A Kò Tí ì Ní Ọ̀pọ̀ Nǹkan Tẹ̀mí Tó Báyìí Rí!
1 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń yán hànhàn fún ọjọ́ náà tí wọn yóò lè sọ pé, “A kò tí ì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tò báyìí rí!” Nínú ọkàn wọn, ọjọ́ kan ń bọ̀ tí wọn yóò ní ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan ti ara, tí yóò lè jẹ́ kí wọ́n ‘farabalẹ̀ pẹ̀sẹ̀, kí wọ́n máa jẹ, kí wọ́n máa mu, kí wọ́n sì máa gbádùn ara wọn.’ (Luku 12:19) Ní ìyàtọ̀, àwá lè sọ nísinsìnyí pé, kò sí ohun kan tí ó dára tí a kò ní, nípa tẹ̀mí. (Orin Da. 34:10) Báwo ni ìyẹn ṣe ṣeé ṣe?
2 Owe 10:22 sọ pé, “ìbùkún Oluwa ní í múni í là, kì í sì í fi làálàá pẹ̀lú rẹ̀.” Àwa tí à ń gbádùn irú ojú rere àtọ̀runwá bẹ́ẹ̀ lè sọ ní tòótọ́ pé, Ọlọrun “ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.” (1 Tim. 6:17) Èyí mú kí a jẹ́ ọlọ́rọ̀ jù lọ ní ayé!
3 Mímọyì Ohun Tí Ọlọrun Ṣe fún Wa: Ìwọ̀nba díẹ̀ nínú wa ló ní ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan ti ara. Síbẹ̀, a jẹ́ ẹni ìbùkún nítorí pé a kì í ṣàníyàn ju bí ó ti yẹ lọ nípa àwọn ohun kòṣeémánìí ojoojúmọ́. Jehofa mọ àwọn nǹkan tí a nílò, ó sì ṣèlérí pé òun yóò pèsè wọn. (Matt. 6:31-33) Ìlérí rẹ̀ fún wa ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí kò ṣeé díyelé ní tòótọ́.
4 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìbùkún tí a ní nípa tẹ̀mí tilẹ̀ ju ìyẹn lọ. Ìwàláàyè wa sinmi lé oúnjẹ tẹ̀mí tí ó ń wá láti ọ̀dọ̀ Jehofa. (Matt. 4:4) Ebi ń pa àwọn tí wọ́n ń gbọ́kàn lé orísun ti ayé láti rí nǹkan ìgbẹ́mìíró nípa tẹ̀mí nígbà tí àwá ń jẹ àjẹyó, tí a sì ń mu àmutẹ́rùn. (Isa. 65:13) ‘Olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà ń jẹ́ kí a rí ìpèsè ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun tí kò lè gbẹ gbà.—Matt. 24:45; Joh. 17:3.
5 Ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé ń mú kí a gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọ́yàyà ti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin onífẹ̀ẹ́ tí ń gbé ní gbogbo apá ilẹ̀ ayé. (Joh. 13:35) Ìjọ àdúgbò jẹ́ ibi àlàáfíà, níbi tí a ti lè rí ìtùnú àti ìtura. Àwọn alàgbà ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn wa, ní ríràn wá lọ́wọ́ láti kojú onírúurú ìṣòro. (Heb. 13:17) Sísún mọ́ àwọn ará wa tímọ́tímọ́ ń yọrí sí ìṣepàṣípààrọ̀ ìṣírí, tí ń fún wa lókun láti máa forí tì í.—Romu 1:11, 12.
6 Ìbùkún ni iṣẹ́ wa pàápàá jẹ́. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ní ń tánni lókun, wọn kì í sì í méso jáde. Nínípìn-ín nínú ìhìn rere náà ń mú ìdùnnú wá fún àwọn ẹlòmíràn, ó sì ń mú ayọ̀ wá fún àwa fúnra wa. (Ìṣe 20:35) Ó ṣeé ṣe fún wa ní tòótọ́ láti rí ohun tí ó dára nínú gbogbo iṣẹ́ takuntakun tí à ń ṣe.—Oniwasu 2:24.
7 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a ní àgbàyanu ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la. (Romu 12:12) À ń fojú sọ́nà fún ayé tuntun òdodo pípé kan, níbi tí a óò máa gbé pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wa nínú ayọ̀ àti àlàáfíà títí láé! Ìrètí yìí jẹ́ ìṣúra tí ó ṣeyebíye ju ohunkóhun tí ayé lè nawọ́ rẹ̀ sí wa lọ.—1 Tim. 6:19.
8 Báwo Ni A Ṣe Lè Fi Ìmọrírì Wa Hàn? A kò lè san ẹ̀san ohun tí Jehofa ti ṣe fún wa padà láé. Kìkì ohun tí a lè ṣe ni láti fi ìmọrírì wa hàn nípa (1) dídúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́ fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ (Efe. 5:20), (2) fífi ìfẹ́ wa hàn nípa jíjẹ́ onígbọràn (1 Joh. 5:3), (3) yíya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́ nípa wíwàásù ìhìn rere náà (Orin Da. 83:18), àti (4) kíkọ́wọ́ ti ìjọ Kristian lẹ́yìn nípa ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tọkàntọkàn wa.—1 Tim. 3:15.
9 A ní ìdí tí ó pọ̀ tó láti jẹ́ ènìyàn tí ó láyọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. (Orin Da. 144:15b) Ǹjẹ́ kí ìwà wa, ìṣesí wa, àti iṣẹ́ ìsìn wa máa fi ìdùnnú tí à ń ní nínú paradise tẹ̀mí wa hàn. A kò tí ì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó báyìí rí!