ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w19 April ojú ìwé 31
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Kò sí Ìkankan Lára Yín Tó Máa Ṣègbé”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • “Nínú Àwọn Ewu Odò”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìrìn Àjò sí Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìfẹ́ Tí Ń Soni Pọ̀
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
w19 April ojú ìwé 31
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá òṣìṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi kan sọ̀rọ̀ nítòsí ọkọ̀ ojú omi kan

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Báwo làwọn èèyàn nígbà àtijọ́ ṣe máa ń ṣètò láti bá ọkọ̀ ojú omi rìn?

LÁYÉ ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ẹrù nìkan lọkọ̀ ojú omi sábà máa ń gbé. Torí náà, tẹ́nì kan bá máa rìnrìn-àjò, ó máa ní láti wádìí bóyá ọkọ̀ ẹrù kan ń lọ síbi tóun ń lọ àti pé ṣé awakọ̀ náà á fẹ́ gbé èrò. (Ìṣe 21:2, 3) Ká tiẹ̀ sọ pé ọkọ̀ náà kò ní débi tí ẹni náà ń lọ, tó bá lè gbé e dé èbúté míì, á wá ọkọ̀ tó máa gbé e débi tó ń lọ.​—Ìṣe 27:1-6.

Kì í ṣe ìgbà gbogbo làwọn ọkọ̀ ojú omi máa ń rìn lójú agbami, torí náà èèyàn ò lè sọ pé ọjọ́ báyìí ni wọ́n máa ṣí. Lára ohun tó máa ń fa ìdíwọ́ ni ojú ọjọ́ tí kò fara rọ tàbí tí awakọ̀ náà bá ní èrò òdì. Ó lè sọ pé torí pé ẹyẹ ìwò kan ké lórí igi tí wọ́n fi di ọkọ̀ mú lòun ò ṣe fẹ́ gbéra. Yàtọ̀ síyẹn, tí wọ́n bá rí àfọ́kù ọkọ̀ ojú omi létí òkun, wọ́n lè kọ̀ láti gbéra. Àmọ́ tí ojú ọjọ́ bá dáa, tí afẹ́fẹ́ kò sì ṣèdíwọ́, awakọ̀ máa gbéra. Tẹ́ni tó ń rìnrìn àjò bá mọ̀ pé ọkọ̀ kan máa rìnrìn àjò, á lọ sítòsí etíkun náà, tòun tẹrù ẹ̀, á sì máa retí ìgbà tí wọ́n máa kéde àsìkò tí ọkọ̀ náà máa gbéra.

Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Lionel Casson sọ pé: “Ìlú Róòmù ní àwọn ètò kan tó mú kó rọrùn fáwọn tó bá fẹ́ rìnrìn àjò. Wọ́n ní èbúté kan ní etíkun Tiber, wọ́n sì ní àwọn ọ́fíìsì mélòó kan nílùú Ostia tí kò jìnnà púpọ̀ sí etíkun náà. Àwọn tó ni ọkọ̀ ojú omi yẹn ló ni àwọn ọ́fíìsì yìí. Ọ̀kan lára wọn jẹ́ ti Narbonne [tá a mọ̀ sórílẹ̀-èdè Faransé báyìí], òmíràn jẹ́ ti Carthage [tá a mọ̀ sórílẹ̀-èdè Tùníṣíà báyìí], . . . àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Torí náà, tẹ́nì kan bá fẹ́ rìnrìn àjò, ohun tó máa ṣe ni pé kó lọ sí ọ̀kan lára àwọn ọ́fíìsì náà, kó sì béèrè èyí tó ń lọ síbi tó fẹ́.”

Ìrìn àjò ojú omi fini lọ́kàn balẹ̀, ó sì yá ju kéèyàn fẹsẹ̀ rìn nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àmọ́ òun náà ní ewu tiẹ̀. Ó ṣe tán, àwọn ìgbà kan wà tí ọkọ̀ tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ rì lójú agbami.​—2 Kọ́r. 11:25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́