ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ONÍWÀÁSÙ 1-6
Gbádùn Gbogbo Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ
Jèhófà fẹ́ ká gbádùn iṣẹ́ wa, ó sì kọ́ wa ní ohun tá a lè ṣe láti gbádùn iṣẹ́ wa. Èèyàn lè gbádùn iṣẹ́ rẹ̀ tó bá kọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́ náà.
O lè gbádùn iṣẹ́ rẹ tó o bá ń . . .
fi ojú tó tọ́ wo iṣẹ́ náà
ronú nípa bí iṣẹ́ rẹ ṣe ń ṣe àwọn míì láǹfààní
ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà, àmọ́ tó o bá ti kúrò níbi iṣẹ́, pọkàn pọ̀ sórí ìdílé rẹ àti ìjọsìn rẹ