ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 2/1 ojú ìwé 3
  • Iṣẹ́ Àṣekára—Ṣé Ó Ṣì Níyì Lóde Òní?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣẹ́ Àṣekára—Ṣé Ó Ṣì Níyì Lóde Òní?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí O Ṣe Lè Gbádùn Iṣẹ́ Àṣekára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • O Lè Gbádùn Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Gbádùn Gbogbo Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? (Apá Kìíní)
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 2/1 ojú ìwé 3
Ọkùnrin kan tí gbogbo nǹkan ti sú jókòó, ó ń ronú, àwọn ìyókù rẹ̀ ń bá iṣẹ́ lọ

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÍ O ṢE LÈ GBÁDÙN IṢẸ́ RẸ

Iṣẹ́ Àṣekára—Ṣé Ó Ṣì Níyì Lóde Òní?

Iléeṣẹ́ akẹ́rù kan ni Alex ti ń ṣiṣẹ́. Lọ́jọ́ kan tó ti ṣiṣẹ́ tó ti rẹ̀ ẹ́, ìrònú bá a, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara rẹ̀ pé: ‘Irú iṣẹ́ rádaràda wo tiẹ̀ ni mò ń ṣe yìí ná? Ìgbà wo lèmi náà máa rí towó ṣe? Kí n má tiẹ̀ ṣiṣẹ́ rárá gan-an sàn ju èyí lọ!’

Bíi ti Alex, ọ̀pọ̀ lónìí ni kò gbádùn kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ àṣekára. Mẹkáníìkì kan tó ń jẹ́ Aaron sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ò fẹ́ ṣe àwọn iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ mọ́, wọ́n á ní ‘kọ́wọ́ máà dilẹ̀ ni mò ń fi eléyìí ṣe títí dìgbà tí màá fi rí iṣẹ́ gidi.’”

Kí nìdí táwọn èèyàn ò fi fẹ́ ṣe iṣẹ́ àṣekára mọ́? Ó lè jẹ́ nítorí èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní lónìí pé ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ìrọ̀rùn tó sì rọra ń jayé lẹni tó ti “rí ṣe.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Matthew, tó máa ń ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́ lára ilé sọ pé: “Àwọn èèyàn gbà pé kò dìgbà téèyàn bá forí ṣe fọrùn ṣe kó tó lówó láyé táa wà yìí, òṣìṣẹ́ ńbẹ lóòrùn, náwó náwó ńbẹ ní ibòji.” Ẹlòmíì tó ń jẹ́ Shane, tó ń ṣiṣẹ́ aṣọ́gbà sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Iṣẹ́ kékeré owó ńlá ni àwọn èèyàn tún ń lé kiri lónìí.”

Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ tó rọ́wọ́ mú lónìí ló gbádùn àtimáa ṣe iṣẹ́ àṣekára. Daniel tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tó sì ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé sọ pé: “Èrè wà nínú iṣẹ́ àṣekára téèyàn bá ń ṣe nǹkan tó ní láárí.” Andre ẹni ọdún mẹ́tàlélógún [23] náà gbà pẹ̀lú òun tí Daniel sọ, ó ní: “Ohun tí mo mọ̀ ni pé ayọ̀ àti ìgbádùn wà nínú iṣẹ́ àṣekára, bó bá jẹ́ pé iṣẹ́ kékeré lèèyàn ń ṣe, kò ní pẹ́ tá a fi sú u, ó sì lè má láyọ̀.”

Kí ló mú kí Daniel àti Andre ní èrò tó yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ èèyàn nípa iṣẹ́ àṣekára? Ìlànà Bíbélì ló ràn wọ́n lọ́wọ́. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé ó dáa kéèyàn ṣiṣẹ́ kára kó sì lẹ́mìí ìfaradà. Àmọ́ ó tún jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè gbádùn iṣẹ́ wa.

Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbádùn iṣẹ́ rẹ? Jẹ́ ká gbé mélòó kan yẹ̀ wò nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́