Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀
Ṣé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ?
Bá a ṣe ń rí i tí àjálù ń ṣẹlẹ̀, tí ìyà sì ń jẹ àwọn èèyàn, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá ni Ọlọ́run rí tiwa rò. Bíbélì sọ pé:
“Nítorí tí ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; ṣùgbọ́n ojú Jèhófà lòdì sí àwọn tí ń ṣe àwọn ohun búburú.”—1 Pétérù 3:12.
Ilé Ìṣọ́ yìí jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ àti ohun tó ń ṣe láti fòpin sí gbogbo ìyà.