Oro Isaaju
KÍ LÈRÒ RẸ?
Ọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin yìí ló gba àfiyèsí jù lọ nínú àwọn ìran inú ìwé Ìfihàn tàbí Ìṣípayá, ìyẹn ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì. Ìran náà máa ń ba àwọn kan lẹ́rù. Ó sì máa ń múnú àwọn míì dùn. Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ báyìí:
“Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tí ń gbọ́.”—Ìṣípayá 1:3.
Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin yìí ṣe lè já sí ìròyìn ayọ̀ fún wa.