náà ti yàtọ̀ tó! Ó tún dẹ́kun jíja judo ó sì béèrè fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú mi lójoojúmọ́. Láìka àtakò láti ọ̀dọ̀ aya àti bàbá rẹ̀ sí, ó tẹ̀síwájú lọ́nà tí ó dára nípa tẹ̀mí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn arákùnrin tí ń gbé nítòsí rẹ̀. Láìpẹ́, ó ṣe ìrìbọmi ó sì ń ṣiṣẹ́sìn lónìí gẹ́gẹ́ bí alàgbà ìjọ. Aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú tẹ́wọ́gba òtítọ́.
Lílọ́wọ́ Nínú Iṣẹ́-Ìsìn Ìjọba
Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ẹni ọdún 14, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tí ń polówó ọjà, níbi tí mo ti kọ́ bí a ṣe ń fi ọ̀dà kọ àkọlé. Èyí wúlò gidigidi, fún ọdún mélòókan ní São Paulo èmi nìkan ní arákùnrin tí ń lo ọ̀dà láti kọ àkọlé sára àwọn ìsọfúnni àgbékiri àti àwọn àmì òpópónà tí ń polówó àwọn àwíyé fún gbogbo ènìyàn àti àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 30 ọdún, mo ní àǹfààní láti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó Ẹ̀ka Iṣẹ́ Tí Ń Kọ Àkọlé ní àpéjọpọ̀. Mo máa ń fìgbà gbogbo tọ́jú àkókò ìsinmi mi kí n baà lè ṣiṣẹ́ ní àwọn àpéjọpọ̀, mo tilẹ̀ máa ń sùn sí gbọ̀ngàn àpéjọpọ̀ náà kí n lè rí i pé a kọ àwọn àkọlé náà lákòókò.
Mo tún ní àǹfààní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Society tí a so gbohùngbohùn mọ́, èyí ṣàjèjì ní àkókò yẹn. A óò gbé àwọn ìtẹ̀jáde Bibeli wa sórí pátákó, bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí a so gbohùngbohùn mọ́ náà bá ti ń gbé ìhìn-iṣẹ́ tí a ti gbà sílẹ̀ náà sáfẹ́fẹ́, a óò máa bá àwọn ènìyàn tí wọ́n jáde wá láti inú ilé wọn láti rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sọ̀rọ̀. Ọ̀nà mìíràn tí a lò láti mú kí ìhìnrere Ìjọba náà di mímọ̀ ni ẹ̀rọ ìkọrin alágbèérìn, mo ṣì ní àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù náà tí a lò láti gbé ìtẹ̀jáde Society kalẹ̀ lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni a tipa bẹ́ẹ̀ fi síta.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki máa ń tòlọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn ní àwọn òpópónà São Paulo, àwọn ọkùnrin ni ó máa ń ṣáájú lọ́pọ̀ ìgbà láti pa ọ̀nà mọ́. Ní ọjọ́ Sunday kan, èmi àti Bàbá ń fi Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! lọni ní òpópónà nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń tòlọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn yọ. Ate Bàbá ń bẹ lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tí ó wà níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń tòlọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn náà kígbe pé: “Ṣí ate rẹ! Ṣé o kò ríi pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tòlọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn bọ̀ ni?” Nígbà tí Bàbá kò ṣí ate rẹ̀, àwọn ọkùnrin púpọ̀ síi wá, wọ́n taari wa sí ẹ̀gbẹ́ fèrèsé ilé ìtajà kan tí wọ́n sì dá wàhálà sílẹ̀. Èyí pe àfiyèsí ọlọ́pàá kan, tí ó wá láti wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin náà di apá rẹ̀ mú, tí ó sì ń fẹ́ láti bá a sọ̀rọ̀. Ọlọ́pàá náà pàṣẹ, ní gbígbá ọwọ́ ọkùnrin náà sọnù pé, “Mọ́wọ́ rẹ kúrò lára aṣọ iṣẹ́ mi!” Lẹ́yìn náà ó béèrè ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Ọkùnrin náà ṣàlàyé pé Bàbá kò fẹ́ ṣí ate rẹ̀ nítorí ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn náà, ó sì fi kún un pé: “Aposteli onísìn Roman Katoliki ni mi.” Ìdáhùn náà tí a kò retí ni pé: “O sọ pé ará Romu ni ọ́? Padà sì Romu nígbà náà! Brazil ni a wà yìí.” Lẹ́yìn náà ni ó yíjú sí wa, ní bíbéèrè pé: “Ta ni ó kọ́kọ́ débí?” Nígbà tí Bàbá dáhùn pé àwa ni, ọlọ́pàá náà lé àwọn ọkùnrin náà lọ ó sì sọ fún wa pé kí a máa bá iṣẹ́ wa lọ. Ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ wa títí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń tòlọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn náà fi wọ́ lọ tán—Bàbá kò ṣí ate rẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀!
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báwọ̀nyí kò wọ́pọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ṣẹlẹ̀, ó máa ń fúnni ní ìṣírí láti mọ̀ pé àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n gbàgbọ́ pé ìdájọ́-òdodo gbọ́dọ̀ wà fún àwọn tí wọ́n kéré tí wọn kò sì gbà pé ohunkóhun tí Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki bá ti sọ ni abẹ́ gé.
Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, mo bá ọ̀dọ́langba kan pàdé tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn tí ó sì ní kí n padà wá ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀lé e. Nígbà tí mo padà dé ibẹ̀ ó gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀ ó sì ní kí n wọlé. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìyàlẹ́nu tó fún mi láti rí ara mi láàárín àjọ-ìpàǹpá àwọn ọ̀dọ́ tí ń fi mi ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n sì ń fẹ́ láti mú mi bínú! Ipò-ọ̀ràn náà burú síi, mo sì nímọ̀lára pé wọn yóò kọlù mí láìpẹ́. Mo sọ fún èyí tí ó késí mi wọlé pé bí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí mi, òun ni yóò dáhùn fún un àti pé ìdílé mi mọ ibi tí mo wà. Mo ní kí wọ́n jẹ́ kí n máa lọ, wọ́n sì gbà. Bí ó ti wù kí ó rí, ṣáájú kí n tó lọ, mo ní bí ẹnikẹ́ni lára wọn bá fẹ́ láti bá mi sọ̀rọ̀ ni òun nìkan, èmi yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, mo gbọ́ pé wọ́n jẹ́ àwùjọ àwọn agbawèrèmẹ́sìn, ọ̀rẹ́ àlùfáà àdúgbò náà tí ó ti fún wọn ní ìṣírí láti ṣètò ìpàdé yìí. Inú mi dùn pé mo bọ́ lọ́wọ́ wọn.
Àmọ́ ṣáá o, ní ìbẹ̀rẹ̀, ìtẹ̀síwájú ní Brazil falẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má tó nǹkan. A wà ní ìpele ìbẹ̀rẹ̀ ti “gbígbìn,” pẹ̀lú àkókò kékeré tí ó wà láti “roko” kí a sì “kórè” èso iṣẹ́ ọwọ́ wa. Ìgbà gbogbo ni a máa ń rántí ohun tí aposteli Paulu kọ pé: “Emi gbìn, Apollo bomirin, ṣugbọn Ọlọrun ń mú kí ó máa dàgbà; tí ó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tí ń gbìn ni ó jẹ́ nǹkankan tabi ẹni tí ń bomirin, bíkòṣe Ọlọrun tí ń mú kí ó dàgbà.” (1 Korinti 3:6, 7) Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege Gileadi méjì dé ní 1945, a nímọ̀lára pé àkókò ìdàgbàsókè tí a ti ń retí tipẹ́tipẹ́ náà ti dé.
Jíjẹ́ Onígboyà Lójú Àtakò
Ìdàgbàsókè kò lè wá láìsí àtakò, bí ó ti wù kí ó rí, ní pàtàkì lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé II bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Europe. Inúnibíni ní tààràtà wà nítorí pé àwọn ènìyàn náà ní gbogbogbòò àti àwọn aláṣẹ kan kò lóye ìdúró àìdásí tọ̀tún tòsì wa. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ní 1940, nígbà tí a ń ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí òpópónà pẹ̀lú ìṣọfúnni àgbékiri ní àárín gbùngbùn São Paulo, ọlọ́pàá kan tọ̀ mí wá látẹ̀yìn, ó ya ìṣọfúnni àgbékiri náà, ó sì di ọwọ́ mi mú láti mú mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Mo ń fojú wá bàbá mi kiri, ṣùgbọ́n n kò rí i. N kò mọ̀ pé, òun àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin mélòókan, àti Arákùnrin Yuille pẹ̀lú, ẹni tí ń bójútó iṣẹ́ ní Brazil, ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá ṣáájú. Bí mo ṣe sọ ní ìpínrọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀, níbẹ̀ ni mo ti pàdé Bàbá lẹ́ẹ̀kan síi.
Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ aláìtójúúbọ́, a kò lè tì mí mọ́lé, ọlọ́pàá kan sì mú mi lọ́ sílé ó sì fà mí lé màmá mi lọ́wọ́. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà a dá àwọn arábìnrin náà sílẹ̀. Lẹ́yìn náà àwọn ọlọ́pàá pinnu láti dá gbogbo àwọn arákùnrin sílẹ̀, àwọn bíi mẹ́wàá, àyàfi Arákùnrin Yuille. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn arákùnrin náà fàáké kọ́rí pé: “Nínú kí gbogbo wa lọ tàbí kí ẹnikẹ́ni má lọ.” Àwọn ọlọ́pàá ranrí, nítorí bẹ́ẹ̀ gbogbo wọn lo òru ọjọ́ náà papọ̀ nínú iyàrá tí ó tutù lórí ilẹ̀yílẹ̀. Ní ọjọ́ kejì a dá gbogbo wọn sílẹ̀ láìsí ipò àfilélẹ̀ kankan. A fàṣẹ ọba mú àwọn arákùnrin ní ìgbà mélòókan fùn jíjẹ́rìí pẹ̀lú ìsọfúnni àgbékiri. Àwọn àkọlé náà máa ń kéde ọ̀rọ̀-àwíyé fún gbogbo ènìyàn àti ìwé pẹlẹbẹ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fascism or Freedom, àwọn aláṣẹ kan sì gbà á sí pé a faramọ́ ètò ìjọba Fascist, èyí tí ó wá yọrí sí àṣìlóye.
Iṣẹ́ ológun tí a kàn nípá tún gbé ìṣòro dìde fún àwọn ọ̀dọ́ arákùnrin. Ní 1948, èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí a jù sẹ́wọ̀n lórí ọ̀ràn yìí ní Brazil. Àwọn aláṣẹ kò mọ ohun tí wọ́n lè ṣe sí mi. A gbé mi lọ sí bárékè àwọn ológun ní Caçapava a sì ní kí n máa gbin ewébẹ̀ kí n sì máa bójútó wọn nínú ọgbà ki n sì tún máa tọjú iyàrá tí àwọn lọ́gàá lọ́gàá ti máa ń fi idà tẹ́ẹ́rẹ́ jà. Mo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti jẹ́rìí kí n sì fi ìtẹ̀jáde sílẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin náà. Ọ̀gá tí ó jẹ́ olùdarí ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó tẹ́wọ́gba ẹ̀dà ìwé Society náà Children. Lẹ́yìn náà, wọ́n yanṣẹ́ fún mi láti bá àwọn sọ́jà bíi 30 tàbí 40 tí kò lè ṣe eré ìdárayá tí a há mọ́ iyàrá kan sọ̀rọ̀ nípa ìsìn. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́wàá nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, a gbọ ẹjọ́ mi a sì dá mi sílẹ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa, ẹni tí ó fún mi ní okun láti lè dojúkọ ìhalẹ̀mọ́ni, àbùkù, àti ìfiniṣeyẹ̀yẹ́ tí mo gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn kan nínú àwọn ọkùnrin náà.
Olùrànlọ́wọ́ Tí Ó Jẹ́ Olùṣòtítọ́ àti Adúróṣinṣin
Ní June 2, 1951, mo gbé Barbara níyàwó, láti ìgbà náà wá ni ó sì ti jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ adúróṣinṣin àti olùṣòtítọ́ ní kíkọ́ àwọn ọmọ wa àti títọ́ wọn dàgbà nínú “ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.” (Efesu 6:4) Nínú àwọn ọmọ wa márùn-ún, mẹ́rin ń fi ìdùnnú-ayọ̀ ṣiṣẹ́sin Jehofa ní àwọn ipò yíyàtọ̀ síra. Ìrètí wa ni pé, papọ̀ pẹ̀lú àwa náà, wọn yóò máa bá a nìṣó láti máa lo ìforítì nínú òtítọ́ wọn yóò sì máa fi kún ìtẹ̀síwájú ètò-àjọ náà àti iṣẹ́ tí ó ti ṣe. Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ń bẹ nínú fọ́tò tí ó wà níhìn-ín jẹ́ ìránṣẹ́ olùṣèyàsímímọ́ fún Jehofa àyàfi èyí tí ó kéré jùlọ, ọmọ kékeré tí a gbé lọ́wọ́. Àwọn mẹ́rin jẹ́ alàgbà méjì lára àwọn alàgbà náà sì tún jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ní ṣíṣàpèjúwe ìjótìítọ́ Owe 17:6 pé: “Ọmọ ọmọ ni adé arúgbó: ògo àwọn ọmọ sì ni bàbá wọn.”
Wàyí o, ni ẹni ọdún 68, ìlera mi kò fi bẹ́ẹ̀ dára. Ní 1991, mo gbà láti farada iṣẹ́-abẹ́ àtúnṣe iṣan-ẹ̀jẹ̀ mẹ́ta àti lẹ́yìn náà iṣẹ́-abẹ fífi rọ́bà tẹ́ẹ́rẹ́ pààrọ̀ iṣan-ẹ̀jẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, inu mi dùn pé mo ń bá a nìṣó ní ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága ní ìjọ kan ní São Bernardo do Campo, ní títẹ̀lé ipasẹ̀ bàbá mi, ẹni tí ó wà lára àwọn ẹni àkọ́kọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà níhìn ín. Ìran wa yàtọ̀ níti gidi, ní níní àǹfààní náà láti ṣàjọpín àǹfààní tí a kò tún ní túnṣe mọ́ láé náà ti kíkéde ìdásílẹ̀ Ìjọba Messia Jehofa. Nítorí náà a kò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ Paulu sí Timoteu láé pé: “Iwọ, bí ó ti wù kí ó rí, . . . ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.”—2 Timoteu 4:5.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn òbí mi, Estefano àti Juliana Maglovsky
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
José àti Barbara pẹ̀lú àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ olùṣèyàsímímọ́ fún Jehofa