ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 4/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo ni ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan ṣe máa dópin?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 4/1 ojú ìwé 16

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Báwo ni ọjọ́ ọlá àwa èèyàn ṣe máa rí?

Ìdílé kan ń fìfẹ́ hàn sí obìnrin àgbàlagbà kan tí wọn kì í ṣe ẹ̀yà kan náà

BÁwo ni ikú Jésù ṣe máa mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn?

Ó dájú pé àwọn èèyàn á ṣì máa tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Àmọ́, ṣé àwọn fúnra wọn lè ṣe ohun tó máa mú kí gbogbo èèyàn nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú? Rárá o. Lóde òní, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwọra ló kún inú ayé. Àmọ́, ohun tó dára gan-an ni Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn.—Ka 2 Pétérù 3:13.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé, lọ́jọ́ iwájú gbogbo èèyàn kárí ayé máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. A ó máa gbé nínú ààbò, ẹnì kankan ò sì ní kó ìpayà bá wa.—Ka Míkà 4:3, 4.

Báwo ni ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan ṣe máa dópin?

Ọlọ́run ò dá ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan mọ́ àwa èèyàn. Àmọ́, nítorí pé ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, èyí mú kó di aláìpé. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ la sì ti jogún ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run máa tipasẹ̀ Jésù sọ aráyé di pípé pa dà.—Ka Róòmù 7:21, 24, 25.

Ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, Jésù kú ikú ìrúbọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwa èèyàn bọ́ lọ́wọ́ ohun tí àìgbọràn ọkùnrin àkọ́kọ́ fà. (Róòmù 5:19) Torí náà, Jésù mú kó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti ní ọjọ́ ọlá àgbàyanu, nígbà tí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan kò ní mú káwọn èèyàn máa hùwà burúkú mọ́.—Ka Sáàmù 37:9-11.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 5 nínú ìwé yìí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́