ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp17 No. 2 ojú ìwé 3-4
  • Ẹ̀bùn Tó Ju Gbogbo Ẹ̀bùn Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀bùn Tó Ju Gbogbo Ẹ̀bùn Lọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí Ẹ̀bùn Yìí Fi Ṣe Iyebíye Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Kí Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Ju Gbogbo Ẹ̀bùn Lọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Bí Iṣẹ́ Tí Jésù Kristi Jẹ́ Ṣe Kàn Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
wp17 No. 2 ojú ìwé 3-4
Bàbá àgbàlagbà kan fún ọmọdékùnrin kan ní ohun èlò kékeré tí wọ́n fi ń gbẹ́ pẹ́ńsù

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ WÀÁ GBA Ẹ̀BÙN ỌLỌ́RUN TÓ DÁRA JÙ?

Ẹ̀bùn Tó Ju Gbogbo Ẹ̀bùn Lọ

JORDAN sọ pé: “Bàbá àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Russell fún mi ní ẹ̀bùn kan nígbà tí mo wà ní kékeré.” Ohun èlò kékeré kan tí wọ́n fi ń gbẹ́ pẹ́ńsù ni ẹ̀bùn náà, ó sì dà bí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú. Síbẹ̀, Jordan ka ẹ̀bùn yẹn sí pàtàkì. Lẹ́yìn tí Russell kú, Jordan wá mọ̀ pé igi lẹ́yìn ọgbà ni Russell jẹ́ fún bàbá bàbá rẹ̀ àtàwọn òbí rẹ̀, pàápàá lásìkò tí nǹkan le koko fún wọn. Jordan sọ pé: “Ní báyìí tí mo ti wá mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Russell, ẹ̀bùn kékeré tó fún mi yìí ti wá ṣe pàtàkì sí mi gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

Bá a ṣe rí i nínú ọ̀rọ̀ Jordan, ẹ̀bùn kan lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lójú ẹnì kan, àmọ́ kó ṣe pàtàkì gan-an lójú ẹlòmíì, pàápàá tó bá jẹ́ ẹni tó máa ń mọyì nǹkan. Bíbélì lo ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó yìí láti ṣàpèjúwe ẹ̀bùn kan tí kò láfiwé, ó ní: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Jòhánù 3:16.

Ẹni tó bá gba ẹ̀bùn yìí máa ní ìyè àìnípẹ̀kun! Ǹjẹ́ ẹ̀bùn míì wà tó tún ṣe pàtakì ju èyí lọ? Òótọ́ ni pé àwọn kan lè má ka ẹ̀bùn yìí sí pàtàkì, àmọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ kà á sí ohun “iyebíye.” (Sáàmù 49:8; 1 Pétérù 1:​18, 19) Kí wá nìdí tí Ọlọ́run fi fi ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ ṣe ẹ̀bùn fún gbogbo aráyé?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 5:12) Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ mọ̀ọ̀mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, torí náà Ọlọ́run fìyà ikú jẹ ẹ́. Ipasẹ̀ Ádámù sì ni ikú gbà wá sórí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, ìyẹn ìran èèyàn lápapọ̀.

“Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Kí àwa èèyàn lè bọ́ lọ́wọ́ ikú, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi wá sáyé, kó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé rúbọ fún aráyé. Nítorí ìrúbọ tí Jésù ṣe yìí, tá a tún mọ̀ sí “ìràpadà,” gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jésù máa ní ìyè àìnípẹ̀kun.​—Róòmù 3:24.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ kan nípa ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fẹ́ fún àwọn olùjọsìn rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi, ó ní: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.” (2 Kọ́ríńtì 9:15) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìràpadà yìí ṣe pàtàkì gan-an débi pé ó kọjá ohun téèyàn lè ṣàpèjúwe. Àmọ́, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìràpadà yìí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ lára gbogbo ẹ̀bùn rere tí Ọlọ́run fún aráyé? Ọ̀nà wo ni ìràpadà fi ju gbogbo àwọn ẹ̀bùn míì tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lọ?a Kí ló sì yẹ ká ṣe sí ẹ̀bùn yìí? A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ méjì tó kàn.

a Jésù “fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fún wa” tinútinú. (1 Jòhánù 3:16) Àmọ́, torí pé ara ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé ni irúbọ Jésù jẹ́, nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí, ipá tí Ọlọ́run kó láti pèsè ìràpadà náà la máa jíròrò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́